Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 70-71

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.

70 (A)Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là,
    Olúwa, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́.

Kí àwọn tí ń wá ọkàn mi
    kí a dójútì wọ́n, kí wọn sì dààmú;
kí àwọn tó ń wá ìparun mi
    yí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú.
Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrè
    ìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Háà! Háà!”
Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀
    kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ,
kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé,
    “Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”

Ṣùgbọ́n mo jẹ́ òtòṣì àti aláìní;
    wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run.
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùdáǹdè mi;
    Olúwa, má ṣe dúró pẹ́.
71 Nínú rẹ, Olúwa, ni mo ní ààbò;
    Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
Gbà mí kí o sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo rẹ;
    dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbà mí.
Jẹ́ àpáta ààbò mi,
    níbi tí èmi lè máa lọ,
pa àṣẹ láti gbà mí,
    nítorí ìwọ ni àpáta àti odi agbára mi.
Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú,
    ní ọwọ́ aláìṣòdodo àti ìkà ọkùnrin.

Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, Olúwa Olódùmarè,
    ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe.
Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi;
    Ìwọ mú mi jáde láti inú ìyá mi wá
èmi ó máa yìn ọ́ títí láé.
Mo di ààmì fún ọ̀pọ̀ ènìyàn,
    ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.
Ìyìn rẹ̀ kún ẹnu mi,
    ó ń sọ ti ọlá rẹ ní ọjọ́ gbogbo.

Má ṣe ta mí nù ní ọjọ́ ogbó mi
    Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́
10 Nítorí àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀-òdì sí mi,
    àwọn tí wọn dúró láti pa mí gbìmọ̀ pọ̀.
11 Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;
    lépa rẹ̀ kí ẹ sì mu,
    nítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.”
12 Má ṣe jìnnà sí mi, Ọlọ́run;
    wa kánkán, Ọlọ́run mi, láti ràn mí lọ́wọ́.
13 Jẹ́ kí wọn kí ó dààmú,
    kí a sì run àwọn tí ń ṣe ọ̀tá ọkàn mi
kí a sì fi ẹ̀gàn àti àbùkù
    bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.

14 Ṣùgbọ́n ní tèmi, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi;
    èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sí i.

15 Ẹnu mi yóò sọ nípa ti òdodo rẹ,
ti ìgbàlà rẹ, ni gbogbo ọjọ́,
lóòtítọ́, èmi kò mọ iye rẹ̀.
16 Èmi ó wá láti wá kéde agbára,
    Olúwa Olódùmarè;
    èmi ó kéde òdodo rẹ̀ nìkan.
17 Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ ti kọ́ mi
    títí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ.
18 Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo sì hewú,
    Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run mi,
títí èmi ó fi ipá rẹ han ìran tí ń bọ̀,
    àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn.

19 Ọlọ́run, òdodo rẹ dé ọ̀run,
    ìwọ tí o ti ṣe ohun ńlá
    Ta ni ó dàbí rẹ, Ọlọ́run?
20 Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò,
    ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí
ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè
    láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá.
Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀
21 Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi
    ìwọ yóò tù mí nínú ní ha gbogbo.

22 Èmi yóò fi dùùrù mi yìn
    fún òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi;
èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù
    ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.
23 Ètè mi yóò kígbe fún ìyìn
    nígbà tí mo bá kọrin ìyìn sí ọ:
    èmi, ẹni tí o rà padà.
24 Ahọ́n mi yóò sọ ti òdodo rẹ ní gbogbo ọjọ́,
    fún àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára,
    a sì dójúti àwọn tí ń wá ìdààmú mi.

Saamu 74

Maskili ti Asafu.

74 Ọlọ́run, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé?
    Èéṣe tí ìbínú rẹ̀ fi dìde sí àwọn àgùntàn pápá rẹ?
Rántí àwọn ènìyàn tí ìwọ ti rà nígbà àtijọ́,
    ẹ̀yà ilẹ̀ ìní rẹ, tí ìwọ ti rà padà
    Òkè Sioni, níbi tí ìwọ ń gbé.
Yí ẹsẹ̀ rẹ padà sí ìparun ayérayé wọn,
    gbogbo ìparun yìí tí ọ̀tá ti mú wá sí ibi mímọ́.

