Book of Common Prayer
106 (A)Yin Olúwa! Ẹ fi ìyìn fún
Olúwa, nítorí tí ó ṣeun.
Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun;
Nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.
2 Ta ni ó lè ròyìn iṣẹ́ agbára Olúwa,
ta ní lè sọ nípa ìyìn rẹ̀?
3 Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́?
Ẹni tí n ṣe ohun tí ó tọ́.
4 Rántí mi, Olúwa,
Nígbà tí o bá fi ojúrere rẹ hàn,
wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n,
5 Kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn,
kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn,
ìní rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo.
6 Àwa ti dẹ́ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe,
àwa ti ṣe ohun tí kò dá a,
a sì ti hùwà búburú
7 Nígbà tí àwọn baba wa wà ní Ejibiti,
iṣẹ́ ìyanu rẹ kò yé wọn,
wọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ,
gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí ọ níbi Òkun, àní níbi Òkun pupa
8 Ṣùgbọ́n o gbà wọ́n là nítorí orúkọ rẹ
láti jẹ́ kí agbára ńlá rẹ di mí mọ̀
9 O bá Òkun pupa wí, ó sì gbẹ;
o sì mú wọn la ìbú já bí aginjù
10 O gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn
láti ọwọ́ ọ̀tá ni o ti gbà wọ́n
11 Omi ya lu àwọn ọ̀tá wọn, bẹ́ẹ̀ ni
kò sí èyí tí ó yè nínú wọn.
12 Nígbà náà wọn gba ìpinnu rẹ gbọ́
wọ́n sì kọrin ìyìn rẹ.
13 Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣe
wọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn rẹ
14 Nínú aginjù ni wọ́n tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́
nínú aṣálẹ̀, wọ́n dán Ọlọ́run wò
15 Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún
ṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn.
16 Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mose
pẹ̀lú Aaroni, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.
17 Ilẹ̀ la ẹnu ó sì gbé Datani mì
ó bo ẹgbẹ́ Abiramu mọ́lẹ̀
18 Ọwọ́ iná yọ ní ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀;
iná jo àwọn ènìyàn búburú.
19 Ní Horebu wọ́n ṣe ẹgbọrọ màlúù
wọ́n sì sin òrìṣà tí a ṣe láti ara irin.
20 Wọ́n pa ògo wọn dà
sí àwòrán màlúù, tí ń jẹ koríko.
21 Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run, ẹni tí ó gbà wọ́n
ẹni tí ó ti ṣe ohun ńlá ní Ejibiti,
22 Iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu
àti ohun ẹ̀rù ni ẹ̀bá Òkun pupa
23 Bẹ́ẹ̀ ni, ó sọ wí pé, òun yóò pa wọ́n run
bí kò bá ṣe ti Mose, tí ó yàn,
tí ó dúró níwájú ẹ̀yà náà
tí ó pa ìbínú rẹ̀ mọ́ láti má pa wọ́n run mọ́.
24 Nígbà náà, wọ́n kẹ́gàn ilẹ̀ dídára náà
wọn kò gba ìlérí rẹ̀ gbọ́.
25 Wọ́n ń kùn nínú àgọ́ wọn
wọn kò sì gbọ́rọ̀ sí Olúwa.
26 Bẹ́ẹ̀ ni ó búra fún wọn nípa gbígbé ọwọ́ rẹ̀ sókè
kí òun lè jẹ́ kí wọn ṣubú nínú aginjù,
27 Láti jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣubú lára orílẹ̀-èdè
láti fọ́n wọn káàkiri lórí ilẹ̀.
28 Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali-Peori,
wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí a rú sí àwọn òkú òrìṣà
29 Wọ́n mú Ọlọ́run bínú pẹ̀lú ohun búburú tí wọn ń ṣe
àjàkálẹ̀-ààrùn jáde láàrín wọn.
