Beginning
Sennakeribu dẹ́rùba Jerusalẹmu
36 (A)Ní ọdún kẹrìnlá ìjọba Hesekiah, Sennakeribu ọba Asiria kọlu gbogbo àwọn ìlú olódi ní ilẹ̀ Juda ó sì kó gbogbo wọn. 2 Lẹ́yìn náà, ọba Asiria rán olórí ogun rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ-ogun láti Lakiṣi sí ọba Hesekiah ní Jerusalẹmu. Nígbà tí ọ̀gágun náà dúró níbi ojúṣàn adágún ti apá òkè, ní ojú ọ̀nà sí pápá Alágbàfọ̀, 3 Ṣebna Eliakimu ọmọ Hilkiah alábojútó ààfin, Ṣebna akọ̀wé, àti Joah ọmọ Asafu akọ̀wé jáde lọ pàdé rẹ̀.
4 Ọ̀gágun náà sọ fún wọn wí pé, “Ẹ sọ fún Hesekiah,
“ ‘Èyí yìí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Asiria sọ pé: Lórí i kí ni ìwọ gbé ìgbẹ́kẹ̀lé tìrẹ yìí lé? 5 Ìwọ sọ wí pé ìwọ ní ète àti agbára ogun—ṣùgbọ́n ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ asán. Ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tí ìwọ fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi? 6 Wò ó nísinsin yìí, ìwọ gbẹ́kẹ̀lé Ejibiti ẹ̀rún igi ọ̀pá lásán tí í gún ni lọ́wọ́ tí í sì í dọ́gbẹ́ sí ni lára tí a bá gbára lé e! Bẹ́ẹ̀ ni Farao ọba Ejibiti sí àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé e. 7 Bí o bá sì sọ fún mi pé, “Àwa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run wa,” kì í ṣe òun ni Hesekiah ti mú àwọn ibi gíga àti pẹpẹ rẹ̀ kúrò, tí ó sì wí fún Juda àti Jerusalẹmu pé, “Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ yìí”?
8 “ ‘Ẹ wá nísinsin yìí, bá ọ̀gá mi pa ìmọ̀ pọ̀, ọba Asiria: Èmi yóò fún ọ ní ẹgbàá ẹṣin bí ìwọ bá le è fi agẹṣin lé wọn lórí! 9 Báwo ni ẹ ṣe lè lé ẹyọ kan ṣoṣo padà nínú èyí tí ó kéré jù nínú àwọn balógun olúwa mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé Ejibiti fún kẹ̀kẹ́-ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin? 10 Síwájú sí i, ǹjẹ́ mo wa lè wá bá ilẹ̀ yìí jà kí n sì pa á run láìsí Olúwa? Olúwa fún rara rẹ̀ ló sọ pé kí n bá orílẹ̀-èdè yìí jà kí n sì pa á run.’ ”
11 Lẹ́yìn náà ni Eliakimu, Ṣebna àti Joah sọ fún ọ̀gágun náà pé, “Jọ̀wọ́ máa bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Aramaiki, nítorí pé àwa gbọ́ ọ. Má ṣe bá wa sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu ní etí àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ògiri mọ́.”
12 Ṣùgbọ́n ọ̀gágun náà dá wọn lóhùn pé, “Ṣé ẹ rò wí pé ọ̀gá yín àti ẹ̀yin nìkan ni ọ̀gá mi rán mi sí láti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ni, tí kì í sì ṣe sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí ó jókòó lórí ògiri, àwọn tí ó jẹ́ pé wọn yóò jẹ ìgbẹ́ wọn tí wọ́n yóò sì mu ìtọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà?”
13 Lẹ́yìn náà ni ọ̀gágun náà dìde tí ó sì ké síta ní èdè Heberu pé, “Ẹ gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Asiria! 14 Ohun tí ọba wí nìyìí: Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah tàn yín jẹ. Òun kò le è gbà yín sílẹ̀! 15 Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah rọ̀ yín láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa nígbà tí ó sọ pé, ‘Olúwa yóò kúkú gbà wá; a kì yóò fi ìlú yìí lé ọba Asiria lọ́wọ́.’
16 “Ẹ má ṣe tẹ́tí sí Hesekiah. Ohun tí ọba Asiria wí nìyìí: Ẹ fi ẹ̀bùn bá mi rẹ́, kí ẹ sì jáde tọ̀ mí wá. Lẹ́yìn náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò sì jẹ nínú àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni yóò sì mu omi nínú kànga rẹ̀, 17 títí tí èmi yóò fi mú un yín lọ sí ilẹ̀ kan tí ó dàbí i tiyín, ilẹ̀ tí ó ní irúgbìn oníhóró àti wáìnì tuntun, ilẹ̀ tí ó ní àkàrà àti ọgbà àjàrà.
