Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Read the Gospels in 40 Days

Read through the four Gospels--Matthew, Mark, Luke, and John--in 40 days.
Duration: 40 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Johanu 19-20

A dá Jesu lẹ́bi láti kàn mọ àgbélébùú

19 Nítorí náà ni Pilatu mú Jesu, ó sì nà án. (A)Àwọn ọmọ-ogun sì hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí, wọ́n sì fi aṣọ ìgúnwà elése àlùkò wọ̀ ọ́. Wọ́n sì wí pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!” Wọ́n sì fi ọwọ́ wọn gbá a ní ojú.

(B)Pilatu sì tún jáde, ó sì wí fún wọn pé, “Wò ó, mo mú u jáde tọ̀ yín wá, kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé, èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀.” Nítorí náà Jesu jáde wá, ti òun ti adé ẹ̀gún àti aṣọ elése àlùkò. Pilatu sì wí fún wọn pé, Ẹ wò ọkùnrin náà!

Nítorí náà nígbà tí àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn oníṣẹ́ rí i, wọ́n kígbe wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú, kàn án mọ́ àgbélébùú.”

Pilatu wí fún wọn pé, “Ẹ mú un fún ara yín, kí ẹ sì kàn án mọ́ àgbélébùú: nítorí èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.”

(C)Àwọn Júù dá a lóhùn wí pé, “Àwa ní òfin kan, àti gẹ́gẹ́ bí òfin, wa ó yẹ fún un láti kú, nítorí ó gbà pé ọmọ Ọlọ́run ni òun ń ṣe.”

Nítorí náà nígbà tí Pilatu gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀rù túbọ̀ bà á. Ó sì tún wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́ lọ, ó sì wí fún Jesu pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Ṣùgbọ́n Jesu kò dá a lóhùn. 10 Nítorí náà, Pilatu wí fún un pé, “Èmi ni ìwọ kò fọhùn sí? Ìwọ kò mọ̀ pé, èmi ní agbára láti dá ọ sílẹ̀, èmi sì ní agbára láti kàn ọ́ mọ́ àgbélébùú?”

11 (D)Jesu dá a lóhùn pé, “Ìwọ kì bá tí ní agbára kan lórí mi, bí kò ṣe pé a fi í fún ọ láti òkè wá: nítorí náà ẹni tí ó fi mí lé ọ lọ́wọ́ ni ó ní ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀jù.”

12 (E)Nítorí èyí, Pilatu ń wá ọ̀nà láti dá a sílẹ̀: ṣùgbọ́n àwọn Júù kígbe, wí pé, “Bí ìwọ bá dá ọkùnrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Kesari: ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ara rẹ̀ ní ọba, ó sọ̀rọ̀-òdì sí Kesari.”

13 Nítorí náà nígbà tí Pilatu gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Jesu jáde wá, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́ ní ibi tí a ń pè ní Òkúta-títẹ́, ṣùgbọ́n ní èdè Heberu, Gabata. 14 (F)Ó jẹ́ ìpalẹ̀mọ́ àjọ ìrékọjá, ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí ẹ̀kẹfà:

Ó sì wí fún àwọn Júù pé, “Ẹ wo ọba yín!”

15 Nítorí náà wọ́n kígbe wí pé, “Mú un kúrò, mú un kúrò. Kàn án mọ́ àgbélébùú.”

Pilatu wí fún wọn pé, “Èmi yóò ha kan ọba yín mọ́ àgbélébùú bí?”

Àwọn olórí àlùfáà dáhùn wí pé, “Àwa kò ní ọba bí kò ṣe Kesari.”

16 Nítorí náà ni Pilatu fà á lé wọn lọ́wọ́ láti kàn án mọ́ àgbélébùú.

Wọ́n kan Jesu mọ́ àgbélébùú

Àwọn ológun gba Jesu lọ́wọ́ Pilatu. 17 (G)Nítorí náà, wọ́n mú Jesu, ó sì jáde lọ, ó ru àgbélébùú fúnrarẹ̀ sí ibi tí à ń pè ní ibi agbárí, ní èdè Heberu tí à ń pè ní Gọlgọta: 18 Níbi tí wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn méjì mìíràn pẹ̀lú rẹ̀, níhà ìhín àti níhà kejì, Jesu sì wà láàrín.

