Add parallel Print Page Options

17 “Ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a fi kálámù irin kọ,
    èyí tí a fi ṣóńṣó òkúta adamante gbẹ́ ẹ,
sórí wàláà oókan àyà wọn,
    àti sórí ìwo pẹpẹ yín.
Kódà àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹ
    àti ère Aṣerah lẹ́bàá igi tí ó tẹ́ rẹrẹ
    àti àwọn òkè gíga.
Àwọn òkè nínú ilẹ̀ àti àwọn ọrọ̀ rẹ̀
    àti ọlá rẹ̀ ni èmi yóò fi sílẹ̀ bí ìjẹ
pẹ̀lú àwọn ibi gíga, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó
    pọ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè yín.
Láti ipasẹ̀ àìṣedéédéé yín ni ẹ̀yin
    yóò ti sọ ogún tí mo fún un yín nù.
Èmi yóò fi yín fún ọ̀tá yín
    bí ẹrú ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò mọ̀; nítorí
    ẹ̀yin ti mú inú bí mi, èyí tí yóò sì wà títí ayé.”

Báyìí ni Olúwa wí:

“Ègbé ni fún àwọn tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ènìyàn,
    tí ó fi agbára rẹ̀ sínú ẹran-ara,
    àti tí ọkàn rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ Olúwa
Yóò dàbí igbó tí ó wà ní ilẹ̀ aláìlọ́ràá,
    kò ní rí ìre, nígbà tí ó bá dé,
yóò máa gbé ní ibi ìyàngbẹ ilẹ̀ aginjù,
    ní ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé.

(A)“Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrin
    náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, tí ó sì fi
    Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.
Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò
    tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò
kò sí ìbẹ̀rù fún un nígbà ooru,
    gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù
kò sí ìjayà fún un ní ọdún ọ̀dá
    bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.”

Ọkàn ènìyàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun
    gbogbo lọ, ó kọjá ohun tí a lè
    wòsàn, ta ni èyí lè yé?

10 (B)“Èmi Olúwa ń wo ọkàn àti èrò
    inú ọmọ ènìyàn láti san èrè
iṣẹ́ rẹ̀ fún un, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀
    àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.”

11 Bí àparò tó pa ẹyin tí kò yé ni
    ọmọ ènìyàn tí ó kó ọrọ̀ jọ ni
ọ̀nà àìṣòdodo. Yóò di ẹni ìkọ̀sílẹ̀
    ní agbede-méjì ayé rẹ̀, àti ní
    òpin rẹ̀ yóò wá di aṣiwèrè.

12 Ìtẹ́ ògo; ibi gíga láti ìpilẹ̀ṣẹ̀
    ní ibi ilé mímọ́ wa.
13 Olúwa ìwọ ni ìrètí Israẹli;
    gbogbo àwọn tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ni ojú ó tì.
Àwọn tí ó padà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ
ni a ó kọ orúkọ wọn sínú ekuru,
    nítorí wọ́n ti kọ Olúwa,
    orísun omi ìyè sílẹ̀.

14 Wò mí sàn Olúwa, èmi yóò di ẹni ìwòsàn,
    gbà mí là, èmi yóò di ẹni ìgbàlà,
    nítorí ìwọ ni ìyìn mi.
15 Wọ́n sọ fún mi wí pé:
    “Níbo ni ọ̀rọ̀ Olúwa wà?
    Jẹ́ kí ó di ìmúṣẹ báyìí.”
    Ni Olúwa wí.
16 Èmi kò sá kúrò láti máa jẹ́ olùṣọ àgùntàn rẹ,
    ìwọ mọ̀ wí pé èmi kò kẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú.
Ohun tí ó jáde ní ètè mi jẹ́ èyí tí ó hàn sí ọ.
17 Má ṣe di ìbẹ̀rù fún mi,
    ìwọ ni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú.
18 Jẹ́ kí ojú ti àwọn ẹni tí ń lépa mi,
    ṣùgbọ́n pa mí mọ́ kúrò nínú ìtìjú,
jẹ́ kí wọn kí ó dààmú.
    Mú ọjọ́ ibi wá sórí wọn,
    fi ìparun ìlọ́po méjì pa wọ́n run.

Pípa ọjọ́ ìsinmi mọ́

19 Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi: “Lọ dúró ní ẹnu-ọ̀nà àwọn ènìyàn níbi tí àwọn ọba Juda ń gbà wọlé tí wọ́n ń gbà jáde àti ní gbogbo ẹnu-bodè Jerusalẹmu. 20 Sọ fún wọ́n pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọba Juda àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé ní Jerusalẹmu tí ń wọlé láti ẹnu ibodè yìí. 21 Báyìí ni Olúwa wí: Ẹ kíyèsi láti máa ru ẹrù lọ́jọ́ ìsinmi tàbí kí ẹ gbé wọlé láti ẹnu ibodè Jerusalẹmu. 22 Má ṣe gbé ẹrù jáde kúrò nínú ilé yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ṣùgbọ́n kí ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ fún àwọn baba ńlá yín. 23 Síbẹ̀ wọn kò gbọ́ tàbí tẹ́tí sílẹ̀, wọ́n jẹ́ ọlọ́rùn líle; wọn kì í fẹ́ gbọ́ tàbí gba ìbáwí. 24 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kíyèsi láti gbọ́ tèmi ní Olúwa wí, tí ẹ kò sì gbe ẹrù gba ẹnu-bodè ìlú ní ọjọ́ ìsinmi, ṣùgbọ́n tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi, sí mímọ́, nípa pé ẹ kò ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà. 25 Nígbà náà ni ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi yóò gba ẹnu ibodè wọlé pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn àti ìjòyè wọn yóò gun ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá, àwọn ọkùnrin Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu yóò tẹ̀lé wọn; ìlú yìí yóò sì di ibi gbígbé títí láéláé. 26 Àwọn ènìyàn yóò wá láti ìlú Juda àti ní agbègbè Jerusalẹmu, láti ilẹ̀ Benjamini, láti pẹ̀tẹ́lẹ̀, àti láti òkè, àti láti gúúsù wá, wọn yóò wá pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, àti ọrẹ ẹran, àti tùràrí, àti àwọn tó mú ìyìn wá sí ilé Olúwa. 27 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá pa òfin mi mọ́ láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, kí ẹ má sì ṣe ru ẹrùkẹ́rù bí ẹ̀yin yóò ṣe máa gba ẹnu ibodè Jerusalẹmu wọlé ní ọjọ́ ìsinmi, nígbà náà ni èmi yóò da iná tí kò ní ṣe é parun ní ẹnu-bodè Jerusalẹmu tí yóò sì jó odi agbára rẹ̀.’ ”

