Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Tí ohun orin “Lílì.” Ti orin àwọn ọmọ Kora. Maskili. Orin ìgbéyàwó.
45 Ọkàn mi mọ ọ̀rọ̀ rere
gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń sọ ohun tí mo ti ṣe fún ọba
ahọ́n mi ni kálámù ayára kọ̀wé.
2 Ìwọ yanjú ju àwọn ọmọ ènìyàn lọ:
a da oore-ọ̀fẹ́ sí ọ ní ètè:
nítorí náà ni Ọlọ́run ṣe bùkún fún ọ láéláé.
3 Gba idà rẹ mọ́ ìhà rẹ, ìwọ alágbára jùlọ
wọ ara rẹ ní ògo àti ọláńlá.
4 Nínú ọláńlá rẹ, máa gẹṣin lọ ní àlàáfíà
lórí òtítọ́, ìwà tútù àti òtítọ́
jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ohun ẹ̀rù.
5 Jẹ́ kí ọfà mímú rẹ̀ dá ọkàn àwọn ọ̀tá ọba lu
jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
6 (A)Ọlọ́run láé, àti láéláé ni ìtẹ́ rẹ,
ọ̀pá aládé ìjọba rẹ, ọ̀pá aládé òtítọ́ ni.
7 Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburú
nígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run rẹ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ,
nípa fífi ààmì òróró ayọ̀ kùn ọ́.
8 Gbogbo aṣọ rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjìá àti aloe àti kasia;
láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe
orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú rẹ̀ dùn.
9 Àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba
wà nínú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀,
ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúró
nínú wúrà ofiri.
10 Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí rẹ sí mi
gbàgbé àwọn ènìyàn rẹ àti ilé baba rẹ
11 Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà rẹ gidigidi
nítorí òun ni olúwa rẹ
kí ìwọ sì máa tẹríba fún un.
12 Ọmọbìnrin ọba Tire yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùn
àwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojúrere rẹ̀.
13 Gbogbo ògo ni ti ọmọbìnrin ọba ní àárín ilé rẹ̀,
iṣẹ́ wúrà ọnà abẹ́rẹ́ ní aṣọ rẹ̀.
14 Nínú aṣọ olówó iyebíye ni a mú un tọ́ ọba wá,
àwọn wúńdíá ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ̀lé e, wọ́n sí mú un tọ̀ ọ́ wá.
15 Wọ́n sì mú un wá pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn
wọ́n sì wọ ààfin ọba.
16 Ọmọ rẹ̀ ni yóò gba ipò baba rẹ̀
ìwọ yóò sì fi wọ́n joyè lórí ilẹ̀ gbogbo.
17 Èmí yóò máa rántí orúkọ rẹ̀ ní ìran gbogbo,
nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò yìn ọ́ láé àti láéláé.
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
47 Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn
ẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀.
2 Báwo ni Olúwa Ọ̀gá-ògo ti ní ẹ̀rù tó
ọba ńlá lórí gbogbo ayé.
3 Ṣe ìkápá àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ wa
àwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa
4 Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa
ọlá Jakọbu, ẹni tí ó fẹ́ wa.
5 Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀,
Olúwa ti òun ti ariwo ìpè.
6 Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn.
Ẹ kọrin ìyìn sí ọba wa, ẹ kọrin ìyìn!
7 Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayé,
ẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Saamu!
8 Ọlọ́run jẹ ọba lórí gbogbo kèfèrí;
Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ rẹ̀.
9 Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọ
gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Abrahamu
nítorí asà ayé ti Ọlọ́run ni,
òun ni ó ga jùlọ.
Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora.
48 Ẹni ńlá ní Olúwa, tí ó sì yẹ láti máa yìn
ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀.
2 (A)Ó dára nínú ipò ìtẹ́ rẹ̀,
ayọ̀ gbogbo ayé
òkè Sioni, ní ìhà àríwá
ní ìlú ọba ńlá.
3 Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin rẹ̀;
ó fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.
4 Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀,
wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ.
5 Wọn rí i bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́n
a yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ
6 Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀,
ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí.
7 Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Tarṣiṣi,
wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà-oòrùn.
8 Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́,
Bẹ́ẹ̀ ni àwa rí,
Ní inú Olúwa àwọn ọmọ-ogun
ní ìlú Ọlọ́run wa,
Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. Sela.
9 Láàrín tẹmpili rẹ, Ọlọ́run,
àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
10 Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ Ọlọ́run,
ìyìn rẹ̀ dé òpin ayé,
ọwọ́ ọ̀tún rẹ kún fún òdodo.
11 Jẹ́ kí òkè Sioni kí ó yọ̀
kí inú àwọn ọmọbìnrin Juda kí ó dùn
nítorí ìdájọ́ rẹ.
12 Rìn Sioni kiri lọ yíká rẹ̀,
ka ilé ìṣọ́ rẹ̀.
