Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Kọrinti 1-4

(A)Paulu aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, àti Timotiu arákùnrin wá, sí ìjọ Ọlọ́run tí ó wà ní Kọrinti pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní gbogbo Akaia:

(B)Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Jesu Kristi Olúwa.

Ọlọ́run gbogbo ìtùnú

(C)Olùbùkún ni Ọlọ́run, àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ìyọ́nú, àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo; (D)Ẹni tí ń tù wá nínú ni gbogbo ìdààmú wa, ki àwa pẹ̀lú lè máa tu àwọn tí ó wá nínú ìdààmú nínú, nípá ìtùnú náà ti a fi ń tú àwa fúnra wa nínú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Nítorí pé bí àwa ti pín nínú ìjìyà Kristi, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ nì ìtùnú wa dí púpọ̀ pẹ̀lú nípa Kristi. Ṣùgbọ́n bí a bá sì ń pọ́n wa lójú, ó jẹ́ fún ìtùnú àti ìgbàlà yín; tàbí bi a bá ń tù wá nínú, ó jẹ́ fún ìtùnú yín ti ń ṣiṣẹ́ sùúrù láti mú yin ní irú ìfaradà ìyà kan náà ti àwa pẹ̀lú ń jẹ́. Àti pé ìrètí wa nípa tiyín dúró ṣinṣin, àwa si mọ̀ pé, bí ẹ̀yin ti jẹ alábápín nínú ìyà wa, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń pín nínú ìtùnú náà pẹ̀lú.

Arákùnrin àti arábìnrin, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè nípa wàhálà tí ó dé bá wa ní agbègbè Asia, ní ti pé a pọ́n wa lójú gidigidi rékọjá agbára ìfaradà wa, tó bẹ́ẹ̀ tí ìrètí kò tilẹ̀ sí fún ẹ̀mí wa mọ́. Nítòótọ́, nínú ọkàn wa a tilẹ̀ ní ìmọ̀lára wí pé a tí gba ìdálẹ́bi ikú, ṣùgbọ́n èyí farahàn láti má mú wa gbẹ́kẹ̀lé ara wa bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń jí òkú dìde: 10 Ẹni tí ó gbà wá kúrò nínú irú ikú tí ó tóbi bẹ́ẹ̀, yóò sí tún gbà wá; òun ní àwa gbẹ́kẹ̀lé pé yóò sí máa gbà wá síbẹ̀síbẹ̀, 11 bí ẹ̀yin pẹ̀lú ti ń fi àdúrà yín ràn wá lọ́wọ́. Àti pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóò dúpẹ́ nítorí wa fún oore-ọ̀fẹ́ ojúrere tí a rí gbà nípa ìdáhùn sí àdúrà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.

Paulu yí ìpinnu rẹ̀ padà

12 Nítorí èyí ní ìṣògo wá, ẹ̀rí láti inú ọkàn wa pẹ̀lú si jẹ́rìí wí pé àwa ń gbé ìgbésí ayé tí ó ní ìtumọ̀ pàápàá jùlọ nínú ìbágbépọ̀ wa pẹ̀lú yín, nínú ìwà mímọ́ àti òtítọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Kì í ṣe nípa ọgbọ́n ti ara ni àwa ń ṣe èyí bí kò ṣe nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. 13 Nítorí pé àwa kò kọ̀wé ohun tí eyín kò lè kà àti ni mòye rẹ̀ sí yín. Mo sì tún ní ìrètí wí pé. 14 Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin pẹ̀lú ti ní ìmọ̀ nípa wa ní apá kan, bákan náà ni ẹ ó ní ìmọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́ tí ẹ ó sì fi wá yangàn, bí àwa pẹ̀lú yóò ṣe fi yín yangàn ní ọjọ́ Jesu Olúwa.

15 Nítorí mo ní ìdánilójú yìí wí pé, mo pinnu láti kọ́kọ́ bẹ̀ yín wò kí ẹ lè jẹ àǹfààní ìgbà méjì. 16 (E)Mo pinnu láti bẹ̀ yín wò ní ìrìnàjò mi sí Makedonia àti láti tún bẹ̀ yín wò nígbà tí mo bá ń padà bọ̀ láti Makedonia àti wí pé kí ẹ̀yin kí ó lè rán mi láti ọ̀dọ̀ yín ní ìrìnàjò mi sí Judea. 17 Nítorí náà nígbà tí èmi ń gbèrò bẹ́ẹ̀, èmi ha ṣiyèméjì bí? Tàbí àwọn ohun tí mo pinnu, mo ha pinnu wọn gẹ́gẹ́ bí ti ará bí, pé kí ó jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ ní, bẹ́ẹ̀ ní” àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bẹ́ẹ̀ kọ́”?

