Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 24

Ti Dafidi. Saamu.

24 (A)Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀,
    ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀;
Nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí Òkun
    ó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.

Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ?
    Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?
(B)Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun,
    ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán
    tí kò sì búra èké.

Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa,
    àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.
Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀,
    tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. Sela.

Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà;
    Kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé!
    Kí ọba ògo le è wọlé.
Ta ni ọba ògo náà?
    Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le,
    Olúwa gan an, tí ó lágbára ní ogun.
Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà;
    kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,
    kí Ọba ògo le è wọlé wá.
10 Ta ni Ọba ògo náà?
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    Òun ni Ọba ògo náà. Sela.

Saamu 29

Saamu ti Dafidi.

29 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,
    Ẹ fi fún Olúwa, ògo àti alágbára.
Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ rẹ̀;
    sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.

Ohùn Olúwa n ré àwọn omi kọjá;
    Ọlọ́run ògo sán àrá,
    Olúwa san ara.
Ohùn Olúwa ní agbára;
    ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.
Ohùn Olúwa fa igi kedari;
    Olúwa náà ló fọ́ igi kedari Lebanoni ya.
Ó mú Lebanoni fo bí i ọmọ màlúù,
    àti Sirioni bí ọmọ àgbáǹréré.
Ohùn Olúwa ń ya
    bí ọwọ́ iná mọ̀nà
Ohùn Olúwa ń mi aginjù.
    Olúwa mi aginjù Kadeṣi.
Ohùn Olúwa ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀nrín bí,
    ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòhò.
Àti nínú tẹmpili rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé “Ògo!”

10 Olúwa jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi;
    Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.
11 Olúwa fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀;
    bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.

Saamu 8

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Saamu ti Dafidi.

Olúwa, Olúwa wa,
    orúkọ rẹ̀ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!

Ìwọ ti gbé ògo rẹ ga
    ju àwọn ọ̀run lọ.
(A)Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmú
    ni o ti yan ìyìn nítorí àwọn ọ̀tá rẹ,
    láti pa àwọn ọ̀tá àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.
Nígbà tí mo ro ọ̀run rẹ,
    iṣẹ́ ìka rẹ,
òṣùpá àti ìràwọ̀,
    tí ìwọ tí gbé kalẹ̀,
kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa rẹ̀,
    àní ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀?

Ìwọ ṣe é ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju Ọlọ́run lọ,
    ìwọ sì dé e ní adé ògo àti ọlá.
Ìwọ mú un jẹ ọba lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ;
    ìwọ sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:
àwọn agbo àgùntàn àti àwọn màlúù,
    àti ẹranko igbó,
ẹyẹ ojú ọrun,
    àti ẹja inú Òkun,
    àti ohun tí ń wẹ nínú ipa Òkun.

Olúwa, Olúwa wa,
    Orúkọ rẹ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!

Saamu 84

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

84 Ibùgbé rẹ̀ ti lẹ́wà tó,
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun!
Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́
    ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá Olúwa
àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀
    sí Ọlọ́run alààyè.
Nítòótọ́ ológoṣẹ́ ri ilé,
    ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀,
    níbi tí yóò máa pa ọmọ rẹ̀ mọ́ sí:
ibùgbé ní tòsí pẹpẹ rẹ̀,
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.
Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé rẹ;
    wọn ó máa yìn ọ́ títí láé.

Ìbùkún ni fún àwọn tí agbára wọn wà nínú rẹ
    àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.
Àwọn tí ń la Àfonífojì omijé lọ
    wọn sọ ọ́ di kànga
    àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó;
Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá
    títí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Sioni.

Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa Ọlọ́run Alágbára;
    tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jakọbu.
Wo asà wa, Ọlọ́run;
    fi ojú àánú wò àwọn ẹni ààmì òróró rẹ.

