Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
21 Háà! Olúwa, ọba yóò yọ̀ nínú agbára rẹ,
àti ní ìgbàlà rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó!
2 Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún un,
bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu rẹ̀. Sela.
3 Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nà
ìwọ fi adé wúrà dé e ní orí.
4 Ó béèrè fún ìyè, ìwọ sì fi fún un,
àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé.
5 Ògo rẹ̀ pọ̀ nípasẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún un;
ìwọ sì jẹ́ kí iyì ọláńlá rẹ̀ wà lára rẹ.
6 Dájúdájú, ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún un:
ìwọ sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u rẹ̀.
7 Ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa;
nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọ̀gá-ògo tí kì í kùnà
kì yóò sípò padà.
8 Ọwọ́ rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀tá a rẹ rí;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò wá àwọn tí o kórìíra rẹ rí.
9 Nígbà tí ìwọ bá yọ
ìwọ yóò mú wọn dàbí iná ìléru.
Olúwa yóò gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀,
àti pé iná rẹ̀ yóò jó wọn run.
10 Ìwọ yóò pa ìrandíran wọn run kúrò lórí ilẹ̀,
àti irú-ọmọ wọn kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.
11 Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n ro èrò ibi sí ọ
wọ́n sì ń pète ìwà ìkà, wọn kì yóò ṣe àṣeyọrí.
12 Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padà
nígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà.
13 Gbígbéga ni ọ́ Olúwa, nínú agbára rẹ;
a ó kọrin, a ó yín agbára a rẹ̀.
Ìparun Olúwa lórí ilẹ̀ ayé
24 Kíyèsi i, Olúwa yóò sọ ohun
gbogbo dòfo ní ilẹ̀ ayé
yóò sì pa á run
òun yóò pa ojú u rẹ̀ rẹ́
yóò sì fọ́n àwọn olùgbé ibẹ̀ káàkiri—
2 bákan náà ni yóò sì rí
fún àlùfáà àti àwọn ènìyàn,
fún ọ̀gá àti ọmọ ọ̀dọ̀,
fún ìyá-ilé àti ọmọbìnrin,
fún olùtà àti olùrà,
fún ayáni àti atọrọ
fún ayánilówó àti onígbèsè.
3 Ilé ayé ni a ó sọ di ahoro pátápátá
a ó sì jẹ gbogbo rẹ̀ run.
Olúwa ni ó ti sọ ọ̀rọ̀ yìí.
4 Ilẹ̀ ayé ti gbẹ ó sì sá,
ayé ń ṣòjòjò, àárẹ̀ mú un,
àwọn ẹni gíga ilẹ̀ ayé wà nínú ìpọ́njú
5 àwọn ènìyàn ayé ti bà á jẹ́;
wọ́n ti pa àwọn òfin run
wọ́n ṣe lòdì sí àwọn ìlànà
wọ́n sì ti ba májẹ̀mú ayérayé jẹ́.
6 Nítorí náà, ègún kan ti jẹ ayé run;
àwọn ènìyàn rẹ̀ ní láti ru ẹ̀bi wọn.
Nítorí náà, àwọn olùgbé ayé ti gbiná dànù,
àwọn ẹ̀tàhóró ló sì kù.
7 Wáìnì tuntun ti gbẹ, àjàrà sì ti rọ,
gbogbo àwọn aláríyá sì kérora.
8 (A)Àríyá ti ṣaworo ti dákẹ́
ariwo àwọn tí ń ṣàjọyọ̀ ti dáwọ́ dúró
ayọ̀ dùùrù ti dákẹ́ jẹ́ẹ́.
9 Kò ṣe é ṣe fún wọn láti máa mu wáìnì pẹ̀lú orin kíkọ mọ́
ọtí líle ti di ìkorò fún àwọn ọ̀mu.
10 Ìlú tí a run ti dahoro,
ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé kọ̀ọ̀kan ni a dí pa.