30 Ṣùgbọ́n Finehasi dìde láti dá sí i,
àjàkálẹ̀-ààrùn náà sì dáwọ́ dúró lọ́gán
31 A sì ka èyí sí òdodo fún un àti
fún àwọn ìrandíran tí ń bọ̀
32 Níbi omi Meriba, wọ́n bí Ọlọ́run nínú,
ohun búburú wá sí orí Mose nítorí wọn.
33 Nítorí tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ẹ̀mí Ọlọ́run.
Ọ̀rọ̀ àìdára sì ti ẹnu Mose wá.
34 Wọn kò pa àwọn ènìyàn run
gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti sọ fún wọn,
35 Ṣùgbọ́n wọ́n dàpọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,
wọ́n sì gbà láti ṣe bí àṣà wọn
36 Wọ́n sì sin àwọn òrìṣà wọn
tí ó di ìkẹ́kùn fún wọn.
37 Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rú ẹbọ
àti àwọn ọmọbìnrin fún òrìṣà.
38 Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.
Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn
ọmọbìnrin wọn.
Wọ́n fi wọ́n rú ẹbọ sí ère Kenaani, ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀
39 Wọ́n sì fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́,
wọ́n sì ṣe àgbèrè lọ pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.
40 Nígbà náà ni Olúwa bínú sí àwọn ènìyàn rẹ̀
ó sì kórìíra àwọn ènìyàn ìní rẹ̀
41 Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́,
àwọn ọ̀tá wọn sì jẹ ọba lórí wọn.
42 Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọn lójú
wọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn.
43 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n,
Síbẹ̀ wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí i
wọ́n sì ṣòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
44 Ṣùgbọ́n ó kíyèsi wọn nítorí ìṣòro
nígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn;
45 Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ nítorí wọn
Nítorí agbára ìfẹ́ rẹ̀, ó ṣàánú wọn.
46 Lójú gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn
ó mú wọn rí àánú.
47 (B)Gbà wá, Olúwa Ọlọ́run wa,
kí o sì ṣà wá jọ kúrò láàrín àwọn kèfèrí,
láti máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ
láti máa ṣògo nínú ìyìn rẹ.
48 Olùbùkún ni Olúwa,
Ọlọ́run Israẹli, láti ìrandíran.
Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kí ó wí pé, “Àmín!”
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa!
11 (A)Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olúwa
má sì ṣe bínú nígbà tí ó bá ń bá ọ wí,
12 Nítorí Olúwa a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wí
bí baba ti í bá ọmọ tí ó bá nínú dídùn sí wí.
13 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀,
ẹni tí ó tún ní òye sí i
14 Nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ
ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ.
15 Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ;
kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.
16 Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;
ní ọwọ́ òsì rẹ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.
17 Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura,
òpópónà rẹ sì jẹ́ ti àlàáfíà.
18 Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á;
àwọn tí ó bá sì dìímú yóò rí ìbùkún gbà.
19 Nípa ọgbọ́n, Olúwa fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn;
20 Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní yà,
àwọsánmọ̀ sì ń sẹ ìrì.
18 (A)Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi ọ̀rọ̀ tàbí ahọ́n fẹ́ràn, bí kò ṣe ni ìṣe àti ní òtítọ́.
19 Àti nípa èyí ni àwa ó mọ̀ pé àwa jẹ́ ti òtítọ́, àti pé àwa ó sì fi ọkàn ara wa balẹ̀ níwájú rẹ̀. 20 Nínú ohunkóhun tí ọkàn wa bá ń dá wa lẹ́bi; nítorí pé Ọlọ́run tóbi ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo. 21 (B)Olùfẹ́, bí ọkàn wa kò bá dá wa lẹ́bi, ǹjẹ́ àwa ni ìgboyà níwájú Ọlọ́run? 22 Àti ohunkóhun tí àwa bá béèrè, ni àwa ń rí gbà lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí tí àwa ń pa òfin rẹ̀ mọ́, àwa sì ń ṣe àwọn nǹkan tí ó dára lójú rẹ̀. 23 (C)Èyí sì ni òfin rẹ̀, pé kí àwa gba orúkọ Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ gbọ́, kí a sì fẹ́ràn ara wá gẹ́gẹ́ bí ó tí fi òfin fún wa. 24 (D)Ẹni tí ó bá sì pa òfin rẹ̀ mọ́ ń gbé inú rẹ̀, àti òun nínú rẹ̀. Àti nípa èyí ni àwa mọ̀ pé ó ń gbé inú wa, nípa Ẹ̀mí tí ó fi fún wa.
