Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

The Daily Audio Bible

This reading plan is provided by Brian Hardin from Daily Audio Bible.
Duration: 731 days

Today's audio is from the NLT. Switch to the NLT to read along with the audio.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 6-7

Ìpè sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ Isaiah

Ní ọdún tí ọba Ussiah kú, mo rí Olúwa tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga tí a gbé sókè, ìṣẹ́tí aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili. Àwọn Serafu wà ní òkè rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà, wọ́n fi ìyẹ́ méjì bo ojú wọn, wọ́n fi méjì bo ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sí ń fi méjì fò. (A)Wọ́n sì ń kọ sí ara wọn wí pé:

“Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”

(B)Nípa ìró ohùn un wọn, òpó ìlẹ̀kùn àti gbogbo ògiri ilé náà sì mì tìtì, gbogbo inú tẹmpili sì kún fún èéfín.

Mo kígbe pé “Ègbé ni fún mi! Mo ti gbé!” Nítorí mo jẹ́ ènìyàn aláìmọ́ ètè, mo sì ń gbé láàrín àwọn ènìyàn aláìmọ́ ètè, ojú mi sì ti rí ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ.

Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn Serafu wọ̀nyí fò wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹ̀yín iná ní ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó ti fi ẹ̀mú mú ní orí pẹpẹ. Èyí ni ó fi kàn mí ní ẹnu tí ó sì wí pé, “Wò ó, èyí ti kan ètè rẹ; a ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù.”

Nígbà náà ni mo sì gbọ́ ohùn Olúwa wí pé, “Ta ni èmi yóò rán? Ta ni yóò sì lọ fún wa?”

Nígbà náà ni èmi sì wí pé, “Èmi nìyí, rán mi!”

(C)Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn yìí lọ kí o sì wí fún wọn pé:

“ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín;
    ní rí rí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’
10 Mú kí àyà àwọn ènìyàn wọ̀nyí yigbì,
    mú kí etí wọn kí ó wúwo,
    kí o sì dìwọ́n ní ojú.
Kí wọn kí ó má ba fi ojú wọn ríran,
    kí wọn kí ó má ba fi etí wọn gbọ́rọ̀,
kí òye kí ó má ba yé ọkàn wọn,
    kí wọn kí ó má ba yípadà
    kí a má ba mú wọn ní ara dá.”

11 Nígbà náà ni mo wí pé, “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó Olúwa?”

Òun sì dáhùn pé:

“Títí àwọn ìlú ńlá yóò fi dahoro,
    láìsí olùgbé nínú rẹ̀ mọ́,
títí tí àwọn ilé yóò fi wà láìsí ènìyàn,
    títí tí ilẹ̀ yóò fi dahoro pátápátá.
12 Títí tí Olúwa yóò fi rán gbogbo wọn jìnnà réré
    tí ilẹ̀ náà sì di ìkọ̀sílẹ̀ pátápátá.
13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdámẹ́wàá ṣẹ́kù lórí ilẹ̀ náà,
    yóò sì tún pàpà padà di rírun.
Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí igi tẹrẹbinti àti igi óákù,
    ti í fi kùkùté sílẹ̀ nígbà tí a bá gé wọn lulẹ̀,
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni irúgbìn mímọ́ náà yóò di kùkùté ní ilẹ̀ náà.”

Ààmì ti Emmanueli

Nígbà tí Ahasi ọmọ Jotamu ọmọ Ussiah jẹ́ ọba Juda, ọba Resini ti Aramu àti Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli gòkè wá láti bá Jerusalẹmu jà, ṣùgbọ́n wọn kò sì le è borí i rẹ̀.

Báyìí, a sọ fún ilé Dafidi pé, “Aramu mà ti lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Efraimu”; fún ìdí èyí, ọkàn Ahasi àti àwọn ènìyàn rẹ̀ wárìrì gẹ́gẹ́ bí igi oko ṣe ń wárìrì níwájú afẹ́fẹ́.

Lẹ́yìn èyí, Olúwa sọ fún Isaiah pé, “Jáde, ìwọ àti ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ Ṣeari-Jaṣubu láti pàdé Ahasi ní ìpẹ̀kun ìṣàn omi ti adágún òkè, ní òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí pápá Alágbàfọ̀. Sọ fún un, ‘Ṣọ́ra à rẹ, fi ọkàn balẹ̀, kí o má ṣe bẹ̀rù. Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí kùkùté igi ìdáná méjèèjì yìí, nítorí ìbínú gbígbóná Resini àti Aramu àti ti ọmọ Remaliah. Aramu, Efraimu àti Remaliah ti dìtẹ̀ ìparun rẹ, wọ́n wí pé, “Jẹ́ kí a kọlu Juda; jẹ́ kí a fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kí a sì pín in láàrín ara wa, kí a sì fi ọmọ Tabeli jẹ ọba lórí i rẹ̀.” Síbẹ̀ èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Èyí kò ní wáyé
    èyí kò le ṣẹlẹ̀,
nítorí Damasku ni orí Aramu,
    orí Damasku sì ni Resini.
Láàrín ọdún márùnlélọ́gọ́ta
    Efraimu yóò ti fọ́ tí kì yóò le jẹ́ ènìyàn mọ́.
Orí Efraimu sì ni Samaria,
    orí Samaria sì ni ọmọ Remaliah.
Bí ẹ̀yin kí yóò bá gbàgbọ́,
    lóòtítọ́, a kì yóò fi ìdí yín múlẹ̀.’ ”

