Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 119:97-120

Òfin Olúwa ni ìfẹ́ pípé

97 Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó!
    Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀
ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá.
98 Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,
    nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé.
99 Èmi ní iyè inú ju gbogbo olùkọ́ mi lọ,
    nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin rẹ.
100 Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ,
    nítorí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.
101 Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibi
    nítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ rẹ.
102 Èmi kò yà kúrò nínú òfin rẹ,
    nítorí ìwọ fúnrarẹ̀ ni ó kọ́ mi.
103 Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó,
    ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi!
104 Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ rẹ;
    nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́.

Òfin Olúwa ni fìtílà mi

105 Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà sí ẹsẹ̀ mi
    àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi
106 Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọn
    wí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo rẹ.
107 A pọ́n mi lójú gidigidi;
    Olúwa, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ
108 Olúwa, gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi,
    kí o sì kọ́ mi ní òfin rẹ̀.
109 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ mi
    nígbà gbogbo,
    èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
110 Àwọn ẹni búburú ti dẹ okùn sílẹ̀ fún mi,
    ṣùgbọ́n èmi kò ṣìnà kúrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
111 Òfin rẹ ni ogún mi láéláé;
    àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi.
112 Ọkàn mi ti lé pípa òfin rẹ mọ́
    láé dé òpin.

Òfin Olúwa ni Ààbò mi

113 Èmi kórìíra àwọn ọlọ́kàn méjì,
    ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin rẹ.
114 Ìwọ ni ààbò mi àti asà mi;
    èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
115 Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin olùṣe búburú,
    kí èmi lè pa àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́!
116 Gbé mi sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ,
    kí èmi kí ó lè yè
    Má sì jẹ́ kí ojú ìrètí mi kí ó tì mí.
117 Gbé mi sókè, èmí yóò sì wa láìléwu;
    nígbà gbogbo ni èmi yóò máa júbà òfin rẹ.
118 Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó ṣìnà kúrò nínú òfin rẹ,
    nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni.
119 Gbogbo àwọn ẹni búburú ní ayé ni ìwọ yọ kúrò bí i ìdàrọ́;
    nítorí náà, èmi fẹ́ òfin rẹ̀.
120 Ara mi wárìrì ní ìbẹ̀rù nítorí rẹ̀:
    èmi dúró ní ìbẹ̀rù òfin rẹ.

Saamu 81-82

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti Asafu.

81 Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa
    Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jakọbu!
Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wá,
    tẹ dùùrù dídùn pẹ̀lú ohun èlò orin mímọ́.

Ẹ fún ìpè ní oṣù tuntun
    àní nígbà tí a yàn;
ní ọjọ́ àjọ wa tí ó ní ìrònú.
Èyí ni àṣẹ fún Israẹli,
    àti òfin Ọlọ́run Jakọbu.
Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Josẹfu
    nígbà tí ó la ilẹ̀ Ejibiti já.

    Níbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa.

Ó wí pé, “Mo gbé àjàgà kúrò ní èjìká yín,
    a tú ọwọ́ wọn sílẹ̀ kúrò nínú apẹ̀rẹ̀.
Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là,
    mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá,
    mo dán an yín wò ní odò Meriba. Sela.

“Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín,
    bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Israẹli.
Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrín yín;
    ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì.
10 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
    ẹni tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti.
    Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un.

11 “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi;
    Israẹli kò ní tẹríba fún mi.
12 Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn
    láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn.

13 “Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmi
    bí Israẹli yóò bá tẹ̀lé ọ̀nà mi,
14 Ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn
    kí n sì yí ọwọ́ mi padà sí ọ̀tá wọn!
15 Àwọn tí ó kórìíra Olúwa yóò tẹríba níwájú rẹ̀.
    Ìjìyà wọn yóò sì pẹ́ títí láé
16 Ṣùgbọ́n a ó fi ọkà tí ó dára bọ́ ọ yín
    èmi ó tẹ́ ẹ yín lọ́rùn pẹ̀lú oyin inú àpáta.”

Saamu ti Asafu.

82 Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá,
    ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn “ọlọ́run òrìṣà”.

“Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìṣòdodo
    kí ó sì ṣe ojú ìṣáájú sí àwọn ènìyàn búburú?
Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba;
    ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára.
Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní;
    gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú.

“Wọn kò mọ̀ ohun kankan,
    wọn kò lóye ohun kankan.
Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn;
    à si mí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé.

(A)“Mo wí pé, ‘Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”;
    ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ.’
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ó kú bí ènìyàn lásán;
    ẹ̀yin ó ṣubú bí ọ̀kan nínú ọmọ-aládé.”

Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé,
    nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè ni ìní rẹ.

Isaiah 59:15-21

15 A kò rí òtítọ́ mọ́,
    àti ẹni tí ó bá sá fun ibi tì di ìjẹ.

Olúwa wò ó ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́
    pé kò sí ìdájọ́ òdodo.
16 Òun rí i pé kò sí ẹnìkan,
    àyà fò ó pé kò sí ẹnìkan láti ṣèrànwọ́;
nítorí apá òun tìkára rẹ̀ ló ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún ara rẹ̀,
    àti òdodo òun tìkára rẹ̀ ló gbé e ró.
17 (A)Ó gbé òdodo wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbàyà rẹ̀,
    àti àṣíborí ìgbàlà ní orí rẹ̀;
ó gbé ẹ̀wù ẹ̀san wọ̀
    ó sì yí ara rẹ̀ ní ìtara bí ẹ̀wù.
18 Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n ti ṣe,
    bẹ́ẹ̀ ni yóò san án
ìbínú fún àwọn ọ̀tá rẹ̀
    àti ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀;
    òun yóò san án fún àwọn erékùṣù ẹ̀tọ́ wọn.
19 (B)Láti ìwọ̀-oòrùn, àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,
    àti láti ìlà-oòrùn, wọn yóò bọ̀wọ̀ fún ògo rẹ̀.
Nítorí òun yóò wá gẹ́gẹ́ bí i rírú omi
    èyí tí èémí Olúwa ń tì lọ.

20 (C)“Olùdáǹdè yóò wá sí Sioni,
    sí àwọn tí ó wà ní Jakọbu tí ó
    ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni Olúwa wí.

21 “Àti fún èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn nìyìí,” ni Olúwa wí, “Ẹ̀mí mi, tí ó wà nínú yín, àti ọ̀rọ̀ mi tí mo ti fi sí ẹnu yín, kì yóò kúrò lẹ́nu yín, tàbí lẹ́nu àwọn ọmọ yín, tàbí láti ẹnu àwọn ìrandíran wọn láti àkókò yìí lọ àti títí láéláé” ni Olúwa wí.

2 Timotiu 1:15-2:13

15 Èyí ni ìwọ mọ̀ pé, gbogbo àwọn ti ó wà ni agbègbè Asia ti fi mí sílẹ̀, nínú àwọn ẹni tí Figeliu àti Hamogene gbé wà.

16 Kí Olúwa fi àánú fún ilé Onesiforu; nítorí ti ó máa ń tù mi lára nígbà púpọ̀, ẹ̀wọ̀n mi kò sì tì í lójú. 17 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wà ni Romu, ó fi ẹ̀sọ̀ wá mi, ó sì rí mi. 18 Kí Olúwa fi fún un kí ó lè rí àánú lọ́dọ̀ Olúwa ni ọjọ́ náà! Ìwọ tìkára rẹ sá à mọ̀ ọ̀nà gbogbo tí ó gbà ràn mí lọ́wọ́ ni Efesu.

Nítorí náà ìwọ ọmọ mi, jẹ́ alágbára nínú oore-ọ̀fẹ́ ti ń bẹ nínú Kristi Jesu. Àwọn ohun ti ìwọ ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀, àwọn náà ni kí ìwọ fi lé àwọn olóòtítọ́ ènìyàn lọ́wọ́, àwọn ti yóò lè máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú. Ṣe alábápín pẹ̀lú mi nínú ìpọ́njú, bí ọmọ-ogun rere Jesu Kristi. Kò sí ẹni tí ń jagun ti ń fi ohun ayé yìí dí ara rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè mú inú ẹni tí ó yàn ni ọmọ-ogun dùn. Ní ọ̀nà kan náà, bí ẹnikẹ́ni bá sì ń díje bí olùdíje, a kì í dé e ládé, bí kò ṣe bí ó bá parí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà Àgbẹ̀ ti ó ń ṣe làálàá ni ó yẹ láti kọ́kọ́ mu nínú àwọn èso. Ronú lórí ohun ti èmi ń sọ; nítorí Olúwa yóò fún ọ lóye nínú ohun gbogbo.

