Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 120-127

Orin fún ìgòkè.

120 Èmi ké pe Olúwa nínú ìpọ́njú mi,
    ó sì dá mi lóhùn
Gbà mí, Olúwa, kúrò lọ́wọ́ ètè èké
    àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.

Kí ni kí a fi fún ọ?
    Àti kí ni kí a túnṣe fún ọ,
    ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn?
Òun yóò bá ọ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun,
    pẹ̀lú ẹ̀yín iná igi ìgbálẹ̀.

Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Meṣeki,
    nítorí èmi gbé nínú àgọ́ Kedari!
Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbé
    láàrín àwọn tí ó kórìíra àlàáfíà.
Ènìyàn àlàáfíà ni mí;
    ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni dúró fun wọn.

Orin fún ìgòkè.

121 Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì—
    níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá
Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa
    Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀;
    ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.
Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́,
    kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.

Olúwa ni olùpamọ́ rẹ;
    Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ
Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán
    tàbí òṣùpá ní ìgbà òru.

Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo
    yóò pa ọkàn rẹ mọ́
Olúwa yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́
    láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.

Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.

122 Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé
    Ẹ jẹ́ kí á lọ sílé Olúwa.
Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè rẹ,
    ìwọ Jerusalẹmu.

Jerusalẹmu, ìwọ tí a kọ́ bí ìlú
    tí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan
Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ,
    àwọn ẹ̀yà Olúwa,
ẹ̀rí fún Israẹli, láti
    máa dúpẹ́ fún orúkọ Olúwa.
Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀,
    àwọn ìtẹ́ ilé Dafidi.

Gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalẹmu;
    àwọn tí ó fẹ́ ọ yóò ṣe rere.
Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi rẹ̀,
    àti ìre nínú ààfin rẹ̀.
Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mi
    èmi yóò wí nísinsin yìí pé,
    kí àlàáfíà kí ó wà nínú rẹ̀;
Nítorí ilé Olúwa Ọlọ́run wa,
    èmi yóò máa wá ìre rẹ̀.

Orin fún ìgòkè.

123 Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí,
    ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run
Kíyèsi, bí ojú àwọn
    ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn,
    àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa,
    títí yóò fi ṣàánú fún wa.

Olúwa, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa;
    nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀.
Ọkàn wa kún púpọ̀
    fún ẹ̀gàn àwọn onírera,
    àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.

Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.

124 “Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa”
    ni kí Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;
“Ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa,”
    Nígbà tí àwọn ènìyàn dúró sí wa:
Nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè
    nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa
Nígbà náà ni omi
    wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀
Nígbà náà ni agbéraga
omi ìbá borí ọkàn wa.

Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́n
    bí ohun ọdẹ fún eyín wọn.
Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ;
    okùn já àwa sì yọ.
Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa,
    tí ó dá ọ̀run òun ayé.

Orin fún ìgòkè.

125 Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Sioni,
    tí a kò lè ṣí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé
Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,
    bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yí ènìyàn ká
    láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburú
    kì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo;
kí àwọn olódodo kí ó máa ba à
    fi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀.

Olúwa ṣe rere fún àwọn ẹni rere,
    àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin.
Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn;
    Olúwa yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

Ṣùgbọ́n àlàáfíà yóò wà lórí Israẹli.

Orin fún ìgòkè.

126 Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà,
    àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá.
Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,
    àti ahọ́n wa kọ orin;
nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé,
    Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.
Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa;
    nítorí náà àwa ń yọ̀.

Olúwa mú ìkólọ wa padà,
    bí ìṣàn omi ní gúúsù.
Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn
    yóò fi ayọ̀ ka.
Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ,
    tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́,
lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá,
    yóò sì ru ìtí rẹ̀.

Orin fún ìgòkè. Ti Solomoni.

127 Bí kò ṣe pé Olúwa bá kọ́ ilé náà
    àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán ni;
    bí kò ṣe pé Olúwa bá pa ìlú mọ́, olùṣọ́ jí lásán.
Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù
    láti pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ làálàá;
    bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ìre fún olùfẹ́ rẹ̀ lójú ọ̀run.

Kíyèsi i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa:
    ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀.
Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára,
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí apó rẹ̀ kún fún wọn;
    ojú kì yóò tì wọ́n,
    ṣùgbọ́n wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá ní ẹnu-ọ̀nà.

2 Ọba 22:1-13

A rí ìwé òfin

22 (A)Josiah jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jedida ọmọbìnrin Adaiah; ó wá láti Boskati. Ó sì ṣe èyí tí ó dára lójú Olúwa, ó sì rìn ní ọ̀nà Dafidi baba a rẹ̀, kò sì yípadà sí apá ọ̀tún tàbí sí apá òsì.

(B)Ní ọdún kejì-dínlógún tí ó fi jẹ ọba. Ọba Josiah rán akọ̀wé, Ṣafani ọmọ Asalia, ọmọ Meṣullamu, sí ilé Olúwa. Ó wí pé; “Gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Hilkiah olórí àlùfáà, kí o sì jẹ́ kí ó ṣírò iye owó tí a mú wá sí ilé Olúwa, tí àwọn olùṣọ́nà ti gbà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn. Ẹ sì jẹ́ kí wọn ó fi lé àwọn ọkùnrin tí a ti yàn láti bojútó iṣẹ́ náà lórí ilé Olúwa. Kí ẹ sì jẹ́ kí àwọn ọkùnrin san án fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń tún ilé Olúwa ṣe. Àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn akọ́lé. Bákan náà ni wọ́n ra igi àti òkúta ọlọ́ṣọ̀ọ́ láti fi tún tẹmpili ṣe. Ṣùgbọ́n wọn kò ní láti ṣe ìṣirò fún owó náà tí a fi fún wọn, nítorí wọ́n ṣe òtítọ́.”

