Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 119:137-144

137 Olódodo ni ìwọ Olúwa
    ìdájọ́ rẹ sì dúró ṣinṣin
138 Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo:
    wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé.
139 Ìtara mi ti pa mí run,
    nítorí àwọn ọ̀tá mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ rẹ dá.
140 Wọ́n ti dán ìpinnu rẹ wò pátápátá
    ìránṣẹ́ rẹ sì fẹ́ràn wọ́n.
141 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gàn
    èmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ.
142 Òdodo rẹ wà títí láé
    òtítọ́ ni òfin rẹ̀.
143 Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi,
    ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ ni inú dídùn mi,
144 Òfin rẹ jẹ́ òtítọ́ láé;
    fún mi ní òye kí èmi lè yè.

Jeremiah 33:14-26

14 “ ‘Àwọn ọjọ́ náà ń bọ̀,’ ni Olúwa wí, ‘tí èmi ó mú ìlérí rere tí mo ṣe fún ilé Israẹli àti ilé Juda ṣẹ.

15 (A)‘Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àti ní àkókò náà,
    Èmi ó gbé olódodo dìde láti ẹ̀ka Dafidi.
    Yóò ṣe ìdájọ́ àti ohun tí ó tọ́ ní ilẹ̀ náà.
16 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Juda yóò di ẹni ìgbàlà.
    Jerusalẹmu yóò sì máa gbé láìséwu
Orúkọ yìí ni a ó máa pè é
    Olúwa wa olódodo.’

17 (B)Nítorí báyìí ni Olúwa wí: ‘Dafidi kò ní kùnà láti rí ọkùnrin tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ ní ilé Israẹli. 18 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà tí ó jẹ́ ọmọ Lefi kò ní kùnà láti ní ọkùnrin kan tí ó dúró níwájú mi ní gbogbo ìgbà láti rú ẹbọ sísun; ẹbọ jíjẹ àti láti pèsè ìrúbọ.’ ”

19 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá wí pé: 20 “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Tí ìwọ bá lè dá májẹ̀mú mi ní òru tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀sán àti òru kò lè sí ní àkókò wọn mọ́. 21 Nígbà náà ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú Dafidi ìránṣẹ́ mi àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú Lefi tí ó jẹ́ àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ níwájú mi lè bàjẹ́, tí Dafidi kò sì rí ẹni láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. 22 Èmi ó mú àwọn ọmọlẹ́yìn Dafidi ìránṣẹ́ mi àti Lefi tí ó jẹ́ oníwàásù níwájú mi di bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí kò ṣe é kà àti bí iyẹ̀pẹ̀ ojú Òkun tí kò ṣe é wọ́n.’ ”

23 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé: 24 “Ǹjẹ́ ìwọ kò kíyèsi pé àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń sọ pé: ‘Olúwa ti kọ àwọn ọba méjèèjì tí ó yàn sílẹ̀’? Nítorí náà, ni wọ́n ti ṣe kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi. Wọn kò sì mọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan. 25 Báyìí ni Olúwa wí: ‘Bí èmi kò bá ti da májẹ̀mú mi pẹ̀lú ọ̀sán àti òru àti pẹ̀lú òfin ọ̀run àti ayé tí kò lè yẹ̀. 26 Nígbà náà ni èmi ó kọ ọmọlẹ́yìn Jakọbu àti Dafidi ìránṣẹ́ mi tí èmi kò sì ní yan ọ̀kan nínú ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ́ alákòóso lórí àwọn ọmọ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu; nítorí èmi ó mú ìkólọ wọn padà; èmi ó sì ṣàánú fún wọn.’ ”

2 Kọrinti 1:1-11

(A)Paulu aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, àti Timotiu arákùnrin wá, sí ìjọ Ọlọ́run tí ó wà ní Kọrinti pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní gbogbo Akaia:

(B)Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Jesu Kristi Olúwa.

Ọlọ́run gbogbo ìtùnú

(C)Olùbùkún ni Ọlọ́run, àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ìyọ́nú, àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo; (D)Ẹni tí ń tù wá nínú ni gbogbo ìdààmú wa, ki àwa pẹ̀lú lè máa tu àwọn tí ó wá nínú ìdààmú nínú, nípá ìtùnú náà ti a fi ń tú àwa fúnra wa nínú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Nítorí pé bí àwa ti pín nínú ìjìyà Kristi, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ nì ìtùnú wa dí púpọ̀ pẹ̀lú nípa Kristi. Ṣùgbọ́n bí a bá sì ń pọ́n wa lójú, ó jẹ́ fún ìtùnú àti ìgbàlà yín; tàbí bi a bá ń tù wá nínú, ó jẹ́ fún ìtùnú yín ti ń ṣiṣẹ́ sùúrù láti mú yin ní irú ìfaradà ìyà kan náà ti àwa pẹ̀lú ń jẹ́. Àti pé ìrètí wa nípa tiyín dúró ṣinṣin, àwa si mọ̀ pé, bí ẹ̀yin ti jẹ alábápín nínú ìyà wa, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń pín nínú ìtùnú náà pẹ̀lú.

Arákùnrin àti arábìnrin, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè nípa wàhálà tí ó dé bá wa ní agbègbè Asia, ní ti pé a pọ́n wa lójú gidigidi rékọjá agbára ìfaradà wa, tó bẹ́ẹ̀ tí ìrètí kò tilẹ̀ sí fún ẹ̀mí wa mọ́. Nítòótọ́, nínú ọkàn wa a tilẹ̀ ní ìmọ̀lára wí pé a tí gba ìdálẹ́bi ikú, ṣùgbọ́n èyí farahàn láti má mú wa gbẹ́kẹ̀lé ara wa bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń jí òkú dìde: 10 Ẹni tí ó gbà wá kúrò nínú irú ikú tí ó tóbi bẹ́ẹ̀, yóò sí tún gbà wá; òun ní àwa gbẹ́kẹ̀lé pé yóò sí máa gbà wá síbẹ̀síbẹ̀, 11 bí ẹ̀yin pẹ̀lú ti ń fi àdúrà yín ràn wá lọ́wọ́. Àti pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóò dúpẹ́ nítorí wa fún oore-ọ̀fẹ́ ojúrere tí a rí gbà nípa ìdáhùn sí àdúrà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.