Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Beginning

Read the Bible from start to finish, from Genesis to Revelation.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Esekiẹli 31-33

Òpépé igi Sedari ni Lebanoni

31 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kẹta ọdún kọkànlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: “Ọmọ ènìyàn, sọ fún Farao ọba Ejibiti àti sí ìjọ rẹ̀:

“ ‘Ta ní a le fiwé ọ ní ọláńlá?
Kíyèsi Asiria, tí ó jẹ́ igi kedari ni
    Lebanoni ní ìgbà kan rí,
pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka dáradára tí ó ṣẹ́ ìji bo igbó náà;
    tí ó ga sókè,
    òkè rẹ̀ lókè ni ewé tí ó nípọn wà.
Omi mú un dàgbàsókè:
    orísun omi tí ó jinlẹ̀ mú kí o dàgbàsókè;
àwọn odo rẹ̀ ń sàn yí ìdí rẹ̀ ká,
    ó sì rán ìṣàn omi rẹ̀ sí gbogbo igi orí pápá.
Nítorí náà ó ga sí òkè fíofío
    ju gbogbo igi orí pápá lọ;
ẹ̀ka rẹ̀ pọ̀ sí i:
    àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gùn,
    wọn tẹ́ rẹrẹ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.
(A)Ẹyẹ ojú ọ̀run
    kọ ilé sí ẹ̀ka rẹ̀
gbogbo ẹranko igbó
    ń bímọ ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀;
gbogbo orílẹ̀-èdè ńlá
    ń gbé abẹ́ ìji rẹ̀.
Ọláńlá ní ẹwà rẹ̀ jẹ́,
    pẹ̀lú títẹ́ rẹrẹ ẹ̀ka rẹ̀,
nítorí gbòǹgbò rẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀
    sí ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi wà.
(B)Àwọn igi kedari nínú ọgbà Ọlọ́run
    kò lè è bò ó mọ́lẹ̀;
tàbí kí àwọn igi junifa
    ṣe déédé pẹ̀lú ẹ̀ka rẹ̀,
tàbí kí a fi igi títẹ́ rẹrẹ wé ẹ̀ka rẹ̀,
    kò sí igi nínú ọgbà Ọlọ́run
    tí ó dà bí rẹ̀ ní ẹwà rẹ̀.
Mo mú kí ó ní ẹwà
    pẹ̀lú ẹ̀ka lọ́pọ̀lọpọ̀
tó fi jẹ́ ìlara àwọn igi gbogbo ní Edeni
    tí í ṣe ọgbà Ọlọ́run.

10 “ ‘Nítorí náà, èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí; Nítorí pé ó ga lọ sókè fíofío, tí ó sì gbé òkè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn lọ, àti nítorí pé gíga rẹ mú kí ó gbéraga, 11 Mo fi lé alákòóso àwọn orílẹ̀-èdè náà lọ́wọ́, fún un láti fi ṣe ẹ̀tọ́ fún un gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú rẹ̀. Mo pa á tì sí ẹ̀gbẹ́ kan, 12 àwọn orílẹ̀-èdè àjèjì aláìláàánú jùlọ ké e lulẹ̀, wọn sì fi kalẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ṣubú sórí òkè àti sí gbogbo àárín àwọn òkè; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tí ó ṣẹ nà sílẹ̀ ní gbogbo àlàfo jíjìn ilẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé jáde kúrò ní abẹ́ ìji rẹ̀ wọn sì fi sílẹ̀. 13 Gbogbo àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ṣe àtìpó ni orí igi tí ó ṣubú lulẹ̀ náà, gbogbo àwọn ẹranko igbó wà ní àárín ẹ̀ka rẹ̀. 14 Nítorí náà kò sí igi mìíràn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tí ó lè fi ìgbéraga ga sókè fíofío, tí yóò sì gbé sókè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn lọ. Kò sí igi mìíràn tí ó ní omi tó bẹ́ẹ̀ tí ó lè ga tó bẹ́ẹ̀; gbogbo wọn ni a kádàrá ikú fún, fún ìsàlẹ̀ ilẹ̀, ní àárín àwọn alààyè ènìyàn, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ọ̀gbun ní ìsàlẹ̀.

