Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Saamu ti Asafu. Orin.
75 A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run,
a yìn ọ́, nítorí orúkọ rẹ súnmọ́ tòsí;
àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu rẹ.
2 Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀;
Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo.
3 Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì,
Èmi ni mo di òpó rẹ̀ mú ṣinṣin.
4 Èmí wí fún àwọn agbéraga pé
Ẹ má ṣe gbéraga mọ́;
àti sí ènìyàn búburú;
Ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè.
5 Ẹ má ṣe gbe ìwo yín sókè sí ọ̀run;
ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọrùn líle.”
6 Nítorí ìgbéga kò ti ìlà-oòrùn wá
tàbí ní ìwọ̀-oòrùn,
bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti gúúsù wá.
7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdájọ́;
Ó ń rẹ ẹnìkan sílẹ̀, ó sì ń gbé ẹlòmíràn ga.
8 Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà,
ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú,
ó fún ọtí àdàlú tí a pò mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde,
àwọn ènìyàn búburú ayé gbogbo mú u pátápátá.
9 Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé;
Èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu.
10 Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú,
Ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Asafu. Orin.
76 Ní Juda ni a mọ Ọlọ́run;
orúkọ rẹ̀ sì lágbára ní Israẹli
2 Àgọ́ rẹ̀ wà ní Salẹmu,
ibùgbé rẹ̀ ni Sioni.
3 Níbẹ̀ ni ó ṣẹ́ ọfà,
asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun. Sela.
4 Ìwọ ni ògo àti ọlá
Ju òkè ńlá ìkógun wọ̀nyí lọ.
5 A kó àwọn alágídí ọkàn ní ìkógun
wọ́n sun oorun ìgbẹ̀yìn wọn;
kò sí ọ̀kan nínú àwọn akọni
tó lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.
6 Ní ìfibú rẹ, Ọlọ́run Jakọbu,
àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.
7 Ìwọ nìkan ni ó yẹ kí a bẹ̀rù.
Ta ló lé dúró níwájú rẹ, nígbà tí ìwọ bá ń bínú?
8 Ìwọ ń ṣe ìdájọ́ láti ọ̀run,
ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ẹ́:
9 Nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run,
bá dìde láti ṣe ìdájọ́,
láti gba àwọn ẹni ìnilára ilẹ̀ náà. Sela.
10 Lóòótọ́, ìbínú rẹ sí àwọn ènìyàn ń mú ìyìn wá fún ọ,
ẹni tí ó yọ nínú ìbínú rẹ ní a dá nígbà tí ìwọ bá fi ìbínú ìyókù di ara rẹ ni àmùrè.
11 Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì mú un ṣẹ;
kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká
mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí ó tọ́ láti bẹ̀rù.
12 Ó ké ẹ̀mí àwọn aládé kúrò;
àwọn ọba ayé sì ń bẹ̀rù rẹ̀.
Saamu ti Dafidi.
23 Olúwa ni Olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.
2 (A)Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù
Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́;
3 Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò
Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo
nítorí orúkọ rẹ̀.
4 Bí mo tilẹ̀ ń rìn
Láàrín àfonífojì òjìji ikú,
èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan;
nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;
ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ
wọ́n ń tù mí nínú.
5 Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi
ní ojú àwọn ọ̀tá à mi;
ìwọ ta òróró sí mi ní orí;
ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.
6 Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn
ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,
èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa
títí láéláé.
Ti Dafidi.
27 Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi;
ta ni èmi yóò bẹ̀rù?
Olúwa ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi,
ẹ̀rù ta ni yóò bà mí?
2 Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi
láti jẹ ẹran-ara mi,
àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi,
wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.
3 Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi,
ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù;
bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi,
nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.
4 Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa,
òhun ni èmi yóò máa wá kiri:
kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa
ní ọjọ́ ayé mi gbogbo,
kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa,
kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.
5 Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú
òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀;
níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́;
yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.
6 Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè
ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká;
èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀;
èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí Olúwa.
7 Gbọ́ ohùn mi nígbà tí ẹ̀mí bá à ń pè, Háà! Olúwa,
ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn;
8 “Wá,” ọkàn mi wí pé, “wá ojú u rẹ̀.”
Ojú rẹ, Olúwa, ni èmí ń wá.
9 Má ṣe fi ojú rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi,
má ṣe fi ìbínú sá ìránṣẹ́ rẹ tì;
ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi,
Má ṣe fi mí sílẹ̀, má sì ṣe kọ̀ mí,
háà! Ọlọ́run ìgbàlà mi.
10 Bí ìyá àti baba bá kọ̀ mí sílẹ̀,
Olúwa yóò tẹ́wọ́ gbà mí.
11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,
kí o sì sìn mi lọ sí ọ̀nà tí ó tẹ́jú
nítorí àwọn ọ̀tá mi.
12 Má ṣe fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́,
nítorí àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi,
wọ́n sì mí ìmí ìkà.
13 Èmi ní ìgbàgbọ́ pé,
èmi yóò rí ìre Olúwa
ní ilẹ̀ alààyè.
14 Dúró de Olúwa;
kí ó jẹ alágbára, kí o sì mú ọkàn le
àní dúró de Olúwa.
