Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Onidajọ 3-5

Àwọn wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa fi sílẹ̀ láti dán àwọn ìran tuntun ní Israẹli wò, àwọn ìran tí kò ì tí ì ní ìrírí ogun àwọn ará Kenaani. (Ó ṣe èyí láti fi kọ́ àwọn ìran Israẹli tí kò rí ogun rí níbí a ti ṣe ń jagun): Àwọn ìjòyè ìlú Filistini márààrún, gbogbo àwọn ará Kenaani, àwọn ará Sidoni, àti àwọn ará Hifi tí ń gbé ní àwọn òkè Lebanoni bẹ̀rẹ̀ láti òkè Baali-Hermoni títí dé Lebo-Hamati. A fi àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ láti dán àwọn Israẹli wò bóyá wọn yóò gbọ́rọ̀ sí àwọn òfin Olúwa, èyí tí ó ti fi fún àwọn baba wọn láti ipasẹ̀ Mose.

Àwọn ọmọ Israẹli gbé láàrín àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti àwọn ará Amori, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi. Dípò kí wọ́n run àwọn ènìyàn wọ̀nyí, Israẹli ń fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọbìnrin Israẹli fún àwọn ará ilẹ̀ náà ní aya, wọ́n sì ń sin àwọn òrìṣà wọn.

Otnieli

Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe èyí tí ó burú níwájú Olúwa, wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń sin Baali àti Aṣerah. Ìbínú Olúwa sì ru sí Israẹli tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ kí Kuṣani-Riṣataimu ọba Aramu-Naharaimu (ìlà-oòrùn Siria) bá wọn jà kí ó sì ṣẹ́gun wọn, Israẹli sì ṣe ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́jọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí Israẹli kígbe sí Olúwa, Òun gbé olùgbàlà kan dìde fún wọn, ẹni náà ni Otnieli ọmọ Kenasi àbúrò Kalebu tí ó jẹ́ ọkùnrin, ẹni tí ó gbà wọ́n sílẹ̀. 10 Ẹ̀mí Olúwa bà lé e, òun sì ṣe ìdájọ́ Israẹli, ó sì síwájú wọn lọ sí ogun. Olúwa sì fi Kuṣani-Riṣataimu ọba Aramu lé Otnieli lọ́wọ́, ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ sì borí Kuṣani-Riṣataimu. 11 Ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún títí tí Otnieli ọmọ Kenasi sì kú.

Ehudu

12 Àwọn ọmọ Israẹli sì tún padà sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n sì ṣe èyí tí ó burú ní iwájú Olúwa, fún ìdí iṣẹ́ búburú yìí, Olúwa fún Egloni, ọba àwọn Moabu ní agbára ní orí Israẹli. 13 Pẹ̀lú ìfi ọwọ́ ṣowọ́pọ̀ ogun àwọn Ammoni àti àwọn ọmọ-ogun Amaleki ní Egloni gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì gba ìlú Ọ̀pẹ (Jeriko). 14 Àwọn ọmọ Israẹli sì sin Egloni ọba Moabu fún ọdún méjì-dínlógún.

15 Ṣùgbọ́n nígbà tí Israẹli tún ké pe Olúwa, Olúwa rán olùgbàlà kan sí wọn, Ehudu ẹni tí ń lo ọwọ́ òsì, ọmọ Gera ti ẹ̀yà Benjamini. Àwọn ọmọ Israẹli fi ẹ̀bùn rán sí Egloni ọba Moabu. 16 Ehudu sì rọ idà kan olójú méjì, ìgbọ̀nwọ́ kan ní gígùn; òun sì sán an ní abẹ́ aṣọ rẹ̀ ní itan rẹ̀ ọ̀tún. 17 Ó sì mú ọrẹ náà wá fún Egloni ọba Moabu, Egloni ẹni tí ó sanra púpọ̀. 18 Lẹ́yìn tí Ehudu ti fi ẹ̀bùn náà fún ọba tan, ó rán àwọn tí ó kó ẹrú náà wá lọ sí ọ̀nà wọn. 19 Ṣùgbọ́n nígbà tí òun fúnrarẹ̀ dé ibi ère fínfín tí ó wà létí Gilgali, ó padà sí Egloni, ó sì wí pé, “Ọba, mo ní ọ̀rọ̀ àṣírí láti bá ọ sọ.”

Ọba sì wí pé “Ẹ dákẹ́!” Gbogbo àwọn tí ń ṣọ sì jáde síta kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀.