15 “ ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: ní ọjọ́ ti a mú u wá sí isà òkú mo fi ọ̀fọ̀ ṣíṣe bo orísun omi jíjìn náà; Mo dá àwọn ìṣàn omi rẹ̀ dúró, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi rẹ̀ ní a dí lọ́nà. Nítorí rẹ̀ mo fi ìwúwo ọkàn wọ Lebanoni ní aṣọ, gbogbo igi igbó gbẹ dànù. 16 Mo mú kí orílẹ̀-èdè wárìrì sì ìró ìṣubú rẹ̀ nígbà tí mo mú un wá sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun ìsàlẹ̀. Nígbà náà gbogbo igi Edeni, àṣàyàn àti èyí tí ó dára jùlọ nínú Lebanoni, gbogbo igi tí ó ní omi dáradára ni a tù nínú ni ayé ìsàlẹ̀. 17 Àwọn tí ó ń gbé ní abẹ́ òjìji rẹ̀, àwọn àjèjì rẹ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè náà, ti lọ sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú rẹ̀, ní dídárapọ̀ mọ́ àwọn tí a fi idà pa.

18 “ ‘Èwo lára igi Edeni ní a lè fiwé ọ ní dídán àti ọláńlá? Síbẹ̀ ìwọ, gan an wá sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn igi Edeni lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀; ìwọ yóò sùn ni àárín àwọn aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.

“ ‘Èyí yìí ní Farao àti ìjọ rẹ̀, ní Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

Ìpohùnréré ẹkún fún Farao

32 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kejìlá, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: “Ọmọ ènìyàn, ṣe ìpohùnréré ẹkún nítorí Farao ọba Ejibiti kí o sì wí fún un:

“ ‘Ìwọ dàbí kìnnìún láàrín àwọn
    orílẹ̀-èdè náà;
ìwọ dàbí ohun ẹ̀mí búburú inú àwọn omi okun to ń lọ
    káàkiri inú àwọn odò rẹ,
ìwọ fi ẹsẹ̀ rẹ tẹ omi
    láti mú kí àwọn odò ní ẹrẹ̀.

“ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìpéjọ ènìyàn
    èmi yóò da àwọ̀n mi bò ọ́
    wọn yóò sì fà ọ́ sókè nínú àwọ̀n mi.
Èmi yóò jù ọ́ sí orí ilẹ̀
    èmi yóò sì fà ọ́ sókè sí orí pápá gbangba.
Èmi yóò jẹ́ kí gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ṣe
    àtìpó ní orí rẹ.
Gbogbo àwọn ẹranko ayé yóò fi
    ìwọra gbé ara wọn lórí rẹ.
Èmi yóò tan ẹran-ara rẹ ká sórí
    àwọn òkè gíga
ìyókù ara rẹ ní wọn yóò fi kún
    àwọn àárín àwọn òkè gíga
Ẹ̀jẹ̀ rẹ ti ń sàn ní èmi yóò sì fi rin ilẹ̀ náà
    gbogbo ọ̀nà sí orí àwọn òkè gíga,
    àwọn àlàfo jíjìn ní wọn yóò kún fún ẹran-ara rẹ.
Nígbà tí mo bá fọ́n ọ jáde, èmi yóò pa ọ̀run dé
    àwọn ìràwọ̀ wọn yóò sì ṣókùnkùn;
èmi yóò sì fi ìkùùkuu bo oòrùn
    òṣùpá kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀
Gbogbo ìmọ́lẹ̀ títàn ní ojú ọ̀run
    ni èmi yóò mú ṣókùnkùn lórí rẹ;
èmi yóò mú òkùnkùn wá sórí ilẹ̀ rẹ,
    ni Olúwa Olódùmarè wí
Èmi yóò da ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn rú
    nígbà tí mo bá mú ìparun rẹ wá
ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ
    kò í tí ì mọ̀.
10 Èmi yóò mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn dẹ́rùbà ọ́,
    àwọn ọba wọn yóò sì wárìrì fún
ìbẹ̀rù pẹ̀lú ìpayà nítorí rẹ,
    nígbà tí mo bá ju idà mi ní iwájú wọn
Ní ọjọ́ ìṣubú rẹ
    ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú wọn yóò wárìrì
    ní gbogbo ìgbà fún ẹ̀mí rẹ.

