Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 129

Orin fún ìgòkè.

129 “Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú
    láti ìgbà èwe mi wá”
    ni kí Israẹli kí ó wí nísinsin yìí;
“Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú
    láti ìgbà èwe mi wá;
    síbẹ̀ wọn kò tí ì borí mi.
Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi:
    wọ́n sì la aporo wọn gígùn.
Olódodo ni Olúwa:
    ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.”

Kí gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni kí ó dààmú,
    kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà.
Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀
    tí ó gbẹ dànù kí ó tó dàgbàsókè:
Èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ rẹ̀:
    bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń di ìtí, kó kún apá rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kò wí pé,
    ìbùkún Olúwa kí ó pẹ̀lú yín:
    àwa ń súre fún yin ní orúkọ Olúwa.

Jeremiah 50:1-7

Àsọtẹ́lẹ̀ ní ti Babeli

50 (A)Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fi sẹ́nu wòlíì Jeremiah láti sọ fún ará ilẹ̀ Babeli:

“Ẹ sọ ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ sì kéde,
    kí ẹ sì gbé àsíá sókè, ẹ kéde rẹ̀
    ẹ má sì ṣe bò ó, wí pé,
‘a kó Babeli,
    ojú tí Beli,
    a fọ́ Merodaki túútúú,
ojú ti àwọn ère rẹ̀,
    a fọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀ túútúú.’
Àwọn ìlú ní apá àríwá yóò
    sì máa gbóguntì wọ́n.
Gbogbo àwọn ènìyàn àti ẹranko ni yóò
    sá kúrò ní ìlú yìí.

“Ní ọjọ́ wọ̀nyí àti ní àkókò náà,”
    ni Olúwa wí,
“Àwọn ọmọ Israẹli yóò jùmọ̀ wá,
àwọn, àti àwọn ọmọ Juda,
    wọn yóò lọ pẹ̀lú ẹkún láti ṣàfẹ́rí
    Olúwa Ọlọ́run wọn
Wọn ó máa béèrè ọ̀nà Sioni, ojú wọn
    yóò sì yí síhà ibẹ̀, wí pé ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a
darapọ̀ mọ́ Olúwa ní májẹ̀mú ayérayé,
    tí a kì yóò gbàgbé.

“Àwọn ènìyàn mi ti jẹ́ àgùntàn tí ó sọnù,
    àwọn olùṣọ́-àgùntàn wọn ti jẹ́ kí wọn ṣìnà,
wọ́n ti jẹ́ kí wọn rìn lórí òkè
    wọ́n ti lọ láti orí òkè ńlá dé òkè kékeré,
    wọn ti gbàgbé ibùsùn wọn.
Gbogbo àwọn tí ó rí wọn, ti pa wọ́n jẹ
    àwọn ọ̀tá wọ́n sì wí pé, ‘Àwa kò jẹ̀bi
nítorí pé wọ́n ti ṣẹ̀ sí Olúwa ibùgbé
    òdodo àti ìrètí àwọn baba wọn.’

Jeremiah 50:17-20

17 “Israẹli jẹ́ àgùntàn tí ó ṣìnà kiri,
    kìnnìún sì ti lé e lọ.
Níṣàájú ọba Asiria pa á jẹ,
    àti níkẹyìn yìí Nebukadnessari ọba Babeli
    fa egungun rẹ̀ ya.”

18 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára, Ọlọ́run Israẹli wí;

“Ǹ ó fi ìyà jẹ ọba Babeli àti ilẹ̀ rẹ̀
    gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fìyà jẹ ọba, Asiria.
19 Ṣùgbọ́n, èmi yóò mú Israẹli
    padà wá pápá oko tútù rẹ̀
òun yóò sì máa bọ́ ara rẹ̀ lórí Karmeli àti Baṣani,
    a ó sì tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ní òkè
    Efraimu àti ní Gileadi
20 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,”
    ni Olúwa wí,
“À ó wá àìṣedéédéé ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli,
ṣùgbọ́n a ki yóò rí ohun;
    àti ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a ki yóò sì rí mọ kankan
    nítorí èmi yóò dáríjì àwọn tí ó ṣẹ́kù tí mo dá sí.

Luku 22:39-46

Jesu gbàdúrà lórí òkè olifi

39 (A)Ó sì jáde, ó sì lọ bí ìṣe rẹ̀ sí òkè olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 40 (B)(C)Nígbà tí ó wà níbẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwò.” 41 Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níwọ̀n ìsọ-òkò kan, ó sì kúnlẹ̀ ó sì ń gbàdúrà. 42 (D)Wí pé, “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, mu ago yìí kúrò lọ́dọ́ mi: ṣùgbọ́n ìfẹ́ ti èmi kọ́, bí kò ṣe tìrẹ ni kí à ṣe.” 43 Angẹli kan sì yọ sí i láti ọ̀run wá, ó ń gbà á ní ìyànjú. 44 Bí ó sì ti wà nínú gbígbóná ara ó ń gbàdúrà sí i kíkankíkan; òógùn rẹ̀ sì dàbí ìró ẹ̀jẹ̀ ńlá, ó ń kán sílẹ̀.

45 Nígbà tí ó sì dìde kúrò ní ibi àdúrà, tí ó sì tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó bá wọn, wọ́n ń sùn nítorí ìbànújẹ́ ti mu kí ó rẹ̀ wọ́n. 46 Ó sì wí fún wọn pé, “Kí ni ẹ̀ yin ń sùn sí? Ẹ dìde, ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwò.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.