Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
137 Olódodo ni ìwọ Olúwa
ìdájọ́ rẹ sì dúró ṣinṣin
138 Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo:
wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé.
139 Ìtara mi ti pa mí run,
nítorí àwọn ọ̀tá mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ rẹ dá.
140 Wọ́n ti dán ìpinnu rẹ wò pátápátá
ìránṣẹ́ rẹ sì fẹ́ràn wọ́n.
141 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gàn
èmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ.
142 Òdodo rẹ wà títí láé
òtítọ́ ni òfin rẹ̀.
143 Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi,
ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ ni inú dídùn mi,
144 Òfin rẹ jẹ́ òtítọ́ láé;
fún mi ní òye kí èmi lè yè.
5 Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú, nítorí tí ọtí wáìnì ni ẹ̀tàn,
agbéraga ènìyàn òun, kò sì ní sinmi
ẹni tí ó sọ ìwọra rẹ di gbígbòòrò bí isà òkú,
ó sì dàbí ikú, a kò sì le tẹ́ ẹ lọ́rùn,
ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí ọ̀dọ̀
ó sì gba gbogbo ènìyàn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.
6 “Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì yóò máa pa òwe sí i tí wọn yóò sì máa kọ orin òwe sí i wí pé,
“ ‘Ègbé ni fún ẹni tí ń mu ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ pọ̀ sí i!
Tí ó sì sọ ara rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ ìlọ́nilọ́wọ́gbà!
Eléyìí yóò ha ti pẹ́ tó?’
7 Ǹjẹ́ ẹni ti ó yọ ọ́ lẹ́nu, kí yóò ha dìde ní òjijì?
Àti àwọn tí ó wàhálà rẹ kì yóò jí, kí wọn ó sì dẹ́rùbà ọ́?
Nígbà náà ni ìwọ yóò wa dí ìkógun fún wọn.
8 Nítorí ìwọ ti kó orílẹ̀-èdè púpọ̀,
àwọn ènìyàn tókù yóò sì kó ọ
nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; nítorí ẹ̀jẹ̀
Ìwọ tí pa ilẹ̀ àti ìlú ńlá run
àti gbogbo ènìyàn to ń gbé inú rẹ̀.
9 “Ègbé ni fún ẹni tí ń jẹ èrè ìjẹkújẹ sí ilé rẹ̀,
tí o sí gbé ìtẹ́ rẹ̀ lórí ibi gíga,
kí a ba le gbà á sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ibi!
10 Ìwọ ti gbìmọ̀ ìtìjú sí ilé rẹ
nípa kíké ènìyàn púpọ̀ kúrò;
ìwọ sì ti pàdánù ẹ̀mí rẹ
11 Nítorí tí òkúta yóò kígbe jáde láti inú ògiri wá,
àti ìtí igi láti inú igi rírẹ́ wá yóò sì dá a lóhùn.
39 Wọ́n dáhùn, wọ́n sì wí fún un pé, “Abrahamu ni baba wa!”
Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìbá ṣe iṣẹ́ Abrahamu 40 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ̀yin ń wá ọ̀nà láti pa mí, ẹni tí ó sọ òtítọ́ fún yín, èyí tí mo ti gbọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run: Abrahamu kò ṣe èyí. 41 (A)Ẹ̀yin ń ṣe iṣẹ́ baba yín.”
Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “a kò bí wa nípa panṣágà: a ní Baba kan, èyí sì ni Ọlọ́run.”
Àwọn ọmọ èṣù
42 (B)Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá ṣe pé Ọlọ́run ni Baba yín, ẹ̀yin ìbá fẹ́ràn mi: nítorí tí èmi ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jáde, mo sì wá; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n òun ni ó rán mi. 43 Èéṣe tí èdè mi kò fi yé yín? Nítorí ẹ kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. 44 (C)Ti èṣù baba yin ni ẹ̀yin jẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ sì ń fẹ́ ṣe. Apànìyàn ni òun jẹ́ láti àtètèkọ́ṣe, kò sì dúró nínú òtítọ́; nítorí tí kò sí òtítọ́ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń ṣèké, nínú ohun tirẹ̀ ni ó ń sọ nítorí èké ni, àti baba èké. 45 Ṣùgbọ́n nítorí tí èmi ń sọ òtítọ́ fún yín, ẹ̀yin kò sì gbà mí gbọ́. 46 Ta ni nínú yín tí ó ti dá mi lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀? Bí mo bá ń ṣọ òtítọ́, èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà mí gbọ́? 47 Ẹni tí ń ṣe ti Ọlọ́run, a máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí èyí ni ẹ̀yin kò ṣe gbọ́, nítorí ẹ̀yin kì í ṣe ti Ọlọ́run.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.