Ẹ dán àwọn ẹ̀mí wò
4 Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹ̀mí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn ẹ̀mí wò bí wọn ba ń ṣe tí Ọlọ́run: nítorí àwọn wòlíì èké púpọ̀ tí jáde lọ sínú ayé. 2 Èyí ni ẹ ó fi mọ Ẹ̀mí Ọlọ́run: gbogbo ẹ̀mí tí ó ba jẹ́wọ́ pé, Jesu Kristi wá nínú ara, ti Ọlọ́run ni: 3 (E)Gbogbo ẹ̀mí tí kò si jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wà nínú ara, kì í ṣe tí Ọlọ́run: èyí sì ni ẹ̀mí aṣòdì sí Kristi náà, tí ẹ̀yin ti gbọ́ pé ó ń bọ̀, àti nísinsin yìí ó sì tí de sínú ayé.
4 Ẹ̀yin ọmọ mi, ti Ọlọ́run ni yín, ẹ̀yin sì tí ṣẹ́gun wọn: nítorí ẹni tí ń bẹ nínú yin tóbi jú ẹni tí ń bẹ nínú ayé lọ. 5 (F)Tí ayé ni wọ́n, nítorí náà ni wọn ṣe ń sọ̀rọ̀ bí ẹni ti ayé, ayé sì ń gbọ́ tí wọn. 6 (G)Ti Ọlọ́run ni àwa: ẹni tí ó bá mọ Ọlọ́run, ó ń gbọ́ tiwa; ẹni tí kì í ṣe ti Ọlọ́run kò ni gbọ́ ti wa. Nípa èyí ni àwa mọ ẹ̀mí òtítọ́, àti ẹ̀mí èké.
Jesu tu àwọn arábìnrin rẹ̀ nínú
17 Nítorí náà nígbà tí Jesu dé, ó rí i pé a ti tẹ́ ẹ sínú ibojì ní ọjọ́ mẹ́rin ná, 18 Ǹjẹ́ Betani súnmọ́ Jerusalẹmu tó ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún: 19 (A)Ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù sì wá sọ́dọ̀ Marta àti Maria láti tù wọ́n nínú nítorí ti arákùnrin wọn. 20 Nítorí náà, nígbà tí Marta gbọ́ pé Jesu ń bọ̀ wá, ó jáde lọ pàdé rẹ̀: ṣùgbọ́n Maria jókòó nínú ilé.
21 Nígbà náà, ni Marta wí fún Jesu pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú. 22 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí náà, mo mọ̀ pé, ohunkóhun tí ìwọ bá béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò fi fún ọ.”
23 Jesu wí fún un pé, “Arákùnrin rẹ yóò jíǹde.”
24 (B)Marta wí fún un pé, “Mo mọ̀ pé yóò jíǹde ní àjíǹde ìkẹyìn.”
25 (C)Jesu wí fún un pé, “Èmi ni àjíǹde àti ìyè: ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè: 26 (D)Ẹnikẹ́ni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì gbà mí gbọ́, kì yóò kú láéláé ìwọ gbà èyí gbọ́?”
27 (E)Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa: èmi gbàgbọ́ pé, ìwọ ni Kristi náà Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ń bọ̀ wá sí ayé.”
28 Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó lọ, ó sì pe Maria arábìnrin rẹ̀ sẹ́yìn wí pé, “Olùkọ́ dé, ó sì ń pè ọ́.” 29 Nígbà tí ó gbọ́, ó dìde lọ́gán, ó sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.