Add parallel Print Page Options

33 Olúwa sọ fún Mose pé, “Fi ìhín yìí sílẹ̀, ìwọ àti àwọn ènìyàn tí o mú gòkè láti Ejibiti wá, kí ẹ sì gòkè lọ sí ilẹ̀ tí èmi ti pinnu ní ìbúra fún Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú-ọmọ rẹ.’ Èmi yóò rán angẹli ṣáájú yín, èmi yóò sì lé àwọn Kenaani, àwọn ará Amori, àwọn ará Hiti, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi jáde. (A)Ẹ gòkè lọ sí ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin. Ṣùgbọ́n èmi kò ní lọ pẹ̀lú yín, nítorí ènìyàn ọlọ́rùn líle ni ẹ̀yin, kí èmi má ba à run yín ní ọ̀nà.”

Nígbà tí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ọ̀rọ̀ ìparun wọ̀nyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì ní kùn, ẹnìkankan kò sì le è wọ ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀. Nítorí Olúwa ti wí fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ènìyàn ọlọ́rùn líle ní ẹ̀yin, bí èmi bá lè wá sí àárín yín ni ìṣẹ́jú kan, èmi lè pa yín run. Ní ṣinṣin yìí, bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ rẹ kúrò, èmi yóò sì gbèrò ohun tí èmi yóò ṣe pẹ̀lú rẹ.’ ” Bẹ́ẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò lára wọn ní òkè Horebu.

Àgọ́ àjọ

Mose máa ń gbé àgọ́ náà, ó sì pa á sí ìta ibùdó, ó jìnnà díẹ̀ sí ibùdó, ó pè é ni “Àgọ́ àjọ.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń béèrè Olúwa yóò lọ sí ibi àgọ́ àjọ náà ní ìta ibùdó. Nígbàkúgbà tí Mose bá jáde lọ sí ibi àgọ́, gbogbo ènìyàn á dìde, wọ́n á sì dúró sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ wọn, wọn yóò máa wo Mose títí yóò fi wọ inú àgọ́ náà. Bí Mose ṣe wọ inú àgọ́ náà, ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀ yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì dúró sí ẹnu ọnà, nígbà tí Olúwa ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Mose. 10 Nígbàkígbà tí àwọn ènìyàn bá rí i ti ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀ bá dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, gbogbo wọn yóò dìde wọn yóò sì sìn, olúkúlùkù ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ rẹ̀. 11 (B)Olúwa máa ń bá Mose sọ̀rọ̀ lójúkojú, gẹ́gẹ́ bí i pé ènìyàn ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nígbà náà ni Mose yóò tún padà lọ sí ibùdó, ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọkùnrin Joṣua ìránṣẹ́ rẹ̀ ọmọ Nuni kò fi àgọ́ sílẹ̀.

Mose àti ògo Olúwa

12 Mose sọ fún Olúwa pé, “Ìwọ ti ń sọ fún mi, ‘Darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,’ ṣùgbọ́n ìwọ kò jẹ́ kí ń mọ ẹni tí ìwọ yóò rán pẹ̀lú mi. Ìwọ ti wí pé, ‘Èmi mọ̀ ọ́n nípa orúkọ, ìwọ sì ti rí ojúrere mi pẹ̀lú.’ 13 Bí ìwọ bá ní inú dídùn pẹ̀lú mi, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, kí èmi kí ó lè mọ̀ ọ́n, kí n sì le máa wá ojúrere rẹ pẹ̀lú. Rántí wí pé orílẹ̀-èdè yìí ènìyàn rẹ ni.”

14 Olúwa dáhùn wí pé, “Ojú mi yóò máa bá ọ lọ, èmi yóò sì fún ọ ní ìsinmi.”

15 Nígbà náà ni, Mose wí fún un pé, “Bí ojú rẹ kò bá bá wa lọ, má ṣe rán wa gòkè láti ìhín lọ. 16 Báwo ni ẹnikẹ́ni yóò ṣe mọ̀ pé inú rẹ dùn pẹ̀lú mi àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ àyàfi ti o bá bá wa lọ? Kí ni yóò lè yà mí àti àwọn ènìyàn rẹ kúrò lára gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé?”

17 Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Èmi yóò ṣe ohun gbogbo tí ìwọ ti béèrè, nítorí inú mi dún sí o, èmi sì mọ̀ ọ́n nípa orúkọ rẹ̀.”

