Book of Common Prayer
93 Olúwa ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ;
ọláńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọ
àti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára.
Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;
kò sì le è yí.
2 Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́;
ìwọ wà títí ayérayé.
3 A ti gbé Òkun sókè, Olúwa,
Òkun ti gbé ohùn wọn sókè;
Òkun ti gbé rírú omi wọn sókè.
4 Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ,
ó ni ògo ju Òkun rírú lọ
Olúwa ga ní ògo.
5 Ẹ̀rí rẹ̀ dúró ṣinṣin;
ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́
fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa.
96 (A)Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa:
Ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.
2 Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀
ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́
3 Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn.
4 Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí;
òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ
5 Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè
ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run
6 Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀
agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.
7 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn
Ẹ fi agbára àti ògo fún Olúwa
8 Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un;
ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀
9 Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀;
ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé.
10 Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “Olúwa jẹ ọba”
a fi ìdí ayé múlẹ̀, tí kò sì lè yí;
ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.
11 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì pariwo
jẹ́ kí pápá Òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun
gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀.
12 Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀
àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀:
nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀
13 Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa,
nítorí tí ó ń bọ̀ wá,
Ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé
yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé
àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fi òtítọ́ rẹ̀ ṣe.
Tí Dafidi. Nígbà tí ó díbọ́n bí ẹni tí ń ṣe wèrè níwájú Abimeleki, ẹni tí ó lé e lọ, ó sì jáde lọ.
34 Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo;
ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.
2 Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú Olúwa;
jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn.
3 Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi;
kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ lékè.
4 Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn;
Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.
5 Wọ́n wò ó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn;
ojú kò sì tì wọ́n.
6 Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, Olúwa sì gbóhùn rẹ̀;
ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
7 Angẹli Olúwa yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká
ó sì gbà wọ́n.
8 Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára;
ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú rẹ̀.
9 Ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́,
nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
10 Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n;
ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá Olúwa kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára.
11 Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi;
èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù Olúwa.
12 (A)Ta ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀;
kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere?
13 Pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi
àti ètè rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ.
14 Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere;
wá àlàáfíà, kí o sì lépa rẹ̀.
15 Ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo;
etí i rẹ̀ sì ṣí sí ẹkún wọn.
16 Ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú;
láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.
17 Nígbà tí olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́,
Olúwa a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn.
18 Olúwa súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn;
ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là.
19 Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀,
ṣùgbọ́n Olúwa gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo rẹ̀.
20 Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́;
kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn.
21 Ibi ni ó mú ikú ìkà wá,
àti àwọn tí ó kórìíra olódodo ni yóò jẹ̀bi.
22 Olúwa ra ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ padà;
kò sí ọ̀kan nínú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé tí yóò jẹ̀bi.
Ìjẹ́wọ́ ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn
10 Nígbà tí Esra ń gbàdúrà tí ó sì ń jẹ́wọ́, ti ó ń sọkún ti ó sì ń gbárayílẹ̀ níwájú ilé Ọlọ́run, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Israẹli ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ọmọdé pagbo yí i ká. Àwọn náà ń sọkún kíkorò. 2 Nígbà náà ni Ṣekaniah ọmọ Jehieli, ọ̀kan lára ìran Elamu, sọ fún Esra pé, Àwa ti jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa nípa fífẹ́ àwọn obìnrin àjèjì láàrín àwọn ènìyàn tí ó wà yí wa ká. Ṣùgbọ́n síbẹ̀ náà, ìrètí sì wà fún Israẹli 3 Ní ṣinṣin yìí, ẹ jẹ́ kí a dá májẹ̀mú níwájú Ọlọ́run wa láti lé àwọn obìnrin yìí àti àwọn ọmọ wọn lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn Esra olúwa mi àti ti àwọn tí ó bẹ̀rù àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa. Ẹ jẹ́ kí a ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin. 4 Dìde, nítorí, ọ̀rọ̀ tìrẹ ni èyí. Gbogbo wà yóò wá pẹ̀lú rẹ, mú ọkàn le kí o sì ṣe é.
5 Nígbà náà ni Esra dìde, ó sì fi àwọn aṣíwájú àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi àti gbogbo Israẹli sí abẹ́ ìbúra, láti ṣe ohun tí wọ́n dá lábàá. Wọ́n sì búra. 6 Nígbà náà ni Esra padà sẹ́yìn kúrò níwájú ilé Ọlọ́run, ó sì lọ sí iyàrá Jehohanani ọmọ Eliaṣibu. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, kò jẹ oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu omi, nítorí ó sì ń káàánú fún àìṣòótọ́ àwọn ìgbèkùn.