18 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah ṣì yín lọ́nà nígbà tí ó sọ wí pé, ‘Olúwa yóò gbà wá.’ Ǹjẹ́ ọlọ́run orílẹ̀-èdè kan ha ti gbà á kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria bí? 19 Níbo ni àwọn òrìṣà Hamati àti Arpadi ha wà? Níbo ni àwọn òrìṣà Sefarfaimi ha wà? Ǹjẹ́ wọn ti já Samaria gbà kúrò lọ́wọ́ mi bí? 20 Èwo nínú àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ló ha ti dáàbò bo ilẹ̀ ẹ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi? Báwo ni Olúwa ṣe wá le gba Jerusalẹmu kúrò lọ́wọ́ mi?”
21 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà dákẹ́ rọ́rọ́ wọn kò sì mú èsì kankan wá, nítorí ọba ti pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe dá a lóhùn.”
22 Lẹ́yìn náà ni Eliakimu ọmọ Hilkiah alákòóso ààfin, Ṣebna akọ̀wé àti Joah ọmọ Asafu akọ̀wé àkọsílẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekiah pẹ̀lú aṣọ wọn ní fífàya, wọ́n sì sọ ohun tí ọ̀gágun ti wí.
A sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìdáǹdè Jerusalẹmu
37 Nígbà tí ọba Hesekiah gbọ́ èyí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara rẹ̀, ó sì wọ inú tẹmpili Olúwa lọ. 2 Òun sì rán Eliakimu alákòóso ààfin, Ṣebna akọ̀wé, àti aṣíwájú àwọn àlùfáà, gbogbo wọn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì Isaiah ọmọ Amosi. 3 Wọ́n sọ fún un pé, “Báyìí ni Hesekiah wí: ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ ìbànújẹ́, ìbáwí àti ẹ̀gàn gẹ́gẹ́ bí ìgbà ìbí àwọn ọmọdé tí kò sì ṣí agbára láti bí wọn. 4 Ó lè jẹ́ pé Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀gágun ẹni tí ọ̀gá rẹ̀ ọba Asiria ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè ṣe ẹlẹ́yà, àti pé òun ni yóò bá a wí nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Nítorí náà gbàdúrà fún àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n sì wà láààyè.”
5 Nígbà tí àwọn ìjòyè ọba Hesekiah dé ọ̀dọ̀ Isaiah, 6 Isaiah sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé, ‘Ohun tí Olúwa sọ nìyìí: Má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba Asiria tí ó wà nínú ìdè ti fi sọ̀rọ̀-òdì sí mi. 7 Tẹ́tí sílẹ̀! Èmi yóò fi ẹ̀mí kan sínú rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bí o bá ti gbọ́ ìròyìn kan, òun yóò padà sí orílẹ̀-èdè rẹ̀, níbẹ̀ ni n ó sì ti jẹ́ kí wọn ké e lulẹ̀ pẹ̀lú idà.’ ”
8 Nígbà tí ọ̀gágun gbọ́ pé ọba Asiria ti fi Lakiṣi sílẹ̀, ó padà sẹ́yìn, ó sì bá ọba tí ń bá Libina jà.
9 Ní àkókò yìí Sennakeribu gbọ́ ìròyìn kan pé Tirakah ará Kuṣi ọba Ejibiti ń jáde bọ̀ wá bá òun jà. Nígbà tí ó gbọ́ èyí, ó rán oníṣẹ́ sí Hesekiah pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: 10 “Ẹ sọ fún Hesekiah ọba Juda pé: Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tàn ọ́ jẹ nígbà tí ó sọ pé, ‘a kì yóò jọ̀wọ́ Jerusalẹmu fún ọba Asiria.’ 11 Dájúdájú, ìwọ ti gbọ́ ohun tí ọba Asiria ti ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó pa wọ́n run pátápátá. Ǹjẹ́ a ó ha dá ọ nídè bí? 12 Ǹjẹ́ àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi parun ha gbà wọ́n sílẹ̀ bí àwọn òrìṣà Gosani, Harani, Reṣefu àti àwọn ènìyàn Edeni tí wọ́n wà ní Teli-Assari? 13 Níbo ni ọba Hamati wà, ọba Arpadi, ọba ìlú Sefarfaimi tàbí Hena tàbí Iffa?”
Àdúrà Hesekiah
14 Hesekiah gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ ó sì kà á. Lẹ́yìn náà ni ó gòkè lọ sí tẹmpili Olúwa ó sì tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú Olúwa. 15 Hesekiah sì gbàdúrà sí Olúwa: 16 Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli, tí ó gúnwà láàrín àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lórí i gbogbo ìjọba orílẹ̀ ayé. Ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé. 17 Tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ Olúwa, kí o gbọ́, ya ojú rẹ, Ìwọ Olúwa, kí o rí i; tẹ́tí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí Sennakeribu rán láti fi àbùkù kan Ọlọ́run alààyè.
