Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 21

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

21 Háà! Olúwa, ọba yóò yọ̀ nínú agbára rẹ,
    àti ní ìgbàlà rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó!

Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún un,
    bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu rẹ̀. Sela.
Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nà
    ìwọ fi adé wúrà dé e ní orí.
Ó béèrè fún ìyè, ìwọ sì fi fún un,
    àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé.
Ògo rẹ̀ pọ̀ nípasẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún un;
    ìwọ sì jẹ́ kí iyì ọláńlá rẹ̀ wà lára rẹ.
Dájúdájú, ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún un:
    ìwọ sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u rẹ̀.
Ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa;
    nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọ̀gá-ògo tí kì í kùnà
    kì yóò sípò padà.

Ọwọ́ rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀tá a rẹ rí;
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò wá àwọn tí o kórìíra rẹ rí.
Nígbà tí ìwọ bá yọ
    ìwọ yóò mú wọn dàbí iná ìléru.
Olúwa yóò gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀,
    àti pé iná rẹ̀ yóò jó wọn run.
10 Ìwọ yóò pa ìrandíran wọn run kúrò lórí ilẹ̀,
    àti irú-ọmọ wọn kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.
11 Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n ro èrò ibi sí ọ
    wọ́n sì ń pète ìwà ìkà, wọn kì yóò ṣe àṣeyọrí.
12 Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padà
    nígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà.

13 Gbígbéga ni ọ́ Olúwa, nínú agbára rẹ;
    a ó kọrin, a ó yín agbára a rẹ̀.

Gẹnẹsisi 15:1-18

Májẹ̀mú Ọlọ́run pẹ̀lú Abramu

15 Lẹ́yìn èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Abramu wá lójú ìran pé:

“Abramu má ṣe bẹ̀rù,
    Èmi ni ààbò rẹ,
    Èmi sì ni èrè ńlá rẹ.”

Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “Olúwa Olódùmarè, kí ni ìwọ yóò fi fún mi níwọ̀n ìgbà tí èmi kò bímọ, Elieseri ará Damasku ni yóò sì jogún mi,” Abramu sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ìwọ kò fún mi ní ọmọ, nítorí náà ẹrú nínú ilé mi sì ni yóò jẹ́ àrólé mi.”

(A)Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ ọ́ wá pé: “Ọkùnrin yìí kọ́ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ bí kò ṣe ọmọ tí ìwọ bí fúnrarẹ̀ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ.” (B)Olúwa sì mú Abramu jáde sí ìta ó sì wí fún un pé, “Gbé ojú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀ bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n.” Ó sì wí fun un pé, “Nítorí náà, báyìí ni irú-ọmọ rẹ yóò rí.”

(C)Abramu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.

Ó sì tún wí fún un pé, “Èmi ni Olúwa tí ó mú ọ jáde láti Uri ti Kaldea láti fún ọ ní ilẹ̀ yìí láti jogún.”

Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “Olúwa Olódùmarè, báwo ni mo ṣe lè mọ̀ pé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ ohun ìní mi?”

Nítorí náà, Olúwa wí fún un pé, “Mú abo màlúù, ewúrẹ́ àti àgbò ọlọ́dún mẹ́ta mẹ́ta wá, àti àdàbà kan àti ọmọ ẹyẹlé kan.”

10 Abramu sì mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, ó sì là wọ́n sí méjì méjì, ó sì fi ẹ̀là èkínní kọjú sí èkejì, ṣùgbọ́n kò la àwọn ẹyẹ ní tiwọn. 11 Àwọn ẹyẹ igún sì ń wá sórí òkú ẹran náà, Abramu sì ń lé wọn.

12 (D)Bí oòrùn ti ń wọ̀, Abramu sùn lọ fọnfọn, òkùnkùn biribiri tí ó kún fún ẹ̀rù sì bò ó. 13 (E)(F)Nígbà náà ni Olúwa wí fún Abramu pé, “Mọ èyí dájú pé, irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì, wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irínwó ọdún (400). 14 Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóò máa sìn, ni èmi ó dá lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà ni wọn ó sì jáde pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀. 15 Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ àwọn baba rẹ lọ ni àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò sì di arúgbó kí a tó gbé ọ sin. 16 Ní ìran kẹrin àwọn ìran rẹ yóò padà wá sí ibi. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Amori kò ì tí ì kún òṣùwọ̀n.”

17 Nígbà tí oòrùn wọ̀ tí ilẹ̀ sì ṣú, ìkòkò iná tí ń ṣèéfín àti ọwọ́ iná sì ń kọjá láàrín ẹ̀là ẹran náà. 18 (G)Ní ọjọ́ náà gan an ni Olúwa dá májẹ̀mú pẹ̀lú Abramu, ó sì wí pé, “Àwọn ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ejibiti dé odò ńlá Eufurate:

Matiu 12:33-37

33 (A)“E sọ igi di rere, èso rẹ̀ a sì di rere tàbí kí ẹ sọ igi di búburú, èso rẹ a sì di búburú, nítorí nípa èso igi ni a ó fi mọ̀ igi. 34 Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀, báwo ni ẹ̀yin tí ẹ jẹ búburú ṣe lè sọ̀rọ̀ rere? Ọkàn ènìyàn ni ó ń darí irú ọ̀rọ̀ tí ó lè jáde lẹ́nu rẹ̀. 35 Ẹni rere láti inú yàrá ìṣúra rere ọkàn rẹ̀ ní mú ohun rere jáde wá: àti ẹni búburú láti inú ìṣúra búburú ni; mu ohun búburú jáde wá. 36 Ṣùgbọ́n, mo sọ èyí fún yín, ẹ̀yin yóò jíyìn gbogbo ìsọkúsọ yín ní ọjọ́ ìdájọ́. 37 Nítorí nípa ọ̀rọ̀ ẹnu yín ni a fi dá yin láre, nípa ọ̀rọ̀ ẹnu yín sì ni a ó fi dá yin lẹ́bi.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.