Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
137 Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó
àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni.
2 Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílò,
tí ó wà láàrín rẹ̀.
3 Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn
tí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa,
àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá wí pé;
ẹ kọ orin Sioni kan fún wa.
4 Àwa ó ti ṣe kọ orin
Olúwa ní ilẹ̀ àjèjì
5 Jerusalẹmu, bí èmi bá gbàgbé rẹ
jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò rẹ̀.
6 Bí èmi kò bá rántí rẹ,
jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi;
bí èmi kò bá fi Jerusalẹmu ṣáájú
olórí ayọ̀ mi gbogbo.
7 Olúwa rántí ọjọ́ Jerusalẹmu,
lára àwọn ọmọ Edomu,
àwọn ẹni tí ń wí pé,
“Wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”
8 Ìwọ, ọmọbìnrin Babeli, ẹni tí a ó parun;
ìbùkún ni fún ẹni tí ó san án fún ọ
bí ìwọ ti rò sí wa.
9 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó mú ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ
tí ó sì fi wọ́n ṣán òkúta.
5 Rántí, Olúwa, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa;
wò ó, kí o sì rí ìtìjú wa.
2 Àwọn ohun ìní wa ti di ti àlejò,
ilé wa ti di ti àjèjì.
3 Àwa ti di aláìní òbí àti aláìní baba,
àwọn ìyá wa ti di opó.
4 A gbọdọ̀ ra omi tí à ń mu;
igi wa di títà fún wa.
5 Àwọn tí ó ń lé wa súnmọ́ wa;
àárẹ̀ mú wa àwa kò sì rí ìsinmi.
6 Àwa jọ̀wọ́ ara wa fún Ejibiti àti Asiria
láti rí oúnjẹ tó tó jẹ.
7 Àwọn baba wa ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣí mọ́,
àwa sì ń ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
8 Àwọn ẹrú ń jẹ ọba lórí wa,
kò sì ṣí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ wọn.
9 Àwa ń rí oúnjẹ wa nínú ewu ẹ̀mí wa
nítorí idà tí ó wà ní aginjù.
10 Ẹran-ara wa gbóná bí ààrò,
ebi sì yó wa bí àárẹ̀.
11 Wọ́n ti fipá bá àwọn obìnrin wa lòpọ̀ ní Sioni,
àti àwọn wúńdíá ti o wa ní ìlú Juda.
12 Àwọn ọmọ ọbakùnrin ti di síso sókè ní ọwọ́ wọn;
kò sí ìbọ̀wọ̀ fún àgbàgbà mọ́.
13 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wa ru òkúta;
àwọn ọmọkùnrin sì ń ṣàárẹ̀ lábẹ́ ẹrù igi.
14 Àwọn àgbàgbà ti lọ kúrò ní ẹnu-bodè ìlú;
àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì dákẹ́ orin wọn
15 Ayọ̀ ti ṣáko ní ọkàn wa;
ọ̀fọ̀ sì ti dúró bí ijó fún wa.
16 Adé ti ṣí kúrò ní orí wa
ègbé ni fún wa, nítorí a ti ṣẹ̀.
17 Nítorí èyí, àárẹ̀ mú ọkàn wa,
nítorí èyí, ojú wa sì ṣú.
18 Fún òkè Sioni tí ó ti di ahoro
lórí rẹ̀ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì ń rìn kiri.
19 Ìwọ, Olúwa, jẹ ọba títí láé;
ìjọba rẹ dúró láti ìran kan dé ìran mìíràn.
20 Kí ló dé tí o ń gbàgbé wa ní gbogbo ìgbà?
Kí ló dé tí o fi kọ̀ wá sílẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́?
21 Mú wa padà sí ọ̀dọ̀ rẹ, Olúwa, kí àwa kí ó le padà;
mú ọjọ́ wa di tuntun bí ìgbàanì
22 Àyàfi tí o bá ti kọ̀ wá sílẹ̀ pátápátá
tí ìbínú rẹ sí wa sì kọjá ìwọ̀n.
Jesu palẹ̀ tẹmpili mọ́
12 (A)Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti kúrò ní Betani, ebi ń pa Jesu. 13 Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lọ́ọ̀ọ́kán tí ewé kún orí rẹ̀. Nígbà náà, ó lọ sí ìdí rẹ̀ láti wò ó bóyá ó léso tàbí kò léso. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ewé lásán ni ó rí, kò rí èso lórí rẹ̀. Nítorí pé àkókò náà kì í ṣe àkókò tí igi ọ̀pọ̀tọ́ máa ń so. 14 Lẹ́yìn náà, Jesu pàṣẹ fún igi náà pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ èso lórí rẹ mọ́ títí láé.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ nígbà tí ó wí bẹ́ẹ̀.
Igi ọ̀pọ̀tọ́ tí kò ní eṣo
20 (A)Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí Jesu fi bú. Wọ́n rí i pé ó ti gbẹ tigbòǹgbò tigbòǹgbò. 21 Peteru rántí pé Jesu ti bá igi náà wí. Nígbà náà ni ó sọ fún Jesu pé, “Rabbi, Wò ó! Igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ìwọ fi bú ti gbẹ!”
22 Jesu sì dáhùn pé, “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, 23 Lóòótọ́ ni mò wí fún un yín, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè ‘ṣídìí, gbé ara rẹ sọ sínú Òkun’ ti kò sì ṣe iyèméjì nínú ọkàn rẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó gbàgbọ́ pé ohun tí òun wí yóò ṣẹ, yóò rí bẹ́ẹ̀ fún un. 24 (B)Torí náà, mo wí fún yín ohunkóhun tí ẹ bá béèrè fún nínú àdúrà, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé, ó tí tẹ̀ yín lọ́wọ́, yóò sì jẹ́ tiyín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.