18 “Òtítọ́ ni Olúwa pé àwọn ọba Asiria ti sọ àwọn ènìyàn àti ilẹ̀ wọn di asán. 19 Wọ́n ti da àwọn òrìṣà wọn sínú iná wọ́n sì ti pa wọ́n run, nítorí àwọn wọ̀nyí kì í ṣe ọlọ́run bí kò ṣe igi àti òkúta lásán, tí a ti ọwọ́ ènìyàn ṣe. 20 Nísinsin yìí, ìwọ Olúwa, Ọlọ́run wa, gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé yóò fi mọ̀ pé Ìwọ, Ìwọ nìkan, Olúwa ni Ọlọ́run.”
Ìṣubú Sennakeribu
21 Lẹ́yìn náà Isaiah ọmọ Amosi rán iṣẹ́ kan sí Hesekiah: “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli sọ pé: Nítorí pé ìwọ ti gbàdúrà sí mi nípa Sennakeribu ọba Asiria, 22 èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀:
“Wúńdíá ọmọbìnrin Sioni
ti kẹ́gàn rẹ, ó sì ti fi ọ ṣe ẹlẹ́yà.
Ọmọbìnrin Jerusalẹmu
ti mi orí rẹ̀ bí ó ti ń sálọ.
23 Ta ni ìwọ ti bú tí ìwọ sì ti sọ̀rọ̀-òdì sí?
Sí ta ní ìwọ ti gbé ohùn rẹ sókè
tí o sì gbé ojú rẹ sókè ní ìgbéraga?
Sí Ẹni Mímọ́ Israẹli!
24 Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ
Ìwọ ti sọ̀rọ̀ búburú sí Olúwa.
Tì wọ sì wí pé,
‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ mi
ni èmi sì fi dé orí àwọn òkè ńlá,
sí ibi gíga jùlọ Lebanoni.
Èmi a sì ké igi kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀,
àti ààyò igi firi rẹ̀.
Èmi ti dé ibi rẹ̀ tí ó ga jùlọ,
igbó rẹ̀ tí ó dára jùlọ.
25 Èmi ti gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì
mo sì mu omi ní ibẹ̀,
pẹ̀lú àtẹ́lẹsẹ̀ mi
Èmi ti gbẹ́ gbogbo omi àwọn odò Ejibiti.’
26 “Ṣé o kò tí ì gbọ́?
Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti fìdí rẹ̀ mulẹ̀.
Láti ìgbà pípẹ́ ni mo ti ṣètò rẹ̀;
ní àkókò yìí ni mo mú wá sí ìmúṣẹ,
pé o ti sọ àwọn ìlú olódi di
àkójọpọ̀ àwọn òkúta
27 Àwọn ènìyàn, tí agbára ti wọ̀ lẹ́wù,
ni wọ́n banújẹ́ tí a sì dójútì.
Wọ́n dàbí ohun ọ̀gbìn nínú pápá,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀jẹ̀lẹ̀ èhíhù tuntun,
gẹ́gẹ́ bí i koríko tí ó ń hù lórí òrùlé,
tí ó jóná kí ó tó dàgbàsókè.
28 “Ṣùgbọ́n mo mọ ibi tí o wà
àti ìgbà tí o wá tí o sì lọ
àti bí inú rẹ ṣe ru sí mi.
29 Nítorí pé inú rẹ ru sí mi
àti nítorí pé orí kunkun rẹ ti
dé etí ìgbọ́ mi,
Èmi yóò fi ìwọ̀ mi sí ọ ní imú,
àti ìjẹ mi sí ọ lẹ́nu,
èmi yóò sì jẹ́ kí o padà
láti ọ̀nà tí o gbà wá.
30 “Èyí ni yóò ṣe ààmì fún ọ Ìwọ Hesekiah:
“Ní ọdún yìí, ìwọ yóò jẹ ohun tí ó hù fúnrarẹ̀,
àti ní ọdún kejì ohun tí ó jáde láti ara rẹ.
Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ gbìn kí ẹ sì kórè,
ẹ gbin ọgbà àjàrà kí ẹ sì jẹ èso wọn.
31 Lẹ́ẹ̀kan sí i, àṣẹ́kù láti ilé Juda
yóò ta gbòǹgbò nísàlẹ̀ yóò sì ṣo èso lókè.
32 Nítorí láti Jerusalẹmu ni àwọn àṣẹ́kù yóò ti wá,
àti láti òkè Sioni ni ikọ̀ àwọn tí ó sálà.
Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ.
