Add parallel Print Page Options

Àwọn ọmọ Israẹli kọ̀ láti lọ sí Kenaani

14 Gbogbo ìjọ ènìyàn sì gbóhùn sókè, wọ́n sì sọkún ní òru ọjọ́ náà. Gbogbo ọmọ Israẹli sì kùn sí Mose àti Aaroni, gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sì wí fún wọn pé; “Àwa ìbá kúkú ti kú ní ilẹ̀ Ejibiti. Tàbí kí a kúkú kú sínú aginjù yìí. (A)Kí ló dé tí Olúwa fi mú wa wá sí ilẹ̀ yìí láti fi idà pa wá? Àwọn ìyàwó wa, àwọn ọmọ wa yóò sì di ìjẹ. Ǹjẹ́ kò wa, ní í dára fún wa bí a bá padà sí Ejibiti?” Wọ́n sì sọ fún ara wọn pé “Ẹ jẹ́ kí á yan olórí kí á sì padà sí Ejibiti.”

Nígbà náà ni Mose àti Aaroni dojúbolẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli. Joṣua ọmọ Nuni àti Kalebu ọmọ Jefunne, tí wọ́n wà lára àwọn to lọ yẹ ilẹ̀ wò sì fa aṣọ wọn ya. Wọ́n sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli pé, “Ilẹ̀ tí a là kọjá láti yẹ̀ wò náà jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀. Bí inú Olúwa bá dùn sí wa, yóò mú wa dé ilẹ̀ náà, ilẹ̀ tó ń sàn fún wàrà àti fún oyin, yóò fún wa ní ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa. Kí ẹ sì má bẹ̀rù àwọn ènìyàn ìlú náà, nítorí pé a ó gbé wọn mì, ààbò wọn ti fi wọ́n sílẹ̀, Olúwa sì wà pẹ̀lú àwa, Ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn.”

10 Ṣùgbọ́n gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń sọ pé àwọn yóò sọ wọ́n lókùúta pa. Nígbà náà ni ògo Olúwa fi ara hàn ní àgọ́ ìpàdé níwájú àwọn ọmọ Israẹli.

Mose bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ènìyàn

11 (B)Olúwa sọ fún Mose pé, “Fún ìgbà wo ni àwọn ènìyàn yìí yóò ti kẹ́gàn mi tó? Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí wọ́n ó fi kọ̀ jálẹ̀ láti gbà mí gbọ́, pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ ààmì tí mo ṣe láàrín wọn? 12 Èmi ó kọlù wọ́n pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn, èmi ó gba ogún wọn lọ́wọ́ wọn, èmi ó sì pa wọ́n run ṣùgbọ́n èmi ó sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá tó sì lágbára jù wọ́n lọ.”

13 Ṣùgbọ́n Mose sọ fún Olúwa pé, “Nígbà náà ni àwọn ará Ejibiti yóò gbọ́; Nítorí pé nípa agbára rẹ ni ìwọ fi mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí jáde kúrò láàrín wọn. 14 Wọ́n ó sì sọ fún àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí. Àwọn tó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ìwọ Olúwa wà láàrín àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti pé wọ́n rí ìwọ, Olúwa, ní ojúkojú, àti pé ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ dúró lórí wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì ń lọ níwájú wọn pẹ̀lú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ní ọ̀sán àti pẹ̀lú ọ̀wọ́n iná ní òru. 15 Bí ìwọ bá pa àwọn ènìyàn wọ̀nyí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, àwọn orílẹ̀-èdè tó bá gbọ́ ìròyìn yìí nípa rẹ yóò wí pé, 16 ‘Nítorí pé Olúwa kò le è mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí dé ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún wọn; torí èyí ló ṣe pa wọ́n sínú aginjù yìí.’