20 Ehudu lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ níbi tí ó ti jókòó ní iyàrá ìtura rẹ̀, Ehudu sì wí fún un pé: “Mo ní ọ̀rọ̀ kan fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Bí ọba sì ti dìde ní orí ìtẹ́ rẹ̀, 21 Ehudu fi ọwọ́ òsì rẹ̀ yọ idà láti ibi itan ọ̀tún rẹ̀ ó sì fi gún ọba nínú ikùn rẹ̀. 22 Àti idà àti èèkù rẹ̀ sì wọlé ó sì yọ ní ẹ̀yìn rẹ̀. Ehudu kò yọ idà náà, ọ̀rá sì bo idà náà. 23 Ehudu ti àwọn ìlẹ̀kùn ní àtì-sínú òun sì bá yàrá òkè jáde, ó sì sálọ.

24 Lẹ́yìn tí ó ti lọ àwọn ìránṣẹ́ ọba dé, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ìlẹ̀kùn yàrá òkè ní títì, wọ́n rò pé, “Bóyá ó wà ní ilé ìyàgbẹ́ ní yàrá nínú ilé.” 25 Nígbà tí wọ́n dúró dé ibi pé ó jẹ́ ìyanu fún wọn, wọ́n mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn. Níbẹ̀ ni wọ́n ti rí Olúwa wọn tí ó ti ṣubú, ó sì ti kú.

26 Nígbà tí wọ́n dúró tí wọn sì ń retí, Ehudu ti sálọ. Ó ti gba ibi tí wọ́n ti ń gbẹ́ òkúta lére, ó sì sálọ sí Seira. 27 Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó fọn ìpè ní orí òkè Efraimu, àwọn ọmọ Israẹli sì ba sọ̀kalẹ̀ lọ láti òkè náà wá, òun sì wà níwájú wọn.

28 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí Olúwa ti fi Moabu ọ̀tá yín lé yín lọ́wọ́.” Wọ́n sì tẹ̀lé e, wọ́n sì gba ìwọdò Jordani tí ó lọ sí ilẹ̀ Moabu, wọn ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá. 29 Ní báyìí, wọ́n ti pa tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin ará Moabu tí wọ́n jẹ́ alágbára àti onígboyà ènìyàn, kò sí ènìyàn tí ó sálà. 30 Ní ọjọ́ náà ni Israẹli ṣẹ́gun àwọn ará Moabu, ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ọgọ́rin ọdún.

Ṣamgari

31 Lẹ́yìn Ehudu, ni Ṣamgari ọmọ Anati ẹni tí ó pa ọgọ́rùn-ún mẹ́fà Filistini pẹ̀lú ọ̀pá tí a fi ń da akọ màlúù, òun pẹ̀lú sì gba Israẹli kúrò nínú ìpọ́njú.

Debora

Lẹ́yìn ikú Ehudu, àwọn ènìyàn Israẹli sì tún ṣẹ̀, wọ́n ṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa. Nítorí náà Olúwa jẹ́ kí Jabini, ọba àwọn Kenaani, ẹni tí ó jẹ ọba ní Hasori, ṣẹ́gun wọn. Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Sisera ẹni tí ń gbé Haroseti-Hagoyimu. Nítorí tí ó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) kẹ̀kẹ́ ogun irin, ó sì ń pọ́n Israẹli lójú gidigidi fún ogún ọdún, Israẹli ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́.

Debora, wòlíì obìnrin, aya Lapidoti ni olórí àti aṣíwájú àwọn ará Israẹli ní àsìkò náà. Òun a máa jókòó ṣe ìdájọ́ ní abẹ́ igi ọ̀pẹ tí a sọ orúkọ rẹ̀ ní ọ̀pẹ Debora láàrín Rama àti Beteli ní ilẹ̀ òkè Efraimu, àwọn ará Israẹli a sì máa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti yanjú èdè-àìyedè tí wọ́n bá ní sí ara wọn, tàbí láti gbọ́ ohùn Olúwa láti ẹnu rẹ̀. Ní ọjọ́ kan, ó ránṣẹ́ pe Baraki ọmọ Abinoamu, ẹni tí ń gbé ní Kedeṣi ní ilẹ̀ Naftali, ó sì wí fún un pé, “Olúwa, Ọlọ́run Israẹli pa á ní àṣẹ fún un pé: ‘Kí ó kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àwọn akọni ọkùnrin jọ láti ẹ̀yà Naftali àti ẹ̀yà Sebuluni bí ẹgbẹ́ ogun, kí o sì síwájú wọn lọ sí òkè Tabori. Èmi yóò sì fa Sisera olórí ogun Jabini, pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ àti àwọn ogun rẹ, sí odò Kiṣoni èmi yóò sì fi lé ọ lọ́wọ́ ìwọ yóò sì ṣẹ́gun wọn níbẹ̀.’ ”