19 Pilatu sì kọ ìwé kan pẹ̀lú, ó sì fi lé e lórí àgbélébùú náà. Ohun tí a sì kọ ni,

jesu ti nasareti ọba àwọn júù.

20 Nítorí náà, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ni ó ka ìwé àkọlé yìí: nítorí ibi tí a gbé kan Jesu mọ́ àgbélébùú súnmọ́ etí ìlú: a sì kọ ọ́ ní èdè Heberu àti Latin, àti ti Giriki. 21 Nítorí náà àwọn olórí àlùfáà àwọn Júù wí fún Pilatu pé, “Má ṣe kọ, ‘ọba àwọn Júù;’ ṣùgbọ́n pé ọkùnrin yìí wí pé, èmi ni ọba àwọn Júù.”

22 Pilatu dáhùn pé, ohun tí mo ti kọ, mo ti kọ ọ́.

23 Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun, nígbà tí wọ́n kan Jesu mọ́ àgbélébùú tán, wọ́n mú aṣọ rẹ̀, wọ́n sì pín wọn sí ipa mẹ́rin, apá kan fún ọmọ-ogun kọ̀ọ̀kan, àti ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀: ṣùgbọ́n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà kò ní ojúràn-án, wọ́n hun ún láti òkè títí jálẹ̀.

24 (H)Nítorí náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ẹ má jẹ́ kí a fà á ya, ṣùgbọ́n kí a ṣẹ́ gègé nítorí rẹ̀.”

Ti ẹni tí yóò jẹ́: kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ, tí ó wí pé,

“Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn,
    wọ́n sì ṣẹ́ gègé fún aṣọ ìlekè mi.”

Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọmọ-ogun ṣe.

25 (I)Ìyá Jesu àti arábìnrin ìyá rẹ̀ Maria aya Kilopa, àti Maria Magdalene sì dúró níbi àgbélébùú, 26 (J)Nígbà tí Jesu rí ìyá rẹ̀ àti ọmọ-ẹ̀yìn náà dúró, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obìnrin, wo ọmọ rẹ!” 27 Lẹ́yìn náà ni ó sì wí fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, “Wo ìyá rẹ!” Láti wákàtí náà lọ ni ọmọ-ẹ̀yìn náà sì ti mú un lọ sí ilé ara rẹ̀.

Ikú Jesu

28 (K)Lẹ́yìn èyí, bí Jesu ti mọ̀ pé, a ti parí ohun gbogbo tán, kí ìwé mímọ́ bà á lè ṣẹ, ó wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ mí.” 29 Ohun èlò kan tí ó kún fún ọtí kíkan wà níbẹ̀, wọ́n tẹ kànìnkànìn tí ó kún fún ọtí kíkan bọ inú rẹ̀, wọ́n sì fi lé orí igi hísópù, wọ́n sì nà án sí i lẹ́nu. 30 Nígbà tí Jesu sì ti gba ọtí kíkan náà, ó wí pé, “Ó parí!” Ó sì tẹ orí rẹ̀ ba, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.

31 (L)Nítorí ó jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́, kí òkú wọn má ba à wà lórí àgbélébùú ní ọjọ́ ìsinmi, (nítorí ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ ìsinmi náà) nítorí náà, àwọn Júù bẹ Pilatu pé kí a ṣẹ́ egungun itan wọn, kí a sì gbé wọn kúrò. 32 Nítorí náà, àwọn ọmọ-ogun wá, wọ́n sì ṣẹ́ egungun itan ti èkínní, àti ti èkejì, tí a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀. 33 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, tí wọ́n sì rí i pé ó ti kú, wọn kò ṣẹ́ egungun itan rẹ̀: 34 (M)Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ogun náà fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́, lójúkan náà, ẹ̀jẹ̀ àti omi sì tú jáde. 35 (N)Ẹni tí ó rí sì jẹ́rìí, òtítọ́ sì ni ẹ̀rí rẹ̀: ó sì mọ̀ pé òtítọ́ ni òun sọ, kí ẹ̀yin ba à lè gbàgbọ́. 36 (O)Nǹkan wọ̀nyí ṣe, kí ìwé mímọ́ ba à lè ṣẹ, tí ó wí pé, “A kì yóò fọ́ egungun rẹ̀.” 37 (P)Ìwé mímọ́ mìíràn pẹ̀lú sì wí pé, “Wọn ó máa wo ẹni tí a gún lọ́kọ̀.”