17 “Judah’s sin is engraved with an iron tool,(A)
    inscribed with a flint point,
on the tablets of their hearts(B)
    and on the horns(C) of their altars.
Even their children remember
    their altars and Asherah poles[a](D)
beside the spreading trees
    and on the high hills.(E)
My mountain in the land
    and your[b] wealth and all your treasures
I will give away as plunder,(F)
    together with your high places,(G)
    because of sin throughout your country.(H)
Through your own fault you will lose
    the inheritance(I) I gave you.
I will enslave you to your enemies(J)
    in a land(K) you do not know,
for you have kindled my anger,
    and it will burn(L) forever.”

This is what the Lord says:

“Cursed is the one who trusts in man,(M)
    who draws strength from mere flesh
    and whose heart turns away from the Lord.(N)
That person will be like a bush in the wastelands;
    they will not see prosperity when it comes.
They will dwell in the parched places(O) of the desert,
    in a salt(P) land where no one lives.

“But blessed(Q) is the one who trusts(R) in the Lord,
    whose confidence is in him.
They will be like a tree planted by the water
    that sends out its roots by the stream.(S)
It does not fear when heat comes;
    its leaves are always green.
It has no worries in a year of drought(T)
    and never fails to bear fruit.”(U)

The heart(V) is deceitful above all things
    and beyond cure.
    Who can understand it?

10 “I the Lord search the heart(W)
    and examine the mind,(X)
to reward(Y) each person according to their conduct,
    according to what their deeds deserve.”(Z)

11 Like a partridge that hatches eggs it did not lay
    are those who gain riches by unjust means.
When their lives are half gone, their riches will desert them,
    and in the end they will prove to be fools.(AA)

12 A glorious throne,(AB) exalted from the beginning,
    is the place of our sanctuary.
13 Lord, you are the hope(AC) of Israel;
    all who forsake(AD) you will be put to shame.
Those who turn away from you will be written in the dust(AE)
    because they have forsaken the Lord,
    the spring of living water.(AF)

14 Heal me, Lord, and I will be healed;(AG)
    save(AH) me and I will be saved,
    for you are the one I praise.(AI)
15 They keep saying to me,
    “Where is the word of the Lord?
    Let it now be fulfilled!”(AJ)
16 I have not run away from being your shepherd;
    you know I have not desired the day of despair.
    What passes my lips(AK) is open before you.
17 Do not be a terror(AL) to me;
    you are my refuge(AM) in the day of disaster.(AN)
18 Let my persecutors be put to shame,
    but keep me from shame;
let them be terrified,
    but keep me from terror.
Bring on them the day of disaster;
    destroy them with double destruction.(AO)

Keeping the Sabbath Day Holy

19 This is what the Lord said to me: “Go and stand at the Gate of the People,[c] through which the kings of Judah go in and out; stand also at all the other gates of Jerusalem.(AP) 20 Say to them, ‘Hear the word of the Lord, you kings of Judah and all people of Judah and everyone living in Jerusalem(AQ) who come through these gates.(AR) 21 This is what the Lord says: Be careful not to carry a load on the Sabbath(AS) day or bring it through the gates of Jerusalem. 22 Do not bring a load out of your houses or do any work on the Sabbath, but keep the Sabbath day holy, as I commanded your ancestors.(AT) 23 Yet they did not listen or pay attention;(AU) they were stiff-necked(AV) and would not listen or respond to discipline.(AW) 24 But if you are careful to obey me, declares the Lord, and bring no load through the gates of this city on the Sabbath, but keep the Sabbath day holy(AX) by not doing any work on it, 25 then kings who sit on David’s throne(AY) will come through the gates of this city with their officials. They and their officials will come riding in chariots and on horses, accompanied by the men of Judah and those living in Jerusalem, and this city will be inhabited forever.(AZ) 26 People will come from the towns of Judah and the villages around Jerusalem, from the territory of Benjamin and the western foothills, from the hill country and the Negev,(BA) bringing burnt offerings and sacrifices, grain offerings and incense, and bringing thank offerings to the house of the Lord. 27 But if you do not obey(BB) me to keep the Sabbath(BC) day holy by not carrying any load as you come through the gates of Jerusalem on the Sabbath day, then I will kindle an unquenchable fire(BD) in the gates of Jerusalem that will consume her fortresses.’”(BE)

Footnotes

  1. Jeremiah 17:2 That is, wooden symbols of the goddess Asherah
  2. Jeremiah 17:3 Or hills / and the mountains of the land. / Your
  3. Jeremiah 17:19 Or Army