Book of Common Prayer
146 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Fi ìyìn fún Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
2 Èmi yóò yin Olúwa ní gbogbo ayé mi;
Èmi yóò kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láààyè.
3 Ẹ má ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ọmọ-aládé,
àní, ọmọ ènìyàn,
lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.
4 Ẹ̀mí rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀:
Ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo:
5 Ìbùkún ni fún ẹni tí
Ọlọ́run Jakọbu ń ṣe ìrànlọ́wọ́ rẹ̀
tí ìrètí rẹ̀ wà nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.
6 Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ayé,
òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn,
ẹni tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí ayé.
7 Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni lára
tí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa
Olúwa, tú àwọn oǹdè sílẹ̀ (ẹlẹ́wọ̀n)
8 Olúwa mú àwọn afọ́jú ríran,
Olúwa, gbé àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ ga,
Olúwa fẹ́ràn àwọn olódodo.
9 Olúwa ń dá ààbò bo àwọn àlejò
ó sì ń dá àwọn aláìní baba àti opó sí
ṣùgbọ́n ó ba ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú jẹ́.
10 Olúwa jẹ ọba títí láé;
Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni, àti fún gbogbo ìran.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
147 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Nítorí ohun rere ni láti máa kọrin ìyìn sí Ọlọ́run wa,
ó yẹ láti kọrin ìyìn sí i!
2 Olúwa kọ́ Jerusalẹmu;
Ó kó àwọn Israẹli tí a lé sọnù jọ.
3 Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn
ó sì di ọgbẹ́ wọ́n.
4 Ó ka iye àwọn ìràwọ̀
ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ
5 Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára
òye rẹ̀ kò sì ní òpin.
6 Olúwa wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni ó rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀.
7 Fi ọpẹ́ kọrin sí Olúwa
fi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run.
8 Ó fi ìkùùkuu bo àwọ̀ sánmọ̀
ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayé
ó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè
9 Ó pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹranko
àti fún àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké.
10 Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹṣin
bẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin
11 Olúwa ni ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú rẹ̀.
12 Yin Olúwa, ìwọ Jerusalẹmu
yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni.
13 Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ibodè rẹ̀ lágbára;
Òun sì ti bùkún fún àwọn ọmọ rẹ̀ nínú rẹ
14 Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè rẹ̀
òun sì fi jéró dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn.
15 Òun sì rán àṣẹ rẹ̀ sí ayé
ọ̀rọ̀ rẹ̀ sáré tete.
16 Ó fi yìnyín fún ni bi irun àgùntàn
ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú
17 Ó rọ òjò yìnyín rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́
ta ni ó lè dúró níwájú òtútù rẹ̀
18 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀
ó mú kí afẹ́fẹ́ rẹ̀ fẹ́
ó sì mú odò rẹ̀ sàn.
19 Ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di mí mọ̀ fún Jakọbu
àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ fún Israẹli
20 Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀-èdè kan rí, Bí ó ṣe ti ìdájọ́ rẹ̀
wọn ko mọ òfin rẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
111 Ẹ máa yin Olúwa.
Èmi yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi,
ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn.
2 Iṣẹ́ Olúwa tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀.
3 Iṣẹ́ rẹ̀ ni ọláńlá àti ògo:
àti òdodo rẹ̀ dúró láéláé.
4 Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, láti máa rántí:
Olúwa ni olóore-ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú.
5 Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀:
òun ń rántí májẹ̀mú rẹ̀.
6 Ó ti fihan àwọn ènìyàn rẹ̀ agbára iṣẹ́ rẹ̀
láti fún wọn ní ilẹ̀ ìlérí ní ìní
7 Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;
gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú.
8 Wọ́n dúró láé àti láé,
ní òtítọ́ àti òdodo ni a ṣe wọ́n.
9 Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn rẹ̀:
ó pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ títí láé:
Mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ̀.
10 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n:
òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀,
ìyìn rẹ̀ dúró láé.
112 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run,
tí ó ní inú dídùn ńlá sí àwọn òfin rẹ̀.
2 Irú-ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé:
ìran àwọn olóòtítọ́ ni a ó bùkún fún.
3 Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé rẹ̀;
òdodo rẹ̀ sì dúró láé.
4 Fún olóòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yóò tàn fún ní òkùnkùn:
olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti òdodo.
5 Ènìyàn rere fi ojúrere hàn,
a sì wínni;
ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀.
6 Dájúdájú a kì yóò le yí ní ipò padà láéláé:
olódodo ni a ó máa ṣe ìrántí rẹ láéláé.
7 Òun kì yóò béèrè ìyìn búburú:
ọkàn rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa.
8 Ó ti mú ọkàn rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bà á,
títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.
9 (A)Ó ti pín ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú;
Nítorí òdodo rẹ̀ dúró láé;
ìwo rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá.
