Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 93

93 Olúwa ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ;
    ọláńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọ
    àti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára.
Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;
    kò sì le è yí.
Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́;
    ìwọ wà títí ayérayé.

A ti gbé Òkun sókè, Olúwa,
    Òkun ti gbé ohùn wọn sókè;
    Òkun ti gbé rírú omi wọn sókè.
Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ,
    ó ni ògo ju Òkun rírú lọ
    Olúwa ga ní ògo.

Ẹ̀rí rẹ̀ dúró ṣinṣin;
    ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́
    fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa.

Saamu 96

96 (A)Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa:
    Ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.
Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀
    ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́
Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
    àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn.

Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí;
    òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ
Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè
    ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run
Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀
    agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.

Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn
    Ẹ fi agbára àti ògo fún Olúwa
Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un;
    ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀
Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀;
    ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé.
10 Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “Olúwa jẹ ọba”
    a fi ìdí ayé múlẹ̀, tí kò sì lè yí;
    ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.

11 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì pariwo
    jẹ́ kí pápá Òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun
gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀.
12     Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀
àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀:
nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀
13     Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa,
    nítorí tí ó ń bọ̀ wá,
Ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé
yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé
    àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fi òtítọ́ rẹ̀ ṣe.

Saamu 34

Tí Dafidi. Nígbà tí ó díbọ́n bí ẹni tí ń ṣe wèrè níwájú Abimeleki, ẹni tí ó lé e lọ, ó sì jáde lọ.

34 Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo;
    ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.
Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú Olúwa;
    jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn.
Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi;
    kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ lékè.

Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn;
    Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.
Wọ́n wò ó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn;
    ojú kò sì tì wọ́n.
Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, Olúwa sì gbóhùn rẹ̀;
    ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
Angẹli Olúwa yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká
    ó sì gbà wọ́n.

Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára;
    ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú rẹ̀.
Ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́,
    nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
10 Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n;
    ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá Olúwa kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára.
11 Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi;
    èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù Olúwa.
12 (A)Ta ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀;
    kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere?
13 Pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi
    àti ètè rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ.
14 Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere;
    wá àlàáfíà, kí o sì lépa rẹ̀.

15 Ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo;
    etí i rẹ̀ sì ṣí sí ẹkún wọn.
16 Ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú;
    láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.

17 Nígbà tí olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́,
    Olúwa a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn.
18 Olúwa súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn;
    ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là.

19 Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀,
    ṣùgbọ́n Olúwa gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo rẹ̀.
20 Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́;
    kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn.

21 Ibi ni ó mú ikú ìkà wá,
    àti àwọn tí ó kórìíra olódodo ni yóò jẹ̀bi.
22 Olúwa ra ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ padà;
    kò sí ọ̀kan nínú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé tí yóò jẹ̀bi.

Jeremiah 6:9-15

Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:

“Jẹ́ kí wọn pèsè ìyókù Israẹli
    ní tónítóní bí àjàrà;
na ọwọ́ rẹ sí àwọn ẹ̀ka nì lẹ́ẹ̀kan sí i
    gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti í kó èso àjàrà jọ.”

10 Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti
    tí mo lè fún ní ìmọ̀ràn? Ta ni
yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi? Etí wọn
    ti di, nítorí náà wọn kò lè gbọ́.
Ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ ohun búburú sí wọn,
    wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀.
11 Èmi kún fún ìbínú
    Olúwa, èmi kò sì le è pa á mọ́ra.

“Tú u sí orí àwọn ọmọ ńigboro, àti
    sórí àwọn ọmọkùnrin tí wọn kó ra
wọn jọ pọ̀, àti ọkọ àti aya ni a ò
    mú sínú rẹ̀, àti àwọn arúgbó
    tí ó ní ọjọ́ kíkún lórí.
12 Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn,
    oko wọn àti àwọn aya wọn,
nígbà tí èmi bá na ọwọ́ mi
    sí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,”
    ni Olúwa wí.
13 “Láti orí ẹni tí ó kéré sí orí
    ẹni tí ó tóbi ju, gbogbo wọn
ni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè,
    àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀
    sì kún fún ẹ̀tàn.
14 Wọ́n sì ń wo ọgbẹ́ àwọn ènìyàn
    mi bí ẹni pé kò tó nǹkan.
Wọ́n ń wí pé, ‘Àlàáfíà, Àlàáfíà,’
    nígbà tí kò sì sí àlàáfíà.
15 Ojú ha a tì wọ́n nítorí ìwà
    ìríra wọn bí? Rárá, wọn kò
ní ìtìjú mọ́, wọn kò tilẹ̀ ní oorun ìtìjú
    Nítorí náà, wọn ó ṣubú láàrín
àwọn tó ṣubú, a ó sì ké wọn
    lulẹ̀ nígbà tí mo bá bẹ̀ wọ́n wò,”
    ni Olúwa wí.

