Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Orin.
87 Ó ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkè mímọ́;
2 Olúwa fẹ́ràn ẹnu-ọ̀nà Sioni
ju gbogbo ibùgbé Jakọbu lọ.
3 Ohun ológo ni a sọ nípa rẹ̀,
ìlú Ọlọ́run;
4 “Èmi ó dárúkọ Rahabu àti Babeli
láàrín àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi:
Filistia pẹ̀lú, àti Tire, pẹ̀lú Kuṣi
yóò sọ pé, ‘Èyí ni a bí ní Sioni.’ ”
5 Nítòótọ́, ti Sioni ni a ó sọ,
“Eléyìí àti eléyìí ni a bí nínú rẹ̀,
àti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ni yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀.”
6 Olúwa yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀:
“Eléyìí ni a bí ní Sioni.”
7 Àti àwọn olórin àti àwọn tí ń lu
ohun èlò orin yóò wí pé,
“Gbogbo orísun mi ń bẹ nínú rẹ.”
Ìbùkún fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run
17 “Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín,
tí ń gbé Sioni òkè mímọ́ mi.
Ìgbà náà ni Jerusalẹmu yóò jẹ́ mímọ́;
àwọn àjèjì kì yóò sì kó o mọ́.
18 “Ní ọjọ́ náà, àwọn òkè ńlá yóò máa kán ọtí wáìnì tuntun sílẹ̀,
àwọn òkè kéékèèkéé yóò máa sàn fún wàrà;
gbogbo odò Juda tí ó gbẹ́ yóò máa sàn fún omi.
Orísun kan yóò sì ṣàn jáde láti inú ilé Olúwa wá,
yóò sì rin omi sí àfonífojì Ṣittimu.
19 Ṣùgbọ́n Ejibiti yóò di ahoro,
Edomu yóò sì di aṣálẹ̀ ahoro,
nítorí ìwà ipá tí a hù sì àwọn ọmọ Juda,
ní ilẹ̀ ẹni tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.
20 Ṣùgbọ́n Juda yóò jẹ́ ibùgbé títí láé,
àti Jerusalẹmu láti ìran dé ìran.
Òwe àwọn ọmọ méjì
28 (A)“Kí ni ẹ rò nípa eléyìí? Ọkùnrin kan ti ó ní àwọn ọmọkùnrin méjì. Ó sọ fún èyí ẹ̀gbọ́n pé, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà lónìí.’
29 “Ó sì dá baba rẹ̀ lóhùn pé, ‘Èmi kò ní í lọ,’ ṣùgbọ́n níkẹyìn ó yí ọkàn padà, ó sì lọ.
30 “Nígbà náà ni baba yìí tún sọ fún èyí àbúrò pé, ‘Lọ ṣiṣẹ́ ní oko.’ Ọmọ náà sì sọ pé, ‘Èmi yóò lọ, baba,’ ṣùgbọ́n kò lọ rárá.
31 “Nínú àwọn méjèèjì yìí, èwo ni ó ṣe ìfẹ́ baba wọn?”
Gbogbo wọn sì fohùn ṣọ̀kan pé, “Èyí ẹ̀gbọ́n ni.”
Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà yóò wọ ìjọba ọ̀run síwájú yín. 32 Nítorí Johanu tọ́ yin wá láti fi ọ̀nà òdodo hàn yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbà á gbọ́, ṣùgbọ́n àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà ronúpìwàdà, bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ rí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí, ẹ kọ̀ láti ronúpìwàdà, ẹ kò gbà á gbọ́.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.