17 “Báyìí, mo gbàdúrà, jẹ́ kí agbára Olúwa tóbi gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti sọ pé: 18 Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ tó dúró ṣinṣin, tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá jì. Bẹ́ẹ̀ ni kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà; tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹta àti ìran kẹrin.’ 19 Dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn yìí jì wọ́n, mo bẹ̀ ọ́, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ńlá rẹ, bí o ti ṣe ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n láti ìgbà tí o ti kó wọn kúrò ní Ejibiti di ìsin yìí.”

20 Olúwa sì dáhùn pé: “Mo ti dáríjì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ; 21 Ṣùgbọ́n nítòótọ́ bí mo ti wà láààyè, gbogbo ayé yóò kún fún ògo Olúwa. 22 (C)Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tó rí ògo mi àti àwọn iṣẹ́ ààmì tí mo ṣe ní ilẹ̀ Ejibiti àti nínú aginjù ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí mi, tí wọn sì dán mi wò ní ìgbà mẹ́wàá yìí, 23 Ọ̀kan nínú wọn kò ní rí ilẹ̀ náà tí mo ṣe ìlérí ní ìbúra láti fún baba ńlá wọn. Kò sí ọ̀kan nínú àwọn tó kẹ́gàn mi tí yóò rí ilẹ̀ náà. 24 Ṣùgbọ́n nítorí pé Kalebu ìránṣẹ́ mi ní ẹ̀mí ọ̀tọ̀, tí ó sì tún tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, èmi ó mu dé ilẹ̀ náà tó lọ yẹ̀ wò, irú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì jogún rẹ̀. 25 Níwọ́n ìgbà tí àwọn ará Amaleki àti àwọn ará Kenaani ń gbé ní Àfonífojì, ẹ yípadà lọ́la kí ẹ sì dojúkọ aginjù lọ́nà Òkun Pupa.”

26 Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé: 27 “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ìjọ ènìyàn búburú yìí yóò fi máa kùn sí mi? Mo ti gbọ́ kíkùn tí àwọn ọmọ Israẹli ń kùn sí mi. 28 Sọ fún wọn, Bí mo ti wà láààyè nítòótọ́ ni Olúwa wí, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ wí létí mi ni èmi ó ṣe fún un yín. 29 (D)Nínú aginjù yìí ni ẹ ó kú sí, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kùn láti ọmọ ogún ọdún ó lé àní gbogbo ẹ̀yin tí a kà. 30 Ọ̀kan nínú yín kò ní í dé ilẹ̀ tí mo búra nípa ìgbọ́wọ́sókè láti fi ṣe ibùgbé yín, bí kò ṣe Kalebu ọmọ Jefunne àti Joṣua ọmọ Nuni. 31 Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ yín tí ẹ wí pé wọn ó di ìjẹ, àwọn ni n ó mú dé bẹ̀ láti gbádùn ilẹ̀ tí ẹ kọ̀sílẹ̀. 32 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, òkú yín yóò ṣubú ní aginjù yìí. 33 (E)Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín yóò sì máa rin kiri nínú aginjù fun ogójì ọdún (40) wọn ó máa jìyà nítorí àìnígbàgbọ́ yín, títí tí ọkàn gbogbo yín yóò fi ṣòfò tán ní aginjù. 34 Fún ogójì ọdún èyí jẹ́ ọdún kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ogójì ọjọ́ tí ẹ fi yẹ ilẹ̀ náà wò ẹ̀yin ó sì jìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì mọ bí ó ti rí láti lòdì sí mi. 35 Èmi, Olúwa, lo sọ bẹ́ẹ̀; Èmi ó sì ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí ìjọ ènìyàn búburú yìí tí wọ́n kó ra wọn jọ lòdì sí mi. Nínú aginjù yìí ni òpin yóò dé bá wọn, ibẹ̀ ni wọn yóò kú sí.”