33 “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọba Asiria:
“Òun kì yóò wọ ìlú yìí wá
tàbí ta ẹyọ ọfà kan níhìn-ín
Òun kì yóò wá síwájú rẹ pẹ̀lú asà
tàbí kí ó kó dágunró sílẹ̀ fún un.
34 Nípa ọ̀nà tí ó gbà wá náà ni yóò padà lọ;
òun kì yóò wọ inú ìlú yìí,”
ni Olúwa wí.
35 “Èmi yóò dáàbò bo ìlú yìí èmi ó sì gbà á là,
nítorí mi àti nítorí Dafidi ìránṣẹ́ mi!”
36 Lẹ́yìn náà ni angẹli Olúwa jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní i ibùdó àwọn Asiria. Nígbà tí àwọn ènìyàn yìí jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì gbogbo wọn ti dòkú! 37 Nítorí náà Sennakeribu ọba Asiria fọ́ bùdó ó sì pẹsẹ̀dà. Òun sì padà sí Ninefe, ó sì dúró síbẹ̀.
38 Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń jọ́sìn nínú tẹmpili Nisroki òrìṣà rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ Adrameleki àti Ṣareseri gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n sì sálọ sí ilẹ̀ Ararati. Bẹ́ẹ̀ ni Esarhadoni ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
Àìsàn Hesekiah
38 Ní ọjọ́ náà ni Hesekiah ṣe àìsàn dé ojú ikú. Wòlíì Isaiah ọmọ Amosi sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ohun tí Olúwa wí nìyìí: Palẹ̀ ilé è rẹ mọ́, bí ó ti yẹ nítorí pé ìwọ yóò kú; ìwọ kì yóò dìde àìsàn yìí.”
2 Hesekiah yí ojú u rẹ̀ sí ara ògiri, ó sì gba àdúrà sí Olúwa, 3 “Rántí, Ìwọ Olúwa, bí mo ti rìn pẹ̀lú òtítọ́ níwájú rẹ, àti bí mo ti fi ọkàn dídúró ṣinṣin ṣe ohun tí ó dára ní ojú ù rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Hesekiah sì sọkún kíkorò.
4 Lẹ́yìn náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Isaiah wá pé 5 “Lọ kí o sì sọ fún Hesekiah pé, ‘Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Ọlọ́run Dafidi baba rẹ sọ pé: Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ; Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ ayé rẹ. 6 Èmi yóò sì gba ìwọ àti ìlú yìí sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria. Èmi yóò sì dáàbò bo ìlú yìí.
7 “ ‘Èyí yìí ni ààmì tí Olúwa fún ọ láti fihàn wí pé Olúwa yóò mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ: 8 Èmi yóò mú òjìji oòrùn kí ó padà sẹ́yìn ní ìṣísẹ̀ mẹ́wàá nínú èyí tí ó fi sọ̀kalẹ̀ ní ibi àtẹ̀gùn ti Ahasi.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni oòrùn padà sẹ́yìn ní ìṣísẹ̀ mẹ́wàá sí ibi tí ó ti dé tẹ́lẹ̀.
9 Ìwé tí Hesekiah ọba Juda kọ lẹ́yìn àìsàn rẹ̀ nígbà tí ó ti gbádùn tán:
10 Èmi wí pé, “Ní àárín gbùngbùn ọjọ́ ayé mi
èmi ó ha kọjá lọ ní ibodè ikú
kí a sì dùn mí ní àwọn ọdún mi tí ó ṣẹ́kù?”
11 Èmi wí pé, “Èmi kì yóò lè tún rí Olúwa mọ́,
àní Olúwa, ní ilẹ̀ àwọn alààyè;
èmi kì yóò lè ṣíjú wo ọmọ ènìyàn mọ́,
tàbí kí n wà pẹ̀lú àwọn tí ó sì ń
gbe orílẹ̀ ayé báyìí.
12 Gẹ́gẹ́ bí àgọ́ olùṣọ́-àgùntàn, ilé mi
ni a ti wó lulẹ̀ tí a sì gbà kúrò lọ́wọ́ mi.
Gẹ́gẹ́ bí ahunṣọ mo ti ká ayé mi nílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni òun sì ti ké mi kúrò lára àṣà;
ọ̀sán àti òru ni ìwọ ṣe òpin mi.
13 Èmi fi sùúrù dúró títí di àfẹ̀mọ́júmọ́,
ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí kìnnìún ó ti fọ́ gbogbo egungun mi;
ọ̀sán àti òru ni ìwọ fi ṣe òpin mi.
14 Èmi dún gẹ́gẹ́ bí àkọ̀ tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀,
Èmi káàánú gẹ́gẹ́ bí aṣọ̀fọ̀ àdàbà.