11 Ní òpópónà ni wọ́n ti ń kígbe fún wáìnì
gbogbo ayọ̀ ọ wọn ti di ìbànújẹ́,
gbogbo àríyá ni a lé kúrò lórí ilẹ̀ ayé.
12 Ìlú ni a ti fi sílẹ̀ ní ahoro,
ìlẹ̀kùn rẹ̀ ni a sì tì pa bámú bámú.
13 Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí ní orí ilẹ̀ ayé
àti láàrín àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú,
gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a lu igi olifi,
tàbí gẹ́gẹ́ bí i pàǹtí tí ó ṣẹ́kù lẹ́yìn
tí a kórè èso tán.
14 Wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì hó fún ayọ̀;
láti ìwọ̀-oòrùn ni wọn yóò ti polongo
ọláńlá Olúwa.
15 Nítorí náà ní ìlà-oòrùn ẹ fi ògo fún Olúwa;
gbé orúkọ Olúwa ga, àní
Ọlọ́run Israẹli,
ní àwọn erékùṣù ti inú Òkun,
16 Láti òpin ayé wá ni a ti gbọ́ orin;
“Ògo ni fún olódodo n nì.”
Ṣùgbọ́n mo wí pé, “Mo ṣègbé, mo ṣègbé!
“Ègbé ni fún mi!
Alárékérekè dalẹ̀!
Pẹ̀lú ìhàlẹ̀ ni àgàbàgebè fi dalẹ̀!”
Gbígbé ìgbé ayé tó wu Ọlọ́run
4 Ní ìparí, ará, a sọ fún un yín bí ẹ ti ń gbé láti wu Ọlọ́run, àní gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí ń ṣe. Nísinsin yìí, a béèrè, a sì ń rọ̀ yín nínú Jesu Olúwa láti ṣe bẹ́ẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ sí. 2 Nítorí pé, ẹ̀yin mọ àṣẹ tí a pa fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa Jesu.
3 (A)Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí ẹ jẹ́ mímọ́, kí ẹ sì yàgò kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè, 4 (B)kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín kọ́ láti ṣàkóso ara rẹ̀ ní ọ̀nà mímọ́ àti pẹ̀lú ọlá, 5 kì í ṣe ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà, ẹni tí kò mọ Ọlọ́run; 6 àti pé nínú ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹnikẹ́ni nínú yín máa ṣe rẹ arákùnrin rẹ̀ jẹ nípa ohunkóhun. Olúwa yóò jẹ àwọn ènìyàn ní yà fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bí a ti ń sọ fún un yín tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. 7 Nítorí Ọlọ́run kò pè wá sínú ìwà èérí, bí kò ṣe sínú ìgbé ayé mímọ́. 8 Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó kọ òfin yìí, kì í ṣe òfin ènìyàn ni ẹni náà kọ̀, bí kò ṣe òfin Ọlọ́run ẹni tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ fún ni.
9 Ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ará, a kò ní láti tún kọ̀wé sí i yín, ìdí ni pé, Ọlọ́run pàápàá ń kọ́ yín láti fẹ́ràn ara yín. 10 Nítòótọ́, ẹ ní ìfẹ́ fún àwọn arákùnrin tí ó wà káàkiri Makedonia. Síbẹ̀síbẹ̀ àwa ń bẹ̀ yín, ará, pé kí ẹ̀yin kí ó máa tẹ̀síwájú nínú rẹ̀. 11 (C)Ẹ jẹ́ kí èyí jẹ́ ìfẹ́ ọkàn yín láti gbé jẹ́ẹ́ àti láti mọ ti ara yín àti kí olúkúlùkù kọjú sí iṣẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti wí fún yín. 12 Èyí yóò mú kí àwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ gbẹ́kẹ̀lé yín àti láti bu ọlá fún yín pẹ̀lú. Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ kò ní máa wo ojú ẹnikẹ́ni láti fún yín ni owó tí ẹ ó fi san gbèsè.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.