18 Mose sì wí pé “Nísinsin yìí fi ògo rẹ hàn mí.”

19 (C)Olúwa sì wí pé, “Èmi yóò sì mú gbogbo ìre mí kọjá níwájú rẹ, Èmi yóò sì pòkìkí orúkọ Olúwa níwájú rẹ. Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí èmi yóò ṣàánú fún, èmi yóò sì ṣoore-ọ̀fẹ́ fún ẹni tí èmi yóò ṣoore-ọ̀fẹ́ fún. 20 Ṣùgbọ́n,” ó wí pé, “Ìwọ kò le è rí ojú mi, nítorí kò sí ènìyàn kan tí ń rí mi, tí ó lè yè.”

21 Olúwa sì wí pé, “Ibìkan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀dọ̀ mi, níbi tí o ti lè dúró lórí àpáta. 22 Nígbà tí ògo mi bá kọjá, èmi yóò gbé ọ sínú pàlàpálá àpáta, èmi yóò sì bò ọ́ pẹ̀lú ọwọ́ mi títí èmi yóò fi rékọjá. 23 Nígbà tí èmi yóò mú ọwọ́ mi kúrò, ìwọ yóò sì rí ẹ̀yìn mi; ṣùgbọ́n ojú mi ni o kò ní rí.”

33 Then the Lord said to Moses, “Leave this place, you and the people you brought up out of Egypt, and go up to the land I promised on oath(A) to Abraham, Isaac and Jacob, saying, ‘I will give it to your descendants.’(B) I will send an angel(C) before you and drive out the Canaanites, Amorites, Hittites, Perizzites, Hivites and Jebusites.(D) Go up to the land flowing with milk and honey.(E) But I will not go with you, because you are a stiff-necked(F) people and I might destroy(G) you on the way.”

When the people heard these distressing words, they began to mourn(H) and no one put on any ornaments. For the Lord had said to Moses, “Tell the Israelites, ‘You are a stiff-necked people.(I) If I were to go with you even for a moment, I might destroy(J) you. Now take off your ornaments and I will decide what to do with you.’” So the Israelites stripped off their ornaments at Mount Horeb.(K)

The Tent of Meeting

Now Moses used to take a tent and pitch it outside the camp some distance away, calling it the “tent of meeting.”(L) Anyone inquiring(M) of the Lord would go to the tent of meeting outside the camp. And whenever Moses went out to the tent, all the people rose and stood at the entrances to their tents,(N) watching Moses until he entered the tent. As Moses went into the tent, the pillar of cloud(O) would come down and stay at the entrance, while the Lord spoke(P) with Moses. 10 Whenever the people saw the pillar of cloud standing at the entrance to the tent, they all stood and worshiped, each at the entrance to their tent.(Q) 11 The Lord would speak to Moses face to face,(R) as one speaks to a friend. Then Moses would return to the camp, but his young aide Joshua(S) son of Nun did not leave the tent.

Moses and the Glory of the Lord

12 Moses said to the Lord, “You have been telling me, ‘Lead these people,’(T) but you have not let me know whom you will send with me. You have said, ‘I know you by name(U) and you have found favor(V) with me.’ 13 If you are pleased with me, teach me your ways(W) so I may know you and continue to find favor with you. Remember that this nation is your people.”(X)

14 The Lord replied, “My Presence(Y) will go with you, and I will give you rest.”(Z)

15 Then Moses said to him, “If your Presence(AA) does not go with us, do not send us up from here. 16 How will anyone know that you are pleased with me and with your people unless you go with us?(AB) What else will distinguish me and your people from all the other people on the face of the earth?”(AC)

17 And the Lord said to Moses, “I will do the very thing you have asked,(AD) because I am pleased with you and I know you by name.”(AE)

18 Then Moses said, “Now show me your glory.”(AF)

19 And the Lord said, “I will cause all my goodness to pass(AG) in front of you, and I will proclaim my name,(AH) the Lord, in your presence. I will have mercy on whom I will have mercy, and I will have compassion on whom I will have compassion.(AI) 20 But,” he said, “you cannot see my face, for no one may see(AJ) me and live.”

21 Then the Lord said, “There is a place near me where you may stand on a rock. 22 When my glory passes by, I will put you in a cleft in the rock(AK) and cover you with my hand(AL) until I have passed by. 23 Then I will remove my hand and you will see my back; but my face must not be seen.”