Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 65

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Orin.

65 Ìyìn ń dúró dè ọ́, Ọlọ́run, ní Sioni;
    sí ọ ni a ó mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.
Ìwọ tí ó ń gbọ́ àdúrà,
    gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ.
Ọ̀ràn àìṣedéédéé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni!
    Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò.
Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàn
    tí o mú wa láti máa gbé àgọ́ rẹ!
A tẹ́ wá lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere inú ilé rẹ,
    ti tẹmpili mímọ́ rẹ.

Ìwọ dá wa lóhùn pẹ̀lú ohun ìyanu ti òdodo,
    Ọlọ́run olùgbàlà wa,
ẹni tí ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo òpin ayé
    àti àwọn tí ó jìnnà nínú Òkun,
Ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára rẹ,
    tí odi ara rẹ ní àmùrè agbára
Ẹni tí ó mú rírú omi Òkun dákẹ́
    ríru ariwo omi wọn,
    àti ìdágìrì àwọn ènìyàn
Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù,
    nítorí ààmì rẹ wọ̀n-ọn-nì;
    ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ́ yọ̀,
    ìwọ pè fún orin ayọ̀.

Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin;
    ìwọ mú un ọ̀rọ̀ púpọ̀.
Odò Ọlọ́run kún fún omi
    láti pèsè ọkà fún àwọn ènìyàn,
nítorí ibẹ̀ ni ìwọ ti yàn án.
10 Ìwọ fi bomirin sí aporo rẹ̀
    ìwọ tẹ́ ògúlùtu rẹ̀;
ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ rẹ̀ rọ̀,
    o sì bùkún ọ̀gbìn rẹ̀.
11 Ìwọ fi oore rẹ dé ọdún ní adé,
    ọ̀rá ń kán ní ipa ọ̀nà rẹ
12 Pápá tútù ní aginjù ń kan
    àwọn òkè kéékèèkéé fi ayọ̀ di ara wọn ní àmùrè.
13 Agbo ẹran ni a fi wọ pápá tútù náà ní aṣọ;
    Àfonífojì ni a fi ọkà bò mọ́lẹ̀,
    wọ́n hó fún ayọ̀, wọ́n ń kọrin pẹ̀lú.

Joẹli 2:12-22

Fa ọkàn rẹ ya

12 “Ǹjẹ́ nítorí náà nísinsin yìí,” ni Olúwa wí,
    “Ẹ fi gbogbo ọkàn yín yípadà sí mi,
    àti pẹ̀lú àwẹ̀, àti pẹ̀lú ẹkún, àti pẹ̀lú ọ̀fọ̀.”

13 Ẹ sì fa ọkàn yín ya,
    kì í sì í ṣe aṣọ yín,
ẹ sì yípadà sí Olúwa Ọlọ́run yín,
    nítorí tí o pọ̀ ní oore-ọ̀fẹ́,
ó sì kún fun àánú, ó lọ́ra láti bínú,
    ó sì ṣeun púpọ̀, ó sì ronúpìwàdà láti ṣe búburú.
14 Ta ni ó mọ̀ bí òun yóò yípadà, kí o sì ronúpìwàdà,
    kí ó sì fi ìbùkún sílẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀—
àní ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu
    fún Olúwa Ọlọ́run yín?

15 Ẹ fún ìpè ní Sioni,
    ẹ ya àwẹ̀ kan sí mímọ́,
    ẹ pe àjọ tí ó ni ìrònú.
16 Ẹ kó àwọn ènìyàn jọ,
    ẹ ya ìjọ sí mímọ́;
ẹ pe àwọn àgbàgbà jọ,
    ẹ kó àwọn ọmọdé jọ,
    àti àwọn tí ń mú ọmú:
jẹ kí ọkọ ìyàwó kúrò nínú ìyẹ̀wù rẹ̀.
    Kí ìyàwó sì kúrò nínú iyàrá rẹ̀
17 Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ Olúwa,
    sọkún láàrín ìloro àti pẹpẹ.
Sí jẹ́ kí wọn wí pé, “Dá àwọn ènìyàn rẹ sí, Olúwa.
    Má sì ṣe fi ìní rẹ fun ẹ̀gàn,
    tí yóò sì di òwe ní àárín àwọn kèfèrí.
Èéṣe tí wọn yóò fi wí láàrín àwọn ènìyàn pé,
    ‘Ọlọ́run wọn ha da?’ ”
18 Nígbà náà ní Olúwa yóò jowú fún ilẹ̀ rẹ̀,
    yóò sì káàánú fún ènìyàn rẹ̀.

19 Nítòótọ́, Olúwa yóò dá wọn lóhùn:

“Yóò sì wí fun àwọn ènìyàn rẹ̀ pé,
    Wò ó èmi yóò rán ọkà, àti ọtí wáìnì tuntun,
àti òróró sí i yín, a ó sì fi wọn tẹ́ yín lọ́rùn:
    èmi kì yóò sì fi yín ṣe ẹ̀gàn mọ́ láàrín àwọn aláìkọlà.

20 “Ṣùgbọ́n èmi yóò lé ogun àríwá jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ yín,
    èmi yóò sì lé e lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣá, tí ó sì di ahoro,
pẹ̀lú ojú rẹ̀ sí Òkun ìlà-oòrùn,
    àti ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìwọ̀-oòrùn Òkun.
Òórùn rẹ̀ yóò sì gòkè,
    òórùn búburú rẹ̀ yóò sì gòkè.”

Nítòótọ́ ó ti ṣe ohun ńlá.
21     Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀;
    jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn kí o sì yọ̀,
nítorí Olúwa ti ṣe ohun ńlá,
22     Ẹ má bẹ̀rù, ẹranko igbó,
    nítorí pápá oko aginjù ń rú,
nítorí igi ń so èso rẹ̀, igi ọ̀pọ̀tọ́
    àti àjàrà ń so èso ọ̀rọ̀ wọn.

Luku 1:46-55

Orin Maria

46 Maria sì dáhùn, ó ní:

“Ọkàn mi yin Olúwa lógo,

47     Ẹ̀mí mi sì yọ̀ sí Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
48 Nítorí tí ó ṣíjú wo ìwà ìrẹ̀lẹ̀
    ọmọbìnrin ọ̀dọ̀ rẹ̀: Sá wò ó.
Láti ìsinsin yìí lọ gbogbo ìran ènìyàn ni yóò máa pè mí ní alábùkún fún.
49     Nítorí ẹni tí ó ní agbára ti ṣe ohun tí ó tóbi fún mi;
    Mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀.
50 Àánú rẹ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀
    láti ìrandíran.
51 Ó ti fi agbára hàn ní apá rẹ̀;
    o ti tú àwọn onígbèéraga ká ní ìrònú ọkàn wọn.
52 Ó ti mú àwọn alágbára kúrò lórí ìtẹ́ wọn,
    o sì gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ lékè.
53 Ó ti fi ohun tí ó dára kún àwọn tí ebi ń pa
    ó sì rán àwọn ọlọ́rọ̀ padà ní òfo.
54 Ó ti ran Israẹli ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́,
    Ní ìrántí àánú rẹ̀;
55 (A)sí Abrahamu àti àwọn ìran rẹ̀ láéláé, baba wa,
    àti bí ó ti sọ fún àwọn baba wa.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.