Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 21

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

21 Háà! Olúwa, ọba yóò yọ̀ nínú agbára rẹ,
    àti ní ìgbàlà rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó!

Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún un,
    bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu rẹ̀. Sela.
Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nà
    ìwọ fi adé wúrà dé e ní orí.
Ó béèrè fún ìyè, ìwọ sì fi fún un,
    àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé.
Ògo rẹ̀ pọ̀ nípasẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún un;
    ìwọ sì jẹ́ kí iyì ọláńlá rẹ̀ wà lára rẹ.
Dájúdájú, ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún un:
    ìwọ sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u rẹ̀.
Ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa;
    nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọ̀gá-ògo tí kì í kùnà
    kì yóò sípò padà.

Ọwọ́ rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀tá a rẹ rí;
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò wá àwọn tí o kórìíra rẹ rí.
Nígbà tí ìwọ bá yọ
    ìwọ yóò mú wọn dàbí iná ìléru.
Olúwa yóò gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀,
    àti pé iná rẹ̀ yóò jó wọn run.
10 Ìwọ yóò pa ìrandíran wọn run kúrò lórí ilẹ̀,
    àti irú-ọmọ wọn kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.
11 Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n ro èrò ibi sí ọ
    wọ́n sì ń pète ìwà ìkà, wọn kì yóò ṣe àṣeyọrí.
12 Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padà
    nígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà.

13 Gbígbéga ni ọ́ Olúwa, nínú agbára rẹ;
    a ó kọrin, a ó yín agbára a rẹ̀.

Isaiah 41:14-20

14 Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu kòkòrò,
    ìwọ Israẹli kékeré,
nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,”
    ni Olúwa wí,
    olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.
15 “Kíyèsi, Èmi yóò sọ ọ́ di òòlù ìpakà tuntun,
    tí ó mú ti eyín rẹ̀ mú, ìwọ yóò lu àwọn òkè ńlá,
ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú,
    a ó sì sọ òkè kékeré di ìyàngbò.
16 Ìwọ yóò fẹ́ wọn, afẹ́fẹ́ yóò sì gbá wọn mú,
    àti ẹ̀fúùfù yóò sì fẹ́ wọn dànù
Ṣùgbọ́n ìwọ yóò yọ̀ nínú Olúwa
    ìwọ yóò sì ṣògo nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.

17 “Àwọn tálákà àti aláìní wá omi,
    ṣùgbọ́n kò sí;
ahọ́n wọn gbẹ fún òǹgbẹ.
    Ṣùgbọ́n Èmi Olúwa yóò dá wọn lóhùn;
    Èmi, Ọlọ́run Israẹli, kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
18 Èmi yóò mú kí odò kí ó sàn ní ibi gíga
àti orísun omi ní àárín Àfonífojì.
    Èmi yóò sọ aṣálẹ̀ di adágún omi,
    àti ilẹ̀ tí ó gbẹ gidigidi di orísun omi.
19 Èmi yóò fi sínú aṣálẹ̀
    igi kedari àti kasia, maritili àti olifi.
Èmi yóò gbin junifa sí inú aginjù,
    igi firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀
20 tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn yóò fi rí i tí wọn yóò sì fi mọ̀,
    kí wọn ṣàkíyèsí kí ó sì yé wọn,
pé ọwọ́ Olúwa ni ó ti ṣe èyí,
    àti pé Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ti dá èyí.

Romu 15:14-21

Paulu wàásù sí àwọn Kèfèrí

14 Ẹ̀yin ará, èmi gan alára ti ní ìdánilójú, pé ẹ̀yin pàápàá kún fún oore, a sì fi gbogbo ìmọ̀ kún un yín, ẹ̀yin sì jáfáfá láti máa kọ́ ara yín. 15 Síbẹ̀ mo ti fi ìgboyà kọ̀wé sí yín lórí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ kan, bí ẹni ti ń rán yín létí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ náà, nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run 16 (A)láti jẹ́ ìránṣẹ́ Kristi Jesu láàrín àwọn Kèfèrí láti polongo ìhìnrere Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ojúṣe àlùfáà, kí àwọn Kèfèrí lè jẹ́ ẹbọ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run, èyí tí a ti fi Ẹ̀mí mímọ́ yà sí mímọ́.

17 Nítorí náà, mo ní ìṣògo nínú Kristi Jesu nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi fún Ọlọ́run. 18 (B)Èmi kò sá à gbọdọ̀ sọ ohun kan bí kò ṣe èyí tí Kristi ti ọwọ́ mi ṣe, ní títọ́ àwọn Kèfèrí ṣọ́nà láti ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe mi: 19 (C)nípa agbára iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu, nípa agbára Ẹ̀mí Ọlọ́run, tó bẹ́ẹ̀ láti Jerusalẹmu àti yíkákiri, àní títí fi dé Illirikoni, mo ti polongo ìhìnrere Kristi ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 20 (D)Ó jẹ́ èrò mi ní gbogbo ìgbà láti wàásù ìhìnrere Kristi ní ibi gbogbo tí wọn kò tí ì mọ̀ ọ́n, kí èmi kí ó má ṣe máa mọ àmọlé lórí ìpìlẹ̀ ẹlòmíràn. 21 (E)Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Àwọn ẹni tí a kò tí ì sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún yóò rí i,
    àti àwọn tí kò tí ì gbọ́, òye yóò sì yé.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.