Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.
139 Olúwa, ìwọ tí wádìí mi,
ìwọ sì ti mọ̀ mí.
2 Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi,
ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.
3 Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi,
gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ.
4 Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi,
kíyèsi i, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.
5 Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú,
ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi.
6 Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù;
ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n.
13 Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi;
ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.
14 Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi;
ìyanu ní iṣẹ́ rẹ;
èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú
15 Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀.
Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
16 ojú rẹ ti rí ohun ara mi
nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé:
àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí,
ní ọjọ́ tí a dá wọn,
nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.
17 Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi,
iye wọn ti pọ̀ tó!
18 Èmi ìbá kà wọ́n,
wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye:
nígbà tí mo bá jí,
èmi yóò wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀.
14 “Nítorí náà, ọjọ́ náà ń bọ̀ wá,” ni Olúwa wí, “tí àwọn ènìyàn kò ní sọ pé, ‘Dájúdájú Olúwa wà láààyè Olúwa ń bẹ Ẹni tí ó mú Israẹli jáde kúrò ní Ejibiti.’ 15 Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Bí Olúwa ṣe wà nítòótọ́ tí ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá àti ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó ti lé wọn.’ Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò dá wọn padà sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn.
16 “Ṣùgbọ́n báyìí, Èmi yóò ránṣẹ́ sí àwọn apẹja púpọ̀,” ni Olúwa wí. “Wọn ó sì dẹ wọ́n lẹ́yìn èyí yìí èmi yóò ránṣẹ́ sí àwọn ọdẹ púpọ̀, wọn yóò dẹ wọ́n lórí gbogbo òkè ńlá àti òkè gíga, àti ní gbogbo pálapàla àpáta. 17 Ojú mi wà ní gbogbo ọ̀nà wọn, wọn kò pamọ́ fún mi bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò fi ara sin lójú mi. 18 Èmi yóò san ẹ̀san ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn ní ìlọ́po méjì, nítorí wọ́n ti ba ilẹ̀ mi jẹ́ pẹ̀lú àwọn ère wọn aláìlẹ́mìí, wọ́n sì fi òkú àti ohun ẹ̀gbin àti ìríra wọn kún ilẹ̀ ìní mi.”
19 Olúwa, alágbára àti okun mi,
ẹni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú
Háà! àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá láti
òpin ayé wí pé,
“Àwọn baba ńlá wa kò ní ohun kan bí kò ṣe ẹ̀gbin òrìṣà,
ìríra tí kò dára fún wọn nínú rẹ̀.
20 Ṣé àwọn ènìyàn lè dá Ọlọ́run
fún ara wọn bí? Bẹ́ẹ̀ ni,
ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí kì í ṣe Ọlọ́run.”
21 “Nítorí náà, Èmi yóò kọ́ wọn ní
àkókò yìí, Èmi yóò kọ́ wọn pẹ̀lú
agbára àti títóbi mi; nígbà
náà ni wọn ó mọ orúkọ mi
ní Olúwa.
17 “Ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a fi kálámù irin kọ,
èyí tí a fi ṣóńṣó òkúta adamante gbẹ́ ẹ,
sórí wàláà oókan àyà wọn,
àti sórí ìwo pẹpẹ yín.
2 Kódà àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹ
àti ère Aṣerah lẹ́bàá igi tí ó tẹ́ rẹrẹ
àti àwọn òkè gíga.
3 Àwọn òkè nínú ilẹ̀ àti àwọn ọrọ̀ rẹ̀
àti ọlá rẹ̀ ni èmi yóò fi sílẹ̀ bí ìjẹ
pẹ̀lú àwọn ibi gíga, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó
pọ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè yín.
4 Láti ipasẹ̀ àìṣedéédéé yín ni ẹ̀yin
yóò ti sọ ogún tí mo fún un yín nù.
Èmi yóò fi yín fún ọ̀tá yín
bí ẹrú ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò mọ̀; nítorí
ẹ̀yin ti mú inú bí mi, èyí tí yóò sì wà títí ayé.”
Àwọn ìkíni ìkẹyìn
7 (A)Gbogbo bí nǹkan ti rí fún mi ní Tikiku yóò jẹ́ kí ẹ mọ̀. Òun jẹ́ arákùnrin olùfẹ́ àti olóòtítọ́ ìránṣẹ́ àti ẹlẹgbẹ́ nínú Olúwa: 8 Ẹni tí èmí ń rán sí yín nítorí èyí kan náà, kí ẹ̀yin lè mọ́ bí a ti wà, kí òun kí ó lè tu ọkàn yín nínú; 9 (B)Òun sì ń bọ̀ pẹ̀lú Onesimu, arákùnrin olóòtítọ́ àti olùfẹ́, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú yín. Àwọn ní yóò sọ ohun gbogbo tí à ń ṣe níhìn-ín-yìí fún un yín.
10 (C)Aristarku, ẹlẹgbẹ́ mí nínú túbú kí i yín, àti Marku, ọmọ arábìnrin Barnaba (Nípasẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ti gba àṣẹ; bí ó bá sì wá sí ọ̀dọ̀ yín, ẹ gbà á).
11 Àti Jesu, ẹni tí à ń pè ní Justu, ẹni tí ń ṣe ti àwọn onílà. Àwọn wọ̀nyí nìkan ni olùbáṣiṣẹ́ mí fún ìjọba Ọlọ́run, àwọn ẹni tí ó tí jásí ìtùnú fún mi.
12 Epafira, ẹni tí ń ṣe ọ̀kan nínú yín àti ìránṣẹ́ Kristi Jesu kí i yín. Òun fi ìwàyáàjà gbàdúrà nígbà gbogbo fún un yín, kí ẹ̀yin kí ó lè dúró ní pípé nínú ohun gbogbo nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. 13 Nítorí mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó ń ṣiṣẹ́ kárakára fún yín, àti fún àwọn tí ó wà ní Laodikea, àti àwọn tí ó wà ní Hirapoli.
14 (D)Luku, arákùnrin wa ọ̀wọ́n, oníṣègùn, àti Dema ki í yín.
15 Ẹ kí àwọn ará tí ó wà ní Laodikea, àti Nimpa, àti ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ̀.
16 Nígbà tí a bá sì ka ìwé yìí ní àárín yín tan, kí ẹ mú kí a kà á pẹ̀lú nínú ìjọ Laodikea; ẹ̀yin pẹ̀lú sì ka èyí tí ó ti Laodikea wá.
17 Kí ẹ sì wí fún Arkippu pe, “Kíyèsi iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ìwọ ti gbà nínú Olúwa kí o sì ṣe é ní kíkún.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.