Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 40

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.

40 Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de Olúwa;
    ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi.
Ó fà mí yọ gòkè
    láti inú ihò ìparun,
láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀,
    ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta,
ó sì jẹ́ kí ìgbésẹ̀ mi wà láìfòyà.
Ó fi orin tuntun sí mi lẹ́nu,
    àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa.
Ọ̀pọ̀ yóò rí i wọn yóò sì bẹ̀rù,
    wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n-ọn-nì
    tí ó fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn
tí wọn kò sì yípadà sí agbéraga,
    tàbí àwọn tí ó yapa
lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn.
Olúwa Ọlọ́run mi, Ọ̀pọ̀lọpọ̀
    ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe.
Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa;
    ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹ
tí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn,
    wọ́n ju ohun tí
ènìyàn le è kà lọ.

(A)Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́,
    ìwọ ti ṣí mi ní etí.
Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀
    ni ìwọ kò béèrè.
Nígbà náà ni mo wí pé,
    “Èmi nìyí;
nínú ìwé kíká ni
    a kọ ọ nípa tèmi wí pé.
Mo ní inú dídùn
    láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ,
ìwọ Ọlọ́run mi;
    Òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”

Èmi ti sọ ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlà
    láàrín àwùjọ ńlá;
wò ó,
    èmi kò pa ètè mi mọ́,
gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti mọ̀,
    ìwọ Olúwa.
10 Èmi kò fi ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà sin ní àyà mi;
    èmí ti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ àti ìgbàlà rẹ.
Èmi kò sì pa ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ mọ́
    kúrò láàrín àwọn ìjọ ńlá.

11 Ìwọ má ṣe,
    fa àánú rẹ tí ó rọ́nú
sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi; Olúwa
    jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ rẹ
àti òtítọ́ rẹ
    kí ó máa pa mi mọ́
títí ayérayé.
12 Nítorí pé àìníye ibi
    ni ó yí mi káàkiri,
ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi,
    títí tí èmi kò fi ríran mọ́;
wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,
    àti wí pé àyà mí ti kùnà.

13 (B)Jẹ́ kí ó wù ọ́,
    ìwọ Olúwa,
láti gbà mí là;
    Olúwa,
yára láti ràn mí lọ́wọ́.

14 Gbogbo àwọn wọ̀n-ọn-nì
    ni kí ojú kí ó tì
kí wọn kí ó sì dààmú
    àwọn tí ń wá ọkàn mi
láti parun:
    jẹ́ kí a lé wọn padà sẹ́yìn
kí a sì dójútì wọ́n,
    àwọn tí ń wá ìpalára mi.
15 Jẹ́ kí àwọn tí ó wí fún mi pé, “Háà! Háà!”
    ó di ẹni à fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí ìtìjú wọn.
16 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ
    kí ó máa yọ̀
kí inú wọn sì máa dùn sí ọ;
    kí gbogbo àwọn tí ó sì fẹ́ ìgbàlà rẹ
kí o máa wí nígbà gbogbo pé,
    “Gbígbéga ni Olúwa!”

17 Bí ó ṣe ti èmi ni,
    tálákà àti aláìní ni èmi,
ṣùgbọ́n Olúwa ń ṣe ìrántí mi.
    Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi
àti ìgbàlà mi;
    Má ṣe jẹ́ kí ó pẹ́,
    ìwọ Ọlọ́run mi.

Saamu 54

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí àwọn ará Sifi lọ sọ fún Saulu pé, “Dafidi sá pamọ́ sọ́dọ̀ wa”.

54 Gbà mí, Ọlọ́run nípa orúkọ rẹ:
    dá mi láre nípa agbára rẹ.
Gbọ́ àdúrà mi, Ọlọ́run;
    fi etí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

Àwọn agbéraga àlejò dìde sí mí.
    Àwọn aninilára sì ń wá mi láti pa,
àwọn ẹni tí kò ka Ọlọ́run sí ní ojú wọn.

Kíyèsi i Ọlọ́run ni Olùrànlọ́wọ́ mi;
    Olúwa ní ẹni tí ó mú mi dúró,
    pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ.

Jẹ́ kí ibi padà sẹ́yìn sí àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi;
    pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ.

Èmí yóò rú ẹbọ àtinúwá sí ọ,
    èmi yóò yin orúkọ rẹ, Olúwa,
    nítorí tí ó dára.
Nítorí tí ó yọ mí kúrò nínú ibi gbogbo
    ojú mi ti wo ìṣẹ́gun lórí ọ̀tá mi.

Saamu 51

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Nígbà ti wòlíì Natani tọ wá, lẹ́yìn tí Dafidi dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè rẹ̀ pẹ̀lú Batṣeba.