10 Ènìyàn búburú yóò ri, inú wọn yóò sì bàjẹ́,
yóò sì pa eyín keke, yó sì yọ dànù:
èròǹgbà ọkàn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.
113 Ẹ máa yin Olúwa.
Yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa,
ẹ yin orúkọ Olúwa.
2 Fi ìbùkún fún orúkọ Olúwa láti
ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
3 Láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀
orúkọ Olúwa ni kí a máa yìn.
4 Olúwa ga lórí gbogbo orílẹ̀-èdè,
àti ògo rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run.
5 Ta ló dàbí Olúwa Ọlọ́run wa,
tí ó gbé ní ibi gíga.
6 Tí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wò
òun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé!
7 Ó gbé òtòṣì dìde láti inú erùpẹ̀, àti pé
ó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá.
8 Kí ó le mú un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé
àní pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àwọn ènìyàn rẹ̀.
9 Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé,
àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ rẹ̀.
Ẹ yin Olúwa.
Ìbẹ̀rẹ̀ dídá ayé
1 (A)Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé. 2 Ayé sì wà ní rúdurùdu, ó sì ṣófo, òkùnkùn sì wà lójú ibú omi, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń rábàbà lójú omi.
3 (B)Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà,” ìmọ́lẹ̀ sì wà. 4 Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì ya ìmọ́lẹ̀ náà sọ́tọ̀ kúrò lára òkùnkùn. 5 Ọlọ́run sì pe ìmọ́lẹ̀ náà ní “Ọ̀sán” àti òkùnkùn ní “Òru.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní.
6 (C)Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí òfúrufú kí ó wà ní àárín àwọn omi, láti pààlà sí àárín àwọn omi.” 7 Ọlọ́run sì dá òfúrufú láti ya omi tí ó wà ní òkè òfúrufú kúrò lára omi tí ó wà ní orí ilẹ̀. Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 8 Ọlọ́run sì pe òfúrufú ní “Ọ̀run,” àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kejì.
9 Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojú kan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 10 Ọlọ́run sì pe ilẹ̀ gbígbẹ náà ní “ilẹ̀,” àti àpapọ̀ omi ní “òkun.” Ọlọ́run sì rí i wí pé ó dára.
11 Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó hu ọ̀gbìn: ewéko ti yóò máa mú èso wá àti igi tí yóò máa so èso ní irú tirẹ̀, tí ó ní irúgbìn nínú.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 12 Ilẹ̀ sì hù ọ̀gbìn: ewéko tí ó ń so èso ní irú tirẹ̀, àti igi tí ń so èso, tí ó ní irúgbìn nínú ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì ri pé ó dára. 13 Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kẹta.
14 Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, láti pààlà sí àárín ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún ààmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún, 15 Kí wọn ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run, láti tan ìmọ́lẹ̀ sí orí ilẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 16 Ọlọ́run dá ìmọ́lẹ̀ ńláńlá méjì, ìmọ́lẹ̀ tí ó tóbi láti ṣe àkóso ọ̀sán àti ìmọ́lẹ̀ tí ó kéré láti ṣe àkóso òru. Ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú. 17 Ọlọ́run sì ṣe wọ́n lọ́jọ̀ sí ojú ọ̀run láti máa tan ìmọ́lẹ̀ si orí ilẹ̀, 18 láti ṣàkóso ọ̀sán àti òru àti láti pààlà sí àárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn: Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. 19 Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kẹrin.
20 Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi kí ó kún fún àwọn ohun alààyè, kí àwọn ẹyẹ kí ó sì máa fò ní òfúrufú.” 21 Nítorí náà Ọlọ́run dá àwọn ẹ̀dá alààyè ńláńlá sí inú Òkun, àwọn ohun ẹlẹ́mìí àti àwọn ohun tí ń rìn ní onírúurú tiwọn, àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́ ní onírúurú tiwọn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. 22 Ọlọ́run súre fún wọn, ó sì wí pé, “Ẹ máa bí sí i, ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ kún inú omi Òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i ní orí ilẹ̀.” 23 Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ karùn-ún.
24 Ọlọ́run sì wí pé, “Kí ilẹ̀ kí ó mú ohun alààyè jáde ní onírúurú wọn: ẹran ọ̀sìn, àwọn ohun afàyàfà àti àwọn ẹran inú igbó, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní irú tirẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 25 Ọlọ́run sì dá ẹranko inú igbó àti ẹran ọ̀sìn gbogbo ní irú tirẹ̀ àti gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ní ilẹ̀ ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára.
26 (D)Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a dá ènìyàn ní àwòrán ara wa, gẹ́gẹ́ bí àwa ti rí, kí wọn kí ó jẹ ọba lórí ẹja Òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, ẹran ọ̀sìn, gbogbo ilẹ̀ àti lórí ohun gbogbo tí ń rìn lórí ilẹ̀.”
