Chronological
Àwọn ọmọ Dafidi
3 (A)Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Dafidi tí a bí fún un ní Hebroni:
Àkọ́bí sì ni Amnoni ọmọ Ahinoamu ti Jesreeli;
èkejì sì ni Daniẹli ọmọ Abigaili ará Karmeli;
2 Ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un;
ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti;
3 Ẹ̀karùnún ni Ṣefatia láti ọ̀dọ̀ Abitali;
àti ẹ̀kẹfà, Itreamu, láti ọ̀dọ̀ Egla aya rẹ̀.
4 (B)Àwọn mẹ́fà wọ̀nyí ni a bí fún Dafidi ni Hebroni, níbi tí ó ti jẹ ọba fún ọdún méje àti oṣù mẹ́fà.
Dafidi sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33). 5 Wọ̀nyí ni ọmọ wẹ́wẹ́ tí a bí fún un ní Jerusalẹmu:
Ṣimea, Ṣobabu, Natani àti Solomoni. Àwọn mẹ́rin wọ̀nyí sì ni a bí láti ọ̀dọ̀ Bati-Ṣua ọmọbìnrin Ammieli.
6 Ibhari sì wà pẹ̀lú, Eliṣama, Elifeleti, 7 Noga, Nefegi, Jafia, 8 Eliṣama, Eliada àti Elifeleti mẹ́sàn-án ni wọ́n.
9 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dafidi yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àlè bí fún un. Tamari sì ni arábìnrin wọn.
Àwọn ọba Juda
10 Ọmọ Solomoni ni Rehoboamu,
Abijah ọmọ rẹ̀,
Asa ọmọ rẹ̀,
Jehoṣafati ọmọ rẹ̀,
11 Jehoramu ọmọ rẹ̀,
Ahasiah ọmọ rẹ̀,
Joaṣi ọmọ rẹ̀,
12 Amasiah ọmọ rẹ̀,
Asariah ọmọ rẹ̀,
Jotamu ọmọ rẹ̀,
13 Ahasi ọmọ rẹ̀,
Hesekiah ọmọ rẹ̀,
Manase ọmọ rẹ̀,
14 Amoni ọmọ rẹ̀,
Josiah ọmọ rẹ̀.
15 Àwọn ọmọ Josiah:
Àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ni Johanani,
èkejì ọmọ rẹ̀ ni Jehoiakimu,
ẹ̀kẹta ọmọ rẹ̀ ni Sedekiah,
ẹ̀kẹrin ọmọ rẹ̀ ni Ṣallumu.
16 Àwọn ìran ọmọ Jehoiakimu:
Jekoniah ọmọ rẹ̀,
àti Sedekiah.
Ìdílé ọba lẹ́yìn ìgbèkùn
17 Àwọn ọmọ Jekoniah tí a mú ní ìgbèkùn:
Ṣealitieli ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, 18 Malkiramu, Pedaiah, Ṣenasari, Jekamiah, Hoṣama àti Nedabiah.
19 Àwọn ọmọ Pedaiah:
Serubbabeli àti Ṣimei.
Àwọn ọmọ Serubbabeli:
Meṣullamu àti Hananiah. Ṣelomiti ni arábìnrin wọn. 20 Àwọn márùn-ún mìíràn sì tún wà: Haṣuba, Oheli, Berekiah, Hasadiah àti Jusabhesedi.
21 Àwọn ọmọ Hananiah:
Pelatiah àti Jeṣaiah, àti àwọn ọmọ Refaiah, ti Arnani, ti Ọbadiah àti ti Ṣekaniah.
22 Àwọn ọmọ Ṣekaniah:
Ṣemaiah àti àwọn ọmọ rẹ̀: Hattusi, Igali, Bariah, Neariah àti Ṣafati, mẹ́fà ni gbogbo wọn.
23 Àwọn ọmọ Neariah:
Elioenai; Hesekiah, àti Asrikamu, mẹ́ta ni gbogbo wọn.
24 Àwọn ọmọ Elioenai:
Hodafiah, Eliaṣibu, Pelaiah, Akkubu, Johanani, Delaiah àti Anani, méje sì ni gbogbo wọn.
Ìran Juda
4 Àwọn ọmọ Juda:
Peresi, Hesroni, Karmi, Huri àti Ṣobali.
2 Reaiah ọmọ Ṣobali ni baba Jahati, àti Jahati baba Ahumai àti Lahadi. Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀yà ará Sorati.
