Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 65

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Orin.

65 Ìyìn ń dúró dè ọ́, Ọlọ́run, ní Sioni;
    sí ọ ni a ó mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.
Ìwọ tí ó ń gbọ́ àdúrà,
    gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ.
Ọ̀ràn àìṣedéédéé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni!
    Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò.
Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàn
    tí o mú wa láti máa gbé àgọ́ rẹ!
A tẹ́ wá lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere inú ilé rẹ,
    ti tẹmpili mímọ́ rẹ.

Ìwọ dá wa lóhùn pẹ̀lú ohun ìyanu ti òdodo,
    Ọlọ́run olùgbàlà wa,
ẹni tí ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo òpin ayé
    àti àwọn tí ó jìnnà nínú Òkun,
Ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára rẹ,
    tí odi ara rẹ ní àmùrè agbára
Ẹni tí ó mú rírú omi Òkun dákẹ́
    ríru ariwo omi wọn,
    àti ìdágìrì àwọn ènìyàn
Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù,
    nítorí ààmì rẹ wọ̀n-ọn-nì;
    ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ́ yọ̀,
    ìwọ pè fún orin ayọ̀.

Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin;
    ìwọ mú un ọ̀rọ̀ púpọ̀.
Odò Ọlọ́run kún fún omi
    láti pèsè ọkà fún àwọn ènìyàn,
nítorí ibẹ̀ ni ìwọ ti yàn án.
10 Ìwọ fi bomirin sí aporo rẹ̀
    ìwọ tẹ́ ògúlùtu rẹ̀;
ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ rẹ̀ rọ̀,
    o sì bùkún ọ̀gbìn rẹ̀.
11 Ìwọ fi oore rẹ dé ọdún ní adé,
    ọ̀rá ń kán ní ipa ọ̀nà rẹ
12 Pápá tútù ní aginjù ń kan
    àwọn òkè kéékèèkéé fi ayọ̀ di ara wọn ní àmùrè.
13 Agbo ẹran ni a fi wọ pápá tútù náà ní aṣọ;
    Àfonífojì ni a fi ọkà bò mọ́lẹ̀,
    wọ́n hó fún ayọ̀, wọ́n ń kọrin pẹ̀lú.

Joẹli 1

Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Joẹli ọmọ Petueli wá.

Ìṣígun Eṣú

Ẹ gbọ́ èyí ẹ̀yin àgbàgbà;
    ẹ fi etí sílẹ̀ gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ará ilẹ̀ náà.
Ǹjẹ́ irú èyí ha wà ní ọjọ́ yín,
    tàbí ní ọjọ́ àwọn baba yín?
Ẹ sọ ọ́ fún àwọn ọmọ yín,
    ki àwọn ọmọ yín sọ fún àwọn ọmọ wọn,
    ki àwọn ọmọ wọn sọ fún àwọn ìran mìíràn.
Èyí tí eṣú tí agénijẹ jẹ kù
    ní ọ̀wọ́ eṣú ńláńlá ti jẹ,
èyí tí ọ̀wọ́ eṣú ńláńlá jẹ kù
    ní eṣú kéékèèkéé jẹ
Èyí tí eṣú kéékèèkéé jẹ kù
    ni eṣú apanirun mìíràn jẹ.

Ẹ jí gbogbo ẹ̀yin ọ̀mùtí kí ẹ sì sọkún
    ẹ hu gbogbo ẹ̀yin ọ̀mu-wáìnì;
ẹ hu nítorí wáìnì tuntun
    nítorí a gbà á kúrò lẹ́nu yín.
(A)Nítorí orílẹ̀-èdè kan ti ṣígun sí ilẹ̀ mìíràn
    ó ní agbára púpọ̀, kò sì ní òǹkà;
ó ní eyín kìnnìún
    ó sì ní èrìgì abo kìnnìún.
Ó ti pa àjàrà mi run,
    ó sì ti ya ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi kúrò,
ó ti bò èèpo rẹ̀ jálẹ̀, ó sì sọ ọ́ nù;
    àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ni a sì sọ di funfun.

Ẹ pohùnréré ẹkún bí wúńdíá
    tí a fi aṣọ ọ̀fọ̀ dí ni àmùrè, nítorí ọkọ ìgbà èwe rẹ̀.
A ké ọrẹ jíjẹ́ àti ọrẹ mímu kúrò
    ní ilé Olúwa;
àwọn àlùfáà ń ṣọ̀fọ̀, àwọn
    ìránṣẹ́ Olúwa,
10 Oko di ìgboro, ilẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀,
    nítorí a fi ọkà ṣòfò:
    ọtí wáìnì tuntun gbẹ, òróró ń bùṣe.