18 Ṣùgbọ́n bí Ọlọ́run tí jẹ́ olóòtítọ́, ọ̀rọ̀ wa fún yín kí í ṣe bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́. 19 (F)Nítorí pé Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí a tí wàásù rẹ̀ láàrín yín nípasẹ̀ èmí àti Silfanu àti Timotiu, kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n nínú rẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ ní. 20 (G)Nítorí tí gbogbo ìlérí Ọlọ́run dí bẹ́ẹ̀ ni nínú Kristi. Nítorí ìdí èyí ní a ṣe ń wí pé “Àmín” nípasẹ̀ rẹ̀ sí ògo Ọlọ́run. 21 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Ọlọ́run ni ó fi ẹsẹ̀ wa múlẹ̀ pẹ̀lú yín nínú Kristi, Òun ni ó ti fi ààmì òróró yàn wá, 22 ó sì fi èdìdì rẹ̀ dì wá pẹ̀lú, ó sì tí fi Ẹ̀mí rẹ́ sí wa ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ó ń bọ̀.

23 Mo sì pe Ọlọ́run ṣe ẹlẹ́rìí ọkàn mi pé nítorí àti dá yín sí ní èmi kò ṣe padà sí Kọrinti. 24 Kì í ṣe nítorí tí àwa jẹ gàba lórí ìgbàgbọ́ yín: ṣùgbọ́n àwa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú yín fún ayọ̀ yín nítorí nípa ìgbàgbọ́ ni ẹ̀yin dúró ṣinṣin. Nítorí náà mo tí pinnu nínú ara mí pé, èmi kì yóò tún fi ìbànújẹ́ tọ̀ yin wá. Nítorí pé bí èmi bá mú inú yín bàjẹ́, ǹjẹ́ ta ni ẹni ti ìbá mú inú mí dùn ní àkókò tí inú mi bá bàjẹ́ bí kò ṣe ẹni tí mo ti ba nínú jẹ́? Èmi sì kọ̀wé bí mo tí kọ sí yín pé, nígbà tí mo bá sì de, kí èmi má ṣe ni ìbànújẹ́ lọ́dọ̀ àwọn ti ìbá mú mi ní ayọ̀: nítorí tí mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú gbogbo yín, wí pé ẹ̀yin yóò jẹ́ alábápín ayọ̀ mi. Nítorí pé nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà àti ìrora ọkàn mí ni mo ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ omijé kọ̀wé sí yín; kì í ṣe nítorí kí a lè bà yín nínú jẹ́, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin bá a lè mọ bí ìfẹ́ tí mo ní sí yín ṣe jinlẹ̀ tó.

Ìdáríjì fún ẹlẹ́ṣẹ̀

Bí ẹnikẹ́ni bá fa ohun ìbànújẹ́ kì í ṣe èmi ni ó bà nínú jẹ́, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnrayín, níwọ̀n ìyówù kí ó jẹ́; n kò fẹ́ sọ ọ́ lọ́nà líle jù. Ìyà náà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti fi jẹ́ irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ tó fún un. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ìbá kúkú dáríjì í, kí ẹ sí tù ú nínú ní gbogbo ọ̀nà, kí ìbànújẹ́ má bà á bo irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀. Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ fi ìdánilójú ìfẹ́ yín hàn sí irú ẹni náà. Ìdí tí mo ṣe kọ̀wé ni kí èmi ba à lè rí ẹ̀rí dìímú nípa ìgbọ́ràn yín nínú ohun gbogbo. 10 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá dáríjì ẹnikẹ́ni, èmi pẹ̀lú dáríjì í. Ohun tí èmi pẹ̀lú bá fi jì, nítorí tiyín ní mo fi jì níwájú Kristi. 11 Kí Satani má ba à rẹ́ wa jẹ. Nítorí àwa kò ṣe aláìmọ́ àrékérekè rẹ̀.

Ìránṣẹ́ májẹ̀mú tuntun

12 (H)Ṣùgbọ́n nígbà ti mo dé Troasi láti wàásù ìhìnrere Kristi, tí mo sì rí i wí pé Olúwa ti ṣí ìlẹ̀kùn fún mi, 13 síbẹ̀ èmi kò ní àlàáfíà lọ́kàn mi, nítorí tí èmi kò rí Titu arákùnrin mi níbẹ̀. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe dágbére fún wọn, mo si rékọjá lọ sí Makedonia.