7 Ìkéde kan jáde lọ jákèjádò Juda àti Jerusalẹmu fún gbogbo àwọn ìgbèkùn láti péjọ sí Jerusalẹmu. 8 Ẹnikẹ́ni tí ó ba kọ̀ láti jáde wá láàrín ọjọ́ mẹ́ta yóò pàdánù ohun ìní rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìpinnu àwọn ìjòyè àti àwọn àgbàgbà, àti pé a ó lé òun fúnrarẹ̀ jáde kúrò láàrín ìpéjọpọ̀ àwọn ìgbèkùn.
9 Láàrín ọjọ́ mẹ́ta náà, gbogbo àwọn ọkùnrin Juda àti Benjamini tí péjọ sí Jerusalẹmu. Ní ogúnjọ́ oṣù kẹsànán, gbogbo àwọn ènìyàn jókòó sí ìta gbangba iwájú ilé Ọlọ́run, wọ́n wà nínú ìbànújẹ́ ńlá nítorí ọ̀ràn yìí, àti nítorí òjò púpọ̀ tó tì rọ̀. 10 Nígbà náà ni àlùfáà Esra dìde, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ṣe àìṣòótọ́, ẹ ti fẹ́ obìnrin àjèjì, ẹ ti dá kún ẹ̀bi Israẹli. 11 Nísinsin yìí, ẹ jẹ́wọ́ níwájú Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba yín, kí ẹ sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn tí ó yí i yín ká àti láàrín àwọn ìyàwó àjèjì yín.”
12 Àpéjọpọ̀ ènìyàn náà sì dáhùn lóhùn rara pé: ohun tí ó sọ dára! A gbọdọ̀ ṣe bí o ti wí. 13 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ni ó wà ni ibi yìí síbẹ̀ àkókò òjò ni; àwa kò sì lè dúró ní ìta. Yàtọ̀ sí èyí, a kò le è yanjú ọ̀rọ̀ yìí láàrín ọjọ́ kan tàbí ọjọ́ méjì, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa pọ̀ jọjọ lórí àwọn nǹkan wọ̀nyí. 14 Jẹ́ kí àwọn ìjòyè wa ṣojú fún gbogbo ìjọ ènìyàn, lẹ́yìn náà, jẹ́ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú àwọn ìlú wa tí ó ti fẹ́ obìnrin àjèjì wá ní àsìkò tí a yàn, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà àti àwọn onídàájọ́ ìlú kọ̀ọ̀kan, títí ìbínú gíga Ọlọ́run wa lórí ọ̀rọ̀ yìí yóò fi kúrò ní orí wa. 15 Jonatani ọmọ Asaheli àti Jahseiah ọmọ Tikfa nìkan pẹ̀lú àtìlẹ́yìn Meṣullamu àti Ṣabbetai ará Lefi, ni wọ́n tako àbá yìí.
16 Nígbà náà ni àwọn ìgbèkùn ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fi ẹnu kò sí. Àlùfáà Esra yan àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ìdílé kọ̀ọ̀kan, gbogbo wọn ni a sì mọ̀ pẹ̀lú orúkọ wọn. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹwàá, wọ́n jókòó láti ṣe àyẹ̀wò àwọn ẹjọ́ náà, 17 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní ni wọn parí pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì.
10 Nígbà tí baálẹ̀ ṣẹ́wọ́ sì i pé kí ó sọ̀rọ̀, Paulu sì dáhùn wí pe: “Bí mo tí mọ̀ pé láti ọdún mélòó yìí wá, ní ìwọ tí ṣe onídàájọ́ orílẹ̀-èdè yìí, nítorí náà mo fi tayọ̀tayọ̀ wí tí ẹnu mi. 11 Ìwọ pẹ̀lú sì ní òye rẹ̀ pé, ìjejìlá ni mo lọ sí Jerusalẹmu láti lọ jọ́sìn. 12 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn olùfisùn mi kò rí mi kí ń máa bá ẹnikẹ́ni jiyàn nínú tẹmpili, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ru àwọn ènìyàn sókè nínú Sinagọgu tàbí ní ibikíbi nínú ìlú: 13 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò lè fi ìdí ẹ̀sùn múlẹ̀ níwájú rẹ, èyí tí wọn fi mí sùn sí nísinsin yìí. 14 Ṣùgbọ́n, èmí jẹ́wọ́ fún ọ pé, èmi ń sin Ọlọ́run àwọn baba wa gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń tẹ̀lé ọ̀nà tí wọ́n ń pè ni ìyapa ìsìn. Èmi ń gbá gbogbo nǹkan ti a kọ sínú ìwé òfin gbọ́, àti tí a kọ sínú ìwé àwọn wòlíì, 15 mo sí ní ìrètí kan náà nínú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí àwọn tìkára wọn jẹ́wọ́ pẹ̀lú, wí pé àjíǹde òkú ń bọ̀, àti tí olóòtítọ́, àti tí aláìṣòótọ́. 16 Nínú èyí ni èmi sì ti ń gbìyànjú láti ní ẹ̀rí ọkàn tí kò lẹ́sẹ̀ sí Ọlọ́run, àti sí ènìyàn nígbà gbogbo.
