Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jeremiah 23:1-6

Ẹ̀ka òtítọ́

23 “Ègbé ni fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn tí ń tú agbo ẹran mi ká tí ó sì ń pa wọ́n run!” ni Olúwa wí. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ ní ti àwọn olùṣọ́-àgùntàn tí ń darí àwọn ènìyàn mi: “Nítorí tí ẹ̀yin tú agbo ẹran mi ká, tí ẹ lé wọn dànù tí ẹ̀yin kò sì bẹ̀ wọ́n wò. Èmi yóò jẹ yín ní yà nítorí nǹkan búburú tí ẹ ti ṣe,” ni Olúwa wí. “Èmi Olúwa tìkára mi yóò kó ìyókù agbo ẹran mi jọ láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo ti lé wọn, Èmi yóò mú wọn padà sínú pápá oko wọn, níbẹ̀ ni wọn ó ti bí sí i, tí wọn ó sì pọ̀ sí i. Èmi ó wá olùṣọ́-àgùntàn fún wọn, tí yóò darí wọn, wọn kì yóò bẹ̀rù tàbí dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan kì yóò sọnù,” ni Olúwa wí.

(A)“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí,
    “tí Èmi yóò gbé ẹ̀ka òdodo dìde fún Dafidi,
ọba tí yóò lo ìjọba pẹ̀lú ọgbọ́n
    tí yóò sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ lórí ilẹ̀ náà.
Ní ọjọ́ rẹ̀ ni a ó gba Juda là,
    Israẹli yóò sì máa gbé ní aláìléwu
Èyí ni orúkọ tí a ó fi máa pè é:
    Olúwa Òdodo wa.

Luku 1:68-79

68 “Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli;
    nítorí tí ó ti bojú wò, tí ó sì ti dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè,
69 Ó sì ti gbé ìwo ìgbàlà sókè fún wa
    ní ilé Dafidi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀;
70 (bí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tipẹ́tipẹ́),
71 Pé, a ó gbà wá là lọ́wọ́
    àwọn ọ̀tá wa àti lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wá.
72 Láti ṣe àánú tí ó ṣèlérí fún àwọn baba wa,
    àti láti rántí májẹ̀mú rẹ̀ mímọ́,
73 ìbúra tí ó ti bú fún Abrahamu baba wa,
74 láti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,
    kí àwa kí ó lè máa sìn láìfòyà,
75     ni ìwà mímọ́ àti ní òdodo níwájú rẹ̀, ní ọjọ́ ayé wa gbogbo.

76 (A)“Àti ìwọ, ọmọ mi, wòlíì Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó máa pè ọ́:
    nítorí ìwọ ni yóò ṣáájú Olúwa láti tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe;
77 (B)láti fi ìmọ̀ ìgbàlà fún àwọn ènìyàn rẹ̀
    fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
78 (C)nítorí ìyọ́nú Ọlọ́run wà;
    nípa èyí tí ìlà-oòrùn láti òkè wá bojú wò wá,
79 (D)Láti fi ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó jókòó ní
    òkùnkùn àti ní òjìji ikú,
àti láti fi ẹsẹ̀ wa lé ọ̀nà àlàáfíà.”

Kolose 1:11-20

11 pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀síwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀. 12 Kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo lọ́wọ́ Baba, ẹni tí ó kà yín láti jẹ́ alábápín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́ nínú ìjọba ìmọ́lẹ̀. 13 (A)Nítorí tí ó ti já wa gbà kúrò nínú agbára òkùnkùn ó sì mú wa wá sí ìjọba Ọmọ tí ó fẹ́ràn. 14 Nínú ẹni tí a ní ìràpadà, àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.

Títóbi Kristi

15 (B)Kristi ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò le rí, àkọ́bí gbogbo ẹ̀dá. 16 Nítorí nípa rẹ̀ ní a dá ohun gbogbo: àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti ní ayé, ohun tí a rí àti èyí tí a kò rí, wọn ìbá ṣe ìtẹ́, tàbí agbára, tàbí àṣẹ, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo àti fún un. 17 (C)Ó ti wà ṣáájú kí ohunkóhun tó wà, nínú rẹ̀ ni a sì so ohun gbogbo papọ̀ ṣọ̀kan. 18 (D)Òun ni orí fún ara, èyí tí í ṣe ìjọ; òun ni ìbẹ̀rẹ̀ àti àkọ́bí nínú àwọn òkú, pé nínú ohun gbogbo kí òun lè ní ipò tí ó ga jùlọ nínú ohunkóhun. 19 Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òun tìkára rẹ̀ lè máa gbé nínú rẹ̀. 20 Àti nípasẹ̀ rẹ̀ láti bá ohun gbogbo làjà àwọn nǹkan tí ń bẹ láyé àti èyí tí ń bẹ ní ọ̀run, nípa mímú àlàáfíà wá nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, tí a ta sílẹ̀ lórí igi àgbélébùú.

Luku 23:33-43

33 (A)Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí a ń pè ní Agbárí, níbẹ̀ ni wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn arúfin náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti ọ̀kan ní ọwọ́ òsì. 34 (B)Jesu sì wí pé, “Baba, dáríjì wọ́n; nítorí tí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” Wọ́n di ìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn.

35 (C)Àwọn ènìyàn sì dúró láti wòran. Àti àwọn ìjòyè pẹ̀lú wọn, wọ́n ń yọ ṣùtì sí i, wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kí ó gbara rẹ̀ là, bí ó bá ṣe Kristi, àyànfẹ́ Ọlọ́run.”

36 (D)Àti àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ń fi ọtí kíkan fún un. 37 Wọ́n sì ń wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe ọba àwọn Júù, gba ara rẹ là.”

38 Wọ́n sì kọ̀wé àkọlé sí ìgbèrí rẹ̀ ní èdè Giriki, àti ti Latin, àti tí Heberu pe:

èyí ni ọba àwọn júù.

39 Àti ọ̀kan nínú àwọn arúfin tí a gbé kọ́ ń fi ṣe ẹlẹ́yà wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Kristi, gba ara rẹ àti àwa náà là.”

40 Ṣùgbọ́n èyí èkejì dáhùn, ó ń bá a wí pé, “Ìwọ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ìwọ wà nínú ẹ̀bi kan náà? 41 (E)Ní tiwa, wọ́n jàre nítorí èrè ohun tí àwa ṣe ni à ń jẹ: ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí kò ṣe ohun búburú kan.”

42 Ó sì wí pé, “Jesu, rántí mi nígbà tí ìwọ bá dé ìjọba rẹ.”

43 (F)Jesu sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Lónìí ni ìwọ ó wà pẹ̀lú mi ní Paradise!”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.