Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.
122 Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé
Ẹ jẹ́ kí á lọ sílé Olúwa.
2 Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè rẹ,
ìwọ Jerusalẹmu.
3 Jerusalẹmu, ìwọ tí a kọ́ bí ìlú
tí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan
4 Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ,
àwọn ẹ̀yà Olúwa,
ẹ̀rí fún Israẹli, láti
máa dúpẹ́ fún orúkọ Olúwa.
5 Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀,
àwọn ìtẹ́ ilé Dafidi.
6 Gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalẹmu;
àwọn tí ó fẹ́ ọ yóò ṣe rere.
7 Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi rẹ̀,
àti ìre nínú ààfin rẹ̀.
8 Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mi
èmi yóò wí nísinsin yìí pé,
kí àlàáfíà kí ó wà nínú rẹ̀;
9 Nítorí ilé Olúwa Ọlọ́run wa,
èmi yóò máa wá ìre rẹ̀.
15 “Ní ìsinsin yìí, Olúwa Ọlọ́run wa, ẹni tí ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá, pẹ̀lú ọwọ́ agbára, tí ó fún ara rẹ̀ ní orúkọ tí ó wà títí di òní, a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búburú. 16 Olúwa, ní ìbámu pẹ̀lú ìwà òdodo rẹ, yí ìbínú àti ìrunú rẹ padà kúrò ní Jerusalẹmu ìlú u rẹ, òkè mímọ́ rẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àìṣedéédéé àwọn baba wa ti mú Jerusalẹmu àti ènìyàn rẹ di ẹ̀gàn fún gbogbo àwọn tí ó yí wọn ká.
17 “Nísinsin yìí, Ọlọ́run wa, gbọ́ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ, nítorí i tìrẹ Olúwa, fi ojú àánú wo ibi mímọ́ rẹ tí ó ti dahoro. 18 Tẹ́ etí rẹ sílẹ̀, Ọlọ́run, kí o gbọ́; ya ojú rẹ sílẹ̀, kí o sì wo ìdahoro ìlú tí a ń fi orúkọ rẹ pè. Àwa kò gbé ẹ̀bẹ̀ wa kalẹ̀ níwájú u rẹ nítorí pé a jẹ́ olódodo, bí kò ṣe nítorí àánú ńlá rẹ. 19 Olúwa, fetísílẹ̀! Olúwa, Dáríjì! Olúwa, gbọ́ kí o sì ṣe é! Nítorí i tìrẹ, Ọlọ́run mi, má ṣe pẹ́ títí, nítorí ìlú rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ ń jẹ́ orúkọ mọ́ ọ lára.”
Ìyọ̀ǹda ara ẹni fún Ọlọ́run
4 Níbo ni ogun ti wá, níbo ni ìjà sì ti wá láàrín yín? Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín ha kọ́ ni tí ó ń jagun nínú àwọn ẹ̀yà ara yín bí? 2 Ẹ̀yin ń fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ẹ kò sì ní: ẹ̀yin ń pànìyàn, ẹ sì ń ṣe ìlara, ẹ kò sì le ní: ẹ̀yin ń jà, ẹ̀yin sì ń jagun; ẹ kò ní, nítorí tí ẹ̀yin kò béèrè. 3 Ẹ̀yin béèrè, ẹ kò sì rí gbà, nítorí tí ẹ̀yin ṣì béèrè, kí ẹ̀yin kí ó lè lò ó fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín.
4 Ẹ̀yin panṣágà ọkùnrin, àti panṣágà obìnrin, ẹ kò mọ̀ pé ìbárẹ́ ayé ìṣọ̀tá Ọlọ́run ni? Nítorí náà ẹni tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé di ọ̀tá Ọlọ́run. 5 Ẹ̀yin ṣe bí Ìwé mímọ́ sọ lásán pé, Ẹ̀mí tí ó fi sínú wa ń jowú gidigidi lórí wa? 6 (A)Ṣùgbọ́n ó fún ni ní oore-ọ̀fẹ́ sí i. Nítorí náà ni ìwé mímọ́ ṣe wí pé,
“Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga,
ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn.”
7 Nítorí náà, ẹ tẹríba fún Ọlọ́run. Ẹ kọ ojú ìjà sí èṣù, òun ó sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín. 8 Ẹ súnmọ́ Ọlọ́run, òun ó sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀; ẹ sì ṣe ọkàn yín ní mímọ́, ẹ̀yin oníyèméjì. 9 Ẹ banújẹ́, ẹ ṣọ̀fọ̀, kí ẹ sì hu fún ẹkún. Ẹ jẹ́ kí ẹ̀rín yín kí ó di ọ̀fọ̀, àti ayọ̀ yín kí ó di ìbànújẹ́. 10 Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Olúwa, òun ó sì gbé yín ga.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.