Ojú mi rẹ̀wẹ̀sì gẹ́gẹ́ bí mo ti ń wo àwọn ọ̀run.
Ìdààmú bá mi; Ìwọ Olúwa, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi!”
15 Ṣùgbọ́n kí ni èmi lè sọ?
Òun ti bá mi sọ̀rọ̀ àti pé òun
tìkára rẹ̀ ló ti ṣe èyí.
Èmi yóò máa rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ mi
nítorí ìpọ́njú ẹ̀mí mi yìí.
16 Olúwa, nípa nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn ń gbé;
àti pé ẹ̀mí mi rí iyè nínú wọn pẹ̀lú.
Ìwọ dá ìlera mi padà
kí o sì jẹ́ kí n wà láààyè
17 Nítòótọ́ fún àlàáfíà ara mi ni,
ní ti pé mo ní ìkorò ńlá.
Nínú ìfẹ́ rẹ ìwọ pa mí mọ́,
kúrò nínú ọ̀gbun ìparun;
ìwọ sì ti fi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.
18 Nítorí pé isà òkú kò le è yìn ọ́,
ipò òkú kò le è kọ orin ìyìn rẹ;
àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ sínú ọ̀gbun
kò lè ní ìrètí fún òtítọ́ rẹ.
19 Alààyè, àwọn alààyè wọ́n ń yìn ọ́,
gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe lónìí;
àwọn baba sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa òtítọ́ rẹ.
20 Olúwa yóò gbà mí là
bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò sì kọrin pẹ̀lú ohun èlò olókùn
ní gbogbo ọjọ́ ayé wa
nínú tẹmpili ti Olúwa.
21 Isaiah ti sọ pé, “Pèsè ìṣù ọ̀pọ̀tọ́ (ohun gbígbóná tí a dì mọ́ ojú egbò) kí o sì fi sí ojú oówo náà, òun yóò sì gbádùn.”
22 Hesekiah si sọ pé, “Kí ni yóò jẹ́ ààmì pé èmi yóò gòkè lọ sí tẹmpili Olúwa?”
Àwọn ikọ̀ ọba láti Babeli
39 (B)Ní àkókò náà ni Merodaki-Baladani ọmọ Baladani ọba Babeli fi ìwé àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Hesekiah, nítorí ó gbọ́ pé ó ṣàìsàn ó sì gbádùn. 2 Hesekiah gba àwọn ikọ̀ yìí tayọ̀tayọ̀, ó sì fi àwọn nǹkan tí ó wà nínú yàrá ìkẹ́rù sí mọ́ hàn wọ́n—fàdákà, wúrà, ohun olóòórùn dídùn, òróró dídára, gbogbo nǹkan ogun rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìṣúra rẹ̀ kò sí ohunkóhun tí ó wà nínú ààfin rẹ̀ tàbí ní ìjọba rẹ̀ tí Hesekiah kò fihàn wọ́n.
3 Lẹ́yìn náà wòlíì Isaiah lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekiah ọba ó sì béèrè pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí, níbo ni wọ́n sì ti wá?”
“Láti ilẹ̀ jíjìnnà,” ni èsì Hesekiah. “Wọ́n wá sọ́dọ̀ mi láti Babeli.”
4 Wòlíì náà sì béèrè pé, “Kí ni wọ́n rí nínú ààfin rẹ?”
Hesekiah si dáhùn pe “Wọ́n rí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin mi” ni ìdáhùn Hesekiah. “Kò sí ohun kankan nínú ìṣúra mi tí èmi kò fihàn wọ́n.”
5 Lẹ́yìn náà ni Isaiah sọ fún Hesekiah pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun: 6 Àsìkò ń bọ̀ nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin rẹ, àti ohun gbogbo tí àwọn baba rẹ ti kójọ títí di ọjọ́ òní yóò di kíkó lọ sí Babeli. Ohun kankan kò ní ṣẹ́kù ni Olúwa wí. 7 Àti díẹ̀ nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ, àwọn ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara rẹ tí a ó bí fún ọ ni a ó kó lọ, wọn yóò sì di ìwẹ̀fà nínú ààfin ọba Babeli.”
8 Hesekiah wí fún Isaiah pé “Rere ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ìwọ sọ,” Nítorí ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Àlàáfíà àti òtítọ́ yóò wà ní ìgbà ayé tèmi.”
Ìtùnú fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run
40 Ẹ tù ú nínú, ẹ tu ènìyàn mi nínú,
ni Ọlọ́run yín wí.
2 Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jerusalẹmu
kí o sì kéde fún un
pé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí,
pé à ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,
pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ Olúwa
ìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
3 (C)Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù:
“Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,
ṣe òpópó tí ó tọ́ ní aginjù fún Ọlọ́run wa.