14 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, ẹni tí ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí wá nígbà gbogbo nínú Kristi, tí a sì ń fi òórùn dídùn ìmọ̀ rẹ̀ hàn nípa wa níbi gbogbo. 15 Nítorí òórùn dídùn Kristi ni àwa jẹ́ fún Ọlọ́run, nínú àwọn tí a ń gbàlà àti nínú àwọn tí ó ń ṣègbé: 16 Fún àwọn kan, àwa jẹ́ òórùn sí ikú, àti fún àwọn mìíràn òórùn ìyè sí ìyè. Ta ni ó ha si tọ́ fún nǹkan wọ̀nyí? 17 Nítorí àwa kò dàbí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣòwò jẹun; ṣùgbọ́n nínú òtítọ́ inú àwa ń sọ̀rọ̀ níwájú Ọlọ́run nínú Kristi gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.

(I)Àwa ha tún bẹ̀rẹ̀ láti máa yín ara wá bí? Tàbí àwa ha ń fẹ́ ìwé ìyìn sọ́dọ̀ yín, tàbí láti ọ̀dọ̀ yín gẹ́gẹ́ bí ẹlòmíràn tí ń ṣe? Ẹ̀yin fúnrayín ni ìwé ìyìn wa, tí a ti kọ sí yín ní ọkàn, ti gbogbo ènìyàn mọ̀, tí wọ́n sì ń kà. (J)Ẹ̀yin sì ń fihàn pé ìwé tí a gbà sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kristi ni yín, kì í ṣe èyí tí a sì fi jẹ́lú kọ, bí kò sẹ Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè, kì í ṣe nínú wàláà òkúta bí kò ṣe nínú wàláà ọkàn ẹran.

Irú ìgbẹ́kẹ̀lé yìí ni àwa ní nípasẹ̀ Kristi sọ́dọ̀ Ọlọ́run: Kì í ṣe pé àwa tó fún ara wa láti ṣírò ohunkóhun bí ẹni pé láti ọ̀dọ̀ àwa tìkára wa; ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní tító wà; Ẹni tí ó mú wa yẹ bí ìránṣẹ́ májẹ̀mú tuntun; kì í ṣe ní ti ìwé àkọsílẹ̀ ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀mí, nítorí ìwé a máa pa ni, ṣùgbọ́n ẹ̀mí a máa sọ ní di ààyè.

Ògo tó wà nínú májẹ̀mú tuntun

(K)Ṣùgbọ́n bí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ikú, tí a tí kọ tí a sì ti gbẹ́ sí ara òkúta bá jẹ́ ológo tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè tẹjúmọ́ wíwo ojú Mose nítorí ògo ojú rẹ̀ (ògo ti ń kọjá lọ); yóò ha ti rí tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ẹ̀mí kì yóò kúkú jẹ́ ògo jù? Nítorí pé bi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìdálẹ́bi bá jẹ́ ológo, mélòó mélòó ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ òdodo yóò tayọ jù ú ní ògo. 10 Nítorí, èyí tí a tí ṣe lógo rí, kó lógo mọ́ báyìí, nítorí ògo tí ó tayọ. 11 Nítorí pé bí èyí ti ń kọjá lọ bá lógo, mélòó mélòó ni èyí tí ó dúró kí yóò ní ògo!

12 Ǹjẹ́ nítorí náà bí a tí ní irú ìrètí bí èyí, àwa ń fi ìgboyà púpọ̀ sọ̀rọ̀. 13 Kì í sì í ṣe bí Mose, ẹni tí ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀, ki àwọn ọmọ Israẹli má ba à lè tẹjúmọ́ wíwo òpin èyí tí ń kọjá lọ 14 Ṣùgbọ́n ojú inú wọn fọ́; nítorí pé títí fi di òní olónìí nípa kíka májẹ̀mú láéláé, ìbòjú kan náà ṣì wà láìká kúrò; nítorí pé nínú Kristi ni a tí lè mú ìbòjú náà kúrò. 15 Ṣùgbọ́n títí di òní olónìí, nígbàkúgbà ti a bá ń ka Mose, ìbòjú náà ń bẹ lọ́kàn wọn. 16 Ṣùgbọ́n nígbà ti òun bá yípadà sí Olúwa, a ó mú ìbòjú náà kúrò. 17 (L)Ǹjẹ́ Olúwa ni Ẹ̀mí náà: níbi tí Ẹ̀mí Olúwa bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira gbé wà 18 Ṣùgbọ́n gbogbo wa ń wo ògo Olúwa láìsí ìbòjú bí ẹni pé nínú àwòjìji, a sì ń pa wa dà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo, àní bí láti ọ̀dọ̀ Olúwa tí í ṣe Ẹ̀mí.