11 Kí ojú kí ó tì yín, ẹ̀yin àgbẹ̀;
    ẹ pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùtọ́jú àjàrà,
nítorí alikama àti nítorí ọkà barle;
    nítorí ìkórè oko ṣègbé.
12 Àjàrà gbẹ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì rọ̀ dànù;
    igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ pẹ̀lú,
àti igi apiili, gbogbo igi igbó ni o rọ:
    Nítorí náà ayọ̀ ọmọ ènìyàn gbẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.

Ìpè fún ìrònúpìwàdà

13 Ẹ di ara yín ni àmùrè,
    sí pohùnréré ẹkún ẹ̀yin àlùfáà:
ẹ pohùnréré ẹkún, ẹ̀yin ìránṣẹ́ pẹpẹ:
    ẹ wá, fi gbogbo òru dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀,
ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run mi: nítorí tí a dá ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ
    mímu dúró ní ilé Ọlọ́run yín.
14 Ẹ yà àwẹ̀ kan sí mímọ́,
    ẹ pe àjọ kan tí o ní ìrònú,
ẹ pe àwọn àgbàgbà,
    àti gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà
jọ sí ilé Olúwa Ọlọ́run yín,
    kí ẹ sí ké pe Olúwa.

15 A! Fún ọjọ́ náà,
    nítorí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀,
    yóò de bí ìparun láti ọwọ́ Olódùmarè.

16 A kò ha ké oúnjẹ kúrò níwájú
    ojú wá yìí,
ayọ̀ àti inú dídùn kúrò nínú ilé
    Ọlọ́run wá?
17 Irúgbìn bàjẹ́ nínú ebè wọn,
    a sọ àká di ahoro, a wó àká palẹ̀;
    nítorí tí a mú ọkà rọ.
18 Àwọn ẹranko tí ń kérora tó!
    Àwọn agbo ẹran dààmú,
nítorí tí wọ́n kò ni pápá oko;
    nítòótọ́, àwọn agbo àgùntàn jìyà.

19 Olúwa, sí ọ ni èmi o ké pè,
    nítorí iná tí run pápá oko tútù aginjù,
    ọwọ́ iná sí ti jó gbogbo igi igbó.
20 Àwọn ẹranko igbó gbé ojú sókè sí ọ pẹ̀lú:
    nítorí tí àwọn ìṣàn omi gbẹ,
    iná sí ti jó àwọn pápá oko aginjù run.

2 Timotiu 3:1-9

Ìwà àwọn ènìyàn ni ọjọ́ ìkẹyìn

Ṣùgbọ́n èyí ni kí o mọ̀: pé ní ìkẹyìn ọjọ́ ìgbà ewu yóò dé. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, olùfẹ́ owó, afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìmọ́. Aláìnífẹ̀ẹ́, aláìlèdáríjì, abanijẹ́, aláìlè-kó-aràwọn-níjánu, òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere, oníkúpani, alágídí, ọlọ́kàn gíga, olùfẹ́ fàájì ju olùfẹ́ Ọlọ́run lọ. Àwọn tí wọn ní àfarawé ìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọn sẹ́ agbára rẹ̀; yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.

Nítorí nínú irú èyí ni àwọn ti ń rákò wọ inú ilé, tí wọ́n sì ń di àwọn obìnrin aláìlọ́gbọ́n tí a di ẹ̀ṣẹ̀ rù ní ìgbèkùn, tí a sì ń fi onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ fà kiri Wọ́n ń fi ìgbà gbogbo kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n kò sì lè dé ojú ìmọ̀ òtítọ́. (A)Ǹjẹ́ gẹ́gẹ́ bí Janesi àti Jamberi ti kọ ojú ìjà sí Mose náà ni wọ́n kọjú ìjà sí òtítọ́: àwọn ènìyàn tí inú wọn díbàjẹ́, àwọn ẹni ìtanù ní ti ọ̀ràn ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n wọn kì yóò lọ síwájú ju bẹ́ẹ̀ lọ: Nítorí òmùgọ̀ wọn yóò farahàn fún gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ti àwọn méjì yìí náà, ti yọrí si.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.