4 (D)Gbogbo Àfonífojì ni a ó gbé sókè,
gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀;
wíwọ́ ni a ó sọ di títọ́ àti
ọ̀nà pálapàla ni a óò sọ di títẹ́jú pẹrẹsẹ,
5 Ògo Olúwa yóò sì di mí mọ̀
gbogbo ènìyàn lápapọ̀ ni yóò sì rí i.
Nítorí ẹnu Olúwa ni ó ti sọ ọ́.”
6 (E)Ohùn kan wí pé, “Kígbe sókè.”
Èmi sì sọ pé, “Igbe kí ni èmi ó ké?”
“Gbogbo ènìyàn dàbí i koríko,
àti gbogbo ògo wọn dàbí ìtànná igbó.
7 Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,
nítorí èémí Olúwa ń fẹ́ lù wọ́n.
Nítòótọ́ koríko ni àwọn ènìyàn.
8 Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,
ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.”
9 (F)Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Sioni,
lọ sí orí òkè gíga.
Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jerusalẹmu,
gbé ohùn rẹ sókè pẹ̀lú ariwo,
gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù;
sọ fún àwọn ìlú u Juda,
“Ọlọ́run rẹ nìyìí!”
10 (G)Wò ó, Olúwa Olódùmarè náà ń bọ̀ wá pẹ̀lú agbára,
apá rẹ̀ sì ń jẹ ọba fún un.
Wò ó, èrè rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀,
àti ìdápadà rẹ̀ tí ń bá a bọ̀ wá.
11 Ó ń tọ́ àwọn agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn:
Ó kó àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ní apá rẹ̀.
Ó sì gbé wọn súnmọ́ oókan àyà rẹ̀;
ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ darí àwọn tí ó ní.
12 Ta ni ó tiwọn omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀,
tàbí pẹ̀lú ìbú ọwọ́ rẹ̀
tí ó wọn àwọn ọ̀run?
Ta ni ó ti kó erùpẹ̀ ilẹ̀ ayé jọ nínú apẹ̀rẹ̀,
tàbí kí ó wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀n
àti òkè kéékèèkéé nínú òṣùwọ̀n?
13 (H)Ta ni ó ti mọ ọkàn Olúwa,
tàbí tí ó ti tọ́ ọ ṣọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀?
14 Ta ni Olúwa ké sí kí ó là á lọ́yẹ
àti ta ni ó kọ́ òun ní ọ̀nà tí ó tọ́?
Ta ni ẹni náà tí ó kọ́ ọ ní ọgbọ́n
tàbí tí ó fi ipa ọ̀nà òye hàn án?
15 Nítòótọ́ àwọn orílẹ̀-èdè dàbí i ẹ̀kún omi
nínú garawa;
a kà wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí eruku lórí ìwọ̀n;
ó wọn àwọn erékùṣù àfi bí eruku múnúmúnú ni wọ́n.
16 Lebanoni kò tó fún pẹpẹ iná,
tàbí kí àwọn ẹranko rẹ̀ kí ó tó fún ẹbọ sísun.
17 Níwájú rẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè dàbí ohun tí kò sí;
gbogbo wọn ló kà sí ohun tí kò wúlò
tí kò tó ohun tí kò sí.
18 Ta ni nígbà náà tí ìwọ yóò fi Ọlọ́run wé?
Ère wo ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé rẹ̀?
19 Ní ti ère, oníṣọ̀nà ni ó dà á,
ti alágbẹ̀dẹ wúrà sì fi wúrà bò ó
tí a sì ṣe ẹ̀wọ̀n ọ̀nà sílífà fún un.
20 Ọkùnrin kan tí ó tálákà jù kí ó lè mú
irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ wá,
wá igi tí kò le è rà.
Ó wá oníṣọ̀nà tí ó
láti ṣe àgbékalẹ̀ ère tí kì yóò le è ṣubú.
21 Ǹjẹ́ o kò tí ì mọ̀
ìwọ kò tí ì gbọ́?
A kò tí ì sọ fún ọ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá?
Ìwọ kò tí ì mọ láti ìgbà ìpìlẹ̀ ayé?
22 Òun jókòó lórí ìtẹ́ ní òkè òbírí ilẹ̀ ayé,
àwọn ènìyàn rẹ̀ sì dàbí i láńtata.
Ó ta àwọn ọ̀run bí ìbòrí ìgúnwà,
ó sì nà wọ́n jáde gẹ́gẹ́ bí àgọ́ láti gbé.
23 Ó sọ àwọn ọmọ ọba di asán
àti àwọn aláṣẹ ayé yìí ni ó ti sọ dòfo.
24 Gẹ́rẹ́ tí a ti gbìn wọ́n,
kété tí a gbìn wọ́n,
kété tí wọ́n fi gbòǹgbò múlẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ó fẹ́ atẹ́gùn lù wọ́n gbogbo wọn sì gbẹ,
bẹ́ ni ìjì líle sì gbá wọn lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò.