3 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Etamu:
Jesreeli, Iṣima, Idbaṣi, orúkọ arábìnrin wọn sì ni Haseleponi 4 Penueli sì ni baba Gedori, àti Eseri baba Huṣa.
Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Huri, àkọ́bí Efrata àti baba Bẹtilẹhẹmu.
5 Aṣihuri baba Tekoa sì ní aya méjì, Hela àti Naara.
6 Naara sì bí Ahussamu, Heferi Temeni àti Haaṣtari. Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Naara.
7 Àwọn ọmọ Hela:
Sereti Sohari, Etani, 8 Àti Kosi ẹni tí ó jẹ́ baba Anubu àti Sobeba àti ti àwọn ẹ̀yà Aharheli ọmọ Harumu.
9 Jabesi sì ní ọlá ju àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin lọ. Ìyá rẹ̀ sì sọ ọ́ ní Jabesi wí pé, “Mo bí i nínú ìpọ́njú.” 10 Jabesi sì kígbe sókè sí Ọlọ́run Israẹli wí pé, “Háà, Ìwọ yóò bùkún fún, ìwọ yóò sì mú agbègbè mi tóbi! Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà pẹ̀lú mi kí o sì pa mi mọ́ kúrò nínú ibi; kí èmi kí ó le ní ìdáǹdè kúrò nínú ìrora.” Ọlọ́run sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀.
11 Kelubu arákùnrin Ṣuha, sì jẹ́ baba Mehiri, ẹni tí ó jẹ́ baba Eṣtoni. 12 Eṣtoni sì jẹ́ baba Beti-Rafa, Pasea àti Tehina ti baba ìlú Nahaṣi. Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin Reka.
13 Àwọn ọmọ Kenasi:
Otnieli àti Seraiah.
Àwọn ọmọ Otnieli:
Hatati àti Meonotai. 14 Meonotai sì ni baba Ofira.
Seraiah sì jẹ́ baba Joabu,
baba Geharaṣinu. A pè báyìí nítorí àwọn ènìyàn àwọn oníṣọ̀nà ní ìwọ̀n.
15 Àwọn ọmọ Kalebu ọmọ Jefunne:
Iru, Ela, àti Naamu.
Àwọn ọmọ Ela:
Kenasi.
16 Àwọn ọmọ Jehaleeli:
Sifi, àti Sifa, Tiria àti Asareeli.
17 Àwọn ọmọ Esra:
Jeteri, Meredi, Eferi àti Jaloni.
Ọ̀kan lára àwọn aya Meredi sì bí Miriamu, Ṣammai àti Iṣba baba Eṣitemoa.
18 Aya rẹ̀ láti ẹ̀yà Juda sì bí Jaredi baba Gedori, àti Heberi baba Soko àti Jekutieli baba Sanoa. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ọmọbìnrin Farao Bitia, ẹni ti Meredi ti fẹ́.
19 Àwọn ọmọ aya Hodiah arábìnrin Nahamu:
Baba Keila ará Garimu, àti Eṣitemoa àwọn ará Maakati.
20 Àwọn ọmọ Ṣimoni:
Amnoni, Rina, Beni-Hanani àti Tiloni.
Àwọn ọmọ Iṣi:
Soheti àti Beni-Soheti.
21 Àwọn ọmọ Ṣela ọmọ Juda:
Eri baba Leka, Lada baba Meraṣa àti àwọn ìdílé ilé àwọn tí ń hun aṣọ oníṣẹ́ ní Beti-Aṣibea.
22 Jokimu, ọkùnrin Koṣeba, àti Joaṣi àti Sarafi, olórí ní Moabu àti Jaṣubi Lehemu. (Àkọsílẹ̀ yìí sì wà láti ìgbà àtijọ́). 23 Àwọn sì ni amọ̀kòkò tí ń gbé ní Netaimu àti Gedera; wọ́n sì dúró níbẹ̀ wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ fún ọba.
Simeoni
24 (C)Àwọn Ọmọ Simeoni:
Nemueli, Jamini, Jaribi, Sera àti Saulu;
25 Ṣallumu sì jẹ́ ọmọ Saulu, Mibsamu ọmọ rẹ̀ Miṣima ọmọ rẹ̀.
26 Àwọn ọmọ Miṣima:
Hamueli ọmọ rẹ̀ Sakkuri ọmọ rẹ̀ àti Ṣimei ọmọ rẹ̀.
