Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.
40 Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de Olúwa;
ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi.
2 Ó fà mí yọ gòkè
láti inú ihò ìparun,
láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀,
ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta,
ó sì jẹ́ kí ìgbésẹ̀ mi wà láìfòyà.
3 Ó fi orin tuntun sí mi lẹ́nu,
àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa.
Ọ̀pọ̀ yóò rí i wọn yóò sì bẹ̀rù,
wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
4 Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n-ọn-nì
tí ó fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn
tí wọn kò sì yípadà sí agbéraga,
tàbí àwọn tí ó yapa
lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn.
5 Olúwa Ọlọ́run mi, Ọ̀pọ̀lọpọ̀
ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe.
Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa;
ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹ
tí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn,
wọ́n ju ohun tí
ènìyàn le è kà lọ.
6 (A)Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́,
ìwọ ti ṣí mi ní etí.
Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀
ni ìwọ kò béèrè.
7 Nígbà náà ni mo wí pé,
“Èmi nìyí;
nínú ìwé kíká ni
a kọ ọ nípa tèmi wí pé.
8 Mo ní inú dídùn
láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ,
ìwọ Ọlọ́run mi;
Òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”
9 Èmi ti sọ ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlà
láàrín àwùjọ ńlá;
wò ó,
èmi kò pa ètè mi mọ́,
gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti mọ̀,
ìwọ Olúwa.
10 Èmi kò fi ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà sin ní àyà mi;
èmí ti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ àti ìgbàlà rẹ.
Èmi kò sì pa ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ mọ́
kúrò láàrín àwọn ìjọ ńlá.
11 Ìwọ má ṣe,
fa àánú rẹ tí ó rọ́nú
sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi; Olúwa
jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ rẹ
àti òtítọ́ rẹ
kí ó máa pa mi mọ́
títí ayérayé.
12 Nítorí pé àìníye ibi
ni ó yí mi káàkiri,
ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi,
títí tí èmi kò fi ríran mọ́;
wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,
àti wí pé àyà mí ti kùnà.
13 (B)Jẹ́ kí ó wù ọ́,
ìwọ Olúwa,
láti gbà mí là;
Olúwa,
yára láti ràn mí lọ́wọ́.
14 Gbogbo àwọn wọ̀n-ọn-nì
ni kí ojú kí ó tì
kí wọn kí ó sì dààmú
àwọn tí ń wá ọkàn mi
láti parun:
jẹ́ kí a lé wọn padà sẹ́yìn
kí a sì dójútì wọ́n,
àwọn tí ń wá ìpalára mi.
15 Jẹ́ kí àwọn tí ó wí fún mi pé, “Háà! Háà!”
ó di ẹni à fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí ìtìjú wọn.
16 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ
kí ó máa yọ̀
kí inú wọn sì máa dùn sí ọ;
kí gbogbo àwọn tí ó sì fẹ́ ìgbàlà rẹ
kí o máa wí nígbà gbogbo pé,
“Gbígbéga ni Olúwa!”
17 Bí ó ṣe ti èmi ni,
tálákà àti aláìní ni èmi,
ṣùgbọ́n Olúwa ń ṣe ìrántí mi.
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi
àti ìgbàlà mi;
Má ṣe jẹ́ kí ó pẹ́,
ìwọ Ọlọ́run mi.
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí àwọn ará Sifi lọ sọ fún Saulu pé, “Dafidi sá pamọ́ sọ́dọ̀ wa”.
54 Gbà mí, Ọlọ́run nípa orúkọ rẹ:
dá mi láre nípa agbára rẹ.
2 Gbọ́ àdúrà mi, Ọlọ́run;
fi etí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
3 Àwọn agbéraga àlejò dìde sí mí.
Àwọn aninilára sì ń wá mi láti pa,
àwọn ẹni tí kò ka Ọlọ́run sí ní ojú wọn.
4 Kíyèsi i Ọlọ́run ni Olùrànlọ́wọ́ mi;
Olúwa ní ẹni tí ó mú mi dúró,
pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ.
5 Jẹ́ kí ibi padà sẹ́yìn sí àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi;
pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ.
6 Èmí yóò rú ẹbọ àtinúwá sí ọ,
èmi yóò yin orúkọ rẹ, Olúwa,
nítorí tí ó dára.
7 Nítorí tí ó yọ mí kúrò nínú ibi gbogbo
ojú mi ti wo ìṣẹ́gun lórí ọ̀tá mi.
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Nígbà ti wòlíì Natani tọ wá, lẹ́yìn tí Dafidi dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè rẹ̀ pẹ̀lú Batṣeba.
