Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 65:17-25

Àwọn ọrun tuntun àti ayé tuntun

17 “Kíyèsi i, Èmi yóò dá
    àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun
A kì yóò rántí ohun àtẹ̀yìnwá mọ́,
    tàbí kí wọn wá sí ọkàn.
18 Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ kí inú yín dùn títí láé
    nínú ohun tí èmi yóò dá,
nítorí èmi yóò dá Jerusalẹmu láti jẹ́ ohun ìdùnnú
    àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ohun ayọ̀.
19 Èmi yóò ṣe àjọyọ̀ lórí Jerusalẹmu
    n ó sì ní inú dídùn nínú àwọn ènìyàn mi;
ariwo ẹkún àti igbe
    ni a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ mọ́.

20 “Títí láé a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀
    ọmọ ọwọ́ tí yóò gbé fún ọjọ́ díẹ̀,
tàbí àgbàlagbà tí kì yóò lo ọjọ́ ayé rẹ̀ tán;
    ẹni tí ó bá kú ní ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún
ni a ó pè ní ọ̀dọ́mọdé;
    ẹni tí kò ba le pé ọgọ́rùn-ún kan
    ni a ó pè ní ẹni ìfibú.
21 Wọn yó ò kọ́ ilé, wọn yóò sì gbé nínú wọn
    wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì jẹ èso wọn.
22 Wọn kì yóò kọ́ ilé fún ẹlòmíràn láti gbé,
    tàbí kí wọn gbìn fún ẹlòmíràn láti jẹ,
Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí igi kan,
    bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí;
àwọn àyànfẹ́ mi yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́
    wọn fún ìgbà pípẹ́.
23 Wọn kì yóò ṣe iṣẹ́ lásán,
    wọn kí yóò bímọ fún wàhálà;
    nítorí wọn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn ti Olúwa bùkún fún,
    àwọn àti àwọn ìrandíran wọn pẹ̀lú wọn.
24 Kí wọn tó pè, èmi yóò dáhùn;
    nígbà tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, èmi yóò gbọ́.
25 (A)Ìkookò àti ọ̀dọ́-àgùntàn yóò jẹun pọ̀,
    kìnnìún yóò sì jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù,
ṣùgbọ́n erùpẹ̀ ni yóò jẹ́ oúnjẹ ejò.
    Wọn kì yóò pa ni lára tàbí pa ni run
ní gbogbo òkè mímọ́ mi,”
    ni Olúwa wí.

Isaiah 12

Orin ìyìn

12 Ní ọjọ́ náà ni ìwọ ó wí pé:

“Èmi ó yìn ọ́, Olúwa.
    Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ò ti bínú sí mi
ìbínú rẹ ti yí kúrò níbẹ̀
ìwọ sì ti tù mí nínú.
Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi,
    èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù.
Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi,
    òun ti di ìgbàlà mi.”
Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omi
    láti inú kànga ìgbàlà.

Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé:

“Fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀,
    Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
ohun tí ó ti ṣe
    kí o sì kéde pé a ti gbé
    orúkọ rẹ̀ ga.
Kọ orin sí Olúwa, nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo,
    jẹ́ kí èyí di mí mọ̀ fún gbogbo ayé.
Kígbe sókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Sioni,
    nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kan ṣoṣo
    ti Israẹli láàrín yín.”

2 Tẹsalonika 3:6-13

Ìkìlọ̀ ní ṣíṣe ìmẹ́lẹ́

(A)Ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wa, àwa pàṣẹ fún un yín ará, pé kí ẹ yẹra fún gbogbo àwọn arákùnrin yín tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́, tí kò sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tí ẹ gbà ní ọ̀dọ̀ wa. (B)Nítorí ẹ̀yin náà mọ̀ bí ó ṣe yẹ kí ẹ máa fi ara wé wa. Àwa kì í ṣe ìmẹ́lẹ́ nígbà tí a wà ní ọ̀dọ̀ yín. (C)Bẹ́ẹ̀ ni àwa kò sì jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, àwa ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán tòru kí a má ba à di àjàgà sí ẹnikẹ́ni nínú yín lọ́rùn. (D)Àwa ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, kì í ṣe nítorí pé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti béèrè fún un, ṣùgbọ́n àwa ń fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ tí ẹ ó tẹ̀lé. 10 (E)Nítorí nígbà tí àwa wà lọ́dọ̀ yín, a ṣe àwọn òfin wọ̀nyí fún un yín pé, “Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.”

11 (F)A gbọ́ pé àwọn kan wà láàrín yín tí wọn jẹ́ ìmẹ́lẹ́. Wọ́n jẹ́ atọjúlékiri. 12 (G)Ǹjẹ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwa ń pàṣẹ fún, tí a sì ń rọ̀ nínú Jesu Kristi Olúwa pé kí wọn ó máa ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ. 13 (H)Ṣùgbọ́n ní tiyín ará, ẹ má ṣe jẹ́ kí agara dá yín ní rere ṣíṣe.

Luku 21:5-19

Àwọn ààmì ìkẹyìn ayé

(A)Bí àwọn kan sì ti ń sọ̀rọ̀ nípa tẹmpili, bí a ti fi òkúta dáradára àti ẹ̀bùn ṣe é ní ọ̀ṣọ́, fun Ọlọ́run, Jesu wí pé (B)“Ohun tí ẹ̀yin ń wò wọ̀nyí, ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”

(C)Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé, “Olùkọ́, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò rí bẹ́ẹ̀? Àti ààmì kín ni yóò wà, nígbà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ?”

(D)Ó sì wí pé, “Ẹ máa kíyèsára, kí a má bá à mú yín ṣìnà: nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ní orúkọ mi, tí yóò máa wí pé, ‘Èmi ní Kristi náà àkókò náà sì kù sí dẹ̀dẹ̀.’ Ẹ má ṣe tọ̀ wọ́n lẹ́yìn. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá gbúròó ogun àti ìdágìrì, ẹ má ṣe fòyà; nítorí nǹkan wọ̀nyí ní láti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀: ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe lójúkan náà.”

10 (E)Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba. 11 Ilẹ̀-rírì ńlá yóò sì wà káàkiri, àti ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn; ohun ẹ̀rù, àti ààmì ńlá yóò sì ti ọ̀run wá.

12 (F)(G) “Ṣùgbọ́n ṣáájú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọn ó nawọ́ mú yín, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí yín, wọn ó mú yín lọ sí Sinagọgu, àti sínú túbú, wọn ó mú yín lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba àti àwọn ìjòyè nítorí orúkọ mi. 13 (H)Ẹ o si jẹ́rìí nípa mi. 14 (I)Nítorí náà ẹ pinnu rẹ̀ ní ọkàn yín pé ẹ ko ronú ṣáájú, bí ẹ ó ti dáhùn. 15 Nítorí tí èmi ó fún yín ní ẹnu àti ọgbọ́n, tí gbogbo àwọn ọ̀tá yín kì yóò lè sọ̀rọ̀-òdì sí, tí wọn kì yóò sì lè kò lójú. 16 (J)A ó sì fi yín hàn láti ọwọ́ àwọn òbí yín wá, àti àwọn arákùnrin, àti àwọn ìbátan, àti àwọn ọ̀rẹ́; on ó sì mú kì a pa nínú yín. 17 (K)A ó sì kórìíra yín lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí orúkọ mi. 18 (L)Ṣùgbọ́n irun orí yín kan kì yóò ṣègbé. 19 (M)Nínú ìdúró ṣinṣin yín ni ẹ̀yin ó jèrè ọkàn yín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.