13 Kíyèsi odi rẹ̀,
kíyèsi àwọn ààfin rẹ̀
kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀.
14 Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé,
Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.
Israẹli dòmìnira
12 (A)“Tẹ́tí sí mi, ìwọ Jakọbu
Israẹli ẹni tí mo pè:
Èmi ni ẹni náà;
Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn.
13 Ọwọ́ mi pàápàá ni ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
àti ọwọ́ ọ̀tún mi ni ó tẹ àwọn ọ̀run;
nígbà tí mo pè wọ́n,
gbogbo wọn dìde sókè papọ̀.
14 “Gbogbo yín, ẹ péjọ kí ẹ sì gbọ́:
Ta nínú wọn ni ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí.
Olúwa ti fẹ́ ẹ,
yóò sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní Babiloni,
apá rẹ̀ ni yóò sì wà ní ará àwọn ará Kaldea.
15 Èmi, àní Èmi ló ti sọ̀rọ̀;
bẹ́ẹ̀ ni, mo ti pè é.
Èmi yóò mú un wá,
òun yóò sì ṣe àṣeyọrí nínú ìrìnàjò rẹ̀.
16 “Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì dẹtí sí èyí:
“Láti ìgbà ìkéde àkọ́kọ́ èmi kò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀;
ní àsìkò tí ó sì ṣẹlẹ̀, Èmi wà níbẹ̀.”
Àti ní àkókò yìí, Olúwa Olódùmarè ni ó ti rán mi,
pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ̀.
17 Èyí ni ohun tí Olúwa wí
Olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli:
“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
tí ó kọ́ ọ ní ohun tí ó dára fún ọ,
tí ó tọ́ ọ ṣọ́nà tí ó yẹ kí o máa rìn.
18 Bí ó bá ṣe pé ìwọ bá ti tẹ́tí sílẹ̀ sí àṣẹ mi,
àlàáfíà rẹ kì bá ti dàbí ì ti odò,
àti òdodo rẹ bí ìgbì Òkun.
19 Àwọn ọmọ rẹ ìbá ti dàbí iyanrìn,
àwọn ọmọ yín bí i hóró ọkà tí a kò lè kà tán;
orúkọ wọn ni a kì yóò ké kúrò
tàbí kí a pa wọ́n run níwájú mi.”
20 Fi Babeli sílẹ̀,
sá fún àwọn ará Babeli,
ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀
kí o sì kéde rẹ̀.
Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé;
wí pé, “Olúwa ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jakọbu nídè.”
21 Òrùngbẹ kò gbẹ wọ́n nígbà tí ó kó wọn
kọjá nínú aginjù;
ó jẹ́ kí omi ó sàn fún wọn láti inú àpáta;
ó fọ́ àpáta
omi sì tú jáde.
18 (A)Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, nígbà náà ni mo gòkè lọ sì Jerusalẹmu láti lọ kì Peteru, mo sì gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní ìjọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, 19 Èmi kò ri ẹlòmíràn nínú àwọn tí ó jẹ́ aposteli, bí kò ṣe Jakọbu arákùnrin Olúwa. 20 Nǹkan tí èmi ń kọ̀wé sí yín yìí, kíyèsi i, níwájú Ọlọ́run èmi kò ṣèké.
21 Lẹ́yìn náà mo sì wá sí agbègbè Siria àti ti Kilikia; 22 Mo sì jẹ́ ẹni tí a kò mọ̀ lójú fún àwọn ìjọ tí ó wà nínú Kristi ni Judea: 23 Wọ́n kàn gbọ́ ìròyìn wí pé, “Ẹni tí ó tí ń ṣe inúnibíni sí wa rí, ní ìsinsin yìí ti ń wàásù ìgbàgbọ́ náà tí ó ti gbìyànjú láti bàjẹ́ nígbà kan rí.” 24 Wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo nítorí mi.
Àwọn aposteli tẹ́wọ́ gba Paulu
2 (B)Lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlá, ni mo tún gòkè lọ sì Jerusalẹmu pẹ̀lú Barnaba, mo sì mú Titu lọ pẹ̀lú mi. 2 Mo gòkè lọ nípa ohun ti a fihàn mi, mo fi ìhìnrere náà tí mo ń wàásù láàrín àwọn aláìkọlà yé àwọn tí ó jẹ́ ẹni ńlá nínú wọn, èyí i nì ní ìkọ̀kọ̀, kí èmi kí ó má ba á sáré, tàbí kí ó máa ba à jẹ́ pé mo ti sáré lásán. 3 Ṣùgbọ́n a kò fi agbára mú Titu tí ó wà pẹ̀lú mi, ẹni tí í ṣe ara Giriki láti kọlà. 4 Ọ̀rọ̀ yìí wáyé nítorí àwọn èké arákùnrin tí wọn yọ́ wọ inú àárín wa láti yọ́ òmìnira wa wò, èyí tí àwa ni nínú Kristi Jesu, kí wọn lè mú wa wá sínú ìdè. 5 (C)Àwọn ẹni ti a kò fún ni àǹfààní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn fún ìṣẹ́jú kan; kí ẹ̀yin kí o lè máa tẹ̀síwájú nínú òtítọ́ ìhìnrere náà.
