Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
20 Kí Olúwa kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú;
kí orúkọ Ọlọ́run Jakọbu kí ó dáàbò bò ọ́.
2 Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́
kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá.
3 Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ rẹ
kí ó sì gba ẹbọ sísun rẹ. Sela
4 Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn rẹ
kí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ rẹ ṣẹ.
5 Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gun
àwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa.
Kí Ọlọ́run kí ó mú gbogbo ìbéèrè rẹ̀ ṣẹ.
6 Nísinsin yìí, èmi mọ̀ wí pé:
Olúwa pa ẹni ààmì òróró rẹ̀ mọ́.
Yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá
pẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
7 Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé kẹ̀kẹ́, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé ẹṣin,
ṣùgbọ́n àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa Ọlọ́run wa.
8 Wọ́n wólẹ̀, ní eékún, wọ́n sì ṣubú,
ṣùgbọ́n àwa dìde, a sì dúró ṣinṣin.
9 Olúwa, fi ìṣẹ́gun fún ọba!
Dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń kígbe pè!
Orin ìyìn kan
26 Ní ọjọ́ náà ni a ó kọ orin yìí ní ilẹ̀ Juda:
Àwa ní ìlú alágbára kan,
Ọlọ́run fi ìgbàlà ṣe
ògiri àti ààbò rẹ̀.
2 Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn
kí àwọn olódodo orílẹ̀-èdè kí ó lè wọlé,
orílẹ̀-èdè tí ó pa ìgbàgbọ́ mọ́.
3 Ìwọ yóò pa á mọ́ ní àlàáfíà pípé
ọkàn ẹni tí ó dúró ṣinṣin,
nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
4 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa títí láé,
nítorí Olúwa, Olúwa ni àpáta
ayérayé náà.
5 Ó sọ àwọn tí ó ń gbé ní òkè di onírẹ̀lẹ̀
ó rẹ ìlú agbéraga náà nílẹ̀;
ó sọ ọ́ di ilẹ̀ pẹrẹsẹ
ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.
6 Ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀
ẹsẹ̀ aninilára n nì,
ipasẹ̀ àwọn òtòṣì.
7 Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́jú
Ìwọ tó dúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nà
àwọn olódodo ṣe geere.
8 Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, rírìn ní ọ̀nà òfin rẹ
àwa dúró dè ọ́;
orúkọ rẹ àti òkìkí rẹ
àwọn ni ohun tí ọkàn wa ń fẹ́.
9 Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru;
ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ.
Nígbà tí ìdájọ́ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayé
àwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo.
16 Nítorí èyí ni àárẹ̀ kò ṣe mú wa; ṣùgbọ́n bí ọkùnrin ti òde wa bá ń parun, síbẹ̀ ọkùnrin tí inú wa ń di tuntun lójoojúmọ́. 17 Nítorí ìpọ́njú díẹ̀ yìí ń pèsè ògo tí ó ní ìwọ̀n ayérayé tí ó pọ̀ rékọjá sílẹ̀ fún wa. 18 Níwọ́n bí kò ti wo ohun tí a ń rí, bí kò ṣé ohun tí a kò rí; nítorí ohun tí a ń rí ni ti ìgbà ìsinsin yìí; ṣùgbọ́n ohun tí a kò rí ni ti ayérayé.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.