10 Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin rẹ
    ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ lọ;
èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run mi
    jù láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú.
11 Nítorí Olúwa Ọlọ́run jẹ́ òòrùn àti asà;
    Olúwa fún ni ní ojúrere àti ọlá;
kò sí ohun rere kan tí yóò fàsẹ́yìn
    fún àwọn tí ó rìn ní àìlábùkù.

12 Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
    ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.

Isaiah 51:9-16

Dìde, dìde! Kí o sì wọ ara rẹ ní agbára
    Ìwọ apá Olúwa;
dìde gẹ́gẹ́ bí i ti ọjọ́ ìgbà n nì,
    àti gẹ́gẹ́ bí i ti ìran àtijọ́.
Ìwọ kọ́ lo ké Rahabu sí wẹ́wẹ́
    tí o sì fa ẹ̀mí búburú ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ?
10 Ìwọ kọ́ ni ó gbẹ omi Òkun bí
    àti àwọn omi inú ọ̀gbun,
Tí o sì ṣe ọ̀nà nínú ìsàlẹ̀ Òkun
    tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹni ìràpadà yóò fi le là á kọjá?
11 Àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá.
    Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin kíkọ;
ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo orí wọn.
    Ayọ̀ àti inú dídùn yóò sì bà lé wọn
    ìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò.

12 “Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú.
    Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran ara,
    àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán,
13 tí ìwọ sì gbàgbé Olúwa ẹlẹ́dàá rẹ,
    ẹni tí ó ta àwọn ọ̀run
tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
    tí ẹ sì ń gbé nínú ìpayà lójoojúmọ́
nítorí ìbínú àwọn aninilára,
    tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀lé ìpanirun?
    Nítorí ibo ni ìbínú àwọn aninilára gbé wà?
14 Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ń ṣojo la ó dá sílẹ̀ ní àìpẹ́ jọjọ
    wọn kò ní kú sínú túbú wọn,
    bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣe aláìní àkàrà.
15 Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
    tí ó ń ru Òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí
ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
16 Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ
    mo sì ti fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́
Èmi tí mo tẹ́ àwọn ọ̀run sí ààyè rẹ̀,
    ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀,
àti ẹni tí ó sọ fún Sioni pé,
    ‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi.’ ”

Heberu 11:8-16

(A)Nípa ìgbàgbọ́ ní Abrahamu, nígbà tí a ti pé e láti jáde lọ sí ibi tí òun yóò gbà fún ilẹ̀ ìní, ó gbọ́, ó sì jáde lọ, láì mọ ibi tí òun ń rè. Nípa ìgbàgbọ́ ní o ṣe àtìpó ní ilẹ̀ ìlérí, bí ẹni pé ni ilẹ̀ àjèjì, o ń gbé inú àgọ́, pẹ̀lú Isaaki àti Jakọbu, àwọn ajogún ìlérí kan náà pẹ̀lú rẹ̀: 10 Nítorí tí ó ń retí ìlú tí ó ní ìpìlẹ̀; èyí tí Ọlọ́run tẹ̀dó tí ó sì kọ́. 11 (B)Nípa ìgbàgbọ́ ni Sara tìkára rẹ̀ pẹ̀lú fi gba agbára láti lóyún, nígbà tí ó kọjá ìgbà rẹ̀, nítorí tí o ka ẹni tí o ṣe ìlérí sí olóòótọ́. 12 (C)Nítorí náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣe ti ara ọkùnrin kan jáde, àní ara ẹni tí o dàbí òkú, ọmọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ́pọ̀lọpọ̀, àti bí iyanrìn etí Òkun láìníye.