51 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí
ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ̀,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀
kí o sì pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́.
2 Wẹ gbogbo àìṣedéédéé mi nù kúrò
kí o sì wẹ̀ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi!
3 Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi,
nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi.
4 (A)Sí ọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí
ni mo sì ṣe búburú níwájú rẹ̀,
kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀,
kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọ bá ń ṣe ìdájọ́.
5 Nítòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi,
nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi.
6 Nítòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú;
ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀kọ̀.
7 Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé hísópù, èmi yóò sì mọ́;
fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju yìnyín lọ.
8 Jẹ́ kí n gbọ́ ayọ̀ àti inú dídùn;
jẹ́ kí gbogbo egungun tí ìwọ ti run kí ó máa yọ̀.
9 Pa ojú rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi
kí o sì pa gbogbo àwọn àìṣedéédéé mi rẹ́.
10 Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run,
kí o sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi.
11 Má ṣe jù mi nù kúrò níwájú rẹ,
kí o má ṣe gba ẹ̀mí mímọ́ rẹ lọ́wọ́ mi.
12 Mú ayọ̀ ìgbàlà rẹ tọ̀ mí wá,
kí o sì fún mi ní ẹ̀mí ìfẹ́, tí yóò mú mi dúró.
13 Nígbà náà ni èmi yóò máa kọ́ àwọn olùrékọjá ní ọ̀nà rẹ,
àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò sì yí padà sí ọ.
14 Gbà mí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, Ọlọ́run,
ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà mi,
ahọ́n mi yóò sì máa kọrin òdodo rẹ kíkan.
15 Olúwa, ṣí mi ní ètè mi gbogbo,
àti ẹnu mi yóò sì máa kéde ìyìn rẹ.
16 Nítorí ìwọ kò ní inú dídùn sí ẹbọ, tí èmi kò bá mú wá;
Ìwọ kò ní inú dídùn sí ọrẹ ẹbọ sísun.
17 Ẹbọ Ọlọ́run ni ìròbìnújẹ́ ọkàn ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà.
18 Ṣe rere ní dídùn inú rẹ sí Sioni,
ṣe rere; tún odi Jerusalẹmu mọ.
19 Nígbà náà ni inú rẹ yóò dùn sí ẹbọ òdodo,
pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ọrẹ ẹbọ sísun,
nígbà náà ni wọn yóò fi akọ màlúù rú ẹbọ lórí pẹpẹ rẹ.
Dídúró nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run
5 Ṣọ́ ìrìn rẹ nígbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọ́run. Kí ìwọ kí ó sì múra láti gbọ́ ju àti ṣe ìrúbọ aṣiwèrè, tí kò mọ̀ wí pé òun ń ṣe búburú.
2 Má ṣe yára pẹ̀lú ẹnu un rẹ,
má sọ ohunkóhun níwájú Ọlọ́run
Ọlọ́run ń bẹ ní ọ̀run
ìwọ sì wà ní ayé,
nítorí náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ ní ìwọ̀n
3 Gẹ́gẹ́ bí àlá tí ń wá, nígbà tí ìlépa púpọ̀ wà
bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ bá pọ̀jù.
4 Nígbà tí o bá ṣe ìlérí sí Ọlọ́run, má ṣe pẹ́ ní mímúṣẹ, kò ní inú dídùn sí òmùgọ̀, mú ìlérí rẹ sẹ. 5 Ó sàn láti má jẹ́ ẹ̀jẹ́, ju wí pé kí a jẹ́ ẹ̀jẹ́ kí a má mu ṣẹ lọ. 6 Má ṣe jẹ́ kí ẹnu rẹ tì ọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀. Má sì ṣe sọ fún òjíṣẹ́ ilé ìsìn pé “Àṣìṣe ni ẹ̀jẹ́ mi.” Kí ló dé tí Ọlọ́run fi le è bínú sí ọ, kí ó sì ba iṣẹ́ ọwọ́ rẹ jẹ́? 7 Asán ni ọ̀pọ̀ àlá àti ọ̀rọ̀ púpọ̀. Nítorí náà dúró nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
Òfin àti ìlérí
15 Ará, èmi ń sọ̀rọ̀ bí ènìyàn, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ènìyàn ti a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, kò sí ẹni tí ó lè sọ ọ́ di asán, tàbí tí ó lè fi kún un mọ́. 16 (A)Ǹjẹ́ fún Abrahamu àti fún irú-ọmọ rẹ̀ ni a ti ṣe àwọn ìlérí náà. Ìwé Mímọ́ kò ṣe wí pé, Fún àwọn irú-ọmọ rẹ̀, bí ẹni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀; ṣùgbọ́n bí ẹni pé ọ̀kan ṣoṣo, àti fún irú-ọmọ rẹ̀, èyí tí í ṣe Kristi. 17 (B)Èyí tí mò ń wí ni pé: májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níṣàájú, òfin ti ó dé lẹ́yìn ọgbọ̀n-lé-nírinwó ọdún kò lè sọ ọ́ di asán, kí ó sì mú ìlérí náà di aláìlágbára. 18 (C)Nítorí bí ogún náà bá dúró lórí ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí í òfin kì í ṣe ti ìlérí mọ́: ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í fún Abrahamu nípa ìlérí.
