Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 119:145-176

Kíkígbe fún ìgbàlà

145 Èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:
    dá mi lóhùn Olúwa,
    èmi yóò sì gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
146 Èmi kígbe pè ọ́; gbà mí
    èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́.
147 Èmi dìde ṣáájú àfẹ̀mọ́júmọ́ èmi ké fún ìrànlọ́wọ́;
    èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
148 Ojú mi ṣáájú ìṣọ́ òru,
    nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ.
149 Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ:
    pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
150 Àwọn tí ń gbìmọ̀ ìlànà búburú wà ní tòsí,
    ṣùgbọ́n wọ́n jìnnà sí òfin rẹ.
151 Síbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, Olúwa,
    àti gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òtítọ́.
152 Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin rẹ
    tí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé.

Pípa òfin mọ́ ni ìpọ́njú

153 Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí,
    nítorí èmi kò gbàgbé òfin rẹ.
154 Gba ẹjọ́ mi rò kí o sì rà mí padà;
    pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
155 Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburú
    nítorí wọn kò wá àṣẹ rẹ.
156 Ìyọ́nú rẹ̀ tóbi, Olúwa;
    pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
157 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀tá tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi,
    ṣùgbọ́n èmi kò tí ì yípadà kúrò nínú òfin rẹ.
158 Èmi wo àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́
    nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́.
159 Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ rẹ;
    pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ.
160 Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ;
    gbogbo òfin òdodo rẹ láéláé ni.
161 Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí,
    ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ.
162 Èmi yọ̀ nínú ìpinnu rẹ
    bí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀.
163 Èmi kórìíra mo sì kọ èké ṣíṣe
    ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin rẹ.
164 Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́
    nítorí òfin òdodo rẹ.
165 Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin rẹ,
    kò sì ṣí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.
166 Èmi yóò dúró de ìgbàlà rẹ, Olúwa,
    èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ.
167 Èmi gba òfin rẹ gbọ́,
    nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀púpọ̀
168 Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ rẹ àti òfin rẹ,
    nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi.
169 Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú rẹ, Olúwa;
    fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
170 Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú rẹ;
    gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
171 Ètè mi yóò sọ ìyìn jáde,
    nítorí ìwọ kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
172 Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ,
    nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo.
173 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣetán láti ràn mí lọ́wọ́,
    nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ rẹ.
174 Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà rẹ, Olúwa,
    àti òfin rẹ jẹ́ dídùn inú mi.
175 Jẹ́ kí èmi wà láààyè ki èmi lè yìn ọ́,
    kí o sì jẹ́ kí òfin rẹ mú mi dúró.
176 Èmí ti ṣìnà bí àgùntàn tí ó
    sọnù, wá ìránṣẹ́ rẹ,
    nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ rẹ.

Saamu 128-130

Orin fún ìgòkè.

Ìbẹ̀rù Olúwa dára

128 Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa:
    tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀
Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ
    ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ
Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere
    eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ;
    àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká.
Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà,
    tí ó bẹ̀rù Olúwa.

Olúwa kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá,
    kí ìwọ kí ó sì máa rí ìre
Jerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo.
    Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì máa rí àti ọmọdọ́mọ rẹ.
Láti àlàáfíà lára Israẹli.

Orin fún ìgòkè.

129 “Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú
    láti ìgbà èwe mi wá”
    ni kí Israẹli kí ó wí nísinsin yìí;
“Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú
    láti ìgbà èwe mi wá;
    síbẹ̀ wọn kò tí ì borí mi.
Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi:
    wọ́n sì la aporo wọn gígùn.
Olódodo ni Olúwa:
    ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.”

Kí gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni kí ó dààmú,
    kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà.
Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀
    tí ó gbẹ dànù kí ó tó dàgbàsókè:
Èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ rẹ̀:
    bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń di ìtí, kó kún apá rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kò wí pé,
    ìbùkún Olúwa kí ó pẹ̀lú yín:
    àwa ń súre fún yin ní orúkọ Olúwa.

Orin fún ìgòkè.

130 Láti inú ibú wá ni
    èmi ń ké pè é ọ́ Olúwa
Olúwa, gbóhùn mi,
    jẹ́ kí etí rẹ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

(A)Olúwa, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀,
    Olúwa, tá ni ìbá dúró.
Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ,
    kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.

Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró,
    àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí
Ọkàn mi dúró de Olúwa,
    ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ,
    àní ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.

Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa:
    nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà,
    àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáǹdè wà.
Òun ó sì dá Israẹli ní ìdè
    kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbogbo.

2 Samuẹli 18:19-23

Dafidi ṣọ̀fọ̀

19 Ahimasi ọmọ Sadoku sì wí pé, “Jẹ́ kí èmi ó súré nísinsin yìí, kí èmi sì mú ìròyìn tọ ọba lọ, bí Olúwa ti gbẹ̀san rẹ̀ lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.”

20 Joabu sì wí fún un pé, “Ìwọ kì yóò mù ìròyìn lọ lónìí, ṣùgbọ́n ìwọ ó mú lọ ní ọjọ́ mìíràn: ṣùgbọ́n lónìí yìí ìwọ kì yóò mú ìròyìn kan lọ, nítorí tí ọmọ ọba ṣe aláìsí.”

21 Joabu sì wí fún Kuṣi pé, “Lọ, kí ìwọ ro ohun tí ìwọ rí fún ọba.” Kuṣi sì wólẹ̀ fún Joabu ó sì sáré.

22 Ahimasi ọmọ Sadoku sì tún wí fún Joabu pé, “Jọ̀wọ́, bí ó ti wù kí ó rí, èmi ó sáré tọ Kuṣi lẹ́yìn.”

Joabu sì bi í pé, “Nítorí kín ni ìwọ ó ṣe sáré, ọmọ mi, ìwọ kò ri pé kò sí ìròyìn rere kan tí ìwọ ó mú lọ.”

23 Ó sì wí pé, “Bí ó ti wù kí ó rí, èmi ó sáré.”

Ó sì wí fún un pé, “Sáré!” Ahimasi sì sáré ní ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀, ó sì sáré kọjá Kuṣi.

Ìṣe àwọn Aposteli 23:23-35

A gbé Paulu lọ Kesarea

23 Ó sì pe méjì nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ múra igba ọmọ-ogun sílẹ̀, láti lọ sí Kesarea, àti àádọ́rin ẹlẹ́ṣin, àti igba ọlọ́kọ̀, ní wákàtí kẹta òru. 24 Ó sì wí pé, kí wọn pèsè ẹṣin, kí wọ́n gbé Paulu gùn ún; kí wọ́n sì lè mú un dé ọ̀dọ̀ Feliksi baálẹ̀ ní àlàáfíà.”

25 Ó sì kọ ìwé kan báyìí pé:

26 Kilaudiu Lisia,

Sí Feliksi baálẹ̀ ọlọ́lá jùlọ:

Àlàáfíà.

27 Àwọn Júù mú ọkùnrin yìí, wọ́n sì ń pète láti pa á: nígbà náà ni mo dé pẹ̀lú ogun, mo sì gbà á lọ́wọ́ wọn nígbà tí mo gbọ́ pé ará Romu ni í ṣe. 28 Nígbà tí mo sì ń fẹ́ mọ ìdí ọ̀ràn tí wọn fi ẹ̀sùn kàn án sí, mo mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí àjọ ìgbìmọ̀ wọn. 29 Ẹni tí mo rí pé, wọ́n fi sùn nítorí ọ̀ràn òfin wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọ̀ràn ohun kan tí ó tọ́ sí ikú àti sí ẹ̀wọ̀n. 30 Nígbà tí a sì tí jí i sọ fún mi pé, wọn yóò dènà de ọkùnrin náà, mo rán an sí ọ lọ́gán, mo sì pàṣẹ fún àwọn olùfisùn rẹ̀ pẹ̀lú, láti sọ ohun tí wọ́n bá rí wí sí i níwájú rẹ̀.