13 (D)Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ó kú nínú ìgbàgbọ́, láìrí àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n tí wọn rí wọn ni òkèrè réré, tí wọ́n sì gbá wọn mú, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ pé àlejò àti àjèjì ni àwọn lórí ilẹ̀ ayé. 14 Nítorí pé àwọn tí o ń sọ irú ohun bẹ́ẹ̀ fihàn gbangba pé, wọn ń ṣe àfẹ́rí ìlú kan tí i ṣe tiwọn. 15 Àti nítòótọ́, ìbá ṣe pé wọ́n fi ìlú tiwọn tí jáde wá sí ọkàn, wọn ìbá ti rí ààyè padà. 16 (E)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n ń fẹ́ ìlú kan tí o dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, èyí yìí ni ti ọ̀run: nítorí náà ojú wọn kò ti Ọlọ́run, pé kí a máa pé òun ni Ọlọ́run wọn; nítorí tí o ti pèsè ìlú kan sílẹ̀ fún wọn.

Johanu 7:14-31

Jesu kọ́ àwọn ènìyàn

14 Nígbà tí àjọ dé àárín; Jesu gòkè lọ sí tẹmpili ó sì ń kọ́ni. 15 Ẹnu sì ya àwọn Júù, wọ́n wí pé, “Ọkùnrin yìí ti ṣe mọ ìwé, nígbà tí kò kọ́ ẹ̀kọ́?”

16 Jesu dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ̀kọ́ mi kì í ṣe tèmi, bí kò ṣe ti ẹni tí ó rán mi. 17 Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ yóò mọ̀ ní ti ẹ̀kọ́ náà, bí ìbá ṣe ti Ọlọ́run, tàbí bí èmi bá sọ ti ara mi. 18 Ẹni tí ń sọ ti ara rẹ̀ ń wá ògo ara rẹ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí ń wá ògo ẹni tí ó rán an, òun ni olóòtítọ́, kò sì sí àìṣòdodo nínú rẹ̀. 19 (A)Mose kò ha fi òfin fún yín, kò sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó pa òfin náà mọ́? Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá ọ̀nà láti pa mí?”

20 (B)Ìjọ ènìyàn dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Ìwọ ní ẹ̀mí èṣù: Ta ni ń wá ọ̀nà láti pa ọ́?”

21 (C)Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Kìkì iṣẹ́ ààmì kan ni mo ṣe, ẹnu sì ya gbogbo yín. 22 (D)Síbẹ̀, nítorí pé Mose fi ìkọlà fún yín (kò tilẹ̀ kúkú wá láti ọ̀dọ̀ Mose bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá yín); nítorí náà ẹ sì ń kọ ènìyàn ní ilà ní ọjọ́ ìsinmi. 23 (E)Bí ènìyàn bá ń gba ìkọlà ní ọjọ́ ìsinmi, kí a má ba à rú òfin Mose, ẹ ha ti ṣe ń bínú sí mi, nítorí mo mú ènìyàn kan láradá ní ọjọ́ ìsinmi? 24 (F)Ẹ má ṣe ìdájọ́ nípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa ṣe ìdájọ́ òdodo.”

Ṣé Jesu ni Kristi?

25 Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn ará Jerusalẹmu wí pé, “ẹni tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa kọ́ yìí? 26 Sì wò ó, ó ń sọ̀rọ̀ ní gbangba, wọn kò sì wí nǹkan kan sí i. Àwọn olórí ha mọ̀ nítòótọ́ pé, èyí ni Kristi náà? 27 (G)Ṣùgbọ́n àwa mọ ibi tí ọkùnrin yí gbé ti wá: ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi bá dé, kò sí ẹni tí yóò mọ ibi tí ó gbé ti wá.”

28 (H)Nígbà náà ni Jesu kígbe ní tẹmpili bí ó ti ń kọ́ni, wí pé, “Ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá: èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀. 29 (I)Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n: nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ̀ ni mo ti wá, òun ni ó rán mi.”

30 (J)Nítorí náà wọ́n ń wá ọ̀nà à ti mú un: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e, nítorí tí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé. 31 (K)Ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn sì gbà á gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Nígbà tí Kristi náà bá dé, yóò ha ṣe iṣẹ́ ààmì jù wọ̀nyí, tí ọkùnrin yìí ti ṣe lọ?”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.