27 Ṣimei sì ní ọmọkùnrin mẹ́rìn-dínlógún àti ọmọbìnrin mẹ́fà, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin kò ní ọmọ púpọ̀; Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìdílé wọn kò sì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn Juda. 28 (D)Wọ́n sì ń gbé ní Beerṣeba, Molada, Hasari-Ṣuali, 29 Àti ní Biliha, àti ní Esemu, àti ní Toladi, 30 Betueli, Horma, Siklagi, 31 Beti-Markaboti Hormah; Hasari Susimu, Beti-Biri àti Ṣaraimi. Àwọn wọ̀nyí ni ìlú wọn títí di ìgbà ọba Dafidi, 32 agbègbè ìlú wọn ni Etamu, Aini, Rimoni, Tokeni, Aṣani àwọn ìlú márùn-ún, 33 àti gbogbo ìletò wọn, tí ó wà yí ìlú náà ká, dé Baali. Àwọn wọ̀nyí ni ibùgbé wọn.
Àti ìtàn ìdílé wọ́n.
34 Meṣobabu àti Jamleki,
Josa ọmọ Amasiah, 35 Joeli,
Jehu ọmọ Josibiah, ọmọ Seraiah, ọmọ Asieli,
36 àti pẹ̀lú Elioenai, Jaakoba, Jeṣohaiah,
Asaiah, Adieli, Jesimieli, Benaiah,
37 àti Sisa ọmọ Ṣifi ọmọ Alloni, ọmọ Jedaiah, ọmọ Ṣimri ọmọ Ṣemaiah.
38 Àwọn ọkùnrin tí a dárúkọ lókè yìí àwọn ni ìjòyè ìdílé wọn.
Àwọn ìdílé sì pọ̀ sí i gidigidi, 39 Wọ́n sì lọ sí ojú ọ̀nà Gedori. Lọ títí dé ìlà-oòrùn àfonífojì láti wá koríko fún àwọn agbo ẹran wọn 40 Wọ́n sì rí koríko tútù tí ó dára ilẹ̀ náà gbòòrò ó sì ní àlàáfíà ó sì gbé jẹ́. Àwọn ọmọ Hamu ni ó ti ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.
41 Àwọn ọkùnrin tí a kọ orúkọ rẹ̀ sókè, dé ní ọjọ́ Hesekiah ọba Juda. Wọ́n sì kọlu àwọn ará Hamu ní àgọ́ wọn àti pẹ̀lú àwọn ará Mehuni tí a rí níbẹ̀ tí ó sì pa wọ́n run pátápátá títí di òní yìí. Wọ́n sì ń gbé ní ipò wọn, nítorí pé koríko ń bẹ níbẹ̀ fún agbo ẹran wọn. 42 Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta nínú àwọn ará Simeoni, lábẹ́ ìdarí pẹ̀lú Pelatiah, Neariah, Refaiah àti Usieli, àwọn ọmọ Iṣi, gbógun sí àwọn òkè ìlú ti Seiri. 43 Wọ́n sì pa àwọn ará Amaleki tí ó kù, àwọn tí ó ti sálà, wọ́n sì ti ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí.
Rubeni
5 (E)Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Reubeni, àkọ́bí Israẹli. (Nítorí òun ni àkọ́bí; ṣùgbọ́n, bí ó ti ṣe pé ó ba ibùsùn baba rẹ̀ jẹ́, a fi ogún ìbí rẹ̀ fún àwọn ọmọ Josẹfu ọmọ Israẹli: a kì yóò sì ka ìtàn ìdílé náà gẹ́gẹ́ bí ipò ìbí. 2 Nítorí Juda borí àwọn arákùnrin rẹ̀, àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni aláṣẹ ti ń jáde wá; ṣùgbọ́n ogún ìbí jẹ́ ti Josẹfu), 3 àwọn ọmọ Reubeni àkọ́bí Israẹli ni:
Hanoku àti Pallu, Hesroni àti Karmi.
4 Àwọn ọmọ Joeli:
Ṣemaiah ọmọ rẹ̀, Gogu ọmọ rẹ̀,
Ṣimei ọmọ rẹ̀. 5 Mika ọmọ rẹ̀,
Reaiah ọmọ rẹ̀, Baali ọmọ rẹ̀.
6 Beera ọmọ rẹ̀, tí Tiglat-Pileseri ọba Asiria kó ní ìgbèkùn lọ. Ìjòyè àwọn ọmọ Reubeni ni Beera jẹ́.
7 Àti àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa ìdílé wọn, nígbà tí a ń ka ìtàn ìdílé ìran wọn:
Jeieli àti Sekariah ni olórí, 8 àti Bela ọmọ Asasi ọmọ Ṣema, ọmọ Joeli.