Ìsìnkú Jesu

38 (Q)Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ní Josẹfu ará Arimatea, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, ní ìkọ̀kọ̀, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, o bẹ Pilatu kí òun lè gbé òkú Jesu kúrò: Pilatu sì fún un ní àṣẹ. Nígbà náà ni ó wá, ó sì gbé òkú Jesu lọ. 39 (R)Nikodemu pẹ̀lú sì wá, ẹni tí ó tọ Jesu wá lóru lákọ̀ọ́kọ́, ó sì mú àdàpọ̀ òjìá àti aloe wá, ó tó ìwọ̀n ọgọ́ọ̀rún lítà. 40 (S)Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé òkú Jesu, wọ́n sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dì í pẹ̀lú tùràrí, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn Júù ti rí ní ìsìnkú wọn. 41 Àgbàlá kan sì wà níbi tí a gbé kàn án mọ́ àgbélébùú; ibojì tuntun kan sì wà nínú àgbàlá náà, nínú èyí tí a kò tí ì tẹ́ ẹnìkan sí rí. 42 Ǹjẹ́ níbẹ̀ ni wọ́n sì tẹ́ Jesu sí, nítorí ìpalẹ̀mọ́ àwọn Júù; àti nítorí ibojì náà wà nítòsí.

Òfo ibojì

20 (T)Ní kùtùkùtù ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, nígbà tí ilẹ̀ kò tí ì mọ́, ni Maria Magdalene wá sí ibojì, ó sì rí i pé, a ti gbé òkúta kúrò lẹ́nu ibojì. Nítorí náà, ó sáré, ó sì tọ Simoni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn wá, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ó sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì, àwa kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.”

(U)Nígbà náà ni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà jáde, wọ́n sì wá sí ibojì. Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ sáré: èyí ọmọ-ẹ̀yìn náà sì sáré ya Peteru, ó sì kọ́kọ́ dé ibojì. Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti wo inú rẹ̀, ó rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀; ṣùgbọ́n òun kò wọ inú rẹ̀. Nígbà náà ni Simoni Peteru tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ dé, ó sì wọ inú ibojì, ó sì rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀. Àti pé, gèlè tí ó wà níbi orí rẹ̀ kò sì wà pẹ̀lú aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, ṣùgbọ́n ó ká jọ ní ibìkan fúnrarẹ̀. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà, ẹni tí ó kọ́ dé ibojì wọ inú rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì rí i, ó sì gbàgbọ́. (V)(Nítorí tí wọn kò sá à tí mọ ìwé mímọ́ pé, Jesu ní láti jíǹde kúrò nínú òkú.) 10 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sì tún padà lọ sí ilé wọn.

Jesu fi ara han Maria Magdalene

11 Ṣùgbọ́n Maria dúró létí ibojì lóde, ó ń sọkún: bí ó ti ń sọkún, bẹ́ẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀, ó sì wo inú ibojì. 12 (W)Ó sì kíyèsi àwọn angẹli méjì aláṣọ funfun, wọ́n jókòó, ọ̀kan níhà orí àti ọ̀kan níhà ẹsẹ̀, níbi tí òkú Jesu gbé ti sùn sí.

13 (X)Wọ́n sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún?”

Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí tí wọ́n ti gbé Olúwa mi, èmi kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.” 14 (Y)Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó yípadà, ó sì rí Jesu dúró, kò sì mọ̀ pé Jesu ni.