36 Àwọn ọkùnrin tí Mose rán láti yẹ ilẹ̀ wò, tí wọ́n sì mú gbogbo ìjọ kùn sí i nípa ìròyìn búburú tí wọ́n mú wá nípa ilẹ̀ náà; 37 Olúwa sì kọlu àwọn ọkùnrin tó mú ìròyìn búburú wá nípa ilẹ̀ náà, àjàkálẹ̀-ààrùn sì pa wọ́n níwájú Olúwa. 38 Nínú gbogbo àwọn tó lọ yẹ ilẹ̀ náà wò, Joṣua ọmọ Nuni àti Kalebu ọmọ Jefunne ló yè é.

39 Nígbà tí Mose sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì sọkún gidigidi. 40 Wọ́n dìde ní àárọ̀ ọjọ́ kejì wọ́n sì gòkè lọ sí ìlú orí òkè, wọ́n wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀, Àwa yóò lọ sí ibi tí Olúwa ṣèlérí fún wa.”

41 Mose sì dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ṣẹ̀ sí òfin Olúwa? Èyí kò le yọrí sí rere! 42 Ẹ má ṣe gòkè lọ nítorí pé Olúwa kò sí láàrín yín. Ki á má ba à lù yín bolẹ̀ níwájú àwọn ọ̀tá yín. 43 Nítorí pé àwọn ará Amaleki àti àwọn ará Kenaani ń bẹ níwájú yín, ẹ̀yin yóò sì ti ipa idà ṣubú. Nítorí pé, ẹ ti yà kúrò ní ọ̀nà Olúwa, Olúwa kò sì ní í wà pẹ̀lú yín.”

44 Síbẹ̀síbẹ̀, pẹ̀lú àìfarabalẹ̀ wọn, wọ́n gòkè lọ sórí òkè náà, láìjẹ́ pé àpótí ẹ̀rí Olúwa tàbí Mose kúrò nínú ibùdó. 45 Àwọn ará Amaleki àti àwọn ará Kenaani tó ń gbé lórí òkè sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n, wọ́n bá wọn jà, wọ́n sì lé wọn títí dé Horma.

The People Rebel

14 That night all the members of the community raised their voices and wept aloud.(A) All the Israelites grumbled(B) against Moses and Aaron, and the whole assembly said to them, “If only we had died in Egypt!(C) Or in this wilderness!(D) Why is the Lord bringing us to this land only to let us fall by the sword?(E) Our wives and children(F) will be taken as plunder.(G) Wouldn’t it be better for us to go back to Egypt?(H) And they said to each other, “We should choose a leader and go back to Egypt.(I)

Then Moses and Aaron fell facedown(J) in front of the whole Israelite assembly(K) gathered there. Joshua son of Nun(L) and Caleb son of Jephunneh, who were among those who had explored the land, tore their clothes(M) and said to the entire Israelite assembly, “The land we passed through and explored is exceedingly good.(N) If the Lord is pleased with us,(O) he will lead us into that land, a land flowing with milk and honey,(P) and will give it to us.(Q) Only do not rebel(R) against the Lord. And do not be afraid(S) of the people of the land,(T) because we will devour them. Their protection is gone, but the Lord is with(U) us.(V) Do not be afraid of them.”(W)

10 But the whole assembly talked about stoning(X) them. Then the glory of the Lord(Y) appeared at the tent of meeting to all the Israelites. 11 The Lord said to Moses, “How long will these people treat me with contempt?(Z) How long will they refuse to believe in me,(AA) in spite of all the signs(AB) I have performed among them? 12 I will strike them down with a plague(AC) and destroy them, but I will make you into a nation(AD) greater and stronger than they.”(AE)

13 Moses said to the Lord, “Then the Egyptians will hear about it! By your power you brought these people up from among them.(AF) 14 And they will tell the inhabitants of this land about it. They have already heard(AG) that you, Lord, are with these people(AH) and that you, Lord, have been seen face to face,(AI) that your cloud stays over them,(AJ) and that you go before them in a pillar of cloud by day and a pillar of fire by night.(AK) 15 If you put all these people to death, leaving none alive, the nations who have heard this report about you will say, 16 ‘The Lord was not able to bring these people into the land he promised them on oath,(AL) so he slaughtered them in the wilderness.’(AM)