Wọ́n tí ń gbé Aroeri àní títí dé Nebo àti Baali-Meoni. 9 Àti níhà àríwá, o tẹ̀dó lọ títí dé àtiwọ aginjù láti odò Eufurate; nítorí tí ẹran ọ̀sìn wọn pọ̀ sí i ní ilẹ̀ Gileadi.
10 Àti ní ọjọ́ Saulu, wọ́n bá àwọn ọmọ Hagari jagun, ẹni tí ó ṣubú nípa ọwọ́ wọn; wọ́n sì ń gbé inú àgọ́ wọn ní gbogbo ilẹ̀ àríwá Gileadi.
Ìdílé Gadi
11 Àti àwọn ọmọ Gadi ń gbé lékè wọn, ní ilẹ̀ Baṣani títí dé Saleka:
12 Joeli jẹ́ olórí, Ṣafamu ìran ọmọ, Janai, àti Ṣafati ni Baṣani,
13 Àti àwọn arákùnrin wọn ti ilẹ̀ àwọn baba wọn ní:
Mikaeli, Meṣullamu Ṣeba, Jorai, Jaka, Sia àti Eberi méje.
14 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Abihaili, ọmọ Huri, ọmọ Jeroa, ọmọ Gileadi, ọmọ Mikaeli, ọmọ Jeṣiṣai, ọmọ Jado ọmọ Busi.
15 Ahi, ọmọ Adbeeli, ọmọ Guni, olórí ilé àwọn baba wọn.
16 Wọ́n sì ń gbé Gileadi ní Baṣani àti nínú àwọn ìlú rẹ̀, àti nínú gbogbo ìgbèríko Ṣaroni, ní agbègbè wọn.
17 Gbogbo wọ̀nyí ni a kà nípa ìtàn ìdílé, ní ọjọ́ Jotamu ọba Juda, àti ní ọjọ́ Jeroboamu ọba Israẹli.
18 Àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase, nínú àwọn ọkùnrin alágbára tí wọ́n ń gbé asà àti idà, tí wọ́n sì ń fi ọrun tafà, tí wọ́n sì mòye ogun, jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ènìyàn ó lé ẹgbẹ̀rìnlélógún dín ogójì, tí ó jáde lọ sí ogún náà. 19 Wọ́n sì bá àwọn ọmọ Hagari jagun, pẹ̀lú Jeturi, àti Nafiṣi àti Nadabu. 20 Nígbà tí wọ́n sì rí ìrànlọ́wọ́ gbà si, a sì fi àwọn ọmọ Hagari lé wọn lọ́wọ́, àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn; nítorí tiwọn ké pe Ọlọ́run ní ogun náà, òun sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn; nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e. 21 Wọ́n sì kó ẹran ọ̀sìn wọn lọ; ìbákasẹ ẹgbàá-mẹ́dọ́gbọ̀n àti àgùntàn ọ̀kẹ́ méjìlá ó lé ẹgbàárùn-ún, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbàá, àti ènìyàn ọ̀kẹ́ márùn-ún. 22 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ṣubú tí a pa, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ogun náà, wọ́n sì jókòó ní ipò wọn títí di ìgbà ìkólọ sí ìgbèkùn.
Ààbọ̀ Ẹ̀yà Manase
23 Àwọn ọmọkùnrin ààbọ̀ ẹ̀yà Manase ń gbé ní ilẹ̀ náà: wọ́n bí sí i láti Baṣani títí dé Baali-Hermoni, àti Seniri àti títí dé òkè Hermoni.
24 Wọ̀nyí sì ni àwọn olórí ilé àwọn baba wọn. Eferi, Iṣi, Elieli, Asrieli, Jeremiah, Hodafiah àti Jahdieli àwọn alágbára akọni ọkùnrin, ọkùnrin olókìkí, àti olórí ilé àwọn baba wọn. 25 Wọ́n sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì ṣe àgbèrè tọ àwọn ọlọ́run ènìyàn ilẹ̀ náà lẹ́yìn, tí Ọlọ́run ti parun ní iwájú wọn. 26 Nítorí náà Ọlọ́run Israẹli ru ẹ̀mí Pulu ọba Asiria sókè (ẹ̀mí Tiglat-Pileseri ọba Asiria), ó si kó wọn lọ, àní àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase lọ sí ìgbèkùn. Ó sì kó wọn wá sí Hala, àti Habori, àti Harani, àti sí etí odò Gosani; títí dí òní yìí.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.