31 Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gbe Paulu, wọ́n sì mú un lóru lọ si Antipatrisi, gẹ́gẹ́ bí a tí pàṣẹ fún wọn. 32 Ní ọjọ́ kejì wọ́n sì fi àwọn ẹlẹ́ṣin sílẹ̀ láti máa bá a lọ, àwọn sì padà wá sínú àgọ́ àwọn ológun. 33 Nígbà tí wọ́n dé Kesarea, tí wọ́n sí fi ìwé fún baálẹ̀, wọ́n mú Paulu pẹ̀lú wá síwájú rẹ̀. 34 Nígbà tí ó sì ti ka ìwé náà, ó béèrè pé agbègbè ìlú wo ni tirẹ̀. Nígbà tí ó sì gbọ́ pé ará Kilikia ni; 35 Ó wí pé, “Èmi yóò gbọ́ ẹjọ́ rẹ, nígbà tí àwọn olùfisùn rẹ pẹ̀lú bá dé.” Ó sì pàṣẹ pé kí wọn pa Paulu mọ́ ní abẹ́ àbojútó àwọn olùṣọ́ ní gbọ̀ngàn ìdájọ́ ààfin Herodu.

Marku 12:13-27

Sísan owó orí fún Kesari

13 (A)(B) Ṣùgbọ́n wọ́n rán àwọn Farisi pẹ̀lú àwọn kan tí í ṣe ọmọ-ẹ̀yìn Herodu wá sọ́dọ̀ Jesu, láti fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, títí yóò fi sọ ohun kan kí wọn lè rí fi mú. 14 Bí wọn ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé: “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé ìwọ máa ń sọ òtítọ́ láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ máa ń kọ́ni. Nísinsin yìí, sọ fún wa, ó tọ́ tàbí kò tọ́ láti máa san owó orí fún Kesari?” 15 Kí àwa kí ó fi fún un, tàbí kí a máa fi fún un?

Ṣùgbọ́n Jesu mọ ìwà àgàbàgebè wọn. Ó sì wí pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi n fi èyí dán mi wo? Ẹ mú owó idẹ kan wá kí n wò ó.” 16 Nígbà tí wọ́n mú owó idẹ náà fún un, ó bi wọ́n léèrè pé, “Ẹ wò ó! Àwòrán àti orúkọ ta ni ó wà níbẹ̀?”

Wọ́n dáhùn pé, “Àwòrán àti orúkọ Kesari ni.”

17 (C)Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari. Ṣùgbọ́n ẹ fi ohun gbogbo tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”

Ẹnu sì yà wọ́n gidigidi sí èsì rẹ̀.

Ìgbéyàwó ní àjíǹde

18 (D)Àwọn Sadusi tún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn wọ̀nyí kò gbàgbọ́ pé àjíǹde ń bẹ. Ìbéèrè wọn ni pé, 19 (E)“Olùkọ́, Mose fún wa ní òfin pé: Nígbà tí ọkùnrin kan bá kú láìbí ọmọ, arákùnrin rẹ̀ gbọdọ̀ ṣú ìyàwó náà lópó kí wọn sì bímọ ní orúkọ ọkọ tí ó kú náà. 20 Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan wà, èyí tí ó dàgbà jùlọ gbéyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ. 21 Arákùnrin rẹ̀ kejì ṣú obìnrin tí ó fi sílẹ̀ lópó, láìpẹ́, òun pẹ̀lú tún kú láìbímọ. Arákùnrin kẹta tó ṣú obìnrin yìí lópó tún kú bákan náà láìbímọ. 22 Àwọn méjèèje sì ṣú u lópó, wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀. Ní ìkẹyìn gbogbo wọn, obìnrin náà kú pẹ̀lú. 23 Ǹjẹ́ ní àjíǹde, nígbà tí wọ́n bá jíǹde, aya ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Àwọn méjèèje ni ó sá ni ní aya?”

24 Jesu dáhùn ó wí fún wọn pé, “Kì í há ṣe nítorí èyí ni ẹ ṣe ṣìnà, pé ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́, tàbí agbára Ọlọ́run. 25 Nítorí pé, nígbà tí àwọn arákùnrin méje yìí àti obìnrin náà bá jí dìde nínú òkú, a kò ní ṣe ìgbéyàwó fún wọn. Wọn yóò dàbí àwọn angẹli tí ń bẹ ní ọ̀run. 26 (F)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa bóyá àjíǹde yóò wà. Àbí ẹ̀yin kò ì tí ka ìwé Eksodu, nípa Mose àti pápá tí ń jó? Ọlọ́run sọ fún Mose pé, ‘Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu.’ 27 Òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú bí kò ṣe Ọlọ́run àwọn alààyè: nítorí ẹ̀yin ṣe àṣìṣe gidigidi.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.