Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Habakuku 1:1-4

Àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Habakuku rí.

Ìráhùn Habakuku

(A)Olúwa, èmi yóò ti ké pẹ́ tó fún ìrànlọ́wọ́,
    Ṣùgbọ́n ti ìwọ kò ni fetí sí mi?
Tàbí kígbe sí ọ ní ti, “Ìwà ipá!”
    ṣùgbọ́n tí ìwọ kò sì gbàlà?
Èéṣe tí ìwọ fi mú mi rí àìṣedéédéé
    Èéṣe tí ìwọ sì fi ààyè gba ìwà ìkà?
Ìparun àti ìwà ipá wà ní iwájú mi;
    ìjà ń bẹ, ìkọlù sì wà pẹ̀lú.
Nítorí náà, òfin di ohun àìkàsí,
    ìdájọ́ òdodo kò sì borí.
Àwọn ẹni búburú yí àwọn olódodo ká,
    Nítorí náà ni ìdájọ́ òdodo ṣe yí padà.

Habakuku 2:1-4

Ìdáhùn Ọlọ́run sí ìráhùn wòlíì Habakuku

(A)Èmi yóò dúró lórí ibusọ́ mi láti máa wòye
    Èmi yóò sì gbé ara mi ka orí alóre
Èmi yóò si ṣọ́ láti gbọ́ ohun tí yóò sọ fún mi
    àti èsì ti èmi yóò fún ẹ̀sùn yìí nígbà tó bá ń bá mi wí.

Ìdáhùn Olúwa

Nígbà náà ni Olúwa dáhùn pé:

“Kọ ìṣípayá náà sílẹ̀
    kí o sì fi hàn ketekete lórí wàláà
    kí ẹni tí ń kà á, lè máa sáré.
(B)Nítorí ìṣípayá náà jẹ́ tí ìgbà kan tí a múra sílẹ̀ dè;
    yóò máa yára sí ìgbẹ̀yìn
    kí yóò sìsọ èké.
Bí o tilẹ̀ lọ́ra, dúró dè é;
    nítorí, dájúdájú, yóò dé, kí yóò sí pẹ́.”

(C)“Kíyèsi, ọkàn rẹ tí ó gbéga;
    Ìfẹ́ rẹ̀ kò dúró ṣinṣin nínú rẹ̀,
    ṣùgbọ́n olódodo yóò wa nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.

Saamu 119:137-144

137 Olódodo ni ìwọ Olúwa
    ìdájọ́ rẹ sì dúró ṣinṣin
138 Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo:
    wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé.
139 Ìtara mi ti pa mí run,
    nítorí àwọn ọ̀tá mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ rẹ dá.
140 Wọ́n ti dán ìpinnu rẹ wò pátápátá
    ìránṣẹ́ rẹ sì fẹ́ràn wọ́n.
141 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gàn
    èmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ.
142 Òdodo rẹ wà títí láé
    òtítọ́ ni òfin rẹ̀.
143 Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi,
    ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ ni inú dídùn mi,
144 Òfin rẹ jẹ́ òtítọ́ láé;
    fún mi ní òye kí èmi lè yè.

2 Tẹsalonika 1:1-4

(A)Paulu, Sila àti Timotiu,

Sí ìjọ Tẹsalonika, nínú Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi Olúwa:

(B)Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Jesu Kristi Olúwa.

Àdúrà àti ìdúpẹ́

(C)Ó yẹ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ará, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, nítorí pé ìgbàgbọ́ yín ń dàgbà gidigidi, àti ìfẹ́ olúkúlùkù yín sí ara yín ń di púpọ̀. Nítorí náà, àwa tìkára wa ń fi yín ṣògo nínú ìjọ Ọlọ́run, nítorí sùúrù àti ìgbàgbọ́ yín nínú gbogbo inúnibíni àti wàhálà yín tí ẹ̀yin náà ń fi ara dà.

2 Tẹsalonika 1:11-12

11 (A)Nítorí èyí, àwa pẹ̀lú ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo, pé kí Ọlọ́run wa kí ó lè kà yín yẹ fún ìpè rẹ̀, àti pé nípa agbára rẹ̀, òun yóò mú gbogbo èrò rere yín ṣẹ àti gbogbo ohun tí ìgbàgbọ́ bá rú jáde. 12 Wọ̀nyí ni àdúrà wa, kí orúkọ Jesu Olúwa wa lè di yíyìn lógo nínú yín àti ẹ̀yin nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run àti ti Jesu Kristi Olúwa.

Luku 19:1-10

Sakeu agbowó òde

19 (A)Jesu sì wọ Jeriko lọ, ó sì ń kọjá láàrín rẹ̀. Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà tí a ń pè ní Sakeu, ó sì jẹ́ olórí agbowó òde kan, ó sì jẹ́ ọlọ́rọ̀. Ó sì ń fẹ́ láti rí ẹni tí Jesu jẹ́: kò sì lè rí i, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti nítorí tí òun jẹ́ ènìyàn kúkúrú. Ó sì súré síwájú, ó gun orí igi sikamore kan, kí ó bà lè rí i: nítorí tí yóò kọjá lọ níhà ibẹ̀.

Nígbà tí Jesu sì dé ibẹ̀, ó gbé ojú sókè, ó sì rí i, ó sì wí fún un pé, “Sakeu! Yára, kí o sì sọ̀kalẹ̀; nítorí pé èmi yóò wọ ilé rẹ lónìí.” Ó sì yára, ó sọ̀kalẹ̀, ó sì fi ayọ̀ gbà á.

(B)Nígbà tí wọ́n sì rí i, gbogbo wọn ń kùn, wí pé, “Ó lọ bá ọkùnrin ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ní àlejò.”

(C)Sakeu sì dìde, ó sì wí fún Olúwa pé, “Wò ó, Olúwa, ààbọ̀ ohun ìní mi ni mo fi fún tálákà; bí mo bá sì fi èké gba ohun kan lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, èmi san án padà ní ìlọ́po mẹ́rin!”

(D)Jesu sì wí fún un pé, “Lónìí ni ìgbàlà wọ ilé yìí, níwọ̀n bí òun pẹ̀lú ti jẹ́ ọmọ Abrahamu. 10 Nítorí Ọmọ Ènìyàn dé láti wá àwọn tí ó nù kiri, àti láti gbà wọ́n là.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.