11 “ ‘Nítorí èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Idà ọba Babeli
    yóò wá sí orí rẹ,
12 Èmi yóò mú kí ìjọ ènìyàn rẹ kí ó
    tí ipa idà àwọn alágbára ènìyàn ṣubú
àwọn orílẹ̀-èdè aláìláàánú jùlọ.
    Wọn yóò tú ìgbéraga Ejibiti ká,
    gbogbo ìjọ rẹ ní a yóò dá ojú wọn bolẹ̀.
13 Gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ ni èmi yóò parun
    ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi
kì i ṣe ẹsẹ̀ ènìyàn ní yóò tẹ ibẹ̀
    ẹsẹ̀ ẹran ọ̀sìn kì yóò sì mú kí ibẹ̀ ni ẹrọ̀fọ̀.
14 Lẹ́yìn náà èmi yóò mú kí omi rẹ̀ tòrò
    kí àwọn odò rẹ̀ kí o sàn bí epo,
    ni Olúwa Olódùmarè wí.
15 Nígbà tí mo bá sọ Ejibiti di ahoro,
    tí mo sì kó gbogbo ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀ náà kúrò.
Nígbà tí mo bá gé àwọn olùgbé ibẹ̀ lulẹ̀,
    nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’

16 “Èyí yìí ni ẹkún tí a yóò sun fún un. Àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀-èdè yóò sun ún; nítorí Ejibiti àti gbogbo ìjọ rẹ, wọn yóò sun ún, ní Olúwa Olódùmarè wí.”

17 Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mí wá: 18 “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún lórí Ejibiti kí o sì ránṣẹ́ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ àti òun àti àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀-èdè alágbára, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ìsàlẹ̀, kòtò. 19 Sọ fún wọn, ‘Ǹjẹ́ ìwọ ní ojúrere jù àwọn tí o kù lọ? Lọ sí ìsàlẹ̀ kí a sì tẹ́ ọ sí àárín àwọn aláìkọlà náà.’ 20 Wọn yóò ṣubú láàrín àwọn tí a fi idà pa. A fa idà yọ; jẹ́ kí a wọ́ Ejibiti kúrò pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀. 21 Láti inú isà òkú alágbára tí í ṣe aṣáájú yóò sọ nípa Ejibiti àti àwọn àlejò rẹ̀, ‘Wọn ti wá sí ìsàlẹ̀, wọn sì sùn pẹ̀lú aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.’

22 “Asiria wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo jagunjagun rẹ̀; àwọn isà òkú àwọn tí a ti pa sì yí i ká, gbogbo àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú. 23 Isà òkú wọn wà ní ibi tí ó jinlẹ̀ gan an nínú kòtò. Gbogbo àwọn tí ó ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè ní a pa, tí ó ti ipa idà ṣubú.

24 “Elamu wà níbẹ̀, o yí isà òkú rẹ̀ ká pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀. Gbogbo wọn ni a pa, àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú. Gbogbo àwọn tí ó ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè lọ sí ìsàlẹ̀ láìkọlà sí abẹ́ ilẹ̀. Wọ́n gba ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò. 25 A ṣe ibùsùn fún un láàrín àwọn tí a pa, pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀ tí ó yí isà òkú ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, tí a fi idà pa. Nítorí pé a tan ẹ̀rù wọn ká ilẹ̀ alààyè, wọn ru ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò; a tẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn tí a pa.

26 “Meṣeki àti Tubali wà níbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ogun wọn yí isà òkú wọn ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, wọ́n fi idà pa wọ́n nítorí ẹ̀rù tiwọn tàn ká ilẹ̀ alààyè. 27 Wọn kì yóò sì dùbúlẹ̀ ti àwọn tí ó ṣubú nínú àwọn aláìkọlà, tí wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí ipò òkú pẹ̀lú ìhámọ́ra ogun wọn, wọ́n tí fi idà wọn rọ orí wọn. Ṣùgbọ́n àìṣedéédéé wọn yóò wà ní orí egungun wọn—bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ ẹ̀rù àwọn alágbára ní ilẹ̀ alààyè.

28 “Ìwọ náà, Farao, ní yóò ṣẹ, ti yóò dùbúlẹ̀ láàrín aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.

29 “Edomu wà níbẹ̀, àwọn ọba rẹ̀ àti gbogbo ọmọbìnrin ọba; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní agbára, a tẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa. Wọn dùbúlẹ̀ pẹ̀lú aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn ti o lọ sínú kòtò.

30 “Gbogbo àwọn ọmọ-aládé ilẹ̀ àríwá àti gbogbo àwọn ará Sidoni wà níbẹ̀; wọn lọ sí ìsàlẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí a pa ní ìtìjú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ṣe okùnfà ẹ̀rù pẹ̀lú agbára wọn. Wọn sùn ní àìkọlà pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa, wọn sì ru ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò.