Baraki sì dá a lóhùn pé, “Èmi yóò lọ tí ìwọ ó bá bá mi lọ, ṣùgbọ́n tí ìwọ kì yóò bá bá mi lọ, èmi kì yóò lọ.”

Debora dá a lóhùn pé, “ó dára, èmi yóò bá ọ lọ. Ṣùgbọ́n ọlá ìṣẹ́gun tí o ń lọ yìí kò ní jẹ́ tìrẹ, nítorí Olúwa yóò fi Sisera lé obìnrin lọ́wọ́” Báyìí Debora bá Baraki lọ sí Kedeṣi. 10 Nígbà tí Baraki pe ẹ̀yà Sebuluni àti ẹ̀yà Naftali sí Kedeṣi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá akíkanjú ọkùnrin ogun tẹ̀lé e, Debora pẹ̀lú bá wọn lọ.

11 Ǹjẹ́ Heberi ọmọ Keni, ti ya ara rẹ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Keni, àní àwọn ọmọ Hobabu, àna Mose, ó sì pa àgọ́ rẹ̀ títí dé ibi igi óákù Saananimu, tí ó wà ni agbègbè Kedeṣi.

12 Nígbà tí a sọ fún Sisera pé Baraki ọmọ Abinoamu ti kó ogun jọ sí òkè Tabori, 13 Sisera kó gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun irin rẹ̀ tí ṣe ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀run (900) àti gbogbo àwọn ènìyàn (ọmọ-ogun) tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, láti Haroseti tí àwọn orílẹ̀-èdè wá sí odò Kiṣoni.

14 Debora sì wí fún Baraki pé, “Lọ! Lónìí ni Olúwa fi Sisera lé ọ lọ́wọ́, Olúwa ti lọ síwájú rẹ.” Baraki sì síwájú, àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì tẹ̀lé e lẹ́yìn, wọ́n sì kọjá sí òkè Tabori. 15 Olúwa sì mú ìdàrúdàpọ̀ wá sí àárín ogun Sisera, Olúwa sì fi ojú idà ṣẹ́gun Sisera àti àwọn oníkẹ̀kẹ́ ogun àti ọmọ-ogun orí ilẹ̀ ní iwájú Baraki. Sisera sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ ó sì fi ẹsẹ̀ sálọ.

16 Baraki àti àwọn ogun rẹ̀ sì lé àwọn ọ̀tá náà, àwọn ọmọ-ogun orílẹ̀ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn títí dé Haroseti ti àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo ogun Sisera sì ti ojú idà ṣubú, kò sí ọ̀kan tí ó lè sálà tàbí tí ó wà láààyè. 17 Ṣùgbọ́n Sisera ti fi ẹsẹ̀ sálọ sí àgọ́ Jaeli aya Heberi ẹ̀yà Keni: nítorí ìbá dá ọ̀rẹ́ àlàáfíà wà láàrín Jabini ọba Hasori àti ìdílé Heberi ti ẹ̀yà Keni.

18 Jaeli sì jáde síta láti pàdé Sisera, ó sì wí fún un pé, “Wọlé sínú àgọ́ mi, Olúwa mi, wọlé wá má ṣe bẹ̀rù nítorí pé ààbò ń bẹ fún ọ.” Ó sì yà sínú àgọ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ bò ó.

19 Sisera wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ́ mí, jọ̀wọ́ fún mi ní omi mu.” Ó sì ṣí awọ wàrà kan, ó sì fún un mu ó sì tún daṣọ bò ó padà.

20 Sisera sọ fún Jaeli pé, “Kí ó dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, àti pé bí ẹnikẹ́ni bá béèrè bóyá òun wà níbẹ̀ kí ó sọ pé, ‘Kò sí ẹnìkankan ní ibẹ̀.’ ”

21 Ṣùgbọ́n Jaeli ìyàwó Heberi mú ìṣó àgọ́ tí ó mú àti òòlù ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì yọ́ wọ inú ibi tí ó sùn, nígbà tí ó ti sùn fọnfọn, nígbà náà ni ó kan ìṣó náà mọ́ òkè ìpéǹpéjú rẹ̀, ó sì wọlé ṣinṣin, ó sì kú.

