Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 145:1-5

Saamu ìyìn. Ti Dafidi.

145 Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi;
    Èmi yóò yin orúkọ rẹ̀ láé àti láéláé
Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́
    èmi yóò sì pòkìkí orúkọ rẹ láé àti láéláé.

Títóbi ni Olúwa. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀:
    kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi rẹ̀.
Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ rẹ dé ìran mìíràn;
    wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára rẹ
Wọn yóò máa sọ ìyìn ọláńlá rẹ tí ó lógo,
    èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu rẹ.

Saamu 145:17-21

17 Olúwa jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀
    àti ìfẹ́ rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá.
18 Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é,
    sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.
19 Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ṣẹ;
    ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n.
20 Olúwa dá gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ sẹ sí
    ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹni
    búburú ní yóò parun.

21 Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ìyìn Olúwa.
    Jẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá yín orúkọ rẹ̀ mímọ́ láé àti láéláé.

Hagai 1

Ìpè láti tún ilé Olúwa kọ́

Ní ọdún kejì ọba Dariusi ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹfà, ọ̀rọ̀ Olúwa wá nípasẹ̀ wòlíì Hagai sí Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, baálẹ̀ Juda, àti Sọ́dọ̀ Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà.

Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí pé, ‘Kò tí ì tó àkókò láti kọ́ ilé Olúwa.’ ”

Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa wá láti ọ̀dọ̀ wòlíì Hagai wí pé: “Ǹjẹ́ àkókò ni fún ẹ̀yin fúnrayín láti máa gbé ní ilé tí a ṣe ní ọ̀ṣọ́ nígbà tí ilé yìí wà ni ahoro?”

Ní ṣinṣin yìí, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín. Ẹ̀yin ti gbìn ohun ti ó pọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kórè díẹ̀ níbẹ̀; Ẹ̀yin jẹun, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yó. Ẹ̀yin mu ṣùgbọ́n kò tẹ́ ẹ yín lọ́run; ẹ̀yin wọ aṣọ, ṣùgbọ́n kò mú òtútù yin lọ; ẹyin gba owó iṣẹ́ ṣùgbọ́n ẹ ń gbà á sínú ajádìí àpò.”

Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín. Ẹ gun orí àwọn òkè ńlá lọ, kí ẹ sì mú igi wá pẹ̀lú yín. Kí ẹ sì kọ́ ilé náà, kí inú mi bà le è dùn sí i, kí a sì yín mí lógo,” ni Olúwa wí. “Ẹyin ti ń retí ọ̀pọ̀, ṣùgbọ́n kíyèsi i, o yípadà sí díẹ̀. Ohun tí ẹ̀yin mú wa ilé, èmi sì fẹ́ ẹ dànù. Nítorí kí ni?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Nítorí ilé mi tí ó dahoro; tí olúkúlùkù yín sì ń sáré fún ilé ara rẹ̀. 10 Nítorí yín ni àwọn ọ̀run ṣe dá ìrì dúró tí ilẹ̀ sì kọ̀ láti mu èso jáde. 11 Mo sì ti pe ọ̀dá sórí ilẹ̀ àti sórí àwọn òkè ńlá, sórí ọkà àti sórí wáìnì tuntun, sórí òróró àti sórí ohun ti ilẹ̀ ń mú jáde, sórí ènìyàn, sórí ẹran àti sórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín.”

12 Nígbà náà ni Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ìyókù, gba ohùn Olúwa Ọlọ́run wọn gbọ́ àti ọ̀rọ̀ wòlíì Hagai, nítorí Olúwa Ọlọ́run ni ó rán an. Àwọn ènìyàn sì bẹ̀rù Olúwa.

13 Nígbà náà ni Hagai ìránṣẹ́ Olúwa ń jíṣẹ́ Olúwa fún àwọn ènìyàn pé, “Èmí wà pẹ̀lú yín,” ni Olúwa wí. 14 Nítorí náà, Olúwa ru ẹ̀mí Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli sókè, baálẹ̀ Juda àti ẹ̀mí Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà àti ẹ̀mí gbogbo ènìyàn ìyókù. Wọ́n sì wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ lórí ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run wọn, 15 ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹfà ní ọdún kejì ọba Dariusi.

Luku 20:1-8

Wọ́n béèrè nípa àṣẹ Jesu

20 (A)Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tẹmpili tí ó sì ń wàásù ìhìnrere, àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà dìde sí i. (B)Wọ́n sì wí fún un pé, “Sọ fún wa, àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Tàbí ta ni ó fún ọ ní àṣẹ yìí?”

Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èmi pẹ̀lú yóò sì bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan; ẹ sì fi ìdáhùn fún mi. Ìtẹ̀bọmi Johanu, láti ọ̀run wá ni tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn?”

Wọ́n sì bá ara wọn gbèrò pé, “Bí àwa bá wí pé, ‘Láti ọ̀run wá ni,’ òun yóò wí pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?’ (C)Ṣùgbọ́n bí àwa bá sì wí pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn,’ gbogbo ènìyàn ni yóò sọ wá ní òkúta, nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé, wòlíì ni Johanu.”

Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa kò mọ̀ ibi tí ó ti wá.”

Jesu sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ èmi kì yóò wí fún yín àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.