25 “Ta ni ẹ ó fi mi wé?
Tàbí ta ni ó bá mi dọ́gba?” ni Ẹni Mímọ́ wí.
26 Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wo àwọn ọ̀run:
Ta ni ó dá àwọn wọ̀nyí?
Ẹni tí ó mú àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ jáde wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan
tí ó sì pè wọ́n ní orúkọ lọ́kọ̀ọ̀kan.
Nítorí agbára ńlá àti ipá rẹ̀,
ọ̀kan ṣoṣo nínú wọn kò sọnù.
27 Èéṣe tí o fi sọ, ìwọ Jakọbu
àti tí o ṣàròyé, ìwọ Israẹli;
“Ọ̀nà mi pamọ́ níwájú Olúwa;
ìṣe mi ni a kò kọbi ara sí
láti ọwọ́ Ọlọ́run mi”?
28 Ìwọ kò tí ì mọ̀?
Ìwọ kò tí ì gbọ́?
Olúwa òun ni Ọlọ́run ayérayé,
Ẹlẹ́dàá gbogbo ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé.
Agara kì yóò da bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣàárẹ̀,
àti òye rẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò le ṣe òdínwọ̀n rẹ̀.
29 Ó ń fi agbára fún àwọn aláàárẹ̀
ó sì fi kún agbára àwọn tí agara dá.
30 Àní, ó ń rẹ̀ wọ́n àwọn ọ̀dọ́, wọ́n ń rẹ̀wẹ̀sì,
àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì ń kọsẹ̀ wọ́n ṣubú;
31 ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa
yóò sọ agbára wọn di ọ̀tun.
Wọn yóò fìyẹ́ fò lókè bí idì;
wọn yóò sáré àárẹ̀ kò ní mú wọn,
wọn yóò rìn òòyì kò ní kọ́ wọn.
Olùrànlọ́wọ́ fún Israẹli
41 “Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú mi ẹ̀yin erékùṣù!
Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè tún agbára wọn ṣe!
Jẹ́ kí wọn wá síwájú kí wọn sọ̀rọ̀:
Jẹ́ kí a pàdé pọ̀ ní ibi ìdájọ́.
2 “Ta ni ó ti ru ẹnìkan sókè láti ìlà-oòrùn wá,
tí ó pè é ní olódodo sí iṣẹ́ tirẹ̀?
Ó gbé àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́
ó sì ṣẹ́gun àwọn ọba níwájú rẹ̀.
Ó sọ wọ́n di erùpẹ̀ pẹ̀lú idà rẹ̀,
láti kù ú ní ìyàngbò pẹ̀lú ọrun rẹ̀.
3 Ó ń lépa wọn ó sì ń kọjá ní àlàáfíà,
ní ojú ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò rìn rí.
4 Ta ni ó ti ṣe èyí tí ó sì ti jẹ́ kí ó wáyé,
tí ó ti pe ìran-ìran láti àtètèkọ́ṣe?
Èmi Olúwa pẹ̀lú ẹni kìn-ín-ní wọn
àti ẹni tí ó gbẹ̀yìn, Èmi náà ni.”
5 Àwọn erékùṣù ti rí i wọ́n bẹ̀rù;
ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé wárìrì.
Wọ́n súnmọ́ tòsí wọ́n sì wá síwájú
6 Èkínní ran èkejì lọ́wọ́
ó sì sọ fún arákùnrin rẹ̀ pé
“Jẹ́ alágbára!”
7 Oníṣọ̀nà gba alágbẹ̀dẹ wúrà níyànjú,
àti ẹni tí ó fi òòlù dán
mú òun lọ́kàn le, àní ẹni tí ó ń lu owú.
Ó sọ nípa àjópọ̀ náà pé, “Ó dára.”
Ó fi ìṣó kan ère náà mọ́lẹ̀ kí ó má ba à wó lulẹ̀.
8 (I)(J) “Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ Israẹli, ìránṣẹ́ mi,
Jakọbu, ẹni tí mo ti yàn,
ẹ̀yin ìran Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi,
9 mo mú ọ láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé,
láti kọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó jìnnà jùlọ ni mo ti pè ọ́.
Èmi wí pé, ‘Ìwọ ni ìránṣẹ́ mi;’
Èmi ti yàn ọ́ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì tí ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
10 (K)Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ;
má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.
Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́.
Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi.
11 “Gbogbo àwọn tí ó bínú sí ọ
ni ojú yóò tì, tí wọn yóò sì di ẹlẹ́yà;
àwọn tó ń bá ọ jà
yóò dàbí asán, wọn yóò ṣègbé.