22 Nígbà tí Baraki dé bí ó ti ń lépa Sisera, Jaeli láti pàdé rẹ̀, wá, èmi yóò fi ẹni tí ìwọ ń wá hàn ọ́, báyìí ni ó tẹ̀lé e wọ inú àgọ́ lọ, kíyèsi Sisera dùbúlẹ̀ síbẹ̀ pẹ̀lú ìṣó àgọ́ ní agbárí rẹ̀ tí a ti kàn mọ́lẹ̀ ṣinṣin tí ó sì ti kú.

23 Ní ọjọ́ náà ni Ọlọ́run ṣẹ́gun Jabini ọba àwọn ará Kenaani ní iwájú àwọn ẹ̀yà Israẹli. 24 Ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli sì le, ó sì ń lágbára síwájú àti síwájú sí i lára Jabini ọba Kenaani, títí wọ́n fi run òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀.

Orin Debora

Nígbà náà ni Debora àti Baraki ọmọ Abinoamu kọ orin ní ọjọ́ náà wí pé:

“Nítorí bí àwọn olórí ti síwájú ní Israẹli,
    nítorí bi àwọn ènìyàn ti fi tọkàntọkàn wa,
    ẹ fi ìbùkún fún Olúwa!

“Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ọba! Ẹ fetí yín sílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ-aládé!
    Èmi yóò kọrin sí Olúwa,
    Èmi yóò kọrin ìyìn sí Olúwa: Ọlọ́run Israẹli.

Olúwa nígbà tí o jáde kúrò ní Seiri,
    nígbà tí ìwọ ń yan jáde wá láti pápá Edomu,
ilẹ̀ mì tìtì, àwọn ọ̀run sì kán sílẹ̀,
    àní àwọsánmọ̀ pẹ̀lú kàn omi sílẹ̀.
Àwọn òkè ńlá wárìrì ní iwájú Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Sinai ní iwájú Olúwa
    Ọlọ́run Israẹli.

“Ní ọjọ́ Ṣamgari ọmọ Anati,
    Ní ọjọ́ Jaeli, àwọn ọ̀nà òpópó dá;
    àwọn arìnrìn-àjò sì ń gba ọ̀nà ìkọ̀kọ̀.
Àwọn olórí tán ní Israẹli,
    wọ́n tán, títí èmi Debora fi dìde
    bí ìyá ní Israẹli.
Wọ́n ti yan ọlọ́run tuntun,
    nígbà náà ni ogun wà ní ibodè
a ha rí asà tàbí ọ̀kọ̀ kan
    láàrín ẹgbàá ogun ní Israẹli bí.
Àyà mi fà sí àwọn aláṣẹ Israẹli
    àwọn tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láàrín àwọn ènìyàn
    Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa!

10 “Ẹ kéde rẹ̀: ẹ̀yin tí ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun,
    ẹ̀yin tí ń jókòó lórí ẹní dáradára,
    àti ẹ̀yin tí ó ń rìn ní ọ̀nà,
Ní ọ̀nà jíjìn sí 11 ariwo àwọn tafàtafà, ní ibi tí a gbé ń fa omi.
    Níbẹ̀ ni wọ́n gbé ń sọ ti iṣẹ́ òdodo Olúwa,
    àní iṣẹ́ òdodo ìjọba rẹ̀ ní Israẹli.

“Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Olúwa
    sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibodè.
12 ‘Jí, jí, Debora!
    Jí, jí, kọ orin dìde!
Dìde ìwọ Baraki!
    Kó àwọn ìgbèkùn rẹ ní ìgbèkùn ìwọ ọmọ Abinoamu.’

