Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
ÌWÉ KEJÌ
Saamu 42–72
Fún adarí orin. Maskili ti àwọn ọmọ Kora.
42 Bí àgbọ̀nrín ti ń mí hẹlẹ sí ipa odò omi,
bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń mí hẹlẹ sí ọ Ọlọ́run.
2 Òùngbẹ Ọlọ́run ń gbẹ ọkàn mi, fún Ọlọ́run alààyè.
Nígbà wo ni èmi ó lọ bá Ọlọ́run?
3 Oúnjẹ mi ni omijé mi
ní ọ̀sán àti ní òru,
nígbà tí àwọn ènìyàn ń wí fún mi ní gbogbo ọjọ́ pé,
“Ọlọ́run rẹ dà?”
4 Nígbà tí mo bá rántí nǹkan yìí,
èmi tú ọkàn mi jáde nínú mi:
èmi ti bá ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn lọ,
èmi bá wọn lọ sí ilé Ọlọ́run
pẹ̀lú ohùn ayọ̀ àti ìyìn,
pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pa ọjọ́ mímọ́ mọ́.
5 Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?
Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?
Ìwọ ṣe ìrètí ní ti Ọlọ́run,
nítorí èmi yóò sá à máa yìn ín,
Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
6 Ọlọ́run mi, ọkàn mi ń rẹ̀wẹ̀sì nínú mi:
nítorí náà, èmi ó rántí rẹ
láti ilẹ̀ Jordani wá,
láti Hermoni láti òkè Mibsari.
7 Ibú omi ń pe ibú omi
nípa híhó omi ṣíṣàn rẹ̀
gbogbo rírú omi àti bíbì omi rẹ̀
bò mí mọ́lẹ̀.
8 Ní ọ̀sán ní Olúwa ran ìfẹ́ rẹ̀,
àti ni àṣálẹ́ ni orin rẹ̀ wà pẹ̀lú mi
àdúrà sí Ọlọ́run ayé mi.
9 Èmi wí fún Ọlọ́run àpáta mi,
“Èéṣe tí ìwọ fi gbàgbé mi?
Èéṣe tí èmi o fi máa rìn nínú ìbànújẹ́,
nítorí ìnilára ọ̀tá?”
10 Bí ẹni pé idà egungun mi ni ẹ̀gàn tí
àwọn ọ̀tá mi ń gàn mí,
Bí wọn ti ń béèrè ní gbogbo ọjọ́.
“Níbo ni Ọlọ́run rẹ wà?”
11 Èéṣe tí ìwọ fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?
Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?
Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,
nítorí èmi yóò sì máa yìn ín, Òun ni
Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
17 Ní àìpẹ́ jọjọ, ǹjẹ́
a kò ní sọ Lebanoni di pápá ẹlẹ́tù lójú
àti pápá ẹlẹ́tù lójú yóò dàbí aginjù?
18 (A)Ní ọjọ́ náà adití yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwé kíká náà,
láti inú fìrífìrí àti òkùnkùn
ni àwọn ojú afọ́jú yóò ríran.
19 Lẹ́ẹ̀kan sí i àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóò yọ̀ nínú Olúwa:
àwọn aláìní yóò yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.
20 Aláìláàánú yóò pòórá,
àwọn tí ń ṣẹlẹ́yà yóò di àwátì,
gbogbo àwọn tí ó ní ojú ibi ni a ó ké lulẹ̀—
21 àwọn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ kan mú ẹnìkan di ẹlẹ́bi,
ẹni tí ń dẹkùn mú olùgbèjà ní ilé ẹjọ́
tí ẹ fi ẹ̀rí èké dun aláìṣẹ̀ ní ìdájọ́.
22 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa, ẹni tí ó ra Abrahamu padà sọ sí ilé Jakọbu:
“Ojú kì yóò ti Jakọbu mọ́;
ojú wọn kì yóò sì rẹ̀wẹ̀sì mọ́.
23 Nígbà tí wọ́n bá rí i láàrín àwọn ọmọ wọn,
àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi,
wọn yóò ya orúkọ mi sí mímọ́,
wọn yóò tẹ́wọ́gbà mímọ́ Ẹni Mímọ́ Jakọbu
wọn yóò dìde dúró ní ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Israẹli.
24 Gbogbo àwọn tí ń rìn ségesège ní yóò jèrè ìmọ̀;
gbogbo àwọn tí ń ṣe àròyé yóò gba ìtọ́sọ́nà.”
Àwọn aposteli wo ọ̀pọ̀ sàn
12 A sì ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu púpọ̀ láàrín àwọn ènìyàn. Gbogbo wọn sì fi ọkàn kan wà ní ìloro Solomoni. 13 Kò sí nínú àwọn ìyókù tí ó jẹ́ gbìyànjú láti darapọ̀ mọ́ wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń fi ọ̀wọ̀ gíga fún wọn. 14 Ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀, a sì ń yan àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó gba Olúwa gbọ́ kún iye wọn sí i. 15 Tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń gbé àwọn abirùn jáde sí òpópónà, tí wọn ń tẹ́ wọn sí orí ibùsùn àti àkéte kí òjìji Peteru ba à le gba orí ẹlòmíràn nínú wọn bí ó bá ti ń kọjá lọ. 16 Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú tí ó yí Jerusalẹmu ká, wọn ń mú àwọn abirùn wá àti àwọn tí ara kan fún ẹ̀mí àìmọ́; a sì mu olúkúlùkù wọn ní ara dá.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.