Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Ti Solomoni
72 Fi ìdájọ́ fún àwọn ọba, Ọlọ́run,
ọmọ-aládé ni ìwọ fi òdodo rẹ fún
2 Yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú òdodo,
yóò sì máa fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà rẹ̀.
3 Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyàn
àti òkè kéékèèkéé nípa òdodo
4 Yóò dáàbò bo àwọn tí a pọ́n lójú láàrín àwọn ènìyàn
yóò gba àwọn ọmọ aláìní;
yóò sì fa àwọn aninilára ya.
5 Àwọn òtòṣì àti aláìní
yóò máa fi ọ̀wọ̀ ńlá fún ọ nígbà gbogbo,
níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá ń ràn,
yóò ti pẹ́ tó, láti ìrandíran.
6 Yóò dàbí òjò tí ó ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀
Bí ọwọ́ òjò tó ń rin ilẹ̀
7 Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀ ni ọjọ́ rẹ̀
ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà yóò sì wà;
títí tí òṣùpá kò fi ní sí mọ́.
18 Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli,
ẹnìkan ṣoṣo tí ó ń ṣe ohun ìyanu.
19 Olùbùkún ni orúkọ rẹ̀ tí ó lógo títí láé;
kí gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.
Àmín àti Àmín.
Ìtùnú fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run
40 Ẹ tù ú nínú, ẹ tu ènìyàn mi nínú,
ni Ọlọ́run yín wí.
2 Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jerusalẹmu
kí o sì kéde fún un
pé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí,
pé à ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,
pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ Olúwa
ìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
3 (A)Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù:
“Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,
ṣe òpópó tí ó tọ́ ní aginjù fún Ọlọ́run wa.
4 (B)Gbogbo Àfonífojì ni a ó gbé sókè,
gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀;
wíwọ́ ni a ó sọ di títọ́ àti
ọ̀nà pálapàla ni a óò sọ di títẹ́jú pẹrẹsẹ,
5 Ògo Olúwa yóò sì di mí mọ̀
gbogbo ènìyàn lápapọ̀ ni yóò sì rí i.
Nítorí ẹnu Olúwa ni ó ti sọ ọ́.”
6 (C)Ohùn kan wí pé, “Kígbe sókè.”
Èmi sì sọ pé, “Igbe kí ni èmi ó ké?”
“Gbogbo ènìyàn dàbí i koríko,
àti gbogbo ògo wọn dàbí ìtànná igbó.
7 Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,
nítorí èémí Olúwa ń fẹ́ lù wọ́n.
Nítòótọ́ koríko ni àwọn ènìyàn.
8 Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,
ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.”
9 (D)Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Sioni,
lọ sí orí òkè gíga.
Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jerusalẹmu,
gbé ohùn rẹ sókè pẹ̀lú ariwo,
gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù;
sọ fún àwọn ìlú u Juda,
“Ọlọ́run rẹ nìyìí!”
10 (E)Wò ó, Olúwa Olódùmarè náà ń bọ̀ wá pẹ̀lú agbára,
apá rẹ̀ sì ń jẹ ọba fún un.
Wò ó, èrè rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀,
àti ìdápadà rẹ̀ tí ń bá a bọ̀ wá.
11 Ó ń tọ́ àwọn agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn:
Ó kó àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ní apá rẹ̀.
Ó sì gbé wọn súnmọ́ oókan àyà rẹ̀;
ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ darí àwọn tí ó ní.
Johanu sọ pé òun kì í ṣe Kristi
19 (A)Èyí sì ni ẹ̀rí Johanu, nígbà tí àwọn Júù rán àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi láti Jerusalẹmu wá láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ẹni tí òun ń ṣe. 20 (B)Òun kò sì kùnà láti jẹ́wọ́, ṣùgbọ́n òun jẹ́wọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ pé, “Èmi kì í ṣe Kristi náà.”
21 (C)Wọ́n sì bi í léèrè pé, “Ta ha ni ìwọ? Elijah ni ìwọ bí?”
Ó sì wí pé, “Èmi kọ́.”
“Ìwọ ni wòlíì náà bí?”
Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.”
22 Ní ìparí wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ í ṣe? Fún wa ní ìdáhùn kí àwa kí ó lè mú èsì padà tọ àwọn tí ó rán wa wá lọ. Kí ni ìwọ wí nípa ti ara rẹ?”
23 (D)Johanu sì fi ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah fún wọn ní èsì pé, “Èmi ni ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ ṣe ọ̀nà Olúwa ní títọ́.’ ”
24 Ọ̀kan nínú àwọn Farisi tí a rán 25 bi í léèrè pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń bamitiisi nígbà náà, bí ìwọ kì í bá ṣe Kristi, tàbí Elijah, tàbí wòlíì náà?”
26 (E)Johanu dá wọn lóhùn, wí pé, “Èmi ń fi omi bamitiisi: ẹnìkan dúró láàrín yín, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀; 27 Òun náà ni ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹni tí èmi kò tó láti tú.”
28 Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣẹlẹ̀ ní Betani ní òdìkejì odò Jordani, níbi tí Johanu ti ń fi omi bamitiisi.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.