1 Kọrinti 6:12-20

Ìwà àgbèrè

12 (A)“Ohun gbogbo ní ó tọ́ fún mi,” ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ní èrè; “Ohun gbogbo ni ó yẹ fún mi,” ṣùgbọ́n èmi kì yóò jẹ́ kí ohunkóhun ṣe olórí fun mi. 13 “Oúnjẹ fún inú àti inú fún oúnjẹ,” ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò fi òpin sí méjèèjì, ara kì í ṣe fún ìwà àgbèrè ṣíṣe, ṣùgbọ́n fún Olúwa, àti Olúwa fún ara náà. 14 Nínú agbára rẹ̀, Ọlọ́run jí Olúwa dìde kúrò nínú òkú bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò jí àwa náà dìde. 15 (B)Ṣé ẹ kò tilẹ̀ mọ̀ pé ara yín gan an jẹ́ ẹ̀yà ara Kristi fún ara rẹ̀? Ǹjẹ́ tí ó ba jẹ́ bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ó yẹ kí ń mú ẹ̀yà ara Kristi kí ń fi ṣe ẹ̀yà ara àgbèrè bí? Kí a má rí i! 16 (C)Tàbí ẹ kò mọ̀ pé bí ẹnìkan bá so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àgbèrè ó jẹ́ ara kan pẹ̀lú rẹ̀? Nítorí a tí kọ ọ́ wí pé, “Àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.” 17 (D)Ṣùgbọ́n ẹni ti ó dàpọ̀ mọ́ Olúwa di ẹ̀mí kan náà pẹ̀lú rẹ̀.

18 Ẹ máa sá fún àgbèrè. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ènìyàn ń dá wà lóde ara, ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbèrè ń ṣe sí ara òun tìkára rẹ̀. 19 (E)Tàbí, ẹ̀yin kò mọ̀ pé ara yín ni tẹmpili Ẹ̀mí Mímọ́, ti ń bẹ nínú yín, ti ẹ̀yin ti gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run? Ẹ̀yin kì í ṣe ti ara yín, 20 (F)nítorí a ti rà yín ni iye kan; Nítorí náà ẹ yìn Ọlọ́run lógo nínú ara yín, àti nínú ẹ̀mí yín, tì í ṣe ti Ọlọ́run.

Marku 5:1-20

Ìwòsàn ọkùnrin ẹlẹ́mìí èṣù

(A)Wọ́n lọ sí apá kejì adágún ní ẹ̀bá ilẹ̀ àwọn ará Gadara. Bí Jesu sì ti ń ti inú ọkọ̀ ojú omi jáde. Ọkùnrin kan tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́ jáde ti ibojì wá pàdé rẹ̀. Ọkùnrin yìí ń gbé nínú ibojì, kò sí ẹni tí ó lè dè é mọ́, kódà ẹ̀wọ̀n kò le dè é. Nítorí pé nígbà púpọ̀ ni wọ́n ti ń fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀, tí ó sì ń já a dànù kúrò ni ẹsẹ̀ rẹ̀. Kò sí ẹnìkan tí ó ní agbára láti káwọ́ rẹ̀. Tọ̀sán tòru láàrín àwọn ibojì àti ní àwọn òkè ni ó máa ń kígbe rara tí ó sì ń fi òkúta ya ara rẹ̀.

Nígbà tí ó sì rí Jesu látòkèrè, ó sì sáré lọ láti pàdé rẹ̀. Ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀. (B)Ó sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tèmi tìrẹ, Jesu Ọmọ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo? Mo fi Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró.” Nítorí tí Ó wí fún un pé, “Jáde kúrò lára ọkùnrin náà, ìwọ ẹ̀mí àìmọ́!”

Jesu sì bi í léèrè pé, “Kí ni orúkọ rẹ?”

Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì dáhùn wí pé, “Ligioni, nítorí àwa pọ̀.” 10 Nígbà náà ni ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jesu gidigidi, kí ó má ṣe rán àwọn jáde kúrò ní agbègbè náà.

11 Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá kan sì ń jẹ lẹ́bàá òkè. 12 Àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ Jesu pé, “Rán wa lọ sínú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ wọ̀n-ọn-nì kí àwa le è wọ inú wọn lọ.” 13 Jesu fún wọn láààyè, àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà lọ. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà tí ó tó ìwọ̀n ẹgbàá sì túká lọ́gán, wọ́n sì sáré lọ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè rọ́ sínú Òkun, wọ́n sì ṣègbé.

14 Àwọn olùtọ́jú ẹran wọ̀nyí sì sálọ sí àwọn ìlú ńlá àti ìlú kéékèèkéé, wọ́n sì ń tan ìròyìn náà ká bí wọ́n ti ń sáré. Àwọn ènìyàn sì tú jáde láti fojú gán-án-ní ohun náà tí ó ṣẹlẹ̀. 15 Nígbà tí wọ́n péjọ sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n rí ọkùnrin náà, ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù, tí ó jókòó níbẹ̀, ó wọ aṣọ ìyè rẹ sì bọ̀ sípò, ẹ̀rù sì bà wọ́n. 16 Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣojú wọn sì ń ròyìn rẹ̀ fún àwọn ènìyàn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin ẹlẹ́mìí àìmọ́, wọ́n si sọ nípa agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà pẹ̀lú. 17 Nígbà náà, àwọn èrò bẹ̀rẹ̀ sí ní bẹ Jesu pé kí ó fi agbègbè àwọn sílẹ̀.

18 Bí Jesu ti ń wọ inú ọkọ̀ ojú omi lọ, ọkùnrin náà tí ó ti ní ẹ̀mí àìmọ́ tẹ́lẹ̀ bẹ̀ Ẹ́ pé kí òun lè bá a lọ. 19 Jesu kò gbà fún un, ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, “Lọ sí ilé sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ, kí o sì sọ fún wọn bí Ọlọ́run ti ṣe ohun ńlá fún ọ, àti bí ó sì ti ṣàánú fún ọ.” 20 (C)Nítorí naà, ọkùnrin yìí padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn ní Dekapoli nípa ohun ńlá tí Jesu ṣe fún un. Ẹnu sì ya gbogbo ènìyàn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.