Rántí Jesu Kristi, ti ó jíǹde kúrò nínú òkú, láti inú irú-ọmọ Dafidi gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere mi. Nínú èyí tí èmi ń rí ìpọ́njú títí dé inú ìdè bí arúfin; ṣùgbọ́n a kò de ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 10 Nítorí náà mo ń faradà ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́; kí àwọn náà pẹ̀lú lè ní ìgbàlà tí ń bẹ nínú Kristi Jesu pẹ̀lú ògo ayérayé.

11 Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà:

Bi àwa bá bá a kú,
    àwa yóò yè pẹ̀lú rẹ̀.
12 Bí àwa bá faradà,
    àwa ó sì bá a jẹ ọba:
Bí àwa bá sẹ́ ẹ,
    òun náà yóò sì sẹ́ wa.
13 Bí àwa kò bá gbàgbọ́,
    òun dúró ni olóòtítọ́:
    Nítorí òun kò lè sẹ́ ara rẹ̀.

Marku 10:1-16

Ìkọ̀sílẹ̀

10 (A)(B) Nígbà náà, Jesu kúrò níbẹ̀, ó sì wá sí ẹkùn Judea níhà òkè odò Jordani. Àwọn ènìyàn sì tún tọ̀ ọ́ wá, bí i ìṣe rẹ̀, ó sì kọ́ wọn.

Àwọn Farisi kan tọ̀ ọ́ wá, láti dán an wò. Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ó ha tọ̀nà fún ènìyàn láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀?”

Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni Mose pàṣẹ fún un yín?”

(C)Wọ́n dáhùn pé, “Mose yọ̀ǹda fún wa láti kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, kí a sì fi sílẹ̀.”

Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn, ó sì wí pé, “Nítorí líle àyà yín ni Mose fi kọ òfin yìí fun un yín. (D)Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, Ọlọ́run dá wọn ní akọ àti abo. (E)Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ yóò sì fi ara mọ́ aya rẹ̀. Òun àti ìyàwó rẹ̀ yóò di ara kan náà. Nítorí náà, wọn kì í túnṣe méjì mọ́ bí kò ṣe ẹyọ ọ̀kan ṣoṣo. Nítorí náà ohun ti Ọlọ́run bá sọ dọ̀kan, ki ẹnikẹ́ni máa ṣe yà wọ́n.”

10 Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jesu nìkan wà nínú ilé pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n tún béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa ohun kan náà. 11 (F)Jesu túbọ̀ ṣe àlàyé fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ tí ó bá sì fẹ́ ẹlòmíràn, irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ṣe panṣágà sí obìnrin tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé níyàwó. 12 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí obìnrin kan bá kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì fẹ́ ọkùnrin mìíràn, irú obìnrin bẹ́ẹ̀ ṣe panṣágà.”

Jesu àti àwọn ọmọdé

13 (G)Lẹ́yìn èyí, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ tọ Jesu wá kí ó lè súre fún wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kígbe mọ́ àwọn tí ń gbé àwọn ọmọdé wọ̀nyí bọ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ yọ Jesu lẹ́nu rárá. 14 Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu rí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, inú rẹ̀ kò dùn sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Nítorí náà, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé kékeré wá sọ́dọ̀ mi. Ẹ má ṣe dá wọn lẹ́kun nítorí pé irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run. 15 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kì yóò le è wọ inú rẹ̀.” 16 (H)Nígbà náà, Jesu gbé àwọn ọmọ náà lé ọwọ́ rẹ̀, ó gbé ọwọ́ lé orí wọn. Ó sì súre fún wọn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.