19 (D)Ǹjẹ́ kí ha ni òfin? A fi kún un nítorí ìrékọjá títí irú-ọmọ tí a ti ṣe ìlérí fún yóò fi dé; a sì tipasẹ̀ àwọn angẹli ṣe ìlànà rẹ̀ láti ọwọ́ alárinà kan wá. 20 Ǹjẹ́ onílàjà kì í ṣe alárinà ti ẹnìkan, ṣùgbọ́n ọ̀kan ni Ọlọ́run.
21 (E)Nítorí náà òfin ha lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọ́run bí? Kí a má rí i; Nítorí ìbá ṣe pé a ti fi òfin kan fún ni tí ó lágbára láti sọ ni di ààyè nítòótọ́ òdodo ìbá ti tipasẹ̀ òfin wà. 22 (F)Ṣùgbọ́n ìwé mímọ́ ti fi yé wa pé gbogbo ènìyàn ni ń bẹ lábẹ́ ìdè ẹ̀ṣẹ̀, kí a lè fi ìlérí nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi fún àwọn tí ó gbàgbọ́.
Jesu rìn lójú omi
22 (A)Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n bọ sínú ọkọ̀ wọn, àti kí wọ́n máa kọjá lọ ṣáájú rẹ̀ sí òdìkejì. Òun náà dúró lẹ́yìn láti tú àwọn ènìyàn ká lọ sí ilé wọn 23 Lẹ́yìn tí ó tú ìjọ ènìyàn ká tán, ó gun orí òkè lọ fúnrarẹ̀ láti lọ gba àdúrà. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, òun wà nìkan níbẹ̀, 24 (B)ní àkókò yìí ọkọ̀ ojú omi náà ti rin jìnnà sí etí bèbè Òkun, tí ìjì omi ń tì í síwá sẹ́yìn, nítorí ìjì ṣe ọwọ́ òdì sí wọn.
25 Ní déédé ago mẹ́rin òwúrọ̀, Jesu tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi. 26 (C)Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù ba wọn gidigidi, wọ́n rò pé “iwin ni” wọ́n kígbe tìbẹ̀rù tìbẹ̀rù.
27 Lójúkan náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni ẹ má ṣe bẹ̀rù.”
28 Peteru sì ké sí i pé, “Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni nítòótọ́, sọ pé kí n tọ̀ ọ́ wà lórí omi.”
29 (D)Jesu dá a lóhùn pé, “Ó dára, máa bọ̀ wá.”
Nígbà náà ni Peteru sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀. Ó ń rìn lórí omi lọ sí ìhà ọ̀dọ̀ Jesu. 30 Nígbà tí ó rí afẹ́fẹ́ líle, ẹ̀rù bà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ó kígbe lóhùn rara pé, “Gbà mí, Olúwa.”
31 (E)Lójúkan náà, Jesu na ọwọ́ rẹ̀, ó dìímú, ó sì gbà á. Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ṣiyèméjì ìwọ onígbàgbọ́ kékeré?”
32 Àti pé, nígbà ti wọ́n sì gòkè sínú ọkọ̀, ìjì náà sì dúró jẹ́ẹ́. 33 (F)Nígbà náà ni àwọn to wà nínú ọkọ̀ náà foríbalẹ̀ fún un wọ́n wí pé, “Nítòótọ́ ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ í ṣe.”
34 (G)Nígbà tí wọn rékọjá sí apá kejì wọ́n gúnlẹ̀ sí Genesareti. 35 Nígbà tiwọn mọ̀ pé Jesu ni, wọn sì ránṣẹ́ sí gbogbo ìlú náà yíká. Wọ́n sì gbé gbogbo àwọn aláìsàn tọ̀ ọ́ wá. 36 (H)Àwọn aláìsàn bẹ̀ ẹ́ pé kí ó gba àwọn láyè láti fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sì rí ìwòsàn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.