Ìṣúra nínú ohun-èlò amọ̀

Nítorí náà, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé nípa àánú Ọlọ́run ni a rí iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí gba, àárẹ̀ kò mú ọkàn wa rara; Ṣùgbọ́n àwa tí kọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ tí ó ní ìtìjú sílẹ̀, àwa kò rìn ní ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò fi ọwọ́ ẹ̀tàn mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n nípa fífi òtítọ́ hàn, àwa ń fi ara wa le ẹ̀rí ọkàn olúkúlùkù ènìyàn lọ́wọ́ níwájú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n báyìí, bí Ìhìnrere wa bá sí fi ara sin, ó fi ara sin fún àwọn tí ó ń ṣègbé. (M)Nínú àwọn ẹni tí ọlọ́run ayé yìí ti sọ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ dí afọ́jú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere Kristi tí ó lógo, ẹni tí í ṣe àwòrán Ọlọ́run, má ṣe mọ́lẹ̀ nínú wọn. Nítorí àwa kò wàásù àwa tìkára wa, bí kò ṣe Kristi Jesu Olúwa; àwa tìkára wa sì jẹ́ ẹrú yín nítorí Jesu. (N)Nítorí Ọlọ́run ni ẹni tí ó wí pé, “Kí ìmọ́lẹ̀ ó tan láti inú òkùnkùn jáde,” òun ní ó ti ń tan mọ́lẹ̀ lọ́kàn wa, láti fún wa ní ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọ́run ní ojú Jesu Kristi.

Ṣùgbọ́n àwa ní ìṣúra yìí nínú ohun èlò amọ̀, kí ọláńlá agbára náà lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má ṣe ti ọ̀dọ̀ wa wá. A ń pọ́n wa lójú níhà gbogbo, ṣùgbọ́n ara kò ni wá: a ń dààmú wa, ṣùgbọ́n a kò sọ ìrètí nù. A ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò kọ̀ wá sílẹ̀; a ń rẹ̀ wá sílẹ̀ ṣùgbọ́n a kò pa wá run. 10 Nígbà gbogbo àwa ń ru ikú Jesu Olúwa kiri ni ará wa, kí a lè fi ìyè Jesu hàn pẹ̀lú lára wa. 11 Nítorí pé nígbà gbogbo ní a ń fi àwa tí ó wà láààyè fún ikú nítorí Jesu, kí a lè fi ìyè hàn nínú ara kíkú wa pẹ̀lú. 12 Bẹ́ẹ̀ ni ikú ń ṣiṣẹ́ nínú wa, ṣùgbọ́n ìyè ṣiṣẹ́ nínú yín.

13 (O)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ pé, “Èmi gbàgbọ́, nítorí náà ni èmi ṣe sọ,” pẹ̀lú ẹ̀mí ìgbàgbọ́ kan náà, a tún gbàgbọ́ àti nítorí náà ni àwa sì ṣe ń sọ. 14 (P)Àwa mọ̀ pé, ẹni tí o jí Jesu Olúwa dìde yóò sì jí wa dìde pẹ̀lú nípa Jesu, yóò sì mú wa wà níwájú rẹ̀ pẹ̀lú yín 15 Nítorí tiyín ní gbogbo rẹ̀, ki ọ̀pẹ lè dí púpọ̀ fún ògo Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ ti ń gbòòrò sí i fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn.

16 Nítorí èyí ni àárẹ̀ kò ṣe mú wa; ṣùgbọ́n bí ọkùnrin ti òde wa bá ń parun, síbẹ̀ ọkùnrin tí inú wa ń di tuntun lójoojúmọ́. 17 Nítorí ìpọ́njú díẹ̀ yìí ń pèsè ògo tí ó ní ìwọ̀n ayérayé tí ó pọ̀ rékọjá sílẹ̀ fún wa. 18 Níwọ́n bí kò ti wo ohun tí a ń rí, bí kò ṣé ohun tí a kò rí; nítorí ohun tí a ń rí ni ti ìgbà ìsinsin yìí; ṣùgbọ́n ohun tí a kò rí ni ti ayérayé.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.