15 Àwa tí a jẹ́ alágbára nínú ìgbàgbọ́ yẹ kí ó máa ru ẹrù àìlera àwọn aláìlera, kí a má sì ṣe ohun tí ó wu ara wa. 2 Olúkúlùkù wa gbọdọ̀ máa ṣe ohun tí ó wu ọmọnìkejì rẹ̀ sí rere, láti gbé e ró. 3 (A)Nítorí Kristi pàápàá kò ṣe ohun tí ó wu ara rẹ̀, ṣùgbọ́n, bí a ti kọ ọ́ pé: “Ẹ̀gàn àwọn ẹni tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mi.” 4 (B)Nítorí ohun gbogbo tí a kọ tẹ́lẹ̀, ni a kọ láti fi kọ́ wa pé, nípa sùúrù àti ìtùnú ìwé mímọ́, kí àwa lè ní ìrètí.
5 (C)Kí Ọlọ́run, ẹni tí ń fún ni ní sùúrù àti ìtùnú fún yin láti ní inú kan sí ara yín gẹ́gẹ́ bí i Jesu Kristi, 6 kí ẹ̀yin kí ó lè fi ọkàn kan àti ẹnu kan fi ògo fún Ọlọ́run, Baba Olúwa wa Jesu Kristi.
7 Nítorí náà ẹ gba ara yín mọ́ra, gẹ́gẹ́ bí Kristi ti gbà wá mọ́ra fún ògo Ọlọ́run. 8 Mo sì wí pé, a rán Kristi láti ṣe ìránṣẹ́ ìkọlà àwọn tí ṣe Júù nítorí òtítọ́ Ọlọ́run, láti fi ìdí àwọn ìlérí tí a ti ṣe fún àwọn baba múlẹ̀, 9 (D)kí àwọn aláìkọlà kí ó lè yin Ọlọ́run lógo nítorí àánú rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
“Nítorí èyí ni èmi ó ṣe yìn ọ́ láàrín àwọn Kèfèrí,
Èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.”
10 (E)Ó sì tún wí pé,
“Ẹ̀yin Kèfèrí, ẹ ma yọ̀, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.”
11 (F)Àti pẹ̀lú,
“Ẹyin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin Kèfèrí;
ẹ kọ orin ìyìn sí, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo.”
12 (G)Isaiah sì tún wí pé,
“Gbòǹgbò Jese kan ń bọ̀ wá,
òun ni ẹni tí yóò dìde ṣe àkóso àwọn Kèfèrí;
Àwọn Kèfèrí yóò ní ìrètí nínú rẹ̀.”
13 Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yin ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrètí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.
Jesu rán ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá lọ wàásù
9 (A)Ó sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá jọ, ó sì fún wọn ní agbára àti àṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí èṣù gbogbo, àti láti wo ààrùn sàn. 2 Ó sì rán wọn lọ wàásù ìjọba Ọlọ́run, àti láti mú àwọn ọlọkùnrùn láradá. 3 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe mú nǹkan lọ́wọ́ fún àjò yín, ọ̀pá, tàbí àpò tàbí àkàrà, tàbí owó: bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má sì ṣe ní ẹ̀wù méjì. 4 Ní ilékílé tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin gbé, láti ibẹ̀ ni kí ẹ̀yin sì ti jáde. 5 (B)Iye àwọn tí kò bá si gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò ní ìlú náà, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín fún ẹ̀rí sí wọn.” 6 Wọ́n sì lọ, wọ́n ń la ìletò kọjá wọ́n sì ń wàásù ìhìnrere, wọ́n sì ń mú ènìyàn láradá níbi gbogbo.
7 (C)Herodu tetrarki gbọ́ nǹkan gbogbo èyí tí a ṣe láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá: ó sì dààmú, nítorí tí àwọn ẹlòmíràn ń wí pé, Johanu ni ó jíǹde kúrò nínú òkú; 8 Àwọn ẹlòmíràn sì wí pé Elijah ni ó farahàn; àwọn ẹlòmíràn sì wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde. 9 (D)Herodu sì wí pé, “Johanu ni mo ti bẹ́ lórí: ṣùgbọ́n ta ni èyí tí èmi ń gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí sí?” Ó sì ń fẹ́ láti rí i.
Jesu bọ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn
10 (E)Nígbà tí àwọn aposteli sì padà dé, wọ́n ròyìn ohun gbogbo fún un tí wọ́n ti ṣe. Ó sì mú wọn, lọ sí apá kan níbi tí a ń pè ní Betisaida. 11 (F)Nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sì mọ̀, wọ́n tẹ̀lé e: ó sì gbà wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún wọn; àwọn tí ó fẹ́ ìmúláradá, ni ó sì mú láradá.
12 Nígbà tí ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ sí rọlẹ̀, àwọn méjìlá wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Tú ìjọ ènìyàn ká, kí wọn lè lọ sí ìletò àti sí ìlú yíká, kí wọn lè wò, àti kí wọn lè wá oúnjẹ: nítorí ijù ni àwa sá wà níhìn-ín.”
13 (G)Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Ẹ fi oúnjẹ fún wọn jẹ!”
Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-ún lọ, pẹ̀lú ẹja méjì: bí kò ṣe pé àwa lọ ra oúnjẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí.” 14 Nítorí àwọn ọkùnrin náà tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn.
Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Kí wọ́n mú wọn jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, ní àràádọ́ta.” 15 Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì mú gbogbo wọn jókòó. 16 (H)Nígbà náà ni ó mú ìṣù àkàrà márùn-ún, àti ẹja méjì náà, nígbà tí ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, kí wọn gbé e kalẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn. 17 Wọ́n sì jẹ, gbogbo wọn sì yó: wọ́n ṣa agbọ̀n méjìlá jọ nínú àjẹkù tí ó kù.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.