Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 12

Orin ìyìn

12 Ní ọjọ́ náà ni ìwọ ó wí pé:

“Èmi ó yìn ọ́, Olúwa.
    Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ò ti bínú sí mi
ìbínú rẹ ti yí kúrò níbẹ̀
ìwọ sì ti tù mí nínú.
Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi,
    èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù.
Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi,
    òun ti di ìgbàlà mi.”
Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omi
    láti inú kànga ìgbàlà.

Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé:

“Fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀,
    Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
ohun tí ó ti ṣe
    kí o sì kéde pé a ti gbé
    orúkọ rẹ̀ ga.
Kọ orin sí Olúwa, nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo,
    jẹ́ kí èyí di mí mọ̀ fún gbogbo ayé.
Kígbe sókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Sioni,
    nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kan ṣoṣo
    ti Israẹli láàrín yín.”

Isaiah 57:14-21

Ìtùnú fún àwọn oníròbìnújẹ́

14 A ó sì sọ wí pé:

“Tún mọ, tún mọ, tún ọ̀nà náà ṣe!
    Ẹ mú àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.”
15 (A)Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí
    ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́:
“Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́,
    ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀,
láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí
    àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí.
16 Èmi kì yóò fẹ̀sùn kan ni títí láé,
    tàbí kí n máa bínú sá á,
nítorí nígbà náà ni ọkàn ènìyàn yóò
    rẹ̀wẹ̀sì níwájú mi
    èémí ènìyàn tí mo ti dá.
17 Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúwà rẹ̀;
    mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojú mi pamọ́ ní ìbínú
    síbẹ̀, ó tẹ̀síwájú nínú tinú-mi-ni n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀.
18 Èmi ti rí ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ṣùgbọ́n Èmi yóò wò ó sàn;
    Èmi yóò tọ́ ọ ṣọ́nà n ó sì mú ìtùnú tọ̀ ọ́ wá,
19 (B)ní dídá ìyìn sí ètè àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli.
    Àlàáfíà, àlàáfíà fún àwọn tí ó wà lókèèrè àti nítòsí,”
    ni Olúwa wí, “Àti pé Èmi yóò wo wọ́n sàn.”
20 Ṣùgbọ́n àwọn ìkà dàbí i ríru Òkun
    tí kò le è sinmi,
    tí ìgbì rẹ̀ ń rú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ àti ẹrọ̀fọ̀ sókè.
21 “Kò sí àlàáfíà,” ni Ọlọ́run mi wí, “fún àwọn ìkà.”

Romu 1:18-25

Ìbínú Ọlọ́run sí orílẹ̀ ayé

18 (A)Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn. 19 Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn. 20 (B)Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀: bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí.

21 (C)Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; wọ́n ń ro èrò asán, ọkàn aṣiwèrè wọn sì ṣókùnkùn. 22 Níwọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀ pátápátá, 23 (D)wọ́n sì yí ògo Ọlọ́run tí kì í díbàjẹ́ sí àwọn àwòrán ère bí i ti ènìyàn tí í díbàjẹ́ àti ti ẹyẹ, àti ti ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti ti ẹranko afàyàfà.

24 Nítorí náà Ọlọ́run fà wọ́n lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun ìríra pẹ̀lú ara wọn èyí tí kò tọ́. 25 Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọ́run sí èké, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ láti máa sin ẹ̀dá dípò ẹlẹ́dàá—ẹni tí ìyìn tọ́ sí láéláé. Àmín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.