Hilkiah olórí àlùfáà sọ fún Ṣafani akọ̀wé pé, “Èmi rí ìwé òfin nílé Olúwa.” Ó fi fún Ṣafani, ẹni tí ó kà á. Nígbà náà, Ṣafani akọ̀wé lọ sí ọ̀dọ̀ ọba. Ó sì sọ fún un pé: “Àwọn ìjòyè rẹ ti san owó náà tí ó wà nínú ilé Olúwa. Èmi sì ti fi lé ọwọ́ àwọn tí ó ń ṣe iṣẹ́ náà àti àwọn alábojútó nílé Olúwa.” 10 Nígbà náà Ṣafani akọ̀wé sọ fún ọba pé, “Hilkiah àlùfáà ti fún un ní ìwé kan.” Ṣafani kà lára rẹ̀ níwájú ọba.

11 Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé òfin, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya. 12 Ó pa àṣẹ yìí fún Ahikamu àlùfáà, Hilkiah ọmọ Ṣafani, Akbori ọmọ Mikaiah, àti Ṣafani akọ̀wé àti Asaiah ìránṣẹ́ ọba. 13 “Lọ, ẹ béèrè lọ́wọ́ Olúwa fún mi àti fún àwọn ènìyàn àti fún gbogbo Juda nípa ohun tí a kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Títóbi ni ìbínú Olúwa tí ó ń jó sí wa nítorí àwọn baba wa kò tẹ̀lé ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí; wọn kò ṣe ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ níbẹ̀ nípa wa.”

1 Kọrinti 11:2

Ìbámu nínú ìsìn

(A)Èmí yìn yín fún rírántí mi nínú ohun gbogbo àti fún dídi gbogbo ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ọ yín mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi lélẹ̀ fún un yín.

1 Kọrinti 11:17-22

Oúnjẹ alẹ́ Olúwa

17 Nínú àwọn àlàkalẹ̀ èmi ko ni yìn yín nítorí pé bí ẹ bá péjọ kì í ṣe fún rere bí ko ṣe fún búburú. 18 (A)Lọ́nà kìn-ín-ní, mo gbọ́ pe ìyapa máa ń wà láàrín yín ní ìgbà tí ẹ bá péjọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ, mo sì gba èyí gbọ́ dé ààyè ibìkan. 19 Kò sí àní àní, ìyàtọ̀ gbọdọ̀ wa láàrín yín, kí àwọn tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run láàrín yín le farahàn kedere. 20 Nígbà tí ẹ bá pàdé láti jẹun, kì í ṣe oúnjẹ alẹ́ Olúwa ni ẹ máa ń jẹ. 21 Ṣùgbọ́n tí ara yín, nígbà tí ẹ bá fẹ́ jẹun, olúkúlùkù yín a máa sáré jẹ oúnjẹ rẹ̀ láìdúró de ẹnìkejì rẹ̀. Ebi a sì máa pa wọ́n, ẹlòmíràn wọ́n sì ń mu àmuyó àti àmupara. 22 Ṣé ẹ̀yin kò ní ilé tí ẹ ti lè jẹ, tí ẹ sì ti lè mu ni? Tàbí ẹ̀yin ń gan ìjọ Ọlọ́run ni? Ẹ̀yin sì ń dójútì àwọn aláìní? Kín ni kí èmi ó wí fún un yín? Èmi yóò ha yìn yín nítorí èyí? A! Rárá o. Èmi kọ́, n kò ní yìn yín.

Matiu 9:1-8

Jesu mú arọ láradá

(A)Jesu bọ́ sínú ọkọ̀, ó sì rékọjá odò lọ sí ìlú abínibí rẹ̀ (B)Àwọn ọkùnrin kan gbé arọ kan tọ̀ ọ́ wá lórí àkéte rẹ̀. Nígbà tí Jesu rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí fún arọ náà pé, “Ọmọ tújúká, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”

Nígbà yìí ni àwọn olùkọ́ òfin wí fún ara wọn pé, “Ọkùnrin yìí ń sọ̀rọ̀-òdì!”

Jesu sì mọ̀ èrò inú wọn, ó wí pé, “Nítorí kín ni ẹ̀yin ṣe ń ro búburú nínú yín? Èwo ni ó rọrùn jù: láti wí pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ;’ tàbí wí pé, ‘Dìde, kí o sì máa rìn?’ Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé Ọmọ Ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì ni.” Ó sì wí fún arọ náà pé, “Dìde, sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa lọ ilé rẹ.” Ọkùnrin náà sì dìde, ó sì lọ ilé rẹ̀. Nígbà tí ìjọ ènìyàn rí í ẹnu sì yà wọ́n, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, ti ó fi irú agbára báyìí fún ènìyàn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.