Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 87

Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Orin.

87 Ó ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkè mímọ́;
Olúwa fẹ́ràn ẹnu-ọ̀nà Sioni
    ju gbogbo ibùgbé Jakọbu lọ.

Ohun ológo ni a sọ nípa rẹ̀,
    ìlú Ọlọ́run;
“Èmi ó dárúkọ Rahabu àti Babeli
    láàrín àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi:
Filistia pẹ̀lú, àti Tire, pẹ̀lú Kuṣi
    yóò sọ pé, ‘Èyí ni a bí ní Sioni.’ ”
Nítòótọ́, ti Sioni ni a ó sọ,
    “Eléyìí àti eléyìí ni a bí nínú rẹ̀,
    àti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ni yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀.”
Olúwa yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀:
    “Eléyìí ni a bí ní Sioni.”

Àti àwọn olórin àti àwọn tí ń lu
    ohun èlò orin yóò wí pé,
    “Gbogbo orísun mi ń bẹ nínú rẹ.”

Joẹli 3:9-16

Ẹ kéde èyí ní àárín àwọn kèfèrí;
    Ẹ dira ogun,
ẹ jí àwọn alágbára,
    Jẹ kí àwọn ajagun kí wọn bẹ̀rẹ̀ ogun,
10 (A)Ẹ fi irin ìtulẹ̀ yín rọ idà,
    àti dòjé yín rọ ọ̀kọ̀.
Jẹ́ kí aláìlera wí pé,
    “Ara mi le koko.”
11 Ẹ wá kánkán, gbogbo ẹ̀yin kèfèrí láti gbogbo àyíká,
    kí ẹ sì gbá ara yín jọ yí káàkiri.

Níbẹ̀ ní kí o mú àwọn alágbára rẹ sọ̀kalẹ̀, Olúwa.

12 “Ẹ jí, ẹ sì gòkè wá sí Àfonífojì
    Jehoṣafati ẹ̀yin kèfèrí:
nítorí níbẹ̀ ní èmi yóò jókòó láti ṣe
    ìdájọ́ àwọn kèfèrí yí káàkiri.
13 Ẹ tẹ dòjé bọ̀ ọ́,
    nítorí ìkórè pọ́n:
ẹ wá, ẹ sọ̀kalẹ̀;
    nítorí ìfúntí kún, nítorí àwọn
    ọpọ́n kún àkúnwọ́sílẹ̀
nítorí ìwà búburú wọn pọ̀!”

14 Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀
    ní àfonífojì ìpinnu,
nítorí ọjọ́ Olúwa kù si dẹ̀dẹ̀
    ní àfonífojì ìdájọ́.
15 Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣú òkùnkùn,
    àti àwọn ìràwọ̀ kí yóò tan ìmọ́lẹ̀ wọn mọ́.
16 Olúwa yóò sí ké ramúramù láti Sioni wá,
    yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jerusalẹmu wá;
    àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtì
Ṣùgbọ́n Olúwa yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀,
    àti agbára àwọn ọmọ Israẹli.

1 Peteru 5:1-11

Sí àwọn alàgbà àti àwọn ọ̀dọ́kùnrin

Àwọn alàgbà tí ń bẹ láàrín yín ni mo gbànímọ̀ràn, èmi ẹni tí ń ṣe alàgbà bí ẹ̀yin, àti ẹlẹ́rìí ìyà Kristi, àti alábápín nínú ògo tí a ó fihàn: Ẹ máa tọ́jú agbo Ọlọ́run tí ń bẹ láàrín yín, ẹ máa bojútó o, kì í ṣe àfipáṣe, bí kò ṣe tìfẹ́tìfẹ́; kó má sì jẹ́ fún èrè ìjẹkújẹ, bí kò ṣe pẹ̀lú ìpinnu tí ó múra tan. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe bí ẹni tí ń lo agbára lórí ìjọ, ṣùgbọ́n kí ẹ ṣe ara yín ní àpẹẹrẹ fún agbo. Nígbà tí olórí Olùṣọ́-àgùntàn bá sì fi ara hàn, ẹ̀yin ó gba adé ògo ti kì í sá.

(A)Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ tẹríba fún àwọn alàgbà. Àní, gbogbo yín ẹ máa tẹríba fún ara yín kí ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ wọ ara yín ní aṣọ: nítorí,

“Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga,
    ṣùgbọ́n ó ń fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”

Nítorí náà, ẹ rẹ ara yin sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run, kí òun lè gbe yín ga lákokò. (B)Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lé e; nítorí tí òun ń ṣe ìtọ́jú yín.

Ẹ máa wà ni àìrékọjá, ẹ máa ṣọ́ra; nítorí èṣù ọ̀tá yín, bí i kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń rìn káàkiri, ó ń wa ẹni tí yóò pajẹ. Ẹ kọ ojú ìjà sí i pẹ̀lú ìdúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé ìyà kan náà ni àwọn ará yín tí ń bẹ nínú ayé ń jẹ.

10 Ọlọ́run oore-ọ̀fẹ́ gbogbo, tí ó ti pè yín sínú ògo rẹ̀ tí kò nípẹ̀kun nínú Kristi Jesu, nígbà tí ẹ̀yin bá ti jìyà díẹ̀, òun tìkára rẹ̀, yóò sì ṣe yín ní àṣepé, yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóò fún yín lágbára, yóò fi ìdí yín kalẹ̀. 11 Tìrẹ ni ògo àti agbára títí láé. Àmín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.