31 “Farao, òun àti gbogbo jagunjagun rẹ̀ yóò rí wọn, a yóò sì tù ú nínú nítorí gbogbo ogun rẹ̀ tí a fi idà pa, ní Olúwa Olódùmarè wí. 32 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè, Farao àti gbogbo ogun rẹ̀ ni a yóò tẹ́ sí àárín aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa ní Olúwa Olódùmarè wí.”

Esekiẹli gẹ́gẹ́ bi olùṣọ́ Israẹli

33 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: “Ọmọ ènìyàn sọ̀rọ̀ sí àwọn ènìyàn ilẹ̀ rẹ kí ó sì sọ fún wọn: ‘Nígbà tí mo bá fi idà kọlu ilẹ̀ kan, tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yan ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin wọn láti jẹ́ alóre wọn, tí ó sì rí i pé idà ń bọ̀ lórí ilẹ̀ náà, tí ó sì fọn ìpè láti kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, nígbà náà tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ìpè ṣùgbọ́n tí kò gbọ́ ìkìlọ̀, tí idà náà wá tí ó sì gba ẹ̀mí rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà lórí ara rẹ̀. Nítorí tí ó gbọ́ ohùn ìpè ṣùgbọ́n tí kò sì gbọ́ ìkìlọ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní orí ara rẹ̀: Tí ó bá gbọ́ ìkìlọ̀, òun ìbá ti gba ara rẹ̀ là. Ṣùgbọ́n bí alóre bá rí idà tí o ń bọ̀, tí kò sì fọn ìpè láti ki àwọn ènìyàn nílọ̀, tí idà náà wá, tí ó sì gba ẹ̀mí ọ̀kan nínú wọn, a yóò mú ọkùnrin náà lọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n èmi yóò béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.’

“Ọmọ ènìyàn, èmi fi ọ ṣe alóre fún ilé Israẹli; nítorí náà gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo sọ, kí o sì fún wọn ni ìkìlọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi. Nígbà ti mo bá sọ fún ẹni búburú pé, ‘A! Ẹni búburú, ìwọ yóò kú dandan,’ ti ìwọ kò sì sọ̀rọ̀ síta láti yí i lọ́kàn padà kúrò ni ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ẹni búburú náà yóò kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èmi yóò sì béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá kìlọ̀ fún ẹni búburú láti yí padà kúrò ni ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, tí òun kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, òun yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ ti gba ọkàn rẹ̀ là.

10 “Ọmọ ènìyàn; sọ fún ilé Israẹli, ‘Èyí yìí ní ìwọ sọ: “Àwọn ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ wa tẹ orí wa ba, àwa sì ń ṣòfò dànù nítorí wọn. Bá wó wa ni a ṣe lè yè?” ’ 11 Sọ fún wọn pé, ‘Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè ni Olúwa Olódùmarè wí, èmi kò ní inú dídùn sí ikú ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, kí wọ̀nyí padà kúrò ní ọ̀nà wọn gbogbo kì wọn kì ó sì yè. Yí! Yípadà kúrò ni ọ̀nà búburú gbogbo! Kí ló dé tí ìwọ yóò kú Háà! Israẹli?’

12 “Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọ fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ rẹ, ‘Ìṣòdodo ti olódodo ènìyàn kì yóò gbà á nígbà tí òun bá ṣe àìgbọ́ràn, ìwà búburú ènìyàn búburú kì yóò mú kí o ṣubú nígbà tí ó bá yí padà kúrò nínú rẹ̀. Bí olódodo ènìyàn bá ṣẹ̀, a kò ni jẹ́ kí ó yè nítorí òdodo rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀.’ 13 Bí mo bá sọ fún olódodo ènìyàn pé òun yóò yè, ṣùgbọ́n nígbà náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé òdodo rẹ̀ tí ó sì ṣe búburú, a kò ní rántí nǹkan kan nínú iṣẹ́ òdodo tí o ti ṣe sẹ́yìn; òun yóò kú nítorí búburú tí ó ṣe. 14 Bí mo bá sọ fún ènìyàn búburú pé, ‘Ìwọ yóò kú dandan,’ ṣùgbọ́n tí ó bá yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ti o sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí o yẹ. 15 Tí ó bá mu ògo padà, tí o sì da ohun tí o ti jí gbé padà, tí ó sì tẹ̀lé òfin tí ó ń fún ni ní ìyè, tí kò sì ṣe búburú, òun yóò yè dandan; òun kì yóò kú. 16 A kò ní rántí ọ̀kan nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá. Ó ti ṣe èyí tí ó tọ àti èyí tí o yẹ; òun yóò sì yè dájúdájú.