10 Bákan náà Olúwa tún bá Ahasi sọ̀rọ̀, 11 “Béèrè fún ààmì lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, bóyá ní ọ̀gbun tí ó jì jùlọ tàbí àwọn òkè tí ó ga jùlọ.”

12 Ṣùgbọ́n Ahasi sọ pé, “Èmi kì yóò béèrè; Èmi kò ní dán Olúwa wò.”

13 Lẹ́yìn náà Isaiah sọ pé, “Gbọ́ ní ìsinsin yìí, ìwọ ilé Dafidi, kò ha tọ́ láti tán ènìyàn ní sùúrù, ìwọ yóò ha tan Ọlọ́run ní sùúrù bí? 14 (D)Nítorí náà, Olúwa fúnra ara rẹ̀ ni yóò fún ọ ní ààmì kan. Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli. 15 Òun yóò jẹ wàrà àti oyin nígbà tí ó bá ní ìmọ̀ tó láti kọ ẹ̀bi àti láti yan rere. 16 Ṣùgbọ́n kí ọ̀dọ́mọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń kọ ẹ̀bi àti láti yan rere, ilẹ̀ àwọn ọba méjèèjì tí ń bà ọ́ lẹ́rù wọ̀nyí yóò ti di ahoro. 17 Olúwa yóò mú àsìkò mìíràn wá fún ọ àti àwọn ènìyàn rẹ àti lórí ilé baba rẹ irú èyí tí kò sí láti ìgbà tí Efraimu ti yà kúrò ní Juda, yóò sì mú ọba Asiria wá.”

18 Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò súfèé pe àwọn eṣinṣin láti àwọn odò tó jìnnà ní Ejibiti wá, àti fún àwọn oyin láti ilẹ̀ Asiria. 19 Gbogbo wọn yóò sì wá dó sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè àti pàlàpálá òkúta, lára koríko ẹ̀gún àti gbogbo ibi ihò omi. 20 Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò lo abẹ fífẹ́lẹ́ tí a yá láti ìkọjá odò Eufurate, ọba Asiria, láti fá irun orí àti ti àwọn ẹsẹ̀ ẹ yín, àti láti mú irùngbọ̀n yín kúrò pẹ̀lú. 21 Ní ọjọ́ náà, ọkùnrin kan yóò máa sin ọ̀dọ́ abo màlúù kan àti ewúrẹ́ méjì. 22 Àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà tí wọn yóò máa fún un, yóò ní wàràǹkàṣì láti jẹ. Gbogbo àwọn tí ó bá kù ní ilẹ̀ náà yóò jẹ wàràǹkàṣì àti oyin. 23 Ní ọjọ́ náà, ni gbogbo ibi tí àjàrà tí ó tó ẹgbẹ̀rún ṣékélì fàdákà, ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n nìkan ni yóò wà níbẹ̀. 24 Àwọn ènìyàn yóò máa lọ síbẹ̀ pẹ̀lú ọrun àti ọfà nítorí pé ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n ni yóò bo gbogbo ilẹ̀ náà. 25 Àti ní orí àwọn òkè kéékèèkéé tí a ti ń fi ọkọ́ ro nígbà kan rí, ẹ kò ní lọ síbẹ̀ mọ́ nítorí ìbẹ̀rù ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n, wọn yóò di ibi tí a ń da màlúù lọ, àti ibi ìtẹ̀mọ́lẹ̀ fún àwọn àgùntàn kéékèèkéé.

2 Kọrinti 11:16-33

Paulu ṣògo nínú ìjìyà rẹ̀

16 Mo sì tún wí pé, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rò pé òmùgọ̀ ni mí; ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ẹ gbà mí bí òmùgọ̀ kí èmi lè gbé ara mi ga díẹ̀. 17 (A)Ohun tí èmi ń sọ, èmi kò sọ ọ́ nípa ti Olúwa, ṣùgbọ́n bí òmùgọ̀ nínú ìgbẹ́kẹ̀lé ìṣògo yìí. 18 Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ni ó ń ṣògo nípa ti ara, èmi ó ṣògo pẹ̀lú. 19 (B)Nítorí ẹ̀yin fi inú dídùn gba àwọn òmùgọ̀ nígbà tí ẹ̀yin tìkára yín jẹ́ ọlọ́gbọ́n. 20 Nítorí ẹ̀yin faradà á bí ẹnìkan bá sọ yín dí òǹdè, bí ẹnìkan bá jẹ́ yín run, bí ẹnìkan bá gbà lọ́wọ́ yín, bí ẹnìkan bá gbé ara rẹ̀ ga, bí ẹnìkan bá gbá yín lójú. 21 Èmi ń wí lọ́nà ẹ̀gàn, bí ẹni pé àwa jẹ́ aláìlera!