51 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí
    ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ̀,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀
    kí o sì pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́.
Wẹ gbogbo àìṣedéédéé mi nù kúrò
    kí o sì wẹ̀ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi!

Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi,
    nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi.
(A)Sí ọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí
    ni mo sì ṣe búburú níwájú rẹ̀,
kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀,
    kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọ bá ń ṣe ìdájọ́.
Nítòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi,
    nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi.
Nítòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú;
    ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀kọ̀.

Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé hísópù, èmi yóò sì mọ́;
    fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju yìnyín lọ.
Jẹ́ kí n gbọ́ ayọ̀ àti inú dídùn;
    jẹ́ kí gbogbo egungun tí ìwọ ti run kí ó máa yọ̀.
Pa ojú rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi
    kí o sì pa gbogbo àwọn àìṣedéédéé mi rẹ́.

10 Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run,
    kí o sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi.
11 Má ṣe jù mi nù kúrò níwájú rẹ,
    kí o má ṣe gba ẹ̀mí mímọ́ rẹ lọ́wọ́ mi.
12 Mú ayọ̀ ìgbàlà rẹ tọ̀ mí wá,
    kí o sì fún mi ní ẹ̀mí ìfẹ́, tí yóò mú mi dúró.

13 Nígbà náà ni èmi yóò máa kọ́ àwọn olùrékọjá ní ọ̀nà rẹ,
    àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò sì yí padà sí ọ.
14 Gbà mí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, Ọlọ́run,
    ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà mi,
ahọ́n mi yóò sì máa kọrin òdodo rẹ kíkan.
15 Olúwa, ṣí mi ní ètè mi gbogbo,
    àti ẹnu mi yóò sì máa kéde ìyìn rẹ.
16 Nítorí ìwọ kò ní inú dídùn sí ẹbọ, tí èmi kò bá mú wá;
    Ìwọ kò ní inú dídùn sí ọrẹ ẹbọ sísun.
17 Ẹbọ Ọlọ́run ni ìròbìnújẹ́ ọkàn ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà.

18 Ṣe rere ní dídùn inú rẹ sí Sioni,
    ṣe rere; tún odi Jerusalẹmu mọ.
19 Nígbà náà ni inú rẹ yóò dùn sí ẹbọ òdodo,
    pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ọrẹ ẹbọ sísun,
    nígbà náà ni wọn yóò fi akọ màlúù rú ẹbọ lórí pẹpẹ rẹ.

Isaiah 10:5-19

Ìdájọ́ Ọlọ́run Lórí Asiria

(A)“Ègbé ni fún àwọn ará Asiria, ọ̀gọ ìbínú mi,
    ní ọwọ́ ẹni tí kùmọ̀ ìbínú mi wà!
Mo rán an sí orílẹ̀-èdè aláìní Ọlọ́run
    Mo dojú rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn tí ó mú mi bínú
láti já ẹrù gbà, àti láti kó ìkógun
    láti tẹ̀ mọ́lẹ̀ bí amọ̀ ní ojú òpópó.
Ṣùgbọ́n, èyí kì í ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣe,
    èyí kọ́ ni ohun tí ó ní lọ́kàn;
èrò rẹ̀ ni láti parun,
    láti fi òpin sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.
‘Kì í ha ṣe pé ọba ni gbogbo àwọn aláṣẹ mi?’ ni Olúwa wí.
‘Kì í ha ṣe pé Kalno dàbí i Karkemiṣi?
    Hamati kò ha dàbí i Arpadi,
    àti Samaria bí i Damasku?
10 Gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ti gbá ìjọba àwọn òrìṣà mú,
    ìjọba tí ère rẹ̀ pọ̀ ju ti Jerusalẹmu àti Samaria lọ.
11 Èmi kì yóò a bá Jerusalẹmu wí àti àwọn ère rẹ̀?’ ”
    Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe sí Samaria àti àwọn ère rẹ̀?

12 Nígbà tí Olúwa ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Sioni àti Jerusalẹmu, yóò sọ wí pé, “Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Asiria nítorí gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojú rẹ̀. 13 Nítorí ó sọ pé:

“ ‘Pẹ̀lú agbára ọwọ́ mi ni mo fi ṣe èyí
    àti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye.
Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀-èdè kúrò,
    Mo sì ti kó ìṣúra wọn.
    Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn.
14 Bí ènìyàn ti í tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ,
    bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi tẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè.
Bí ènìyàn ti í kó ẹyin tí a kọ̀sílẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni mo kó àwọn orílẹ̀-èdè
kò sí èyí tí ó fi apá lu apá,
    tàbí kí ó ya ẹnu láti dún.’ ”

