Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì ti Májẹ̀mú.” Ti Safu. Saamu.
80 Gbọ́ tiwa, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn Israẹli;
ìwọ tí ó darí Josẹfu bí ọ̀wọ́ ẹran;
ìwọ tí o jókòó lórí ìtẹ́ láàrín Kérúbù, tàn jáde
2 Níwájú Efraimu, Benjamini àti Manase.
Ru agbára rẹ̀ sókè;
wá fún ìgbàlà wa.
3 Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run;
jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,
kí a bá à lè gbà wá là.
4 Olúwa Ọlọ́run alágbára,
ìbínú rẹ̀ yóò ti pẹ́ tó
sí àdúrà àwọn ènìyàn rẹ?
5 Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn
ìwọ ti mú wọn wa ẹkún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́
6 Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa,
àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá.
7 Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára;
jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa,
kí a ba à lè gbà wá là.
17 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára ọkùnrin tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,
ọmọ ènìyàn tí ìwọ tí gbé kalẹ̀ fún ara rẹ.
18 Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ;
mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ rẹ.
19 Tún wa yípadà, Olúwa Ọlọ́run alágbára;
kí ojú rẹ̀ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,
kí á ba à lè gbà wá là.
Àdúrà Dafidi
18 Dafidi ọba sì wọlé lọ, ó sì dúró níwájú Olúwa, ó sì wí pé:
“Olúwa Olódùmarè, ta ni èmi, àti kí sì ni ìdílé mi, tí ìwọ fi mú mi di ìsinsin yìí? 19 Nǹkan kékeré ni èyí sá à jásí lójú rẹ, Olúwa Olódùmarè; ìwọ sì ti sọ nípa ìdílé ìránṣẹ́ rẹ pẹ̀lú ní ti àkókò tí o jìnnà. Èyí ha ṣe ìwà ènìyàn bí, Olúwa Olódùmarè?
20 “Àti kín ní ó tún kù tí Dafidi ìbá tún máa wí fún ọ? Ìwọ, Olúwa Olódùmarè mọ̀ ìránṣẹ́ rẹ. 21 Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ, ni ìwọ ṣe ṣe gbogbo nǹkan ńlá wọ̀nyí, kí ìránṣẹ́ rẹ lè mọ̀.
22 “Ìwọ sì tóbi, Olúwa Olódùmarè! Kò sì sí ẹni tí ó dàbí rẹ, kò sì sí Ọlọ́run kan lẹ́yìn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí àwa fi etí wá gbọ́.
4 Ǹjẹ́ ohun tí mo ń wí ni pé, níwọ̀n ìgbà tí àrólé náà bá wà ní èwe, kò yàtọ̀ nínú ohunkóhun sí ẹrú bí ó tilẹ̀ jẹ́ Olúwa ohun gbogbo. 2 Ṣùgbọ́n ó wà lábẹ́ olùtọ́jú àti ìríjú títí àkókò tí baba ti yàn tẹ́lẹ̀. 3 (A)Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwa, nígbà tí àwa wà ní èwe, àwa wà nínú ìdè lábẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. 4 Ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kíkún náà dé, Ọlọ́run rán ọmọ rẹ̀ jáde wá, ẹni tí a bí nínú obìnrin tí a bí lábẹ́ òfin. 5 Láti ra àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin padà, kí àwa lè gba ìsọdọmọ, 6 (B)Àti nítorí tí ẹ̀yin jẹ́ ọmọ, Ọlọ́run sì ti rán Ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ wá sínú ọkàn yín, tí ń ké pé, “Ábbà, Baba.” 7 Nítorí náà ìwọ kì í ṣe ẹrú, bí kò ṣe ọmọ; àti bí ìwọ bá ń ṣe ọmọ, ǹjẹ́ ìwọ di àrólé Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.