Ṣùgbọ́n nínú ohunkóhun tí ẹnìkan ti ní ìgboyà, èmi ń sọ̀rọ̀ bí òmùgọ̀, èmi ní ìgboyà pẹ̀lú. 22 Heberu ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Israẹli ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Irú-ọmọ Abrahamu ní òun bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. 23 (C)Ìránṣẹ́ Kristi ni wọ́n bí? Èmi ń sọ bí òmùgọ̀, mo ta wọ́n yọ; ní ti làálàá lọ́pọ̀lọpọ̀, ní ti pàṣán, mo rékọjá, ní ti túbú nígbàkúgbà, ní ti fífẹ́rẹ kú nígbà púpọ̀. 24 (D)Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín ẹyọ kan lọ́wọ́ àwọn Júù. 25 (E)Nígbà mẹ́ta ni a fi ọ̀gọ̀ lù mí, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni a sọ mí ní òkúta, ẹ̀ẹ̀mẹta ni ọkọ̀ ojú omi mi rì, ọ̀sán kan àti òru kan ni mo wà nínú ibú. 26 (F)Ní ìrìnàjò nígbàkúgbà, nínú ewu omi, nínú ewu àwọn ọlọ́ṣà, nínú ewu àwọn ará ìlú mi, nínú ewu àwọn aláìkọlà, nínú ewu ni ìlú, nínú ewu ní aginjù, nínú ewu lójú Òkun, nínú ewu láàrín àwọn èké arákùnrin. 27 (G)Nínú làálàá àti ìrora, nínú ìṣọ́ òru nígbàkúgbà, nínú ebi àti òǹgbẹ, nínú àwẹ̀ nígbàkúgbà, nínú òtútù àti ìhòhò. 28 Pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí tí ó jẹ́ tí òde, ọ̀pọ̀ ni èyí tí ń wọn n dúró tì mí lójoojúmọ́, àní àníyàn fún gbogbo ìjọ. 29 (H)Ta ni ó ṣe àìlera, tí èmi kò ṣe àìlera? Tàbí a mú kọsẹ̀, tí ara mi kò gbiná?

30 Bí èmi yóò bá ṣògo, èmi ó kúkú máa ṣògo nípa àwọn nǹkan tí ó jẹ́ ti àìlera mi. 31 Ọlọ́run àti Baba Olúwa wá Jesu Kristi, ẹni tí ó jẹ́ olùbùkún jùlọ láéláé mọ̀ pé èmi kò ṣèké. 32 (I)Ní Damasku, baálẹ̀ tí ó wà lábẹ́ ọba Areta fi ẹgbẹ́ ogun ká ìlú àwọn ará Damasku mọ́, ó ń fẹ́ láti mú mi bí arúfin: 33 Láti ojú fèrèsé nínú agbọ̀n ni a sì ti sọ̀ mí kalẹ̀ lẹ́yìn odi, tí mo sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

Saamu 54

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí àwọn ará Sifi lọ sọ fún Saulu pé, “Dafidi sá pamọ́ sọ́dọ̀ wa”.

54 Gbà mí, Ọlọ́run nípa orúkọ rẹ:
    dá mi láre nípa agbára rẹ.
Gbọ́ àdúrà mi, Ọlọ́run;
    fi etí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

Àwọn agbéraga àlejò dìde sí mí.
    Àwọn aninilára sì ń wá mi láti pa,
àwọn ẹni tí kò ka Ọlọ́run sí ní ojú wọn.

Kíyèsi i Ọlọ́run ni Olùrànlọ́wọ́ mi;
    Olúwa ní ẹni tí ó mú mi dúró,
    pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ.

Jẹ́ kí ibi padà sẹ́yìn sí àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi;
    pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ.

Èmí yóò rú ẹbọ àtinúwá sí ọ,
    èmi yóò yin orúkọ rẹ, Olúwa,
    nítorí tí ó dára.
Nítorí tí ó yọ mí kúrò nínú ibi gbogbo
    ojú mi ti wo ìṣẹ́gun lórí ọ̀tá mi.

Òwe 23:1-3

Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ohun àdídùn

23 Nígbà tí ìwọ bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun,
    kíyèsi ohun tí ó wà níwájú rẹ gidigidi.
Ìwọ a sì fi ọ̀bẹ lé ara rẹ ní ọ̀fun,
    bí ìwọ bá jẹ́ òkúndùn ènìyàn.
Má ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀:
    nítorí pé oúnjẹ ẹ̀tàn ni.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.