Beginning
Orúkọ rere sàn ju ọrọ̀ lọ
22 Yíyan orúkọ rere sàn ju púpọ̀ ọrọ̀ lọ,
àti ojúrere dára ju fàdákà àti wúrà lọ.
2 Ọlọ́rọ̀ àti tálákà péjọpọ̀:
Olúwa ni ẹlẹ́dàá gbogbo wọn.
3 Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀,
ó ṣé ara rẹ̀ mọ́:
ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n ní yà.
4 Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Olúwa ni ọrọ̀ ọlá, àti ìyè.
5 Ègún àti ìdẹ̀kùn ń bẹ ní ọ̀nà aláyídáyidà:
ẹni tí ó bá pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóò jìnnà sí wọn.
6 Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀:
nígbà tí ó bá dàgbà, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.
7 Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú,
ajigbèsè sì ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni tí a jẹ ní gbèsè.
8 (A)Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn ẹ̀ṣẹ̀, yóò ká asán:
ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò kùnà.
9 Ẹni tí ó ní ojú àánú ni a ó bùkún fún;
nítorí tí ó fi nínú oúnjẹ rẹ̀ fún olùpọ́njú.
10 Lé ẹlẹ́gàn sí ìta, ìjà yóò sì jáde;
nítòótọ́ ìjà àti ẹ̀gàn yóò dẹ́kun.
11 Ẹni tí ó fẹ́ ìwà funfun ti àyà,
tí ó sì ń sọ̀rọ̀ iyì jáde, ọba yóò ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀.
12 Ojú Olúwa pa ìmọ̀ mọ́,
ó sì yí ọ̀rọ̀ olùrékọjá pò.
13 Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún ń bẹ lóde!
Yóò pa mí ní ìgboro!”
14 Ẹnu àwọn àjèjì obìnrin, ihò jíjìn ni;
ẹni tí a ń bínú sí láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá ni yóò ṣubú sínú rẹ̀.
15 Àyà ọmọdé ni ìwà wèrè dì sí;
ṣùgbọ́n pàṣán ìtọ́ni ni yóò lé e jìnnà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
16 Ẹni tó ń ni tálákà lára láti ní ọrọ̀,
tí ó sì ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ,
yóò di aláìní bí ó ti wù kó rí.
Gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn.
Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n
17 Dẹtí rẹ sílẹ̀,
kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n,
kí o sì fi àyà rẹ sí ẹ̀kọ́ mi.
18 Nítorí ohun dídùn ni bí ìwọ bá pa wọ́n mọ́ ní inú rẹ;
nígbà tí a sì pèsè wọn tán ní ètè rẹ.
19 Kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ lè wà ní ti Olúwa,
èmi fihàn ọ́ lónìí, àní fún ọ.
20 Èmi kò ha ti kọ̀wé ohun dáradára
sí ọ ní ti ìmọ̀ràn àti ní ti ẹ̀kọ́,
21 kí ó lè mú ọ mọ ìdájú ọ̀rọ̀ òtítọ́;
kí ìwọ le máa fi ìdáhùn òtítọ́
fún àwọn tí ó rán ọ?
22 Má ṣe ja tálákà ní olè, nítorí tí ó jẹ́ tálákà:
bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe ni olùpọ́njú lára ní ibodè,
23 nítorí Olúwa yóò gbèjà wọn,
yóò sì gba ọkàn àwọn tí ń gba tiwọn náà.
24 Má ṣe bá oníbìínú ènìyàn ṣe ọ̀rẹ́;
má sì ṣe bá ọkùnrin onínú-fùfù rìn.
25 Kí ìwọ má ba à kọ́ ìwà rẹ̀, ìwọ a sì gba ìkẹ́kùn fún ara rẹ.
26 Má ṣe wà nínú àwọn tí ń ṣe ìgbọ̀nwọ́,
tàbí nínú àwọn tí ó dúró fún gbèsè.
27 Bí ìwọ kò bá ní nǹkan tí ìwọ ó fi san,
nítorí kín ni yóò ṣe gba ẹni rẹ kúrò lábẹ́ rẹ?
28 Má ṣe yẹ ààlà ilẹ̀ ìgbàanì,
tí àwọn baba rẹ ti pa.
29 Ìwọ ha rí ènìyàn tí ó ń fi àìṣe ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀?
Òun yóò dúró níwájú àwọn ọba;
òun kì yóò dúró níwájú àwọn ènìyàn lásán.
Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ohun àdídùn
23 Nígbà tí ìwọ bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun,
kíyèsi ohun tí ó wà níwájú rẹ gidigidi.
2 Ìwọ a sì fi ọ̀bẹ lé ara rẹ ní ọ̀fun,
bí ìwọ bá jẹ́ òkúndùn ènìyàn.
3 Má ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀:
nítorí pé oúnjẹ ẹ̀tàn ni.
4 Má ṣe ṣe làálàá láti lọ́rọ̀:
ṣíwọ́ kúrò nínú ọgbọ́n ara rẹ.
5 Ìwọ ó ha fi ojú rẹ lépa ohun tí kò sí?
