Add parallel Print Page Options

Ọmọ ta ni Kristi?

41 (A)Bí àwọn Farisi ti kó ara wọn jọ, Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, 42 “Kí ni ẹ rò nípa Kristi? Ọmọ ta ni òun ń ṣe?”

Wọ́n dáhùn pé, “Ọmọ Dafidi.”

43 Ó sì wí fún wọn pé, “Kí lo dé tí Dafidi, tí ẹ̀mí ń darí, pè é ní ‘Olúwa’? Nítorí ó wí pé,

44 “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé,
    “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
títí tí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ
    sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.” ’

45 Ǹjẹ́ bí Dafidi bá pè é ni ‘Olúwa,’ báwo ni òun ṣe lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?” 46 (B)Kò sí ẹnìkan tí ó lè sọ ọ̀rọ̀ kan ni ìdáhùn, kò tún sí ẹni tí ó tún bí i léèrè ohun kan mọ́ láti ọjọ́ náà mọ́.

Read full chapter

Ọmọ ta ni Jesu n ṣe

41 (A)Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí wọ́n fi ń wí pé, Ọmọ Dafidi ni Kristi? 42 Dafidi tìkára rẹ̀ sì wí nínú ìwé Saamu pé:

“ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:
    “Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
43 títí èmi ó fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
    di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’

44 Ǹjẹ́ bí Dafidi bá pè é ní ‘Olúwa.’ Òun ha sì ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”

Read full chapter