Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Asafu. Orin.
76 Ní Juda ni a mọ Ọlọ́run;
orúkọ rẹ̀ sì lágbára ní Israẹli
2 Àgọ́ rẹ̀ wà ní Salẹmu,
ibùgbé rẹ̀ ni Sioni.
3 Níbẹ̀ ni ó ṣẹ́ ọfà,
asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun. Sela.
4 Ìwọ ni ògo àti ọlá
Ju òkè ńlá ìkógun wọ̀nyí lọ.
5 A kó àwọn alágídí ọkàn ní ìkógun
wọ́n sun oorun ìgbẹ̀yìn wọn;
kò sí ọ̀kan nínú àwọn akọni
tó lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.
6 Ní ìfibú rẹ, Ọlọ́run Jakọbu,
àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.
7 Ìwọ nìkan ni ó yẹ kí a bẹ̀rù.
Ta ló lé dúró níwájú rẹ, nígbà tí ìwọ bá ń bínú?
8 Ìwọ ń ṣe ìdájọ́ láti ọ̀run,
ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ẹ́:
9 Nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run,
bá dìde láti ṣe ìdájọ́,
láti gba àwọn ẹni ìnilára ilẹ̀ náà. Sela.
10 Lóòótọ́, ìbínú rẹ sí àwọn ènìyàn ń mú ìyìn wá fún ọ,
ẹni tí ó yọ nínú ìbínú rẹ ní a dá nígbà tí ìwọ bá fi ìbínú ìyókù di ara rẹ ni àmùrè.
11 Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì mú un ṣẹ;
kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká
mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí ó tọ́ láti bẹ̀rù.
12 Ó ké ẹ̀mí àwọn aládé kúrò;
àwọn ọba ayé sì ń bẹ̀rù rẹ̀.
17 Dípò idẹ, èmi ó mú wúrà wá fún ọ,
dípò fàdákà èmi ó mú irin wá. Dípò igi yóò mú idẹ wá fún ọ,
àti irin dípò òkúta.
Èmi yóò fi àlàáfíà ṣe àwọn ìjòyè rẹ
àti òdodo gẹ́gẹ́ bí alákòóso rẹ.
18 A kì yóò gbọ́ nípa rògbòdìyàn ní ilẹ̀ rẹ mọ́,
tàbí ìdahoro àti ìparun nínú agbègbè rẹ,
ṣùgbọ́n ìwọ yóò pe ògiri rẹ ní ìgbàlà
àti àwọn ẹnu-bodè rẹ ní ìyìn.
19 Òòrùn kì yóò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ní ọ̀sán mọ́,
tàbí kí ìtànṣán òṣùpá tún ràn sí ọ mọ́,
nítorí Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ayérayé,
àti Ọlọ́run rẹ yóò jẹ́ ògo rẹ.
20 Òòrùn rẹ kì yóò sì wọ̀ mọ́,
àti òṣùpá rẹ kì yóò sì wọ òòkùn mọ́;
Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé rẹ,
àti àwọn ọjọ́ arò rẹ yóò sì dópin.
21 Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn ènìyàn rẹ yóò di òdodo
àwọn ni yóò sì jogún ilẹ̀ náà títí ayé.
Àwọn ni irúgbìn tí mo ti gbìn,
iṣẹ́ ọwọ́ mi,
láti fi ọláńlá mi hàn.
22 Èyí tí ó kéré jù nínú yín yóò di ẹgbẹ̀rún kan,
èyí tí ó kéré yóò di orílẹ̀-èdè ńlá.
Èmi ni Olúwa;
ní àkókò rẹ̀ Èmi yóò ṣe èyí kánkán.”
25 (A)Nítorí náà ẹ fi èké ṣíṣe sílẹ̀, ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí ẹ̀yà ara ọmọnìkejì wa ni àwa jẹ́. 26 Nínú ìbínú yín, ẹ máa ṣe ṣẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá ìbínú yín: 27 Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi ààyè ẹ̀gbẹ́ kan fún Èṣù. 28 Kí ẹni tí ń jalè má ṣe jalè mọ́: ṣùgbọ́n kí ó kúkú máa ṣe làálàá, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ ohun tí ó dára, kí òun lè ní láti pín fún ẹni tí ó ṣe aláìní.
29 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìdíbàjẹ́ kan ti ẹnu yín jáde, ṣùgbọ́n irú èyí tí ó lè ràn ìdàgbàsókè wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n nílò, kí ó lè máa fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn tí ń gbọ́. 30 Ẹ má sì ṣe mú Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run bínú, ẹni tí a fi ṣe èdìdì yín dé ọjọ́ ìdáǹdè. 31 Gbogbo ìwà kíkorò àti ìbínú, àti ìrunú, àti ariwo, àti ọ̀rọ̀ búburú ni kí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, pẹ̀lú gbogbo àrankàn: 32 Ẹ máa ṣoore fún ọmọnìkejì yín, ẹ ní ìyọ́nú, ẹ máa dáríjì ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run nínú Kristi ti dáríjì yín. 5 1 Nítorí náà, ẹ máa ṣe àfarawé Ọlọ́run bí àwọn olùfẹ́ ọmọ, 2 (B)ẹ sì máa rìn ní ìfẹ́, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti fẹ́ wa, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún wa ní ọrẹ àti ẹbọ fún Ọlọ́run fún òórùn dídùn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.