Nítorí tí ọ̀rọ̀ hu ìyẹ́ apá fún ara rẹ̀,
ó sì ń fò bí idì ní ojú ọ̀run.
6 Má ṣe jẹ oúnjẹ ẹni tí ó háwọ́,
bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀.
7 Nítorí pé bí ẹni tí ń ṣírò ní ọkàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí:
“Máa jẹ, kí o sì máa mu,” ni ó ń wí fún ọ;
ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò pẹ̀lú rẹ.
8 Òkèlè tí ìwọ jẹ ni ìwọ ó pọ̀ jáde,
ìwọ a sì sọ ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀ nù.
9 Má ṣe sọ̀rọ̀ ní etí aṣiwèrè;
nítorí tí yóò gan ọgbọ́n ọ̀rọ̀ rẹ.
10 Má ṣe ṣí ààlà àtijọ́ kúrò;
má sì ṣe bọ́ sínú oko aláìní baba.
11 Nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára;
yóò gba ìjà wọn jà sí ọ.
12 Fi àyà sí ẹ̀kọ́,
àti etí rẹ sí ọ̀rọ̀-ìmọ̀.
13 Má ṣe fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kúrò lára ọmọdé,
nítorí pé bí ìwọ bá fi pàṣán nà án, òun kì yóò kú.
14 Bí ìwọ fi pàṣán nà án,
ìwọ ó sì gbà ọkàn rẹ̀ là kúrò ní ọ̀run àpáàdì.
Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n fún ọmọ rere
15 Ọmọ mi, bí ọkàn rẹ bá gbọ́n,
ọkàn mi yóò yọ̀, àní èmi pẹ̀lú.
16 Inú mi yóò sì dùn nígbà tí ètè rẹ̀ bá ń sọ̀rọ̀ títọ́.
17 Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ ó ṣe ìlara sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
ṣùgbọ́n kí ìwọ ó wà ní ìbẹ̀rù Olúwa,
ní ọjọ́ gbogbo.
18 Nítorí pé ìgbẹ̀yìn ń bẹ nítòótọ́;
ìrètí rẹ̀ kì yóò sì gé kúrò.
19 Gbọ́, ìwọ ọmọ mi, kí o sì gbọ́n,
kí o sì máa tọ́ àyà rẹ sí ọ̀nà títọ́.
20 Má ṣe wà nínú àwọn ọ̀mùtí;
àti àwọn wọ̀bìà alájẹkì ọ̀jẹun;
21 Nítorí pé ọ̀mùtí àti ọ̀jẹun ni yóò di tálákà;
ìmúni-tòògbé ní sì ń fi àkísà wọ ọkùnrin láṣọ.
22 Fetí sí ti baba rẹ tí ó bí ọ,
má sì ṣe gan ìyá rẹ, nígbà tí o bá gbó
23 Ra òtítọ́, kí o má sì ṣe tà á;
ra ọgbọ́n pẹ̀lú àti ẹ̀kọ́ àti òye.
24 Baba olódodo ni yóò yọ̀ gidigidi:
ẹni tí ó sì bí ọmọ ọlọ́gbọ́n,
yóò ní ayọ̀ nínú rẹ̀.
25 Jẹ́ kí baba rẹ àti ìyá rẹ ó yọ̀,
sì jẹ́ kí inú ẹni tí ó bí ọ dùn.
26 Ọmọ mi, fi àyà rẹ fún mi,
kí o sì jẹ́ kí ojú rẹ ní inú dídùn sí ọ̀nà mi.
27 Nítorí pé panṣágà obìnrin ọ̀gbun jíjìn ni;
àti àjèjì obìnrin kànga híhá ni.
28 Òun á sì ba ní bùba bí olè,
a sì sọ àwọn olùrékọjá di púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn.
29 Ta ni ó ni òsì? Ta ni ó ni ìbànújẹ́?
Ta ni ó ni ìjà? Ta ni ó ni asọ̀? Ta ni ó ni ọgbẹ́ láìnídìí?
30 Àwọn tí ó dúró pẹ́ níbi ọtí wáìnì;
àwọn tí ń lọ láti dán ọtí wáìnì àdàlú wò.
31 Ìwọ má ṣe wò ọtí wáìnì nígbà tí ó pọ́n,
nígbà tí ó bá ń fi àwọ̀ rẹ̀ hàn nínú ago,
tí a gbé e mì, tí ó ń dùn.
32 Níkẹyìn òun á bu ni ṣán bí ejò,
a sì bunijẹ bí i paramọ́lẹ̀.
33 Ojú rẹ yóò wò àwọn àjèjì obìnrin,
àyà rẹ yóò sì sọ̀rọ̀ àyídáyidà.
34 Nítòótọ́, ìwọ ó dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ ní àárín Òkun,
tàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ lókè-ọkọ̀.
35 Ìwọ ó sì wí pé, “Wọ́n lù mí; kò dùn mí;
wọ́n lù mí, èmi kò sì mọ̀:
nígbà wo ni èmi ó jí?
Èmi ó tún máa wá òmíràn láti mu.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.