Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Orin.
65 Ìyìn ń dúró dè ọ́, Ọlọ́run, ní Sioni;
sí ọ ni a ó mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.
2 Ìwọ tí ó ń gbọ́ àdúrà,
gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ.
3 Ọ̀ràn àìṣedéédéé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni!
Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò.
4 Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàn
tí o mú wa láti máa gbé àgọ́ rẹ!
A tẹ́ wá lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere inú ilé rẹ,
ti tẹmpili mímọ́ rẹ.
5 Ìwọ dá wa lóhùn pẹ̀lú ohun ìyanu ti òdodo,
Ọlọ́run olùgbàlà wa,
ẹni tí ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo òpin ayé
àti àwọn tí ó jìnnà nínú Òkun,
6 Ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára rẹ,
tí odi ara rẹ ní àmùrè agbára
7 Ẹni tí ó mú rírú omi Òkun dákẹ́
ríru ariwo omi wọn,
àti ìdágìrì àwọn ènìyàn
8 Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù,
nítorí ààmì rẹ wọ̀n-ọn-nì;
ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ́ yọ̀,
ìwọ pè fún orin ayọ̀.
9 Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin;
ìwọ mú un ọ̀rọ̀ púpọ̀.
Odò Ọlọ́run kún fún omi
láti pèsè ọkà fún àwọn ènìyàn,
nítorí ibẹ̀ ni ìwọ ti yàn án.
10 Ìwọ fi bomirin sí aporo rẹ̀
ìwọ tẹ́ ògúlùtu rẹ̀;
ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ rẹ̀ rọ̀,
o sì bùkún ọ̀gbìn rẹ̀.
11 Ìwọ fi oore rẹ dé ọdún ní adé,
ọ̀rá ń kán ní ipa ọ̀nà rẹ
12 Pápá tútù ní aginjù ń kan
àwọn òkè kéékèèkéé fi ayọ̀ di ara wọn ní àmùrè.
13 Agbo ẹran ni a fi wọ pápá tútù náà ní aṣọ;
Àfonífojì ni a fi ọkà bò mọ́lẹ̀,
wọ́n hó fún ayọ̀, wọ́n ń kọrin pẹ̀lú.
Àwọn jagunjagun eṣú
2 Ẹ fun ìpè ní Sioni,
ẹ sì fún ìpè ìdágìrì ní òkè mímọ́ mi.
Jẹ́ kí àwọn ará ilẹ̀ náà wárìrì,
nítorí tí ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ wá,
nítorí ó kù sí dẹ̀dẹ̀.
2 Ọjọ́ òkùnkùn àti ìrọ́kẹ̀kẹ̀,
ọjọ́ ìkùùkuu àti òkùnkùn biribiri,
Bí ọyẹ́ òwúrọ̀ ti í la bo orí àwọn òkè ńlá:
àwọn ènìyàn ńlá àti alágbára; ya dé,
ti kó ti ì sí irú rẹ̀ rí,
bẹ́ẹ̀ ni irú rẹ̀ kì yóò sí mọ́ lẹ́yìn rẹ̀, títí dé ọdún ìran dé ìran.
3 Iná ń jó níwájú wọ́n;
ọwọ́ iná sì ń jó lẹ́yìn wọn:
Ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Edeni níwájú wọn,
àti lẹ́yìn wọn bí ahoro ijù;
nítòótọ́, kò sì sí ohun tí yóò bọ́ lọ́wọ́ wọn.
4 (A)Ìrí wọn dàbí ìrí àwọn ẹṣin;
wọ́n ń sáré lọ bí àwọn ẹlẹ́ṣin ogun
5 Bí ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ni
wọn ń fo ní orí òkè
bí ariwo ọ̀wọ́-iná tí ń jó koríko gbígbẹ,
bí akọni ènìyàn tí a kójọ fún ogun.
6 Ní ojú wọn, àwọn ènìyàn yóò jẹ ìrora púpọ̀:
gbogbo ojú ní yóò ṣú dudu.
7 Wọn yóò sáré bi àwọn alágbára;
wọn yóò gùn odi bí ọkùnrin ológun;
olúkúlùkù wọn yóò sì rìn lọ ní ọ̀nà rẹ̀,
wọn kì yóò sì yà kúrò ni ọ̀nà wọn.
8 Bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò kọlu ẹnìkejì rẹ̀;
olúkúlùkù wọn yóò rìn ní ọ̀nà rẹ̀:
nígbà tí wọn bá sì ṣubú lù idà
wọn kì yóò gbọgbẹ́.
9 Wọn yóò sáré síwá sẹ́yìn ní ìlú;
wọn yóò súré lórí odi,
wọn yóò gùn orí ilé;
wọn yóò gbà ojú fèrèsé wọ̀ inú ilé bí olè.
10 (B)Ayé yóò mì níwájú wọn;
àwọn ọ̀run yóò wárìrì;
oòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn,
àwọn ìràwọ̀ yóò sì fà ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn.
11 (C)Olúwa yóò sì bú ramúramù
jáde níwájú ogun rẹ̀:
nítorí ibùdó rẹ̀ tóbi gidigidi;
nítorí alágbára ní òun, tí n mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ;
nítorí ọjọ́ Olúwa tóbi ó sì ní ẹ̀rù gidigidi;
ara ta ni ó lè gbà á?
Ọ̀rọ̀ ìyànjú Paulu sí Timotiu
10 Ṣùgbọ́n ìwọ ti mọ ẹ̀kọ́ mi, ìgbésí ayé mi, ìpinnu, ìgbàgbọ́, ìpamọ́ra, ìfẹ́ sùúrù. 11 (A)Inúnibíni, ìyà; àwọn ohun tí ó dé bá mi ní Antioku, ní Ikoniomu ní Lysra; àwọn inúnibíni tí mo faradà: Olúwa sì gbà mi kúrò nínú gbogbo wọn. 12 Nítòótọ́, gbogbo àwọn tí ó fẹ́ máa gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run nínú Kristi Jesu yóò faradà inúnibíni 13 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú, àti àwọn ẹlẹ́tàn yóò máa burú síwájú sí i, wọn ó máa tannijẹ, a ó sì máa tàn wọ́n jẹ. 14 Ṣùgbọ́n ìwọ dúró nínú nǹkan wọ̀nyí tí ìwọ ti kọ́, tí a sì ti jẹ́ kí ojú rẹ dá ṣáṣá sí, kí ìwọ sì mọ̀ ọ̀dọ̀ ẹni tí ìwọ gbé kọ́ wọn. 15 Àti pé láti ìgbà ọmọdé ni ìwọ ti mọ Ìwé Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n sí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.