17 “Síbẹ̀ àwọn ènìyàn ilẹ̀ rẹ sọ pé, ‘ọ̀nà Olúwa kò tọ́.’ Ṣùgbọ́n ọ̀nà tí àwọn ní ó tọ́. 18 Bí olódodo ènìyàn ba yípadà kúrò nínú òdodo rẹ̀, tí o sì ṣe búburú, òun yóò kú nítorí rẹ̀. 19 Bí ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú búburú rẹ̀, tí ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ, òun yóò yè nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀. 20 Síbẹ̀, ilé Israẹli ìwọ wí pé, ‘ọ̀nà Olúwa ki i ṣe òtítọ́.’ Ṣùgbọ́n èmi yóò ṣe ìdájọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ ṣe rí.”

A ṣàlàyé ìṣubú Jerusalẹmu

21 Ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kẹwàá, ọdún kejìlá ìkólọ wa, ọkùnrin kan tí ó sá kúrò ni Jerusalẹmu wá sọ́dọ̀ mi, ó sì wí pé, “Ìlú ńlá náà ti ṣubú!” 22 Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó ku ọ̀la tí ẹni tí ó sálọ náà yóò dé, ọwọ́ Olúwa sì níbẹ̀ lára mi, o sì ya ẹnu mi ki ọkùnrin náà tó wá sọ́dọ̀ mi ní òwúrọ̀. Ẹnu mí sì ṣí, èmi kò sì yadi mọ́.

23 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 24 “Ọmọ ènìyàn, àwọn ènìyàn tí ó ń gbé nínú ìparun ní ilẹ̀ Israẹli ń wí pé, ‘Abrahamu jẹ́ ọkùnrin kan, síbẹ̀ o gba ilẹ̀ ìní náà. Ṣùgbọ́n àwa pọ̀: Lóòótọ́ a ti fi ilẹ̀ náà fún wa gẹ́gẹ́ bí ìní wa.’ 25 Nítorí náà sọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Níwọ́n ìgbà tí ẹ̀yin jẹ ẹran pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ni inú rẹ̀, tí ẹ̀yin sì wó àwọn ère yín, tí ẹ sì ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, Ẹ̀yin yóò ha gba ilẹ̀ náà? 26 Ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀lé idà yín, ẹ̀yin ṣe nǹkan ìríra, ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú yín ba á obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́. Ẹ̀yin yóò ha gba ilẹ̀ náà?’

27 “Sọ èyí fún wọn: ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Bí mo ti wà láààyè, àwọn tí ó kúrò nínú ìparun yóò ti ipa idà ṣubú, àwọn tí ẹranko búburú yóò pajẹ, àwọn tí ó sì wà ní ilé ìṣọ́ àti inú ihò òkúta ni àjàkálẹ̀-ààrùn yóò pa. 28 Èmi yóò mú kí ilẹ̀ náà di ahoro, ọ̀ṣọ́ ńlá agbára rẹ̀ kì yóò sí mọ́, àwọn òkè Israẹli yóò sì di ahoro, tí ẹnikẹ́ni kò ní le là á kọjá. 29 Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá mú ilẹ̀ náà di ahoro nítorí gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ti ṣe.’

30 “Ní tìrẹ, ọmọ ènìyàn, àwọn ènìyàn ìlú n sọ̀rọ̀ nípa rẹ ní ẹ̀gbẹ́ ògiri àti ní ẹnu-ọ̀nà ilé wọn, wọ́n ń sọ sí ara wọn wí pé, ‘Ẹ wá gbọ́ iṣẹ́ ti a ran láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá.’ 31 Àwọn ènìyàn mi wá sọ́dọ̀ rẹ, gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe ń ṣe, wọn sì jókòó níwájú rẹ láti fetísí ọ̀rọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò mú wá sí ìṣe. Ẹnu wọn ni wọ́n fi n sọ̀rọ̀ ìfọkànsìn, ṣùgbọ́n ọkàn wọn ní ìwọra èrè tí kò tọ́. 32 Nítòótọ́ lójú wọn, ìwọ jẹ́ ẹni kan tí ó ń kọrin ìfẹ́ pẹ̀lú ohun dídára àti ohun èlò orin kíkọ, nítorí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ṣùgbọ́n wọn kò mu wá sí ìṣe.

33 “Nígbà tí gbogbo ìwọ̀nyí bá ṣẹ tí yóò sì ṣẹ dandan, nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé wòlíì kan ti wa láàrín wọn rí.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.