17 “Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún púpọ̀, mo wá sí Jerusalẹmu láti mu ẹ̀bùn wá fún àwọn ènìyàn mi fún aláìní àti láti fi ọrẹ lélẹ̀. 18 Nínú ṣíṣe nǹkan wọ̀nyí, wọ́n rí mí nínú ìyẹ̀wù tẹmpili, bí mo ti ń parí ètò ìwẹ̀nù, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ní àárín àwùjọ ènìyàn, tàbí pẹ̀lú ariwo. 19 Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan láti ẹkùn Asia wà níbẹ̀, àwọn tí ìbá wà níhìn-ín yìí níwájú rẹ, kí wọn já mi nírọ́, bí wọ́n bá ní ohunkóhun sí mi. 20 Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí tìkára wọn sọ iṣẹ́ búburú tí wọ́n rí lọ́wọ́ mi, nígbà tí mo dúró níwájú àjọ ìgbìmọ̀. 21 Bí kò ṣe tí gbólóhùn kan yìí, tí mo kégbe rẹ̀ síta nígbà tí mo dúró láàrín wọn: ‘Èyí ni tìtorí àjíǹde òkú ni a ṣe ba mi wíjọ́ lọ́dọ̀ yín ló ni yìí!’ ”
12 (A)Nígbà náà ni ó sì wí fún alásè tí ó pè é pé, “Nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè má ṣe pe àwọn arákùnrin rẹ tàbí àwọn ìbátan rẹ, tàbí àwọn ọlọ́rọ̀ aládùúgbò rẹ̀; nítorí kí wọn má ṣe pè ọ́ padà láti san ẹ̀san padà. 13 (B)Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè, pe àwọn tálákà, àwọn alábùkún ara, àwọn amúnkùn ún, àti àwọn afọ́jú: 14 Ìwọ ó sì jẹ́ alábùkún fún; nítorí wọn kò ní ohun tí wọn ó fi san án fún ọ: ṣùgbọ́n a ó san án fún ọ ní àjíǹde, àwọn olóòtítọ́.”
Òwe nípa àsè ńlá
15 (C)Nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n jọ jókòó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó wí fún Jesu pé, “Alábùkún ni fún ẹni tí yóò jẹ oúnjẹ àsè ní ìjọba Ọlọ́run!”
16 (D)Jesu dá a lóhùn pé, “Ọkùnrin kan ṣe àsè alẹ́ ńlá, ó sì pe ènìyàn púpọ̀. 17 Ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní wákàtí àsè alẹ́ náà láti sọ fún àwọn tí a ti pè pé, ‘Ẹ wá; nítorí ohun gbogbo ṣetán!’
18 “Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwáwí ohun kan. ‘Èkínní wí fún un pé, mo ra ilẹ̀ kan, mo sì fẹ́ lọ wò ó wò, mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’
19 “Èkejì sì wí pé, ‘Mo ra àjàgà màlúù márùn-ún, mo sì ń lọ wò wọ́n wò: mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’
20 (E)“Ẹ̀kẹta sì wí pé, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, nítorí náà ni èmi kò fi lè wá.’
21 (F)“Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì padà dé, ó sọ nǹkan wọ̀nyí fún olúwa rẹ̀. Nígbà náà ni baálé ilé bínú, ó wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, ‘Jáde lọ sí ìgboro, àti sí òpópó ọ̀nà, kí o sì mú àwọn tálákà, àti àwọn amúnkùn ún, àti àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú wá sí ìhín yìí.’
22 “Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì wí pé, ‘Olúwa a ti ṣe bí o ti pàṣẹ, ààyè sì ń bẹ síbẹ̀.’
23 “Olúwa náà sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ náà pé, ‘Jáde lọ sí òpópó, àti sí ọ̀nà ọgbà, kí o sì rọ̀ wọ́n láti wọlé wá, kí ilé mi lè kún. 24 Nítorí mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí a ti pè, kì yóò tọ́wò nínú àsè ńlá mi!’ ”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.