12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yóò wá àwọn ọ̀tá rẹ,
ìwọ kì yóò rí wọn.
Gbogbo àwọn tí ó gbóguntì ọ́
yóò dàbí ohun tí kò sí.
13 Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
tí ó di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú
tí ó sì sọ fún ọ pé, má ṣe bẹ̀rù;
Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.
14 Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu kòkòrò,
ìwọ Israẹli kékeré,
nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,”
ni Olúwa wí,
olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.
15 “Kíyèsi, Èmi yóò sọ ọ́ di òòlù ìpakà tuntun,
tí ó mú ti eyín rẹ̀ mú, ìwọ yóò lu àwọn òkè ńlá,
ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú,
a ó sì sọ òkè kékeré di ìyàngbò.
16 Ìwọ yóò fẹ́ wọn, afẹ́fẹ́ yóò sì gbá wọn mú,
àti ẹ̀fúùfù yóò sì fẹ́ wọn dànù
Ṣùgbọ́n ìwọ yóò yọ̀ nínú Olúwa
ìwọ yóò sì ṣògo nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.
17 “Àwọn tálákà àti aláìní wá omi,
ṣùgbọ́n kò sí;
ahọ́n wọn gbẹ fún òǹgbẹ.
Ṣùgbọ́n Èmi Olúwa yóò dá wọn lóhùn;
Èmi, Ọlọ́run Israẹli, kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
18 Èmi yóò mú kí odò kí ó sàn ní ibi gíga
àti orísun omi ní àárín Àfonífojì.
Èmi yóò sọ aṣálẹ̀ di adágún omi,
àti ilẹ̀ tí ó gbẹ gidigidi di orísun omi.
19 Èmi yóò fi sínú aṣálẹ̀
igi kedari àti kasia, maritili àti olifi.
Èmi yóò gbin junifa sí inú aginjù,
igi firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀
20 tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn yóò fi rí i tí wọn yóò sì fi mọ̀,
kí wọn ṣàkíyèsí kí ó sì yé wọn,
pé ọwọ́ Olúwa ni ó ti ṣe èyí,
àti pé Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ti dá èyí.
21 “Mú ẹjọ́ wá,” ni Olúwa wí.
“Tẹ́ àwọn àwíjàre rẹ sílẹ̀,” ni ọba Jakọbu wí
22 “Mú àwọn ère òrìṣà rẹ wọlé láti sọ fún wa
ohun tí yóò ṣẹlẹ̀.
Sọ fún wa ohun tí àwọn nǹkan àtijọ́ jẹ́,
kí àwa lè ṣe àgbéyẹ̀wò wọn
kí àwa sì mọ àbájáde wọn ní ìparí.
Tàbí kí o sọ fún wa ohun tí ó ń bọ̀ wá,
23 ẹ sọ fún wa ohun ti ọjọ́ iwájú mú dání
kí àwa kí ó lè mọ̀ pé ọlọ́run ni yín.
Ẹ ṣe nǹkan kan, ìbá à ṣe rere tàbí búburú,
tó bẹ́ẹ̀ tí àyà yóò fi fò wá tí ẹ̀rù yóò sì fi kún inú wa.
24 Ṣùgbọ́n ẹ̀yìn ko jásí nǹkan kan
iṣẹ́ yín ni kò sì wúlò fún ohunkóhun;
ẹni tí ó yàn yín jẹ́ ẹni ìríra.
25 “Èmi ti ru ẹnìkan sókè láti àríwá, òun sì ń bọ
ẹnìkan láti ìlà-oòrùn tí ó pe orúkọ mi.
Òun gun àwọn aláṣẹ mọ́lẹ̀ bí ẹni pé odò ni wọ́n,
àfi bí ẹni pé amọ̀kòkò nì ti ń gún amọ̀.
26 Ta ni ó sọ èyí láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, tí àwa kò bá fi mọ̀,
tàbí ṣáájú àkókò, tí àwa kò bá fi wí pé, ‘Òun sọ òtítọ́’?
Ẹnikẹ́ni kò sọ nípa èyí,
ẹnikẹ́ni kò sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀,
ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.
27 Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó sọ fún Sioni pé, ‘Wò ó, àwọn nìyìí!’
Mo fún Jerusalẹmu ní ìránṣẹ́ ìrò ìròyìn ayọ̀ kan.
28 Èmi wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan—
kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó lè mú ìmọ̀ràn wá,
kò sí ẹnìkan tí ó lè dáhùn nígbà tí mo bi wọ́n.
29 Kíyèsi i, irọ́ ni gbogbo wọn!
Gbogbo ìṣe wọn jásí asán;
àwọn ère wọn kò ṣé kò yà fún afẹ́fẹ́ àti dàrúdàpọ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.