13 “Nígbà náà ni àwọn tókù sọ̀kalẹ̀ àwọn ọlọ́lá lọ;
    àwọn ènìyàn Olúwa tọ̀ mí wá pẹ̀lú àwọn alágbára.
14 Àwọn kan jáde wá láti Efraimu, àwọn tí gbòǹgbò wọn wà ní Amaleki;
    Benjamini wà pẹ̀lú àwọn tí ó tẹ̀lé ọ.
Láti Makiri ni àwọn aláṣẹ ti sọ̀kalẹ̀ wá,
    láti Sebuluni ni àwọn ẹni tí ń mú ọ̀pá oyè lọ́wọ́.
15 Àwọn ọmọ-aládé Isakari wá pẹ̀lú Debora;
    bí Isakari ti ṣe olóòtítọ́ sí Baraki,
    wọ́n fi ẹsẹ̀ súré tẹ̀lé wọn lọ sí àfonífojì náà.
Ní ipadò Reubeni
    ni ìgbèrò púpọ̀ wà.
16 Èéṣe tí ìwọ fi dúró pẹ́ láàrín agbo àgùntàn
    láti máa gbọ́ fèrè olùṣọ́-àgùntàn?
Ní ipadò Reubeni
    ni ìgbèrò púpọ̀ wà.
17 Gileadi dúró ní òkè odò Jordani.
    Èéṣe tí Dani fi dúró nínú ọkọ̀ ojú omi?
Aṣeri jókòó ní etí bèbè Òkun,
    ó sì ń gbé èbúté rẹ̀.
18 Àwọn ènìyàn Sebuluni fi ẹ̀mí wọn wéwu ikú;
    bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn Naftali ní ibi gíga pápá.

19 “Àwọn ọba wá, wọ́n sì jà;
    àwọn ọba Kenaani jà
ní Taanaki ní etí odo Megido,
    ṣùgbọ́n wọn kò sì gba èrè owó.
20 Àwọn ìràwọ̀ já láti ojú ọ̀run wá
    láti inú ipa ọ̀nà wọn ni wọ́n bá Sisera jà.
21 Odò Kiṣoni gbá wọn lọ,
    odò ìgbàanì, odò Kiṣoni.
    Máa yan lọ, ìwọ ọkàn mi, nínú agbára!
22 Nígbà náà ni pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin ki ilẹ̀,
    nítorí eré sísá, eré sísá àwọn alágbára wọn.
23 ‘Ẹ fi Merosi bú’ ni angẹli Olúwa wí.
    ‘Ẹ fi àwọn ènìyàn inú rẹ̀ bú ìbú kíkorò,
nítorí wọn kò wá sí ìrànlọ́wọ́ Olúwa,
    láti dojúkọ àwọn alágbára.’

24 “Ìbùkún ni fún Jaeli,
    aya Heberi ará Keni ju àwọn obìnrin lọ,
    ìbùkún ni fún un ju àwọn obìnrin tí ń gbé nínú àgọ́.
25 Ó béèrè omi, ó fún un ní wàrà;
    ó mú òrí-àmọ́ tọ̀ ọ́ wá nínú àwo iyebíye tí ó yẹ fún àwọn ọlọ́lá.
26 Ó na ọwọ́ rẹ̀ mú ìṣó àgọ́,
    ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú òòlù awọ gbẹ́nàgbẹ́nà,
òòlù náà ni ó sì fi lu Sisera, ó gbá a mọ́ ọn ní orí,
    ó sì gun, ó sì kàn ẹ̀bátí rẹ̀ mọ́lẹ̀ ṣinṣin.
27 Ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀
    ó ṣubú; ó dùbúlẹ̀,
ó wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ṣubú níbi tí ó gbé ń wólẹ̀;
    níbẹ̀ náà ni ó ṣubú kú sí.

28 “Ìyá Sisera yọjú láti ojú fèrèsé,
    ó sì kígbe, ó kígbe ní ojú fèrèsé ọlọ́nà pé,
‘Èéṣe tí kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ fi pẹ́ bẹ́ẹ̀ láti dé?
    Èéṣe tí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ fi dúró lẹ́yìn?’
29 Àwọn amòye obìnrin rẹ̀ dá a lóhùn;
    àní òun náà pẹ̀lú ti dá ara rẹ̀ lóhùn pé,
30 ‘Wọn kò ha ń wa kiri, wọn kò ha ti pín ìkógun bi:
    ọmọbìnrin kan tàbí méjì fún ọkùnrin kan,
fún Sisera ìkógun aṣọ aláràbarà,
    ìkógun aṣọ aláràbarà àti ọlọ́nà,
àwọn aṣọ ọlọ́nà iyebíye fún ọrùn mi,
    gbogbo èyí tí a kó ní ogun?’

31 (A)“Bẹ́ẹ̀ ni kí ó jẹ́ kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kí ó ṣègbé Olúwa!
    Ṣùgbọ́n jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ọ ràn bí oòrùn,
    nígbà tí ó bá yọ nínú agbára rẹ̀.”

Ilẹ̀ náà sì sinmi ní ogójì ọdún.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.