17 “Now may the Lord’s strength be displayed, just as you have declared: 18 ‘The Lord is slow to anger, abounding in love and forgiving sin and rebellion.(AN) Yet he does not leave the guilty unpunished; he punishes the children for the sin of the parents to the third and fourth generation.’(AO) 19 In accordance with your great love, forgive(AP) the sin of these people,(AQ) just as you have pardoned them from the time they left Egypt until now.”(AR)

20 The Lord replied, “I have forgiven them,(AS) as you asked. 21 Nevertheless, as surely as I live(AT) and as surely as the glory of the Lord(AU) fills the whole earth,(AV) 22 not one of those who saw my glory and the signs(AW) I performed in Egypt and in the wilderness but who disobeyed me and tested me ten times(AX) 23 not one of them will ever see the land I promised on oath(AY) to their ancestors. No one who has treated me with contempt(AZ) will ever see it.(BA) 24 But because my servant Caleb(BB) has a different spirit and follows me wholeheartedly,(BC) I will bring him into the land he went to, and his descendants will inherit it.(BD) 25 Since the Amalekites(BE) and the Canaanites(BF) are living in the valleys, turn(BG) back tomorrow and set out toward the desert along the route to the Red Sea.[a](BH)

26 The Lord said to Moses and Aaron: 27 “How long will this wicked community grumble against me? I have heard the complaints of these grumbling Israelites.(BI) 28 So tell them, ‘As surely as I live,(BJ) declares the Lord, I will do to you(BK) the very thing I heard you say: 29 In this wilderness your bodies will fall(BL)—every one of you twenty years old or more(BM) who was counted in the census(BN) and who has grumbled against me. 30 Not one of you will enter the land(BO) I swore with uplifted hand(BP) to make your home, except Caleb son of Jephunneh(BQ) and Joshua son of Nun.(BR) 31 As for your children that you said would be taken as plunder, I will bring them in to enjoy the land you have rejected.(BS) 32 But as for you, your bodies will fall(BT) in this wilderness. 33 Your children will be shepherds here for forty years,(BU) suffering for your unfaithfulness, until the last of your bodies lies in the wilderness. 34 For forty years(BV)—one year for each of the forty days you explored the land(BW)—you will suffer for your sins and know what it is like to have me against you.’ 35 I, the Lord, have spoken, and I will surely do these things(BX) to this whole wicked community, which has banded together against me. They will meet their end in this wilderness; here they will die.(BY)

36 So the men Moses had sent(BZ) to explore the land, who returned and made the whole community grumble(CA) against him by spreading a bad report(CB) about it— 37 these men who were responsible for spreading the bad report(CC) about the land were struck down and died of a plague(CD) before the Lord. 38 Of the men who went to explore the land,(CE) only Joshua son of Nun and Caleb son of Jephunneh survived.(CF)

39 When Moses reported this(CG) to all the Israelites, they mourned(CH) bitterly. 40 Early the next morning they set out for the highest point in the hill country,(CI) saying, “Now we are ready to go up to the land the Lord promised. Surely we have sinned!(CJ)

41 But Moses said, “Why are you disobeying the Lord’s command? This will not succeed!(CK) 42 Do not go up, because the Lord is not with you. You will be defeated by your enemies,(CL) 43 for the Amalekites(CM) and the Canaanites(CN) will face you there. Because you have turned away from the Lord, he will not be with you(CO) and you will fall by the sword.”

44 Nevertheless, in their presumption they went up(CP) toward the highest point in the hill country, though neither Moses nor the ark of the Lord’s covenant moved from the camp.(CQ) 45 Then the Amalekites and the Canaanites(CR) who lived in that hill country(CS) came down and attacked them and beat them down all the way to Hormah.(CT)

Footnotes

  1. Numbers 14:25 Or the Sea of Reeds