6 (D)Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ó dàbí ẹni pàtàkì—ohunkóhun tí ó wù kì wọn jásí, kò jẹ́ nǹkan kan fún mi; Ọlọ́run kò fi bí ẹnikẹ́ni ṣe rí ṣe ìdájọ́ rẹ̀—àwọn ènìyàn yìí kò fi ohunkóhun kún ọ̀rọ̀ mi. 7 Ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọn rí i pé a tí fi ìhìnrere tí àwọn aláìkọlà le mi lọ́wọ́, bí a tí fi ìhìnrere tí àwọn onílà lé Peteru lọ́wọ́. 8 Nítorí Ọlọ́run, ẹni tí ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Peteru gẹ́gẹ́ bí aposteli sí àwọn Júù, òun kan náà ni ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí aposteli sí àwọn aláìkọlà. 9 Jakọbu, Peteru, àti Johanu, àwọn ẹni tí ó dàbí ọ̀wọ́n, fún èmi àti Barnaba ni ọwọ́ ọ̀tún ìdàpọ̀ nígbà tí wọ́n rí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, wọ́n sì gbà pé kí àwa náà tọ àwọn aláìkọlà lọ, nígbà ti àwọn náà lọ sọ́dọ̀ àwọn Júù. 10 Ohun gbogbo tí wọ́n béèrè fún ni wí pé, kí a máa rántí àwọn tálákà, ohun kan náà gan an tí mo ń làkàkà láti ṣe.
Wòlíì tí kò ní ọlá
6 (A)Jesu fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí ìlú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ 2 (B)Nígbà tí ó di ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sí Sinagọgu láti kọ́ àwọn ènìyàn: ẹnu sì ya àwọn ènìyàn púpọ̀ tí ó gbọ́.
Wọ́n wí pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí gbé ti rí nǹkan wọ̀nyí? Irú ọgbọ́n kí ni èyí tí a fi fún un, tí irú iṣẹ́ ìyanu báyìí ń ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe? 3 (C)Gbẹ́nàgbẹ́nà náà kọ́ yìí? Ọmọ Maria àti arákùnrin Jakọbu àti Josẹfu, Judasi àti Simoni? Àwọn arábìnrin rẹ̀ gbogbo ha kọ́ ni ó ń bá wa gbé níhìn-ín yìí?” Wọ́n sì kọsẹ̀ lára rẹ̀.
4 Nígbà náà, Jesu wí fún wọn pé, “A máa ń bu ọlá fún wòlíì níbi gbogbo àfi ní ìlú ara rẹ̀ àti láàrín àwọn ìdílé àti àwọn ẹbí òun pàápàá.” 5 (D)Nítorí àìgbàgbọ́ wọn, òun kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá láàrín wọn, àfi àwọn aláìsàn díẹ̀ tí ó gbé ọwọ́ lé lórí, tí wọ́n sì rí ìwòsàn.
Jesu rán ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá jáde
6 (E)Ẹnu si yà á nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, Jesu lọ sí àárín àwọn ìletò kéékèèkéé, ó sì ń kọ́ wọn. 7 (F)(G)Ó sì pe àwọn méjìlá náà sọ́dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí rán wọn lọ ní méjì méjì, Ó sì fi àṣẹ fún wọn lórí ẹ̀mí àìmọ́.
8 O sọ fún wọn pé, wọn kò gbọdọ̀ mú ohunkóhun lọ́wọ́, àfi ọ̀pá ìtìlẹ̀ wọn. Wọn kò gbọdọ̀ mú oúnjẹ, àpò ìgbànú, tàbí owó lọ́wọ́. 9 Wọn kò tilẹ̀ gbọdọ̀ mú ìpààrọ̀ bàtà tàbí aṣọ lọ́wọ́. 10 Jesu wí pé, “Ẹ dúró sí ilé kan ní ìletò kan. Ẹ má ṣe sípò padà láti ilé dé ilé, nígbà tí ẹ bá wà ní ìlú náà. 11 (H)Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tí kò sì gbọ́rọ̀ yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò níbẹ̀, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín síbẹ̀ fún ẹ̀rí fún wọn.”
12 (I)Wọ́n jáde lọ láti wàásù ìrònúpìwàdà fún àwọn ènìyàn. 13 (J)Wọ́n lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde. Wọ́n sì ń fi òróró kun orí àwọn tí ara wọn kò dá, wọ́n sì mú wọn láradá.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.