Àwọn ọ̀tá rẹ ń bú ramúramù
    láàrín ènìyàn rẹ,
wọ́n ń gbé àsíá wọn sókè fún ààmì;
Wọ́n ń rí bí ọkùnrin tí ó gbé àáké rẹ̀ sókè
    láti gé igi igbó dídí.
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, iṣẹ́ ọnà fínfín,
    ni wọ́n fi àáké wó lulẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan náà.
Wọ́n sun ibi mímọ́ rẹ lulẹ̀
    wọ́n ba ibùgbé orúkọ rẹ jẹ́
Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátápátá!”
    Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà.

A kò fún wa ní ààmì iṣẹ́ ìyanu kankan;
    kò sí wòlíì kankan
    ẹnìkankan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà.
10 Àwọn ọ̀tá yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run?
    Àwọn ọ̀tá yóò ha ba orúkọ rẹ jẹ́ títí láé?
11 Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún rẹ?
    Mú un kúrò nínú ìṣẹ́po aṣọ rẹ kí o sì run wọ́n!

12 Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run ni ọba mi láti ìgbà pípẹ́;
    Ó mú ìgbàlà wá sórí ilẹ̀ ayé.

13 Ìwọ ni ó la Òkun sílẹ̀ nípa agbára rẹ;
    Ìwọ fọ́ orí ẹ̀mí búburú nínú omi
14 Ìwọ fọ́ orí Lefitani túútúú, o sì fi ṣe oúnjẹ fun àwọn ẹ̀dá tí ń gbé inú ijù
    Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ sì ni alẹ́ pẹ̀lú;
    ìwọ fi ìdí oòrùn àti òṣùpá lélẹ̀.
15 Ìwọ ya orísun omi àti ìṣàn omi;
    Ìwọ mú kí odò tó ń sàn gbẹ
16 Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú;
    ìwọ yà oòrùn àti òṣùpá.
17 Ìwọ pààlà etí ayé;
    Ìwọ dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù.

18 Rántí bí àwọn ọ̀tá ń kẹ́gàn rẹ, Olúwa
    bí àwọn aṣiwèrè ènìyàn ti ń ba orúkọ rẹ jẹ́.
19 Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà rẹ fún ẹranko igbó búburú;
    Má ṣe gbàgbé ẹ̀mí àwọn ènìyàn rẹ tí a ń pọ́n lójú títí láé.
20 Bojú wo májẹ̀mú rẹ,
    nítorí ibi òkùnkùn ayé kún fún ibùgbé ìkà.
21 Má ṣe jẹ́ kí àwọn aninilára padà sẹ́yìn nínú ìtìjú
    jẹ́ kí àwọn aláìní àti tálákà yin orúkọ rẹ.
22 Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara rẹ rò;
    rántí bí àwọn aṣiwèrè ti ń kẹ́gàn rẹ ní gbogbo ọjọ́.
23 Má ṣe gbàgbé ohùn àwọn ọ̀tá rẹ,
    bíbú àwọn ọ̀tá rẹ, tí ó ń pọ̀ sí i nígbà gbogbo.

Oniwaasu 11:1-8

Àkàrà lórí omi

11 Fún àkàrà rẹ sórí omi,
    nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò rí i padà
Fi ìpín fún méje, àní fún mẹ́jọ pẹ̀lú,
    nítorí ìwọ kò mọ ohun ìparun tí ó le è wá sórí ilẹ̀.

Bí àwọsánmọ̀ bá kún fún omi,
    ayé ni wọ́n ń rọ òjò sí
Bí igi wó sí ìhà gúúsù tàbí sí ìhà àríwá
    níbi tí ó wó sí náà, ni yóò dùbúlẹ̀ sí.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo afẹ́fẹ́ kò ní fúnrúgbìn;
    ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo àwọsánmọ̀ kò ní kórè.

Gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́
    tàbí mọ bí ọmọ tí ń dàgbà nínú ikùn ìyáarẹ̀,
bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ kò le è ní òye iṣẹ́ Ọlọ́run
    ẹlẹ́dàá ohun gbogbo.

Fún irúgbìn rẹ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù,
    má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣọlẹ̀ ní àṣálẹ́,
nítorí ìwọ kò mọ èyí tí yóò ṣe rere
    bóyá èyí tàbí ìyẹn
    tàbí àwọn méjèèjì ni yóò ṣe dáradára bákan náà.

Rántí ẹlẹ́dàá rẹ ní ìgbà èwe rẹ

Ìmọ́lẹ̀ dùn;
    Ó sì dára fún ojú láti rí oòrùn.
Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn jẹ̀gbádùn gbogbo iye ọdún
    tí ó le è lò láyé
ṣùgbọ́n jẹ́ kí ó rántí ọjọ́ òkùnkùn
    nítorí wọn ó pọ̀
    Gbogbo ohun tí ó ń bọ̀ asán ni.

Galatia 5:16-24

Ìyè nípa ti ẹ̀mí

16 Ǹjẹ́ mo ní, Ẹ máa rìn nípa ti Ẹ̀mí, ẹ̀yin kì yóò sì mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara ṣẹ. 17 (A)Nítorí ti ara ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lòdì sí Ẹ̀mí, àti Ẹ̀mí lòdì sí ara: àwọn wọ̀nyí sì lòdì sí ara wọn; kí ẹ má ba à lè ṣe ohun tí ẹ̀yin ń fẹ́. 18 Ṣùgbọ́n bí a bá ń ti ọwọ́ Ẹ̀mí ṣamọ̀nà yín, ẹ̀yin kò sí lábẹ́ òfin.

19 (B)Ǹjẹ́ àwọn iṣẹ́ tí ara farahàn, tí í ṣe wọ̀nyí; panṣágà, àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà, 20 Ìbọ̀rìṣà, oṣó, ìkórìíra, ìjà, ìlara, ìbínú, ìmọtaraẹni nìkan, ìyapa, ẹ̀kọ́ òdì. 21 Àrankàn, ìpànìyàn, ìmutípara, ìréde òru, àti irú ìwọ̀nyí; àwọn ohun tí mo ń wí fún yín tẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún yín tẹ́lẹ̀ rí pé, àwọn tí ń ṣe nǹkan báwọ̀nyí kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.

22 Ṣùgbọ́n èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwà pẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́, 23 ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni níjanu: òfin kan kò lòdì sí irú wọ̀nyí, 24 Àwọn tí í ṣe ti Kristi Jesu ti kan ara wọn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.

Matiu 16:13-20

Peteru jẹ́wọ́ Kristi

13 (A)Nígbà tí Jesu sì dé Kesarea-Filipi, ó bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi Ọmọ ènìyàn pè?”

14 (B)Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ni Johanu onítẹ̀bọmi ni, àwọn mìíràn wí pé, Elijah ni, àwọn mìíràn wí pé, Jeremiah ni, tàbí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì.”

15 “Ṣùgbọ́n ẹyin ń kọ?” Ó bi í léèrè pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fi mi pè?”

16 (C)Simoni Peteru dáhùn pé, “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”

17 (D)Jesu sì wí fún un pé, “Alábùkún fún ni ìwọ Simoni ọmọ Jona, nítorí ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ kọ́ ló fi èyí hàn bí kò ṣe Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run. 18 Èmi wí fún ọ, ìwọ ni Peteru àti pé orí àpáta yìí ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi lé, àti ẹnu-ọ̀nà ipò òkú kì yóò lè borí rẹ̀. 19 Èmi yóò fún ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba Ọ̀run; Ohun tí ìwọ bá dè ní ayé, òun ni a ó dè ní ọ̀run. Ohunkóhun tí ìwọ bá sì tú ní ayé yìí, a ó sì tú ní ọ̀run.” 20 (E)Nígbà náà ó kìlọ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni pé Òun ni Kristi náà.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.