27 (E)(F) Nítorí náà, Ọlọ́run dá ènìyàn ní àwòrán ara rẹ̀,
ní àwòrán Ọlọ́run ni Ó dá a,
akọ àti abo ni Ó dá wọn.
28 Ọlọ́run sì súre fún wọn, Ọlọ́run sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì gbilẹ̀, kí ẹ ṣe ìkápá ayé. Ẹ ṣe àkóso àwọn ẹja inú Òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó ń rìn ní orí ilẹ̀.”
29 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí pé, “Mo fi gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ń so èso fún un yín bí oúnjẹ àti àwọn igi eléso pẹ̀lú. Gbogbo rẹ̀ yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín. 30 Àti fún àwọn ẹranko inú igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ohun afàyàfà: gbogbo ohun tó ní èémí ìyè nínú ni mo fi ewéko fún bí oúnjẹ.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.
31 Ọlọ́run sì rí àwọn ohun gbogbo tí ó dá, ó dára gidigidi. Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀, ó jẹ́ ọjọ́ kẹfà.
2 (G)Báyìí ni Ọlọ́run parí dídá àwọn ọ̀run àti ayé, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.
2 (H)(I) Ní ọjọ́ keje Ọlọ́run sì parí iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ń ṣe; ó sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo tí ó ti ń ṣe. 3 Ọlọ́run sì súre fún ọjọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ní ọjọ́ náà ni ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ dídá ayé tí ó ti ń ṣe.
Ìbùkún ti Ẹ̀mí Mímọ́ nínú Kristi
3 (A)Ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, ẹni tí ó ti bùkún wa láti inú ọ̀run wá pẹ̀lú àwọn ìbùkún ẹ̀mí gbogbo nínú Kristi. 4 Àní, gẹ́gẹ́ bí o ti yàn wá nínú rẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, láti jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù níwájú rẹ̀ nínú ìfẹ́ 5 Ẹni tí Ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ sí ìsọdọmọ nípa Jesu Kristi fún ara rẹ̀, ní ìbámu ìdùnnú ìfẹ́ rẹ̀ 6 (B)fún ìyìn ògo oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, èyí tí Ó ti fi fún wa nínú Àyànfẹ́ rẹ̀: 7 (C)Nínú rẹ̀ ni àwa rí ìràpadà gba nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ àti ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run 8 èyí tí ó fún wa lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n àti ìmòye, 9 Ó ti sọ ohun ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mí mọ̀ fún wa gẹ́gẹ́ bí ìdùnnú rere rẹ̀, èyí ti o pinnu nínú Kristi, 10 (D)èyí tí yóò jẹ jáde ní kíkún àkókò, láti ṣe àkójọpọ̀ àwọn ohun tí ọ̀run àti ti ayé lábẹ́ Kristi.
11 Nínú rẹ̀ ni a yàn wá fẹ́ lẹ́yìn tí ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ohun gbogbo ní ìbámu ìfẹ́ rẹ̀, 12 kí àwa kí ó le wà fún ìyìn ògo rẹ̀, àwa tí a ti ni ìrètí ṣáájú nínú Kristi. 13 Àti ẹ̀yin pẹ̀lú darapọ̀ nínú Kristi nígbà tí ẹ̀yin gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà àní ìhìnrere ìgbàlà yin. Nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́, a fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe èdìdì ayé yin nínú rẹ, èyí tí a ti ṣe ìlérí rẹ̀ tẹ́lẹ̀, 14 (E)èyí tí ó jẹ́ ìdánilójú àṣansílẹ̀ ogún wa títí yóò fi di àkókò ìràpadà àwọn tí í ṣe ti Ọlọ́run sí ìyìn ògo rẹ̀.
Jesu jẹ́ Ọ̀dọ́-Àgùntàn Ọlọ́run
29 (A)Ní ọjọ́ kejì, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run, ẹni tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ! 30 Èyí ni ẹni tí mo ń sọ nígbà tí mo wí pé, ‘Ọkùnrin kan tí ń bọ̀ wá lẹ́yìn mi, tí ó pọ̀jù mí lọ, nítorí tí ó ti wà ṣáájú mi.’ 31 Èmi gan an kò sì mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ìdí tí mo fi wá ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi ni kí a lè fi í hàn fún Israẹli.”
32 (B)Nígbà náà ni Johanu jẹ́rìí sí i pé: “Mo rí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá bí àdàbà, tí ó sì bà lé e. 33 Èmí kì bá tí mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe pé ẹni tí ó rán mi láti fi omi bamitiisi sọ fún mi pé, ‘Ọkùnrin tí ìwọ rí tí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ tí ó bà lé lórí ni ẹni tí yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi.’ 34 Èmi ti rí i, mo sì jẹ́rìí pé, èyí ni Ọmọ Ọlọ́run.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.