Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
117 (A)Ẹ yin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè;
ẹ pòkìkí rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn.
2 Nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó ní sí wa,
àti òtítọ́ Olúwa dúró láéláé.
Ẹ yin Olúwa!
31 “Nígbà náà, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo ìdílé ìran Israẹli, àwọn náà yóò sì jẹ́ ènìyàn mi,” ni Olúwa wí.
2 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Àwọn ènìyàn tí ó sá àsálà lọ́wọ́ idà
yóò rí ojúrere Olúwa ní aṣálẹ̀,
Èmi yóò sì fi ìsinmi fún Israẹli.”
3 Olúwa ti fi ara rẹ̀ hàn wá ní ìgbà kan rí, ó wí pé:
“Èmi ti nífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin;
mo ti fi ìfẹ́ ńlá fà yín,
4 Èmi yóò tún gbé e yín sókè,
àní a ó tún gbé e yín ró ìwọ wúńdíá ilẹ̀ Israẹli.
Àní ẹ ó tún tún ohun èlò orin yín gbé,
ẹ ó sì jáde síta pẹ̀lú ijó àti ayọ̀.
5 Ẹ ó tún gbin ọgbà àjàrà
ní orí òkè Samaria;
àwọn àgbẹ̀ yóò sì máa
gbádùn èso oko wọn.
6 Ọjọ́ kan máa wà tí àwọn olùṣọ́ yóò kígbe jáde
lórí òkè Efraimu wí pé,
‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí Sioni,
ní ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa.’ ”
1 Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó ti dáwọ́lé títo àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì jọ lẹ́sẹẹsẹ, èyí tí ó ti múlẹ̀ ṣinṣin láàrín wa, 2 (A)àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó ṣe ojú wọn láti ìbẹ̀rẹ̀ ti fi lé wa lọ́wọ́. 3 (B)Nítorí náà, ó sì yẹ fún èmi pẹ̀lú, láti kọ̀wé sí ọ lẹ́sẹẹsẹ bí mo ti wádìí ohun gbogbo fínní fínní sí láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, Teofilu ọlọ́lá jùlọ, 4 (C)kí ìwọ kí ó le mọ òtítọ́ ohun wọ̀n-ọn-nì, tí a ti kọ́ ọ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.