15 Ǹjẹ́ àáké le gbé ara rẹ̀ sókè kọjá ẹni tí ó ń fì í,
    tàbí kí ayùn fọ́nnu sí ẹni tí ó ń lò ó?
Àfi bí ẹni pé ọ̀pá ó na ẹni tí ó gbé e sókè,
    tàbí kí kùmọ̀ lu èyí tí kì í ṣe igi.
16 Nítorí náà, ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
    yóò rán ààrùn ìrẹ̀dànù sórí
àwọn akíkanjú jagunjagun,
    lábẹ́ ògo rẹ̀ ni iná kan yóò ti sọ
    gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun.
17 Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóò di iná,
    Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ọ̀wọ́-iná,
ní ọjọ́ kan ṣoṣo yóò jó yóò sì run
    àti ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n.
18 Gbogbo ẹwà igbó o rẹ̀, àti àwọn pápá ọlọ́ràá
    gbogbo rẹ̀ ni yóò run pátápátá,
gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ṣàìsàn ti í ṣòfò dànù.
19 Àwọn igi tí yóò kù nínú igbó o rẹ̀
    yóò kéré níye,
    tí ọ̀dọ́mọdé yóò fi le kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

2 Peteru 2:17-22

17 Àwọn wọ̀nyí ni kànga tí kò ní omi, ìkùùkuu tí ẹ̀fúùfù ń gbá kiri; àwọn ẹni tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè títí láé. 18 Nítorí ìgbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ asán, nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, wọn a máa tan àwọn tí wọ́n fẹ́rẹ̀ má tí ì bọ́ tán kúrò lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n wà nínú ìṣìnà. 19 Wọn a máa ṣe ìlérí òmìnira fún wọn, nígbà tí àwọn pàápàá jẹ́ ẹrú ìdíbàjẹ́; nítorí ènìyàn tí di ẹrú ohunkóhun tí ó bá ṣe ọ̀gá rẹ̀. 20 Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yọ tán kúrò nínú èérí ayé nípa mímọ́ Olúwa àti Olùgbàlà wá Jesu Kristi, bí wọn bá sì tún fi ara kó o, tí a sì ṣẹ́gun wọn, ìgbẹ̀yìn wọn a burú jú ti ìṣáájú lọ. 21 Nítorí ìbá sàn fún wọn, kí wọn má mọ́ ọ̀nà òdodo, jù pé lẹ́yìn tí wọ́n mọ̀ ọ́n tán, kí wọn yípadà kúrò nínú òfin mímọ́ tí a fi fún wọn. 22 (A)Òwe òtítọ́ náà ṣẹ sí wọn lára: “Ajá tún padà sí èébì ara rẹ̀; àti ẹlẹ́dẹ̀ tí a ti wẹ̀mọ́ tún padà ń yíràá nínú ẹrọ̀fọ̀.”

Matiu 11:2-15

(A)Nígbà tí Johanu gbọ́ ohun tí Kristi ṣe nínú ẹ̀wọ̀n, ó rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ (B)láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣe ìwọ ni ẹni tó ń bọ̀ wá tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?”

Jesu dáhùn ó wí pé, “Ẹ padà lọ, ẹ sì sọ fún Johanu ohun tí ẹ̀yin gbọ́, àti èyí tí ẹ̀yin rí. Àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúnkùn ún rìn, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ wọn, àwọn adití ń gbọ́rọ̀, a ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì. Alábùkún fún ni ẹni tí kò rí ohun ìkọ̀sẹ̀ nípa mi.”

Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ti lọ tán, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn nípa ti Johanu: “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ wò ní aginjù? Ewéko tí afẹ́fẹ́ ń mi? Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, kí ni ẹ̀yin lọ òde lọ í wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ni aṣọ dáradára? Rárá àwọn ti ó wọ aṣọ dáradára wà ní ààfin ọba. Àní kí ní ẹ jáde láti lọ wò? Wòlíì? Bẹ́ẹ̀ ni, mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ.” 10 Èyí ni ẹni tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:

“ ‘Èmi yóò rán ìránṣẹ́ mi síwájú rẹ,
    ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ.’

11 Lóòótọ́ ni mó wí fún yín, nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí ẹni tí ó tí í dìde tí ó ga ju Johanu onítẹ̀bọmi lọ, síbẹ̀ ẹni tí ó kéré jù ní ìjọba ọ̀run ni ó pọ̀jù ú lọ. 12 Láti ìgbà ọjọ́ Johanu onítẹ̀bọmi títí di àkókò yìí ni ìjọba ọ̀run ti di à fi agbára wọ̀, àwọn alágbára ló ń fi ipá gbà á. 13 Nítorí náà gbogbo òfin àti wòlíì ni ó sọtẹ́lẹ̀ kí Johanu kí ó tó dé. 14 Bí ẹ̀yin yóò bá gbà á, èyí ni Elijah tó ń bọ̀ wá. 15 Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.