15 Jesu wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún? Ta ni ìwọ ń wá?”

Òun ṣe bí olùṣọ́gbà ní í ṣe, ó wí fún un pé, “Alàgbà, bí ìwọ bá ti gbé e kúrò níhìn-ín yìí, sọ ibi tí ìwọ tẹ́ ẹ sí fún mi, èmi yóò sì gbé e kúrò.”

16 Jesu wí fún un pé, “Maria!”

Ó sì yípadà, ó wí fún un ní èdè Heberu pé, “Rabboni!” (èyí tí ó túmọ̀ sí “Olùkọ́”).

17 (Z)Jesu wí fún un pé, “Má ṣe fi ọwọ́ kàn mí; nítorí tí èmi kò tí ì gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba mi: ṣùgbọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin mi, sì wí fún wọn pé, ‘Èmi ń gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba mi, àti Baba yín: àti sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi, àti Ọlọ́run yín.’ ”

18 (AA)Maria Magdalene wá, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, “Òun ti rí Olúwa!” Àti pé, ó sì ti fi nǹkan wọ̀nyí fún òun.

Jesu fi ara han àwọn Aposteli

19 (AB)Ní ọjọ́ kan náà, lọ́jọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀ nígbà tí alẹ́ lẹ́, tí a sì ti ìlẹ̀kùn ibi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbé péjọ, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni Jesu dé, ó dúró láàrín, ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín.” 20 Nígbà tí ó sì ti wí bẹ́ẹ̀ tán, ó fi ọwọ́ àti ìhà rẹ̀ hàn wọ́n. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yọ̀, nígbà tí wọ́n rí Olúwa.

21 (AC)Nítorí náà, Jesu sì tún wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín: gẹ́gẹ́ bí Baba ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán yín.” 22 (AD)Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó mí sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gba Ẹ̀mí mímọ́! 23 (AE)Ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá fi jì, a fi jì wọ́n; ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá dádúró, a dá wọn dúró.”

Jesu fi ara han Tomasi

24 (AF)Ṣùgbọ́n Tomasi, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, tí a ń pè ní Didimu, kò wà pẹ̀lú wọn nígbà tí Jesu dé. 25 Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù wí fún un pé, “Àwa ti rí Olúwa!”

Ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, “Bí kò ṣe pé mo bá rí àpá ìṣó ni ọwọ́ rẹ̀ kí èmi sì fi ìka mi sí àpá ìṣó náà, kí èmi sì fi ọwọ́ mi sí ìhà rẹ̀, èmi kì yóò gbàgbọ́!”

26 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́jọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì tún wà nínú ilé, àti Tomasi pẹ̀lú wọn: nígbà tí a sì ti ti ìlẹ̀kùn, Jesu dé, ó sì dúró láàrín, ó wí pé, “Àlàáfíà fún yín.” 27 (AG)Nígbà náà ni ó wí fún Tomasi pé, “Mú ìka rẹ wá níhìn-ín yìí, kí o sì wo ọwọ́ mi; sì mú ọwọ́ rẹ wá níhìn-ín, kí o sì fi sí ìhà mi: kí ìwọ má ṣe jẹ́ aláìgbàgbọ́ mọ́, ṣùgbọ́n jẹ́ onígbàgbọ́.”

28 Tomasi dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Olúwa mi àti Ọlọ́run mi!”

29 (AH)Jesu wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ rí mi ni ìwọ ṣe gbàgbọ́: alábùkún fún ni àwọn tí kò rí mi, tí wọ́n sì gbàgbọ́!”

30 (AI)Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ààmì mìíràn ni Jesu ṣe níwájú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, tí a kò kọ sínú ìwé yìí: 31 (AJ)Ṣùgbọ́n wọ̀nyí ni a kọ, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé Jesu ní í ṣe Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run, àti pé nípa gbígbàgbọ́, kí ẹ̀yin lè ní ìyè ní orúkọ rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.